2 Kings 9 (BOYCB)

1 Wòlíì Eliṣa fi àṣẹ pe ọkùnrin kan láti ẹgbẹ́ àwọn wòlíì, ó sì wí fún un pé, “Ki agbádá rẹ sínú ọ̀já àmùrè rẹ, gba ṣágo kékeré òróró yìí pẹ̀lú rẹ, kí o sì lọ sí Ramoti Gileadi. 2 Nígbà tí o bá dé bẹ̀, wá Jehu ọmọ Jehoṣafati, ọmọ Nimṣi kiri. Lọ sí ọ̀dọ̀ ọ rẹ̀, mú un kúrò lọ́dọ̀ àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀, kí o sì mú un wọ inú yàrá lọ́hùn ún lọ. 3 Nígbà náà, mú ṣágo kékeré yìí, kí o sì da òróró náà lé e lórí, kí o sì wí pé, ‘Èyí ni ohun tí OLÚWA wí, “Èmi fi àmì òróró yàn ọ́ ní ọba lórí Israẹli.” ’ Nígbà náà, ṣí ìlẹ̀kùn, kí o sì sáré, má ṣe jáfara!” 4 Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀dọ́mọkùnrin náà, wòlíì náà lọ sí Ramoti Gileadi. 5 Nígbà tí ó dé, ó rí àwọn olórí ẹgbẹ́ ọmọ-ogun tí wọ́n jókòó papọ̀. “Èmi ní iṣẹ́ fún ọ, olórí,” Ó wí.“Sí ta ni nínú wa?” Jehu béèrè.Òun sì wí pé, “Sí ọ, balógun,” Ó dáhùn. 6 Jehu dìde sókè, ó sì wọ inú ilé lọ. Nígbà náà, wòlíì náà da òróró náà sórí Jehu; ó sì wí pé, “Èyí ni ohun tí OLÚWA Ọlọ́run Israẹli wí: ‘Èmi fi àmì òróró yàn ọ́ ní ọba lórí àwọn ènìyàn OLÚWA Israẹli. 7 Kí ìwọ kí ó pa ilé Ahabu ọ̀gá à rẹ̀ run, Èmi yóò sì gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ gbogbo àwọn ìránṣẹ́ mi wòlíì àti gbogbo ẹ̀jẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ OLÚWA tí a ta sílẹ̀ látọwọ́ ọ Jesebeli. 8 Gbogbo ilé Ahabu yóò ṣègbé. Èmi yóò gé e kúrò láti orí Ahabu gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó gbẹ̀yìn ni Israẹli, ẹrú tàbí òmìnira. 9 Èmi yóò ṣe ilé Ahabu gẹ́gẹ́ bí ilé Jeroboamu ọmọ Nebati àti ilé Baaṣa ọmọ Ahijah. 10 Fún Jesebeli, ajá ni yóò jẹ ẹ́ ní oko Jesreeli, kò sì sí ẹni tí yóò sin òkú rẹ̀.’ ” Nígbà náà ó ṣí ìlẹ̀kùn, ó sì sálọ. 11 Nígbà tí Jehu jáde lọ bá àwọn ọgbà ìjòyè e rẹ̀, ọ̀kan nínú wọn sì bi í pé, “Ṣé gbogbo nǹkan dára?”Kí ni ó dé tí aṣiwèrè fi tọ̀ ọ́ wá, “Ìwọ mọ ọkùnrin náà àti irú nǹkan tí ó ń sọ,” Jehu fèsì. 12 “Ìyẹn kì í ṣe òótọ́!” Wọ́n wí. “Sọ fún wa.”Jehu wí, “Èyí ni ohun tí ó sọ fún mi: ‘Èyí ni ohun tí OLÚWA wí, “Èmi fi àmì òróró yàn ọ́ ní ọba lórí Israẹli.” ’ ” 13 Wọ́n ṣe gírí, wọ́n sì mú agbádá a wọn, wọ́n sì tàn wọ́n sí abẹ́ rẹ̀ ní orí àtẹ̀gùn. Nígbà náà, wọ́n fọn ìpè, wọ́n sì kígbe, “Jehu jẹ ọba!” 14 Bẹ́ẹ̀ ni Jehu ọmọ Jehoṣafati, ọmọ Nimṣi, dìtẹ̀ sí Joramu. (Nísinsin yìí Joramu àti gbogbo Israẹli ti ń dáàbò bo Ramoti Gileadi nítorí Hasaeli ọba Aramu. 15 ṣùgbọ́n ọba Joramu ti padà sí Jesreeli láti lọ sàn nínú ọgbẹ́ tí àwọn ará Aramu ti dá sí i lára nínú ogun pẹ̀lú ọba Hasaeli ti Aramu.) Jehu wí pé, “Tí èyí bá jẹ́ ọ̀nà tí ò ń rò, má ṣe jẹ́ kí ẹnìkankan kí ó yọ jáde nínú ìlú ńlá láti lọ sọ ìròyìn náà ní Jesreeli.” 16 Nígbà náà Jehu wọ inú kẹ̀kẹ́ rẹ̀, ó sì gùn ún lọ sí Jesreeli, nítorí Joramu ń sinmi níbẹ̀ àti Ahasiah ọba Juda sì sọ̀kalẹ̀ láti wá wò Joramu. 17 Nígbà tí olùṣọ́ kan tí ó dúró ní ilé ìṣọ́ ní Jesreeli, rí ọ̀wọ́ ogun Jehu tí wọ́n ń súnmọ́ tòsí, ó pè jáde, “Mo rí àwọn ọ̀wọ́ ogun tí ó ń bọ̀.”“Mú ọkùnrin ẹlẹ́ṣin kan,” Joramu pa á láṣẹ. “Rán an lọ sí ọ̀dọ̀ wọn kí o sì béèrè pé, ‘Ṣé ẹ̀yin wá pẹ̀lú àlàáfíà?’ ” 18 Ọkùnrin ẹlẹ́ṣin náà, lọ láti lọ bá Jehu ó sì wí pé, “Èyí ni ohun tí ọba wí: ‘Ṣé ìwọ wá pẹ̀lú àlàáfíà?’ ”“Kí ni ìwọ ní ṣe pẹ̀lú àlàáfíà?” Jehu sì dáhùn. “Bọ́ sí ẹ̀yìn mi.”Olùṣọ́ náà sì wí fún un pé, “Ìránṣẹ́ náà ti dé ọ̀dọ̀ wọn, ṣùgbọ́n kò tún padà wá mọ́.” 19 Bẹ́ẹ̀ ni, ọba rán ọkùnrin ẹlẹ́ṣin kejì. Nígbà náà ó wá sí ọ̀dọ̀ wọn, ó wí pé, “Èyí ni ohun tí ọba sọ:“Ṣé ìwọ wá pẹ̀lú àlàáfíà?” Jehu dáhùn, “Dúró sí ẹ̀yìn mi.” 20 Olùṣọ́ náà sì fi sùn. “Ó ti dé ọ̀dọ̀ wọn, ṣùgbọ́n kò tún padà wá mọ́ pẹ̀lú. Wíwá rẹ̀ sì dàbí ti Jehu ọmọ Nimṣi, ó ń wa kẹ̀kẹ́ bí ti aṣiwèrè.” 21 “Fi ìwọ̀ kọ́ kẹ̀kẹ́ ogun mi.” Joramu pa á láṣẹ. Àti nígbà tí a fi kọ́, Joramu ọba Israẹli àti Ahasiah ọba Juda, gun kẹ̀kẹ́ lọ, olúkúlùkù nínú kẹ̀kẹ́ ogun tirẹ̀, láti lọ bá Jehu. Wọ́n bá a pàdé ní ibi oko tí ó ti jẹ́ ti Naboti ará Jesreeli. 22 Nígbà tí Joramu rí Jehu, ó béèrè pé, “Ṣé ìwọ wá pẹ̀lú àlàáfíà, Jehu?”“Báwo ni àlàáfíà yóò ṣe wà,” Jehu dáhùn, “Ní ìwọ̀n ìgbà tí gbogbo ìbọ̀rìṣà àti iṣẹ́ àjẹ́ ti màmá rẹ Jesebeli di púpọ̀?” 23 Joramu yí ọwọ́ rẹ̀ padà, ó sì sálọ, ó sì ń pe Ahasiah, “Ọ̀tẹ̀ dé, Ahasiah!” 24 Nígbà náà, Jehu fa ọrun rẹ̀, ó sì yin Joramu láàrín èjìká méjèèjì. Ọfà náà sì wọ inú ọkàn rẹ̀, ó sì ṣubú lulẹ̀ láti orí kẹ̀kẹ́ rẹ̀. 25 Jehu sọ fún Bidikari, balógun kẹ̀kẹ́ ẹ rẹ̀ pé, “Gbé e sókè kí ó sì jù ú sí orí oko tí ó jẹ́ ti Naboti ará Jesreeli. Rántí bí èmi àti ìwọ ti ń gun kẹ̀kẹ́ papọ̀ lẹ́yìn Ahabu baba à rẹ nígbà tí OLÚWA sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀, 26 ‘Ní àná, mo rí ẹ̀jẹ̀ Naboti pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, ni OLÚWA wí.’ Ǹjẹ́ nítorí náà, ẹ gbé e sókè, kí o sì jù ú sí orí ilẹ̀ oko náà ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ OLÚWA.” 27 Nígbà tí Ahasiah ọba, Juda rí ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀, ó sálọ sójú ọ̀nà sí Beti-Haggani. Jehu sì lépa rẹ̀, ó ń kígbe, “Pa á pẹ̀lú!” Wọ́n ṣá a ní ọgbẹ́ nínú kẹ̀kẹ́ ẹ rẹ̀ ní ọ̀nà lọ sí Guri lẹ́bàá a Ibleamu, ṣùgbọ́n ó sálọ sí Megido, ó sì kú síbẹ̀. 28 Ìránṣẹ́ rẹ̀ sì gbé e pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ lọ sí Jerusalẹmu, ó sì sin ín pẹ̀lú, baba a rẹ̀ nínú ibojì rẹ̀ ní ìlú ńlá ti Dafidi. 29 (Ní ọdún kọkànlá ti Joramu ọmọ Ahabu, Ahasiah ti di ọba Juda.) 30 Nígbà náà Jehu lọ sí Jesreeli. Nígbà tí Jesebeli gbọ́ nípa rẹ̀, ó kun ojú u rẹ̀, ó to irun rẹ̀, ó sì wò jáde láti ojú fèrèsé. 31 Bí Jehu ti wọ ẹnu ìlẹ̀kùn, ó béèrè, “Ṣé ìwọ wá ní àlàáfíà, Simri, ìwọ olùpa ọ̀gá à rẹ?” 32 Ó gbójú sókè láti wo fèrèsé, ó sì pè jáde, “Ta ni ó wà ní ẹ̀gbẹ́ mi? Ta ni?” Ìwẹ̀fà méjì tàbí mẹ́ta bojú wò ó nílẹ̀. 33 Jehu sọ wí pé, “Gbé e jù sílẹ̀!” Wọ́n sì jù ú sílẹ̀. Díẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sì fọ́n sí ara ògiri àti àwọn ẹṣin bí wọ́n ti tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ wọn. 34 Jehu wọ inú ilé lọ, ó jẹ, ó sì mu. “Tọ́jú obìnrin yẹn tí a fi bú,” Ó wí, “Kí o sì sin ín, nítorí ọmọbìnrin ọba ni ó jẹ́.” 35 Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n jáde lọ láti lọ sin ín, wọn kò rí nǹkan kan àyàfi agbárí i rẹ̀, ẹsẹ̀ rẹ̀ méjèèjì àti ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì. 36 Wọ́n padà lọ sọ fún Jehu, ẹni tí ó wí pé, “Èyí ni ọ̀rọ̀ OLÚWA tí ó sọ nípasẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀ Elijah ará Tiṣibi wí pé, ‘Ní orí oko Jesreeli ni àwọn ajá yóò ti jẹ ẹran-ara Jesebeli. 37 Òkú Jesebeli yóò dàbí ohun ẹ̀gbin ní orí oko Jesreeli, dé bi pé, ẹnikẹ́ni kì yóò lè sọ pé, “Jesebeli ni èyí.” ’ ”

In Other Versions

2 Kings 9 in the ANGEFD

2 Kings 9 in the ANTPNG2D

2 Kings 9 in the AS21

2 Kings 9 in the BAGH

2 Kings 9 in the BBPNG

2 Kings 9 in the BBT1E

2 Kings 9 in the BDS

2 Kings 9 in the BEV

2 Kings 9 in the BHAD

2 Kings 9 in the BIB

2 Kings 9 in the BLPT

2 Kings 9 in the BNT

2 Kings 9 in the BNTABOOT

2 Kings 9 in the BNTLV

2 Kings 9 in the BOATCB

2 Kings 9 in the BOATCB2

2 Kings 9 in the BOBCV

2 Kings 9 in the BOCNT

2 Kings 9 in the BOECS

2 Kings 9 in the BOGWICC

2 Kings 9 in the BOHCB

2 Kings 9 in the BOHCV

2 Kings 9 in the BOHLNT

2 Kings 9 in the BOHNTLTAL

2 Kings 9 in the BOICB

2 Kings 9 in the BOILNTAP

2 Kings 9 in the BOITCV

2 Kings 9 in the BOKCV

2 Kings 9 in the BOKCV2

2 Kings 9 in the BOKHWOG

2 Kings 9 in the BOKSSV

2 Kings 9 in the BOLCB

2 Kings 9 in the BOLCB2

2 Kings 9 in the BOMCV

2 Kings 9 in the BONAV

2 Kings 9 in the BONCB

2 Kings 9 in the BONLT

2 Kings 9 in the BONUT2

2 Kings 9 in the BOPLNT

2 Kings 9 in the BOSCB

2 Kings 9 in the BOSNC

2 Kings 9 in the BOTLNT

2 Kings 9 in the BOVCB

2 Kings 9 in the BPBB

2 Kings 9 in the BPH

2 Kings 9 in the BSB

2 Kings 9 in the CCB

2 Kings 9 in the CUV

2 Kings 9 in the CUVS

2 Kings 9 in the DBT

2 Kings 9 in the DGDNT

2 Kings 9 in the DHNT

2 Kings 9 in the DNT

2 Kings 9 in the ELBE

2 Kings 9 in the EMTV

2 Kings 9 in the ESV

2 Kings 9 in the FBV

2 Kings 9 in the FEB

2 Kings 9 in the GGMNT

2 Kings 9 in the GNT

2 Kings 9 in the HARY

2 Kings 9 in the HNT

2 Kings 9 in the IRVA

2 Kings 9 in the IRVB

2 Kings 9 in the IRVG

2 Kings 9 in the IRVH

2 Kings 9 in the IRVK

2 Kings 9 in the IRVM

2 Kings 9 in the IRVM2

2 Kings 9 in the IRVO

2 Kings 9 in the IRVP

2 Kings 9 in the IRVT

2 Kings 9 in the IRVT2

2 Kings 9 in the IRVU

2 Kings 9 in the ISVN

2 Kings 9 in the JSNT

2 Kings 9 in the KAPI

2 Kings 9 in the KBT1ETNIK

2 Kings 9 in the KBV

2 Kings 9 in the KJV

2 Kings 9 in the KNFD

2 Kings 9 in the LBA

2 Kings 9 in the LBLA

2 Kings 9 in the LNT

2 Kings 9 in the LSV

2 Kings 9 in the MAAL

2 Kings 9 in the MBV

2 Kings 9 in the MBV2

2 Kings 9 in the MHNT

2 Kings 9 in the MKNFD

2 Kings 9 in the MNG

2 Kings 9 in the MNT

2 Kings 9 in the MNT2

2 Kings 9 in the MRS1T

2 Kings 9 in the NAA

2 Kings 9 in the NASB

2 Kings 9 in the NBLA

2 Kings 9 in the NBS

2 Kings 9 in the NBVTP

2 Kings 9 in the NET2

2 Kings 9 in the NIV11

2 Kings 9 in the NNT

2 Kings 9 in the NNT2

2 Kings 9 in the NNT3

2 Kings 9 in the PDDPT

2 Kings 9 in the PFNT

2 Kings 9 in the RMNT

2 Kings 9 in the SBIAS

2 Kings 9 in the SBIBS

2 Kings 9 in the SBIBS2

2 Kings 9 in the SBICS

2 Kings 9 in the SBIDS

2 Kings 9 in the SBIGS

2 Kings 9 in the SBIHS

2 Kings 9 in the SBIIS

2 Kings 9 in the SBIIS2

2 Kings 9 in the SBIIS3

2 Kings 9 in the SBIKS

2 Kings 9 in the SBIKS2

2 Kings 9 in the SBIMS

2 Kings 9 in the SBIOS

2 Kings 9 in the SBIPS

2 Kings 9 in the SBISS

2 Kings 9 in the SBITS

2 Kings 9 in the SBITS2

2 Kings 9 in the SBITS3

2 Kings 9 in the SBITS4

2 Kings 9 in the SBIUS

2 Kings 9 in the SBIVS

2 Kings 9 in the SBT

2 Kings 9 in the SBT1E

2 Kings 9 in the SCHL

2 Kings 9 in the SNT

2 Kings 9 in the SUSU

2 Kings 9 in the SUSU2

2 Kings 9 in the SYNO

2 Kings 9 in the TBIAOTANT

2 Kings 9 in the TBT1E

2 Kings 9 in the TBT1E2

2 Kings 9 in the TFTIP

2 Kings 9 in the TFTU

2 Kings 9 in the TGNTATF3T

2 Kings 9 in the THAI

2 Kings 9 in the TNFD

2 Kings 9 in the TNT

2 Kings 9 in the TNTIK

2 Kings 9 in the TNTIL

2 Kings 9 in the TNTIN

2 Kings 9 in the TNTIP

2 Kings 9 in the TNTIZ

2 Kings 9 in the TOMA

2 Kings 9 in the TTENT

2 Kings 9 in the UBG

2 Kings 9 in the UGV

2 Kings 9 in the UGV2

2 Kings 9 in the UGV3

2 Kings 9 in the VBL

2 Kings 9 in the VDCC

2 Kings 9 in the YALU

2 Kings 9 in the YAPE

2 Kings 9 in the YBVTP

2 Kings 9 in the ZBP