Leviticus 3 (BOYCB)

1 “ ‘Bí ọrẹ ẹnìkan bá jẹ́ ọrẹ àlàáfíà, tí ó sì mú ẹran wá láti inú agbo màlúù yálà akọ tàbí abo, kí ó mú èyí tí kò ní àbùkù wá síwájú OLÚWA. 2 Kí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e lórí, kí ó sì pa á ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ. Nígbà náà ni àwọn ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà yóò wọ́n ẹ̀jẹ̀ ẹran náà yí pẹpẹ ká. 3 Láti ara ọrẹ àlàáfíà ni kí ẹni náà ti mú ẹbọ tí a fi iná sun sí OLÚWA, gbogbo ọ̀nà tí ó bo nǹkan inú ẹran náà àti gbogbo ọ̀rá tí ó so mọ́ wọn. 4 Kíndìnrín méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá ara rẹ̀ tí ń bẹ lẹ́bàá ìhà rẹ̀, àti gbogbo ọ̀rá tí ó bo ẹ̀dọ̀, kí ó yọ ọ́ jáde pẹ̀lú kíndìnrín. 5 Nígbà náà ni àwọn ọmọ Aaroni yóò sun ún lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sísun tí a fi iná sun, àní òórùn dídùn sí OLÚWA. 6 “ ‘Bí ó bá ṣe inú agbo ewúrẹ́ àti àgùntàn ni ó ti mú ọrẹ àlàáfíà wá fún OLÚWA kí ó mú akọ tàbí abo tí kò ní àbùkù. 7 Bí ó bá ṣe pé ọ̀dọ́-àgùntàn ni ó mú, kí ó mú un wá síwájú OLÚWA. 8 Kí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e lórí, kí ó sì pa á níwájú àgọ́ ìpàdé, kí àwọn ọmọ Aaroni wọ́n ẹ̀jẹ̀ ẹran náà yí pẹpẹ ká. 9 Kí o sì mú wá nínú ẹbọ àlàáfíà náà, fún ẹbọ tí a fi iná ṣe sí OLÚWA; ọ̀rá rẹ̀ àti gbogbo ìrù rẹ̀ tí ó ní ọ̀rá, òun ni kí o mú kúrò súnmọ́ egungun ẹ̀yìn àti ọ̀rá tí ó bo ìfun lórí; àti gbogbo ọ̀rá tí ń bẹ lára ìfun. 10 Kíndìnrín méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá tí ń bẹ lẹ́bàá ìhà rẹ̀ àti ọ̀rá tí ó bo ẹ̀dọ̀, kí o yọ ọ́ jáde pẹ̀lú kíndìnrín. 11 Kí àlùfáà sun ún lórí pẹpẹ bí oúnjẹ ọrẹ tí a fi iná sun sí OLÚWA. 12 “ ‘Bí ó bá ṣe pé ewúrẹ́ ni ó mú, kí ó mú un wá síwájú OLÚWA. 13 Kí ó gbé ọwọ́ lé e lórí. Kí ó sì pa á ní iwájú àgọ́ ìpàdé. Nígbà náà ni àwọn ọmọ Aaroni yóò wọ́n ẹ̀jẹ̀ ẹran náà yí pẹpẹ ká. 14 Lára ọrẹ tó mú wá, kí ó mú ẹbọ sísun fún OLÚWA, gbogbo ọ̀rá tí ó bo nǹkan inú rẹ̀ àti ohun gbogbo tó so mọ́ ọn. 15 Kíndìnrín méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá ara rẹ̀ tí ń bẹ lẹ́bàá ìhà rẹ̀ àti ọ̀rá tí ó bo ẹ̀dọ̀, kí ó yọ ọ́ jáde pẹ̀lú kíndìnrín. 16 Kí àlùfáà sun ún lórí pẹpẹ bí oúnjẹ, ọrẹ tí a fi iná sun, ní òórùn dídùn. Gbogbo ọ̀rá rẹ̀ jẹ́ ti OLÚWA. 17 “ ‘Èyí jẹ́ ìlànà láéláé fún àwọn ìran tó ń bọ̀, ní gbogbo ibi tí ẹ bá ń gbé, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ọ̀rá tàbí ẹ̀jẹ̀.’ ”

In Other Versions

Leviticus 3 in the ANGEFD

Leviticus 3 in the ANTPNG2D

Leviticus 3 in the AS21

Leviticus 3 in the BAGH

Leviticus 3 in the BBPNG

Leviticus 3 in the BBT1E

Leviticus 3 in the BDS

Leviticus 3 in the BEV

Leviticus 3 in the BHAD

Leviticus 3 in the BIB

Leviticus 3 in the BLPT

Leviticus 3 in the BNT

Leviticus 3 in the BNTABOOT

Leviticus 3 in the BNTLV

Leviticus 3 in the BOATCB

Leviticus 3 in the BOATCB2

Leviticus 3 in the BOBCV

Leviticus 3 in the BOCNT

Leviticus 3 in the BOECS

Leviticus 3 in the BOGWICC

Leviticus 3 in the BOHCB

Leviticus 3 in the BOHCV

Leviticus 3 in the BOHLNT

Leviticus 3 in the BOHNTLTAL

Leviticus 3 in the BOICB

Leviticus 3 in the BOILNTAP

Leviticus 3 in the BOITCV

Leviticus 3 in the BOKCV

Leviticus 3 in the BOKCV2

Leviticus 3 in the BOKHWOG

Leviticus 3 in the BOKSSV

Leviticus 3 in the BOLCB

Leviticus 3 in the BOLCB2

Leviticus 3 in the BOMCV

Leviticus 3 in the BONAV

Leviticus 3 in the BONCB

Leviticus 3 in the BONLT

Leviticus 3 in the BONUT2

Leviticus 3 in the BOPLNT

Leviticus 3 in the BOSCB

Leviticus 3 in the BOSNC

Leviticus 3 in the BOTLNT

Leviticus 3 in the BOVCB

Leviticus 3 in the BPBB

Leviticus 3 in the BPH

Leviticus 3 in the BSB

Leviticus 3 in the CCB

Leviticus 3 in the CUV

Leviticus 3 in the CUVS

Leviticus 3 in the DBT

Leviticus 3 in the DGDNT

Leviticus 3 in the DHNT

Leviticus 3 in the DNT

Leviticus 3 in the ELBE

Leviticus 3 in the EMTV

Leviticus 3 in the ESV

Leviticus 3 in the FBV

Leviticus 3 in the FEB

Leviticus 3 in the GGMNT

Leviticus 3 in the GNT

Leviticus 3 in the HARY

Leviticus 3 in the HNT

Leviticus 3 in the IRVA

Leviticus 3 in the IRVB

Leviticus 3 in the IRVG

Leviticus 3 in the IRVH

Leviticus 3 in the IRVK

Leviticus 3 in the IRVM

Leviticus 3 in the IRVM2

Leviticus 3 in the IRVO

Leviticus 3 in the IRVP

Leviticus 3 in the IRVT

Leviticus 3 in the IRVT2

Leviticus 3 in the IRVU

Leviticus 3 in the ISVN

Leviticus 3 in the JSNT

Leviticus 3 in the KAPI

Leviticus 3 in the KBT1ETNIK

Leviticus 3 in the KBV

Leviticus 3 in the KJV

Leviticus 3 in the KNFD

Leviticus 3 in the LBA

Leviticus 3 in the LBLA

Leviticus 3 in the LNT

Leviticus 3 in the LSV

Leviticus 3 in the MAAL

Leviticus 3 in the MBV

Leviticus 3 in the MBV2

Leviticus 3 in the MHNT

Leviticus 3 in the MKNFD

Leviticus 3 in the MNG

Leviticus 3 in the MNT

Leviticus 3 in the MNT2

Leviticus 3 in the MRS1T

Leviticus 3 in the NAA

Leviticus 3 in the NASB

Leviticus 3 in the NBLA

Leviticus 3 in the NBS

Leviticus 3 in the NBVTP

Leviticus 3 in the NET2

Leviticus 3 in the NIV11

Leviticus 3 in the NNT

Leviticus 3 in the NNT2

Leviticus 3 in the NNT3

Leviticus 3 in the PDDPT

Leviticus 3 in the PFNT

Leviticus 3 in the RMNT

Leviticus 3 in the SBIAS

Leviticus 3 in the SBIBS

Leviticus 3 in the SBIBS2

Leviticus 3 in the SBICS

Leviticus 3 in the SBIDS

Leviticus 3 in the SBIGS

Leviticus 3 in the SBIHS

Leviticus 3 in the SBIIS

Leviticus 3 in the SBIIS2

Leviticus 3 in the SBIIS3

Leviticus 3 in the SBIKS

Leviticus 3 in the SBIKS2

Leviticus 3 in the SBIMS

Leviticus 3 in the SBIOS

Leviticus 3 in the SBIPS

Leviticus 3 in the SBISS

Leviticus 3 in the SBITS

Leviticus 3 in the SBITS2

Leviticus 3 in the SBITS3

Leviticus 3 in the SBITS4

Leviticus 3 in the SBIUS

Leviticus 3 in the SBIVS

Leviticus 3 in the SBT

Leviticus 3 in the SBT1E

Leviticus 3 in the SCHL

Leviticus 3 in the SNT

Leviticus 3 in the SUSU

Leviticus 3 in the SUSU2

Leviticus 3 in the SYNO

Leviticus 3 in the TBIAOTANT

Leviticus 3 in the TBT1E

Leviticus 3 in the TBT1E2

Leviticus 3 in the TFTIP

Leviticus 3 in the TFTU

Leviticus 3 in the TGNTATF3T

Leviticus 3 in the THAI

Leviticus 3 in the TNFD

Leviticus 3 in the TNT

Leviticus 3 in the TNTIK

Leviticus 3 in the TNTIL

Leviticus 3 in the TNTIN

Leviticus 3 in the TNTIP

Leviticus 3 in the TNTIZ

Leviticus 3 in the TOMA

Leviticus 3 in the TTENT

Leviticus 3 in the UBG

Leviticus 3 in the UGV

Leviticus 3 in the UGV2

Leviticus 3 in the UGV3

Leviticus 3 in the VBL

Leviticus 3 in the VDCC

Leviticus 3 in the YALU

Leviticus 3 in the YAPE

Leviticus 3 in the YBVTP

Leviticus 3 in the ZBP