Zechariah 7 (BOYCB)
1 Ó sì ṣe ní ọdún kẹrin Dariusi ọba, ọ̀rọ̀ OLÚWA tọ́ Sekariah wá ni ọjọ́ kẹrin oṣù Kisleu tí ń ṣe oṣù kẹsànán. 2 Nígbà tí wọ́n ènìyàn Beteli rán Ṣareseri àti Regemmeleki, àti àwọn ènìyàn wọn sí ilé Ọlọ́run láti wá ojúrere OLÚWA. 3 Àti láti bá àwọn àlùfáà tí ó wà ní ilé OLÚWA àwọn ọmọ-ogun, àti àwọn wòlíì sọ̀rọ̀ wí pé, “Ṣé kí èmi ó sọkún ní oṣù karùn-ún kí èmi ya ara mi sọ́tọ̀, bí mo ti ń ṣe láti ọdún mélòó wọ̀nyí wá bí?” 4 Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ OLÚWA àwọn ọmọ-ogun tọ̀ mí wá pé, 5 “Sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà, àti fún àwọn àlùfáà pé, ‘Nígbà tí ẹ̀yin gbààwẹ̀, tí ẹ sì ṣọ̀fọ̀ ní oṣù karùn-ún àti keje, àní fun àádọ́rin ọdún wọ̀nyí, ǹjẹ́ èmi ni ẹ̀yin ha ń gbààwẹ̀ yín fún? 6 Nígbà tí ẹ sì jẹ, àti nígbà tí ẹ mu, fún ara yín kọ́ ni ẹ̀yin jẹ, àti fún ara yín kọ́ ni ẹ̀yin mú bí? 7 Wọ̀nyí kọ́ ni ọ̀rọ̀ ti OLÚWA ti kígbe láti ọ̀dọ̀ àwọn wòlíì ìṣáájú wá, nígbà tí a ń gbé Jerusalẹmu, tí ó sì wà ní àlàáfíà, pẹ̀lú àwọn ìlú rẹ̀ tí ó yí i káàkiri, nígbà tí a ń gbé gúúsù àti pẹ̀tẹ́lẹ̀.’ ” 8 Ọ̀rọ̀ OLÚWA sì tọ Sekariah wá, wí pé, 9 “Báyìí ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí pé, ‘Ṣe ìdájọ́ òtítọ́, kí ẹ sì ṣe àánú àti ìyọ́nú olúkúlùkù sí arákùnrin rẹ̀. 10 Má sì ṣe ni opó lára tàbí aláìní baba, àlejò, tàbí tálákà; kí ẹnikẹ́ni nínú yín má ṣe gbèrò ibi ní ọkàn sí arákùnrin rẹ̀.’ 11 “Ṣùgbọ́n wọ́n kọ̀ láti gbọ́, wọ́n sì gún èjìká, wọ́n sì pa ẹ̀yìn dà, wọ́n di etí wọn, kí wọn má ba à gbọ́. 12 Wọ́n sé ọkàn wọn bí òkúta líle, kí wọn má ba à gbọ́ òfin, àti ọ̀rọ̀ tí OLÚWA àwọn ọmọ-ogun ti fi ẹ̀mí rẹ̀ rán nípa ọwọ́ àwọn wòlíì ìṣáájú wá. Ìbínú ńlá sì dé láti ọ̀dọ̀ OLÚWA àwọn ọmọ-ogun. 13 “ ‘Ó sì ṣe, gẹ́gẹ́ bí ó ti kígbe, tí wọn kò sì fẹ́ gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kígbe, tí èmi kò sì fẹ́ gbọ́,’ ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí. 14 ‘Mo sì fi ìjì tú wọn ká sí gbogbo orílẹ̀-èdè tí wọn kò mọ̀. Ilẹ̀ náà sì dahoro lẹ́yìn wọn, tí ẹnikẹ́ni kò là á kọjá tàbí kí ó padà bọ̀, wọ́n sì sọ ilẹ̀ ààyò náà dahoro.’ ”
In Other Versions
Zechariah 7 in the ANGEFD
Zechariah 7 in the ANTPNG2D
Zechariah 7 in the AS21
Zechariah 7 in the BAGH
Zechariah 7 in the BBPNG
Zechariah 7 in the BBT1E
Zechariah 7 in the BDS
Zechariah 7 in the BEV
Zechariah 7 in the BHAD
Zechariah 7 in the BIB
Zechariah 7 in the BLPT
Zechariah 7 in the BNT
Zechariah 7 in the BNTABOOT
Zechariah 7 in the BNTLV
Zechariah 7 in the BOATCB
Zechariah 7 in the BOATCB2
Zechariah 7 in the BOBCV
Zechariah 7 in the BOCNT
Zechariah 7 in the BOECS
Zechariah 7 in the BOGWICC
Zechariah 7 in the BOHCB
Zechariah 7 in the BOHCV
Zechariah 7 in the BOHLNT
Zechariah 7 in the BOHNTLTAL
Zechariah 7 in the BOICB
Zechariah 7 in the BOILNTAP
Zechariah 7 in the BOITCV
Zechariah 7 in the BOKCV
Zechariah 7 in the BOKCV2
Zechariah 7 in the BOKHWOG
Zechariah 7 in the BOKSSV
Zechariah 7 in the BOLCB
Zechariah 7 in the BOLCB2
Zechariah 7 in the BOMCV
Zechariah 7 in the BONAV
Zechariah 7 in the BONCB
Zechariah 7 in the BONLT
Zechariah 7 in the BONUT2
Zechariah 7 in the BOPLNT
Zechariah 7 in the BOSCB
Zechariah 7 in the BOSNC
Zechariah 7 in the BOTLNT
Zechariah 7 in the BOVCB
Zechariah 7 in the BPBB
Zechariah 7 in the BPH
Zechariah 7 in the BSB
Zechariah 7 in the CCB
Zechariah 7 in the CUV
Zechariah 7 in the CUVS
Zechariah 7 in the DBT
Zechariah 7 in the DGDNT
Zechariah 7 in the DHNT
Zechariah 7 in the DNT
Zechariah 7 in the ELBE
Zechariah 7 in the EMTV
Zechariah 7 in the ESV
Zechariah 7 in the FBV
Zechariah 7 in the FEB
Zechariah 7 in the GGMNT
Zechariah 7 in the GNT
Zechariah 7 in the HARY
Zechariah 7 in the HNT
Zechariah 7 in the IRVA
Zechariah 7 in the IRVB
Zechariah 7 in the IRVG
Zechariah 7 in the IRVH
Zechariah 7 in the IRVK
Zechariah 7 in the IRVM
Zechariah 7 in the IRVM2
Zechariah 7 in the IRVO
Zechariah 7 in the IRVP
Zechariah 7 in the IRVT
Zechariah 7 in the IRVT2
Zechariah 7 in the IRVU
Zechariah 7 in the ISVN
Zechariah 7 in the JSNT
Zechariah 7 in the KAPI
Zechariah 7 in the KBT1ETNIK
Zechariah 7 in the KBV
Zechariah 7 in the KJV
Zechariah 7 in the KNFD
Zechariah 7 in the LBA
Zechariah 7 in the LBLA
Zechariah 7 in the LNT
Zechariah 7 in the LSV
Zechariah 7 in the MAAL
Zechariah 7 in the MBV
Zechariah 7 in the MBV2
Zechariah 7 in the MHNT
Zechariah 7 in the MKNFD
Zechariah 7 in the MNG
Zechariah 7 in the MNT
Zechariah 7 in the MNT2
Zechariah 7 in the MRS1T
Zechariah 7 in the NAA
Zechariah 7 in the NASB
Zechariah 7 in the NBLA
Zechariah 7 in the NBS
Zechariah 7 in the NBVTP
Zechariah 7 in the NET2
Zechariah 7 in the NIV11
Zechariah 7 in the NNT
Zechariah 7 in the NNT2
Zechariah 7 in the NNT3
Zechariah 7 in the PDDPT
Zechariah 7 in the PFNT
Zechariah 7 in the RMNT
Zechariah 7 in the SBIAS
Zechariah 7 in the SBIBS
Zechariah 7 in the SBIBS2
Zechariah 7 in the SBICS
Zechariah 7 in the SBIDS
Zechariah 7 in the SBIGS
Zechariah 7 in the SBIHS
Zechariah 7 in the SBIIS
Zechariah 7 in the SBIIS2
Zechariah 7 in the SBIIS3
Zechariah 7 in the SBIKS
Zechariah 7 in the SBIKS2
Zechariah 7 in the SBIMS
Zechariah 7 in the SBIOS
Zechariah 7 in the SBIPS
Zechariah 7 in the SBISS
Zechariah 7 in the SBITS
Zechariah 7 in the SBITS2
Zechariah 7 in the SBITS3
Zechariah 7 in the SBITS4
Zechariah 7 in the SBIUS
Zechariah 7 in the SBIVS
Zechariah 7 in the SBT
Zechariah 7 in the SBT1E
Zechariah 7 in the SCHL
Zechariah 7 in the SNT
Zechariah 7 in the SUSU
Zechariah 7 in the SUSU2
Zechariah 7 in the SYNO
Zechariah 7 in the TBIAOTANT
Zechariah 7 in the TBT1E
Zechariah 7 in the TBT1E2
Zechariah 7 in the TFTIP
Zechariah 7 in the TFTU
Zechariah 7 in the TGNTATF3T
Zechariah 7 in the THAI
Zechariah 7 in the TNFD
Zechariah 7 in the TNT
Zechariah 7 in the TNTIK
Zechariah 7 in the TNTIL
Zechariah 7 in the TNTIN
Zechariah 7 in the TNTIP
Zechariah 7 in the TNTIZ
Zechariah 7 in the TOMA
Zechariah 7 in the TTENT
Zechariah 7 in the UBG
Zechariah 7 in the UGV
Zechariah 7 in the UGV2
Zechariah 7 in the UGV3
Zechariah 7 in the VBL
Zechariah 7 in the VDCC
Zechariah 7 in the YALU
Zechariah 7 in the YAPE
Zechariah 7 in the YBVTP
Zechariah 7 in the ZBP