Daniel 12 (BOYCB)

1 “Ní àkókò náà, ni Mikaeli, ọmọ-aládé ńlá, ẹni tí o ń dáàbò bo àwọn ènìyàn an rẹ̀ yóò dìde. Àkókò ìpọ́njú yóò wà, irú èyí tí kò tí ì ṣẹlẹ̀ rí láti ìbẹ̀rẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè títí di àkókò náà. Ṣùgbọ́n ní àkókò náà àwọn ènìyàn rẹ̀, gbogbo àwọn tí a bá ti rí orúkọ wọn nínú ìwé ni a ó gbàlà. 2 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí ó sùn nínú erùpẹ̀ ilẹ̀ ni yóò jí: àwọn mìíràn sí ìyè àìnípẹ̀kun, àwọn tókù sí ìtìjú àti sí ẹ̀gàn àìnípẹ̀kun. 3 Àwọn tí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n yóò máa tàn bí ìmọ́lẹ̀ ọ̀run, àti àwọn tí ó ń tọ́nisọ́nà sí òdodo, yóò máa tàn bí ìràwọ̀ láé àti láéláé. 4 Ṣùgbọ́n ìwọ Daniẹli, pa ìwé náà dé kí o sì pa ọ̀rọ̀ ọ rẹ̀ mọ́ títí àkókò ìgbẹ̀yìn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò máa lọ sí ìhín sí ọ̀hún láti jẹ́ kí ìmọ̀ wọn di púpọ̀.” 5 Nígbà náà, ni èmi Daniẹli, wò, ní iwájú mi àwọn méjì mìíràn dúró, ọ̀kan dúró sí apá ìhín ní etí bèbè odò ẹnìkan náà ní apá òdìkejì ọ̀hún etí i bèbè. 6 Ọ̀kan lára wọn sọ fún ọkùnrin tí ó wọ aṣọ àlà, ẹni tí ó wà lórí omi odò pé, “Báwo ni yóò ṣe pẹ́ tó kí àwọn nǹkan ìyanu wọ̀nyí tó wá sí ìmúṣẹ?” 7 Ọkùnrin tí ó wọ aṣọ àlà, ẹni tí ó wà lórí omi odò, gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti ọwọ́ òsì rẹ̀, mo gbọ́ tí ó fi ẹni tí ó wà títí láé búra, ó sọ wí pé, “Yóò ṣe ní àkókò kan, àkókò méjì àti ààbọ̀. Nígbà tí agbára àwọn ẹni mímọ́ yóò ti fọ́ tán pátápátá, gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò sì parí.” 8 Èmi gbọ́, ṣùgbọ́n kò yé mi. Nígbà náà ni mo béèrè pé, “Olúwa mi, kí ni yóò jẹ́ àbábọ̀ àwọn nǹkan wọ̀nyí?” 9 Ó sì dáhùn pé, “Máa lọ ní ọ̀nà rẹ, Daniẹli nítorí tí a ti pa ọ̀rọ̀ náà dé, a sì ti fi èdìdì dì í di ìgbà ìkẹyìn. 10 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni a ó fọ̀ mọ́, wọn yóò wà láìlábàwọ́n, a ó sì tún wọn ṣe, ṣùgbọ́n àwọn ẹni búburú yóò máa ṣe búburú lọ, kò sí ẹni búburú tí òye yóò yé ṣùgbọ́n òye yóò yé àwọn ọlọ́gbọ́n. 11 “Láti àkókò tí a ó mú ẹbọ ojoojúmọ́ kúrò, tí a ó sì gbé ìríra tí ó ń fa ìsọdahoro kalẹ̀ yóò sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún àti igba lé àádọ́rùn-ún ọjọ́ (1,290). 12 Ìbùkún ni fún ẹni tí ó dúró, ti ó sì di òpin ẹgbẹ̀rún àti ọ̀ọ́dúnrún lé àrùndínlógójì (1,335) ọjọ́. 13 “Ṣùgbọ́n ìwọ, máa lọ ní ọ̀nà rẹ, títí di òpin. Ìwọ yóò sinmi, àti ní òpin ọjọ́ ìwọ yóò dìde láti gba èrè rẹ.”

In Other Versions

Daniel 12 in the ANGEFD

Daniel 12 in the ANTPNG2D

Daniel 12 in the AS21

Daniel 12 in the BAGH

Daniel 12 in the BBPNG

Daniel 12 in the BBT1E

Daniel 12 in the BDS

Daniel 12 in the BEV

Daniel 12 in the BHAD

Daniel 12 in the BIB

Daniel 12 in the BLPT

Daniel 12 in the BNT

Daniel 12 in the BNTABOOT

Daniel 12 in the BNTLV

Daniel 12 in the BOATCB

Daniel 12 in the BOATCB2

Daniel 12 in the BOBCV

Daniel 12 in the BOCNT

Daniel 12 in the BOECS

Daniel 12 in the BOGWICC

Daniel 12 in the BOHCB

Daniel 12 in the BOHCV

Daniel 12 in the BOHLNT

Daniel 12 in the BOHNTLTAL

Daniel 12 in the BOICB

Daniel 12 in the BOILNTAP

Daniel 12 in the BOITCV

Daniel 12 in the BOKCV

Daniel 12 in the BOKCV2

Daniel 12 in the BOKHWOG

Daniel 12 in the BOKSSV

Daniel 12 in the BOLCB

Daniel 12 in the BOLCB2

Daniel 12 in the BOMCV

Daniel 12 in the BONAV

Daniel 12 in the BONCB

Daniel 12 in the BONLT

Daniel 12 in the BONUT2

Daniel 12 in the BOPLNT

Daniel 12 in the BOSCB

Daniel 12 in the BOSNC

Daniel 12 in the BOTLNT

Daniel 12 in the BOVCB

Daniel 12 in the BPBB

Daniel 12 in the BPH

Daniel 12 in the BSB

Daniel 12 in the CCB

Daniel 12 in the CUV

Daniel 12 in the CUVS

Daniel 12 in the DBT

Daniel 12 in the DGDNT

Daniel 12 in the DHNT

Daniel 12 in the DNT

Daniel 12 in the ELBE

Daniel 12 in the EMTV

Daniel 12 in the ESV

Daniel 12 in the FBV

Daniel 12 in the FEB

Daniel 12 in the GGMNT

Daniel 12 in the GNT

Daniel 12 in the HARY

Daniel 12 in the HNT

Daniel 12 in the IRVA

Daniel 12 in the IRVB

Daniel 12 in the IRVG

Daniel 12 in the IRVH

Daniel 12 in the IRVK

Daniel 12 in the IRVM

Daniel 12 in the IRVM2

Daniel 12 in the IRVO

Daniel 12 in the IRVP

Daniel 12 in the IRVT

Daniel 12 in the IRVT2

Daniel 12 in the IRVU

Daniel 12 in the ISVN

Daniel 12 in the JSNT

Daniel 12 in the KAPI

Daniel 12 in the KBT1ETNIK

Daniel 12 in the KBV

Daniel 12 in the KJV

Daniel 12 in the KNFD

Daniel 12 in the LBA

Daniel 12 in the LBLA

Daniel 12 in the LNT

Daniel 12 in the LSV

Daniel 12 in the MAAL

Daniel 12 in the MBV

Daniel 12 in the MBV2

Daniel 12 in the MHNT

Daniel 12 in the MKNFD

Daniel 12 in the MNG

Daniel 12 in the MNT

Daniel 12 in the MNT2

Daniel 12 in the MRS1T

Daniel 12 in the NAA

Daniel 12 in the NASB

Daniel 12 in the NBLA

Daniel 12 in the NBS

Daniel 12 in the NBVTP

Daniel 12 in the NET2

Daniel 12 in the NIV11

Daniel 12 in the NNT

Daniel 12 in the NNT2

Daniel 12 in the NNT3

Daniel 12 in the PDDPT

Daniel 12 in the PFNT

Daniel 12 in the RMNT

Daniel 12 in the SBIAS

Daniel 12 in the SBIBS

Daniel 12 in the SBIBS2

Daniel 12 in the SBICS

Daniel 12 in the SBIDS

Daniel 12 in the SBIGS

Daniel 12 in the SBIHS

Daniel 12 in the SBIIS

Daniel 12 in the SBIIS2

Daniel 12 in the SBIIS3

Daniel 12 in the SBIKS

Daniel 12 in the SBIKS2

Daniel 12 in the SBIMS

Daniel 12 in the SBIOS

Daniel 12 in the SBIPS

Daniel 12 in the SBISS

Daniel 12 in the SBITS

Daniel 12 in the SBITS2

Daniel 12 in the SBITS3

Daniel 12 in the SBITS4

Daniel 12 in the SBIUS

Daniel 12 in the SBIVS

Daniel 12 in the SBT

Daniel 12 in the SBT1E

Daniel 12 in the SCHL

Daniel 12 in the SNT

Daniel 12 in the SUSU

Daniel 12 in the SUSU2

Daniel 12 in the SYNO

Daniel 12 in the TBIAOTANT

Daniel 12 in the TBT1E

Daniel 12 in the TBT1E2

Daniel 12 in the TFTIP

Daniel 12 in the TFTU

Daniel 12 in the TGNTATF3T

Daniel 12 in the THAI

Daniel 12 in the TNFD

Daniel 12 in the TNT

Daniel 12 in the TNTIK

Daniel 12 in the TNTIL

Daniel 12 in the TNTIN

Daniel 12 in the TNTIP

Daniel 12 in the TNTIZ

Daniel 12 in the TOMA

Daniel 12 in the TTENT

Daniel 12 in the UBG

Daniel 12 in the UGV

Daniel 12 in the UGV2

Daniel 12 in the UGV3

Daniel 12 in the VBL

Daniel 12 in the VDCC

Daniel 12 in the YALU

Daniel 12 in the YAPE

Daniel 12 in the YBVTP

Daniel 12 in the ZBP