Ezekiel 21 (BOYCB)

1 Ọ̀rọ̀ OLÚWA tọ mi wá: 2 “Ọmọ ènìyàn, kọ ojú rẹ sí ìhà Jerusalẹmu, kí o sì wàásù lòdì sí ibi mímọ́. Sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí ilẹ̀ Israẹli. 3 Kí ó sì sọ fún un pe, ‘Èyí yìí ni OLÚWA wí, Èmi lòdì sí ọ. Èmi yóò fa idà mi yọ kúrò nínú àkọ̀ rẹ̀, Èmi yóò sì ké olódodo àti ènìyàn búburú kúrò ni àárín yín. 4 Nítorí pé, èmi yóò ké olódodo àti olùṣe búburú kúrò, idà mi yóò jáde láti inú àkọ̀ rẹ̀ lòdì sí gbogbo ènìyàn láti gúúsù títí dé àríwá. 5 Nígbà náà gbogbo ènìyàn yóò mọ̀ pé, Èmi OLÚWA ti yọ idà mi kúrò nínú àkọ̀ rẹ̀; kì yóò sì padà sínú rẹ̀ mọ́.’ 6 “Nítorí náà, mí ìmí ẹ̀dùn ìwọ ọmọ ènìyàn! Mí ìmí ẹ̀dùn pẹ̀lú ọkàn ìbànújẹ́ àti ẹ̀dùn ọkàn kíkorò ní iwájú wọn. 7 Bí wọ́n bá sì bi ọ́, wí pé, ‘Kí ni ó dé tí ìwọ fi ń mí ìmí ẹ̀dùn?’ Ìwọ yóò wí pé, ‘Nítorí ìròyìn tí ó ń bẹ. Gbogbo ọkàn ni yóò yọ́, gbogbo ọwọ́ ni yóò sì di aláìlera; gbogbo ọkàn ní yóò dákú, gbogbo eékún ni yóò sì di aláìlera bí omi?’ Ó ń bọ̀! Yóò sì wa sí ìmúṣẹ dandan, ni OLÚWA Olódùmarè wí.” 8 Ọ̀rọ̀ OLÚWA si tún tọ̀ mí wá pé: 9 “Ọmọ ènìyàn, sọtẹ́lẹ̀ wí pé, èyí yìí ní Olúwa wí pé,“ ‘Idà kan, idà kan,tí a pọ́n, tí a sì dán pẹ̀lú, 10 a pọ́n láti pa ènìyàn púpọ̀,a dán an láti máa kọ mọ̀nà!“ ‘Àwa o ha máa ṣe àríyá ọ̀gọ ọmọ mi? Idà gán gbogbo irú igi bẹ́ẹ̀. 11 “ ‘Idà ní a yàn láti pọ́n,kí ó lè ṣe é gbámú;a pọ́n ọn, a sì dán an,ó ṣetán fún ọwọ́ àwọn apani. 12 Sọkún síta, kí ó sì pohùnréré ẹ̀kún, ọmọ ènìyàn,nítorí yóò wá sórí àwọn ènìyàn mi;yóò wá sórí gbogbo ọmọ-aládé Israẹliìbẹ̀rù ńlá yóò wá sórí àwọn ènìyàn minítorí idà náà;nítorí náà lu oókan àyà rẹ. 13 “ ‘Ìdánwò yóò dé dandan. Tí ọ̀pá aládé Juda èyí tí idà kẹ́gàn, kò bá tẹ̀síwájú mọ́ ń kọ́? Ni OLÚWA Olódùmarè wí.’ 14 “Nítorí náà, ọmọ ènìyàn,sọtẹ́lẹ̀ kí ó sì fi ọwọ́ lu ọwọ́.Jẹ́ kí idà lu ara wọn lẹ́ẹ̀méjì,kódà ní ẹ̀ẹ̀mẹta.Ó jẹ́ idà fún ìpànìyànidà fún ìpànìyàn lọ́pọ̀lọ́pọ̀,tí yóò sé wọn mọ́ níhìn-ín àti lọ́hùnnún. 15 Kí ọkàn kí ó lè yọ́kí àwọn tí ó ṣubú le pọ̀,mo ti gbé idà sí gbogbo bodè fún ìparun.Háà! A mú kí ó kọ bí ìmọ̀nàmọ́ná,a gbá a mú fún ìparun. 16 Ìwọ idà, jà sí ọ̀túnkí o sì jà sí òsìlọ ibikíbi tí ẹnu rẹ bá dojúkọ. 17 Èmi gan an yóò pàtẹ́wọ́ìbínú mi yóò sì rẹlẹ̀.Èmi OLÚWA ti sọ̀rọ̀.” 18 Ọ̀rọ̀ OLÚWA tọ mi wá: 19 “Ọmọ ènìyàn la ọ̀nà méjì fún idà ọba Babeli láti gbà, kí méjèèjì bẹ̀rẹ̀ láti ìlú kan náà. Ṣe àmì sí ìkóríta ọ̀nà tí ó lọ sí ìlú náà. 20 La ọ̀nà kan fún idà láti wá kọlu Rabba ti àwọn ará Ammoni kí òmíràn kọlu Juda, kí ó sì kọlu Jerusalẹmu ìlú olódi. 21 Nítorí ọba Babeli yóò dúró ni ìyànà ní ojú ọ̀nà, ní ìkóríta, láti máa lo àfọ̀ṣẹ. Yóò fi ọfà di ìbò, yóò béèrè lọ́wọ́ àwọn òrìṣà rẹ̀, òun yóò ṣe àyẹ̀wò ẹ̀dọ̀. 22 Nínú ọwọ́ ọ̀tún rẹ ni ìbò Jerusalẹmu yóò ti wá, ní ibi tí yóò ti gbé afárá kalẹ̀, láti pàṣẹ fún àwọn apànìyàn, láti mú ki wọn hó ìhó ogun láti gbé òòlù dí ẹnu-ọ̀nà ibodè, láti mọ odi, àti láti kọ́ ilé ìṣọ́. 23 Àfọ̀ṣẹ náà yóò dàbí àmì èké sí àwọn tí ó ti búra ìtẹríba fún un, ṣùgbọ́n òun yóò ran wọn létí ẹbí wọn yóò sì mú wọn lọ sí ìgbèkùn. 24 “Nítorí náà èyí ní ohun tí OLÚWA Olódùmarè wí: ‘Nítorí ti ẹ̀yin ti mú ẹ̀bi yín wá sí ìrántí nípa ìṣọ̀tẹ̀ ní gbangba, ní ṣíṣe àfihàn àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ nínú gbogbo ohun tí ó ṣe, nítorí tí ẹ̀yin ti ṣe èyí, a yóò mú yín ní ìgbèkùn. 25 “ ‘Ìwọ aláìmọ́ àti ẹni búburú ọmọ-aládé Israẹli, ẹni ti ọjọ́ rẹ̀ ti dé, ẹni tí àsìkò ìjìyà rẹ̀ ti dé góńgó, 26 èyí yìí ní ohun tí OLÚWA Olódùmarè wí, tú ìwérí kúrò kí o sì gbé adé kúrò. Kò ní rí bí ti tẹ́lẹ̀, ẹni ìgbéga ni a yóò sì rẹ̀ sílẹ̀. 27 Ìparun! Ìparun! Èmi yóò ṣé e ni ìparun! Kì yóò padà bọ̀ sípò bí kò ṣe pé tí ó bá wá sí ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ní ẹ̀tọ́ láti ni in; òun ni èmi yóò fi fún.’ 28 “Àti ìwọ, ọmọ ènìyàn sọtẹ́lẹ̀ kí ó sì wí pé, ‘Èyí yìí ní ohun tí OLÚWA Olódùmarè wí nípa àwọn ará Ammoni àti àbùkù wọn:“ ‘Idà kan idà kantí á fa yọ fún ìpànìyàntí a dán láti fi ènìyàn ṣòfòàti láti kọ bí ìmọ̀nàmọ́ná! 29 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a rí èké nípa yínàti àfọ̀ṣẹ èké nípa yína yóò gbé e lé àwọn ọrùnènìyàn búburú ti a ó pa,àwọn tí ọjọ́ wọn ti dé,àwọn tí ọjọ́ ìjìyà wọn ti dé góńgó. 30 “ ‘Dá idà padà sínú àkọ̀ rẹ̀.Níbi tí a gbé ṣẹ̀dá yín,ní ibi tí ẹ̀yin ti ṣẹ̀ wá. 31 Níbẹ̀ ni èmi yóò ti ṣe ìdájọ́ yín,èmi o sì fi èémí ìbínú gbígbónámi bá yín jà. 32 Ẹ̀yin yóò jẹ́ èpò fún iná náà,a yóò ta ẹ̀jẹ̀ yin sórí ilẹ̀ yín,a kì yóò rántí yín mọ́;nítorí Èmi OLÚWA ní ó ti wí bẹ́ẹ̀.’ ”

In Other Versions

Ezekiel 21 in the ANGEFD

Ezekiel 21 in the ANTPNG2D

Ezekiel 21 in the AS21

Ezekiel 21 in the BAGH

Ezekiel 21 in the BBPNG

Ezekiel 21 in the BBT1E

Ezekiel 21 in the BDS

Ezekiel 21 in the BEV

Ezekiel 21 in the BHAD

Ezekiel 21 in the BIB

Ezekiel 21 in the BLPT

Ezekiel 21 in the BNT

Ezekiel 21 in the BNTABOOT

Ezekiel 21 in the BNTLV

Ezekiel 21 in the BOATCB

Ezekiel 21 in the BOATCB2

Ezekiel 21 in the BOBCV

Ezekiel 21 in the BOCNT

Ezekiel 21 in the BOECS

Ezekiel 21 in the BOGWICC

Ezekiel 21 in the BOHCB

Ezekiel 21 in the BOHCV

Ezekiel 21 in the BOHLNT

Ezekiel 21 in the BOHNTLTAL

Ezekiel 21 in the BOICB

Ezekiel 21 in the BOILNTAP

Ezekiel 21 in the BOITCV

Ezekiel 21 in the BOKCV

Ezekiel 21 in the BOKCV2

Ezekiel 21 in the BOKHWOG

Ezekiel 21 in the BOKSSV

Ezekiel 21 in the BOLCB

Ezekiel 21 in the BOLCB2

Ezekiel 21 in the BOMCV

Ezekiel 21 in the BONAV

Ezekiel 21 in the BONCB

Ezekiel 21 in the BONLT

Ezekiel 21 in the BONUT2

Ezekiel 21 in the BOPLNT

Ezekiel 21 in the BOSCB

Ezekiel 21 in the BOSNC

Ezekiel 21 in the BOTLNT

Ezekiel 21 in the BOVCB

Ezekiel 21 in the BPBB

Ezekiel 21 in the BPH

Ezekiel 21 in the BSB

Ezekiel 21 in the CCB

Ezekiel 21 in the CUV

Ezekiel 21 in the CUVS

Ezekiel 21 in the DBT

Ezekiel 21 in the DGDNT

Ezekiel 21 in the DHNT

Ezekiel 21 in the DNT

Ezekiel 21 in the ELBE

Ezekiel 21 in the EMTV

Ezekiel 21 in the ESV

Ezekiel 21 in the FBV

Ezekiel 21 in the FEB

Ezekiel 21 in the GGMNT

Ezekiel 21 in the GNT

Ezekiel 21 in the HARY

Ezekiel 21 in the HNT

Ezekiel 21 in the IRVA

Ezekiel 21 in the IRVB

Ezekiel 21 in the IRVG

Ezekiel 21 in the IRVH

Ezekiel 21 in the IRVK

Ezekiel 21 in the IRVM

Ezekiel 21 in the IRVM2

Ezekiel 21 in the IRVO

Ezekiel 21 in the IRVP

Ezekiel 21 in the IRVT

Ezekiel 21 in the IRVT2

Ezekiel 21 in the IRVU

Ezekiel 21 in the ISVN

Ezekiel 21 in the JSNT

Ezekiel 21 in the KAPI

Ezekiel 21 in the KBT1ETNIK

Ezekiel 21 in the KBV

Ezekiel 21 in the KJV

Ezekiel 21 in the KNFD

Ezekiel 21 in the LBA

Ezekiel 21 in the LBLA

Ezekiel 21 in the LNT

Ezekiel 21 in the LSV

Ezekiel 21 in the MAAL

Ezekiel 21 in the MBV

Ezekiel 21 in the MBV2

Ezekiel 21 in the MHNT

Ezekiel 21 in the MKNFD

Ezekiel 21 in the MNG

Ezekiel 21 in the MNT

Ezekiel 21 in the MNT2

Ezekiel 21 in the MRS1T

Ezekiel 21 in the NAA

Ezekiel 21 in the NASB

Ezekiel 21 in the NBLA

Ezekiel 21 in the NBS

Ezekiel 21 in the NBVTP

Ezekiel 21 in the NET2

Ezekiel 21 in the NIV11

Ezekiel 21 in the NNT

Ezekiel 21 in the NNT2

Ezekiel 21 in the NNT3

Ezekiel 21 in the PDDPT

Ezekiel 21 in the PFNT

Ezekiel 21 in the RMNT

Ezekiel 21 in the SBIAS

Ezekiel 21 in the SBIBS

Ezekiel 21 in the SBIBS2

Ezekiel 21 in the SBICS

Ezekiel 21 in the SBIDS

Ezekiel 21 in the SBIGS

Ezekiel 21 in the SBIHS

Ezekiel 21 in the SBIIS

Ezekiel 21 in the SBIIS2

Ezekiel 21 in the SBIIS3

Ezekiel 21 in the SBIKS

Ezekiel 21 in the SBIKS2

Ezekiel 21 in the SBIMS

Ezekiel 21 in the SBIOS

Ezekiel 21 in the SBIPS

Ezekiel 21 in the SBISS

Ezekiel 21 in the SBITS

Ezekiel 21 in the SBITS2

Ezekiel 21 in the SBITS3

Ezekiel 21 in the SBITS4

Ezekiel 21 in the SBIUS

Ezekiel 21 in the SBIVS

Ezekiel 21 in the SBT

Ezekiel 21 in the SBT1E

Ezekiel 21 in the SCHL

Ezekiel 21 in the SNT

Ezekiel 21 in the SUSU

Ezekiel 21 in the SUSU2

Ezekiel 21 in the SYNO

Ezekiel 21 in the TBIAOTANT

Ezekiel 21 in the TBT1E

Ezekiel 21 in the TBT1E2

Ezekiel 21 in the TFTIP

Ezekiel 21 in the TFTU

Ezekiel 21 in the TGNTATF3T

Ezekiel 21 in the THAI

Ezekiel 21 in the TNFD

Ezekiel 21 in the TNT

Ezekiel 21 in the TNTIK

Ezekiel 21 in the TNTIL

Ezekiel 21 in the TNTIN

Ezekiel 21 in the TNTIP

Ezekiel 21 in the TNTIZ

Ezekiel 21 in the TOMA

Ezekiel 21 in the TTENT

Ezekiel 21 in the UBG

Ezekiel 21 in the UGV

Ezekiel 21 in the UGV2

Ezekiel 21 in the UGV3

Ezekiel 21 in the VBL

Ezekiel 21 in the VDCC

Ezekiel 21 in the YALU

Ezekiel 21 in the YAPE

Ezekiel 21 in the YBVTP

Ezekiel 21 in the ZBP