Leviticus 2 (BOYCB)

1 “ ‘Bí ẹnìkan bá mú ọrẹ ẹbọ ohun jíjẹ wá fún OLÚWA ọrẹ rẹ̀ gbọdọ̀ jẹ́ ìyẹ̀fun dáradára, kí ó da òróró sí i, kí o sì fi tùràrí sí i, 2 kí ó sì gbé lọ fún àwọn ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà. Àlùfáà yóò bu ẹ̀kúnwọ́ kan nínú ìyẹ̀fun àti òróró náà, pẹ̀lú gbogbo tùràrí kí ó sì sun ún gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìrántí lórí pẹpẹ, ọrẹ tí a fi iná ṣe, àní òórùn dídùn sí OLÚWA. 3 Ìyókù nínú ọrẹ ohun jíjẹ náà jẹ́ ti Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀, ó jẹ́ ìpín tí ó mọ́ jùlọ nínú ọrẹ tí a fi iná sun sí OLÚWA. 4 “ ‘Bí ẹ bá mú ọrẹ ohun jíjẹ, èyí tí a yan lórí ààrò iná, kí ó jẹ́ ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára, àkàrà tí a ṣe láìní ìwúkàrà, tí a sì fi òróró pò àti àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí a ṣe láìní ìwúkàrà èyí tí a fi òróró pò. 5 Bí ọrẹ ẹbọ rẹ bá jẹ́ inú àwo pẹẹrẹ ni o ti ṣe ohun jíjẹ rẹ, kí ó jẹ́ ìyẹ̀fun dáradára tí a fi òróró pò, kò sì gbọdọ̀ ní ìwúkàrà. 6 Rún un kí o sì da òróró sí i lórí, ọrẹ ohun jíjẹ ni. 7 Bí ọrẹ ẹbọ rẹ bá jẹ́ ẹbọ ohun jíjẹ, tí a yan nínú apẹ, ìyẹ̀fun dáradára ni kí o fi ṣè é pẹ̀lú òróró. 8 Mú ọrẹ ohun jíjẹ tí a fi àwọn nǹkan wọ̀nyí ṣe wá fún OLÚWA gbé e fún àlùfáà, ẹni tí yóò gbe e lọ sí ibi pẹpẹ. 9 Àlùfáà yóò sì mú ẹbọ ìrántí nínú ọrẹ ohun jíjẹ yìí, yóò sì sun ún lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ tí a fi iná sun, àní òórùn dídùn sí OLÚWA. 10 Ìyókù nínú ọrẹ ohun jíjẹ yìí jẹ́ ti Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀, ó jẹ́ èyí tí ó mọ́ jùlọ nínú ọrẹ tí a fi iná sun sí OLÚWA. 11 “ ‘Gbogbo ọrẹ ohun jíjẹ tí ẹ bá mú wá fún OLÚWA kò gbọdọ̀ ní ìwúkàrà nínú, nítorí pé ẹ kò gbọdọ̀ sun ohun wíwú tàbí oyin nínú ọrẹ tí ẹ fi iná sun sí OLÚWA. 12 Ẹ lè mú wọn wá fún OLÚWA gẹ́gẹ́ bí ọrẹ àkọ́so ṣùgbọ́n ẹ kò gbọdọ̀ mú wọn wá sórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí òórùn dídùn. 13 Ẹ fi iyọ̀ dun gbogbo ọrẹ ohun jíjẹ yín. Ẹ má ṣe aláìfi iyọ̀ májẹ̀mú Ọlọ́run yín sínú àwọn ọrẹ ohun jíjẹ yín, ẹ fi iyọ̀ sí gbogbo ọrẹ yín. 14 “ ‘Bí ẹ bá mú ọrẹ ohun jíjẹ ti àkọ́so oko yín wá fún OLÚWA kí ẹ mú ọkà tuntun tí a fi iná yan. 15 Kí ẹ da òróró lé e lórí, kí ẹ sì fi tùràrí sí i, ó jẹ́ ọrẹ ohun jíjẹ. 16 Àlùfáà yóò sun ẹbọ ìrántí lára ọkà àti òróró náà, pẹ̀lú gbogbo tùràrí gẹ́gẹ́ bí ọrẹ tí a fi iná sun sí OLÚWA.

In Other Versions

Leviticus 2 in the ANGEFD

Leviticus 2 in the ANTPNG2D

Leviticus 2 in the AS21

Leviticus 2 in the BAGH

Leviticus 2 in the BBPNG

Leviticus 2 in the BBT1E

Leviticus 2 in the BDS

Leviticus 2 in the BEV

Leviticus 2 in the BHAD

Leviticus 2 in the BIB

Leviticus 2 in the BLPT

Leviticus 2 in the BNT

Leviticus 2 in the BNTABOOT

Leviticus 2 in the BNTLV

Leviticus 2 in the BOATCB

Leviticus 2 in the BOATCB2

Leviticus 2 in the BOBCV

Leviticus 2 in the BOCNT

Leviticus 2 in the BOECS

Leviticus 2 in the BOGWICC

Leviticus 2 in the BOHCB

Leviticus 2 in the BOHCV

Leviticus 2 in the BOHLNT

Leviticus 2 in the BOHNTLTAL

Leviticus 2 in the BOICB

Leviticus 2 in the BOILNTAP

Leviticus 2 in the BOITCV

Leviticus 2 in the BOKCV

Leviticus 2 in the BOKCV2

Leviticus 2 in the BOKHWOG

Leviticus 2 in the BOKSSV

Leviticus 2 in the BOLCB

Leviticus 2 in the BOLCB2

Leviticus 2 in the BOMCV

Leviticus 2 in the BONAV

Leviticus 2 in the BONCB

Leviticus 2 in the BONLT

Leviticus 2 in the BONUT2

Leviticus 2 in the BOPLNT

Leviticus 2 in the BOSCB

Leviticus 2 in the BOSNC

Leviticus 2 in the BOTLNT

Leviticus 2 in the BOVCB

Leviticus 2 in the BPBB

Leviticus 2 in the BPH

Leviticus 2 in the BSB

Leviticus 2 in the CCB

Leviticus 2 in the CUV

Leviticus 2 in the CUVS

Leviticus 2 in the DBT

Leviticus 2 in the DGDNT

Leviticus 2 in the DHNT

Leviticus 2 in the DNT

Leviticus 2 in the ELBE

Leviticus 2 in the EMTV

Leviticus 2 in the ESV

Leviticus 2 in the FBV

Leviticus 2 in the FEB

Leviticus 2 in the GGMNT

Leviticus 2 in the GNT

Leviticus 2 in the HARY

Leviticus 2 in the HNT

Leviticus 2 in the IRVA

Leviticus 2 in the IRVB

Leviticus 2 in the IRVG

Leviticus 2 in the IRVH

Leviticus 2 in the IRVK

Leviticus 2 in the IRVM

Leviticus 2 in the IRVM2

Leviticus 2 in the IRVO

Leviticus 2 in the IRVP

Leviticus 2 in the IRVT

Leviticus 2 in the IRVT2

Leviticus 2 in the IRVU

Leviticus 2 in the ISVN

Leviticus 2 in the JSNT

Leviticus 2 in the KAPI

Leviticus 2 in the KBT1ETNIK

Leviticus 2 in the KBV

Leviticus 2 in the KJV

Leviticus 2 in the KNFD

Leviticus 2 in the LBA

Leviticus 2 in the LBLA

Leviticus 2 in the LNT

Leviticus 2 in the LSV

Leviticus 2 in the MAAL

Leviticus 2 in the MBV

Leviticus 2 in the MBV2

Leviticus 2 in the MHNT

Leviticus 2 in the MKNFD

Leviticus 2 in the MNG

Leviticus 2 in the MNT

Leviticus 2 in the MNT2

Leviticus 2 in the MRS1T

Leviticus 2 in the NAA

Leviticus 2 in the NASB

Leviticus 2 in the NBLA

Leviticus 2 in the NBS

Leviticus 2 in the NBVTP

Leviticus 2 in the NET2

Leviticus 2 in the NIV11

Leviticus 2 in the NNT

Leviticus 2 in the NNT2

Leviticus 2 in the NNT3

Leviticus 2 in the PDDPT

Leviticus 2 in the PFNT

Leviticus 2 in the RMNT

Leviticus 2 in the SBIAS

Leviticus 2 in the SBIBS

Leviticus 2 in the SBIBS2

Leviticus 2 in the SBICS

Leviticus 2 in the SBIDS

Leviticus 2 in the SBIGS

Leviticus 2 in the SBIHS

Leviticus 2 in the SBIIS

Leviticus 2 in the SBIIS2

Leviticus 2 in the SBIIS3

Leviticus 2 in the SBIKS

Leviticus 2 in the SBIKS2

Leviticus 2 in the SBIMS

Leviticus 2 in the SBIOS

Leviticus 2 in the SBIPS

Leviticus 2 in the SBISS

Leviticus 2 in the SBITS

Leviticus 2 in the SBITS2

Leviticus 2 in the SBITS3

Leviticus 2 in the SBITS4

Leviticus 2 in the SBIUS

Leviticus 2 in the SBIVS

Leviticus 2 in the SBT

Leviticus 2 in the SBT1E

Leviticus 2 in the SCHL

Leviticus 2 in the SNT

Leviticus 2 in the SUSU

Leviticus 2 in the SUSU2

Leviticus 2 in the SYNO

Leviticus 2 in the TBIAOTANT

Leviticus 2 in the TBT1E

Leviticus 2 in the TBT1E2

Leviticus 2 in the TFTIP

Leviticus 2 in the TFTU

Leviticus 2 in the TGNTATF3T

Leviticus 2 in the THAI

Leviticus 2 in the TNFD

Leviticus 2 in the TNT

Leviticus 2 in the TNTIK

Leviticus 2 in the TNTIL

Leviticus 2 in the TNTIN

Leviticus 2 in the TNTIP

Leviticus 2 in the TNTIZ

Leviticus 2 in the TOMA

Leviticus 2 in the TTENT

Leviticus 2 in the UBG

Leviticus 2 in the UGV

Leviticus 2 in the UGV2

Leviticus 2 in the UGV3

Leviticus 2 in the VBL

Leviticus 2 in the VDCC

Leviticus 2 in the YALU

Leviticus 2 in the YAPE

Leviticus 2 in the YBVTP

Leviticus 2 in the ZBP