Psalms 136 (BOYCB)
1 Ẹ fi ọpẹ́ fún OLÚWA nítorí tí ó ṣeun;nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. 2 Ẹ fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run àwọn ọlọ́run:nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. 3 Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa àwọn olúwa,nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. 4 Fún Òun nìkan tí ń ṣiṣẹ́ ìyanu ńlá;nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. 5 Fún ẹni tí ó fi ọgbọ́n dá ọ̀run;nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. 6 Fún ẹni tí ó tẹ́ ilẹ̀ lórí omi;nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. 7 Fún ẹni tí ó dá àwọn ìmọ́lẹ̀ ńlá;nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. 8 Òòrùn láti jẹ ọba ọ̀sán;nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. 9 Òṣùpá àti ìràwọ̀ láti jẹ ọba òru;nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. 10 Fún ẹni tí ó kọlu Ejibiti lára àwọn àkọ́bí wọn;nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. 11 Ó sì mú Israẹli jáde kúrò láàrín wọn;nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. 12 Pẹ̀lú ọwọ́ agbára àti apá nínà;nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. 13 Fún ẹni tí ó pín Òkun pupa ní ìyà;nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. 14 Ó sì mú Israẹli kọjá láàrín rẹ̀nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. 15 Ṣùgbọ́n ó bi Farao àti ogun rẹ̀ ṣubú nínú Òkun pupa;nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. 16 Fún ẹni tí ó sin àwọn ènìyàn rẹ̀ la aginjù jánítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. 17 Fún ẹni tí ó kọlu àwọn ọba ńlá;nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. 18 Ó sì pa àwọn ọba olókìkínítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. 19 Sihoni, ọba àwọn ará Amorinítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. 20 Àti Ogu, ọba Baṣani;nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. 21 Ó sì fi ilẹ̀ wọn fún ni ní ìní,nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. 22 Ìní fún Israẹli, ìránṣẹ́ rẹ̀,nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. 23 Ẹni tí ó rántí wa ní ìwà ìrẹ̀lẹ̀ wa;nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. 24 Ó sì dá wa ní ìdè lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa;nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. 25 Ẹni tí ó fi oúnjẹ fún àwọn ẹ̀dá gbogbonítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. 26 Ẹ fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run ọ̀run;nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.