1 Kings 2 (BOYCB)

1 Nígbà tí ọjọ́ ikú Dafidi súnmọ́ etílé, ó pàṣẹ fún Solomoni ọmọ rẹ̀. 2 Ó sì wí pé, “Èmi ti fẹ́ lọ sí ọ̀nà gbogbo ayé, nítorí náà jẹ́ alágbára kí o sì fi ara rẹ hàn bí ọkùnrin, 3 kí o sì wòye ohun tí OLÚWA Ọlọ́run rẹ béèrè, rìn ní ọ̀nà rẹ̀, kí o sì pa àṣẹ àti òfin rẹ̀ mọ́, àti ìdájọ́ rẹ, àti ẹ̀rí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé òfin Mose, nítorí kí ìwọ kí ó le è máa ṣe rere ní ohun gbogbo tí ìwọ ṣe, àti ní ibikíbi tí ìwọ bá lọ, 4 kí OLÚWA kí ó lè pa ìlérí rẹ̀ tí ó sọ nípa tèmi mọ́ pé, ‘Bí àwọn ọmọ rẹ bá kíyèsi ọ̀nà wọn, tí wọ́n bá sì fi gbogbo àyà wọn àti ọkàn wọn rìn níwájú mi ní òtítọ́, o kì yóò sì kùnà láti ní ọkùnrin kan lórí ìtẹ́ Israẹli.’ 5 “Ìwọ pẹ̀lú sì mọ ohun tí Joabu ọmọ Seruiah ṣe sí mi àti ohun tí ó ṣe sí balógun méjì nínú àwọn ológun Israẹli, sí Abneri ọmọ Neri àti sí Amasa ọmọ Jeteri. Ó sì pa wọ́n, ó sì ta ẹ̀jẹ̀ wọn sílẹ̀ ní ìgbà àlàáfíà bí í ti ojú ogun ó sì fi ẹ̀jẹ̀ náà sí ara àmùrè rẹ̀ tí ń bẹ ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, àti sí ara sálúbàtà rẹ̀ tí ń bẹ ní ẹsẹ̀ rẹ̀. 6 Ṣe sí í gẹ́gẹ́ bí ọgbọ́n rẹ̀, ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí ewú orí rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí isà òkú ní àlàáfíà. 7 “Ṣùgbọ́n fi inú rere hàn sí àwọn ọmọ Barsillai, ti Gileadi, jẹ́ kí wọn wà lára àwọn tí ó ń jẹun lórí tábìlì rẹ̀. Wọ́n dúró tì mí nígbà tí mo sá kúrò níwájú Absalomu arákùnrin rẹ. 8 “Àti kí o rántí, Ṣimei ọmọ Gera ẹ̀yà Benjamini tí Bahurimu wà pẹ̀lú rẹ̀, tí ó bú mi ní èébú tí ó korò ní ọjọ́ tí mo lọ sí Mahanaimu. Nígbà tí ó sọ̀kalẹ̀ wá pàdé mi ní Jordani, mo fi OLÚWA búra fún un pé, ‘Èmi kì yóò fi idà pa ọ́.’ 9 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, má ṣe kíyèsi í gẹ́gẹ́ bí aláìlẹ́ṣẹ̀, ọkùnrin ọlọ́gbọ́n ni ìwọ ṣe; ìwọ yóò mọ ohun tí ìwọ yóò ṣe sí i. Mú ewú orí rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sínú isà òkú pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀.” 10 Nígbà náà ni Dafidi sinmi pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín ní ìlú Dafidi. 11 Dafidi ti jẹ ọba lórí Israẹli ní ogójì ọdún, ọdún méje ni Hebroni àti ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n ní Jerusalẹmu. 12 Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi baba rẹ̀, ìjọba rẹ̀ sì fi ìdí múlẹ̀ gidigidi. 13 Wàyí, Adonijah ọmọ Haggiti tọ Batṣeba, ìyá Solomoni wá. Batṣeba sì bi í pé, “Àlàáfíà ni o bá wa bí?”Ó sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, àlàáfíà ni.” 14 Nígbà náà ni ó sì fi kún un pé, “Mo ní ohun kan láti sọ fún ọ.”Batṣeba sì wí pé, “Máa wí.” 15 Ó wí pé, “Gẹ́gẹ́ bí o ti mọ̀, ti tèmi ni ìjọba náà. Gbogbo Israẹli ti wò mí bí ọba wọn. Ṣùgbọ́n nǹkan yípadà, ìjọba náà sì ti lọ sí ọ̀dọ̀ arákùnrin mi, nítorí ó ti wá sọ́dọ̀ rẹ̀ láti ọwọ́ OLÚWA wá. 16 Nísinsin yìí mo ní ìbéèrè kan láti bi ọ́, má ṣe kọ̀ fún mi.”Ó wí pé, “O lè wí.” 17 Bẹ́ẹ̀ ni ó sì tẹ̀síwájú pé, “Mo bẹ̀ ọ́, jọ̀wọ́ sọ fún Solomoni ọba (òun kì yóò kọ̀ fún ọ́) kí ó fún mi ní Abiṣagi ará Ṣunemu ní aya.” 18 Batṣeba sì dáhùn pé, “Ó dára èmi yóò bá ọba sọ̀rọ̀ nítorí rẹ̀.” 19 Nígbà tí Batṣeba sì tọ Solomoni ọba lọ láti bá a sọ̀rọ̀ nítorí Adonijah, ọba sì dìde láti pàdé rẹ̀, ó sì tẹríba fún un, ó sì jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀. Ó sì tẹ́ ìtẹ́ kan fún ìyá ọba, ó sì jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀. 20 Ó sì wí pé, “Mo ní ìbéèrè kékeré kan láti béèrè lọ́wọ́ rẹ, má ṣe kọ̀ fún mi.”Ọba sì dáhùn wí pé, “Béèrè, ìyá mi; èmi kì yóò kọ̀ ọ́.” 21 Nígbà náà ni ó wí pé, “Jẹ́ kí a fi Abiṣagi ará Ṣunemu fún Adonijah arákùnrin rẹ ní aya.” 22 Solomoni ọba sì dá ìyá rẹ̀ lóhùn pé, “Èéṣe tí ìwọ fi béèrè Abiṣagi ará Ṣunemu fún Adonijah! Ìwọ ìbá sì béèrè ìjọba fún un pẹ̀lú nítorí ẹ̀gbọ́n mi ní í ṣe, fún òun pàápàá àti fún Abiatari àlùfáà àti fun Joabu ọmọ Seruiah!” 23 Nígbà náà ni Solomoni ọba fi OLÚWA búra pé, “Kí Ọlọ́run ki ó jẹ mí ní yà, àti jù bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú, bí Adonijah kò bá ní fi ẹ̀mí rẹ̀ san ìbéèrè yìí! 24 Àti nísinsin yìí, bí ó ti dájú pé OLÚWA wà láààyè, ẹni tí ó ti mú mi jókòó lórí ìtẹ́ baba mi Dafidi, àti tí ó sì ti kọ́ ilé fún mi bí ó ti ṣèlérí, lónìí ni a ó pa Adonijah!” 25 Solomoni ọba sì pàṣẹ fún Benaiah ọmọ Jehoiada, ó sì kọlu Adonijah, ó sì kú. 26 Ọba sì wí fún Abiatari àlùfáà pé, “Padà lọ sí pápá rẹ ni Anatoti, ó yẹ fún ọ láti kú, ṣùgbọ́n èmi kì yóò pa ọ́ nísinsin yìí, nítorí o ti gbé àpótí ẹ̀rí OLÚWA Olódùmarè níwájú Dafidi baba mi, o sì ti ní ìpín nínú gbogbo ìyà tí baba mi jẹ.” 27 Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni yọ Abiatari kúrò nínú iṣẹ́ àlùfáà OLÚWA, kí ó lè mú ọ̀rọ̀ OLÚWA tí ó ti sọ nípa ilé Eli ní Ṣilo ṣẹ. 28 Nígbà tí ìròyìn sì dé ọ̀dọ̀ Joabu, ẹni tí ó ti dìtẹ̀ pẹ̀lú Adonijah bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò wà pẹ̀lú Absalomu, ó sì sálọ sínú àgọ́ OLÚWA, ó sì di ìwo pẹpẹ mú. 29 A sì sọ fún Solomoni ọba pé Joabu ti sálọ sínú àgọ́ OLÚWA àti pé ó wà ní ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ. Nígbà náà ni Solomoni pàṣẹ fún Benaiah ọmọ Jehoiada pé, “Lọ, kí o sì kọlù ú.” 30 Benaiah sì wọ inú àgọ́ OLÚWA, ó sì wí fún Joabu pé, “Ọba sọ wí pé, ‘Jáde wá.’ ”Ṣùgbọ́n ó dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, èmi yóò kú níhìn-ín.”Benaiah sì mú èsì fún ọba, “Báyìí ni Joabu ṣe dá mi lóhùn.” 31 Ọba sì pàṣẹ fún Benaiah pé, “Ṣe bí ó ti wí. Kọlù ú, kí o sì sin ín, kí o sì mú ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ mi àti kúrò lọ́dọ̀ ilé baba mi, tí Joabu ti ta sílẹ̀. 32 OLÚWA yóò sì san ẹ̀jẹ̀ tí ó ti ta sílẹ̀ padà fún un, nítorí tí ó kọlu ọkùnrin méjì, ó sì fi idà rẹ̀ pa wọ́n, Dafidi baba mi kò sì mọ̀. Àwọn méjèèjì ni Abneri ọmọ Neri olórí ogun Israẹli, àti Amasa ọmọ Jeteri olórí ogun Juda, wọ́n jẹ́ olódodo, wọ́n sì sàn ju òun fúnra rẹ̀ lọ. 33 Kí ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ wọn wá sórí Joabu àti sórí irú-ọmọ rẹ̀ títí láé. Ṣùgbọ́n sórí Dafidi àti irú-ọmọ rẹ̀, sí ilé rẹ̀ àti sí ìtẹ́ rẹ̀, ni kí àlàáfíà OLÚWA wà títí láé.” 34 Bẹ́ẹ̀ ni Benaiah ọmọ Jehoiada sì gòkè lọ, ó sì kọlu Joabu, ó sì pa á, a sì sin ín ní ilẹ̀ ibojì ara rẹ̀ ní aginjù. 35 Ọba sì fi Benaiah ọmọ Jehoiada jẹ olórí ogun ní ipò Joabu àti Sadoku àlùfáà ní ipò Abiatari. 36 Nígbà náà ni ọba ránṣẹ́ sí Ṣimei, ó sì wí fún un pé, “Kọ́ ilé fún ara rẹ ní Jerusalẹmu, kí o sì máa gbé ibẹ̀, ṣùgbọ́n kí o má sì ṣe lọ sí ibòmíràn. 37 Ọjọ́ tí ìwọ bá jáde, tí o sì kọjá àfonífojì Kidironi, kí ìwọ kí ó mọ̀ dájúdájú pé ìwọ yóò kú; ẹ̀jẹ̀ rẹ yóò sì wà lórí ara rẹ.” 38 Ṣimei sì dá ọba lóhùn pé, “Ohun tí ìwọ sọ dára. Ìránṣẹ́ rẹ yóò ṣe bí olúwa mi ọba ti wí.” Ṣimei sì gbé ní Jerusalẹmu fún ìgbà pípẹ́. 39 Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ọdún mẹ́ta, àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ Ṣimei méjì sì sálọ sọ́dọ̀ Akiṣi ọmọ Maaka, ọba Gati, a sì sọ fún Ṣimei pé, “Àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ méjì wà ní Gati.” 40 Fún ìdí èyí, ó sì di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní gàárì, ó sì lọ sọ́dọ̀ Akiṣi ní Gati láti wá àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni Ṣimei sì lọ, ó sì mú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ padà bọ̀ láti Gati. 41 Nígbà tí a sì sọ fún Solomoni pé Ṣimei ti lọ láti Jerusalẹmu sí Gati, ó sì ti padà. 42 Ọba pe Ṣimei lẹ́jọ́, ó wí fún un pé, “Ǹjẹ́ èmi kò ti mú ọ búra ní ti OLÚWA, èmi sì ti kìlọ̀ fún ọ pé, ‘Ní ọjọ́ tí ìwọ bá kúrò láti lọ sí ibikíbi, kí o mọ̀ dájú pé ìwọ yóò kú.’ Nígbà náà ni ìwọ sì sọ fún mi pé, ‘Ohun tí ìwọ sọ dára. Èmi yóò ṣe ìgbọ́ràn.’ 43 Èéṣe, nígbà náà tí ìwọ kò pa ìbúra OLÚWA mọ́, àti kí o sì ṣe ìgbọ́ràn sí àṣẹ tí mo pa fún ọ?” 44 Ọba sì tún wí fún Ṣimei pé, “Ìwọ mọ̀ ní ọkàn rẹ gbogbo búburú tí ìwọ ti ṣe sí Dafidi baba mi. Báyìí, OLÚWA yóò san gbogbo ìṣe búburú rẹ padà fún ọ. 45 Ṣùgbọ́n a ó sì bùkún fún Solomoni ọba, ìtẹ́ Dafidi yóò sì wà láìfòyà níwájú OLÚWA títí láéláé.” 46 Nígbà náà ni ọba pàṣẹ fún Benaiah ọmọ Jehoiada, ó sì jáde lọ, ó sì kọlu Ṣimei, ó sì pa á.Ìjọba náà sì wá fi ìdí múlẹ̀ ní ọwọ́ Solomoni.

In Other Versions

1 Kings 2 in the ANGEFD

1 Kings 2 in the ANTPNG2D

1 Kings 2 in the AS21

1 Kings 2 in the BAGH

1 Kings 2 in the BBPNG

1 Kings 2 in the BBT1E

1 Kings 2 in the BDS

1 Kings 2 in the BEV

1 Kings 2 in the BHAD

1 Kings 2 in the BIB

1 Kings 2 in the BLPT

1 Kings 2 in the BNT

1 Kings 2 in the BNTABOOT

1 Kings 2 in the BNTLV

1 Kings 2 in the BOATCB

1 Kings 2 in the BOATCB2

1 Kings 2 in the BOBCV

1 Kings 2 in the BOCNT

1 Kings 2 in the BOECS

1 Kings 2 in the BOGWICC

1 Kings 2 in the BOHCB

1 Kings 2 in the BOHCV

1 Kings 2 in the BOHLNT

1 Kings 2 in the BOHNTLTAL

1 Kings 2 in the BOICB

1 Kings 2 in the BOILNTAP

1 Kings 2 in the BOITCV

1 Kings 2 in the BOKCV

1 Kings 2 in the BOKCV2

1 Kings 2 in the BOKHWOG

1 Kings 2 in the BOKSSV

1 Kings 2 in the BOLCB

1 Kings 2 in the BOLCB2

1 Kings 2 in the BOMCV

1 Kings 2 in the BONAV

1 Kings 2 in the BONCB

1 Kings 2 in the BONLT

1 Kings 2 in the BONUT2

1 Kings 2 in the BOPLNT

1 Kings 2 in the BOSCB

1 Kings 2 in the BOSNC

1 Kings 2 in the BOTLNT

1 Kings 2 in the BOVCB

1 Kings 2 in the BPBB

1 Kings 2 in the BPH

1 Kings 2 in the BSB

1 Kings 2 in the CCB

1 Kings 2 in the CUV

1 Kings 2 in the CUVS

1 Kings 2 in the DBT

1 Kings 2 in the DGDNT

1 Kings 2 in the DHNT

1 Kings 2 in the DNT

1 Kings 2 in the ELBE

1 Kings 2 in the EMTV

1 Kings 2 in the ESV

1 Kings 2 in the FBV

1 Kings 2 in the FEB

1 Kings 2 in the GGMNT

1 Kings 2 in the GNT

1 Kings 2 in the HARY

1 Kings 2 in the HNT

1 Kings 2 in the IRVA

1 Kings 2 in the IRVB

1 Kings 2 in the IRVG

1 Kings 2 in the IRVH

1 Kings 2 in the IRVK

1 Kings 2 in the IRVM

1 Kings 2 in the IRVM2

1 Kings 2 in the IRVO

1 Kings 2 in the IRVP

1 Kings 2 in the IRVT

1 Kings 2 in the IRVT2

1 Kings 2 in the IRVU

1 Kings 2 in the ISVN

1 Kings 2 in the JSNT

1 Kings 2 in the KAPI

1 Kings 2 in the KBT1ETNIK

1 Kings 2 in the KBV

1 Kings 2 in the KJV

1 Kings 2 in the KNFD

1 Kings 2 in the LBA

1 Kings 2 in the LBLA

1 Kings 2 in the LNT

1 Kings 2 in the LSV

1 Kings 2 in the MAAL

1 Kings 2 in the MBV

1 Kings 2 in the MBV2

1 Kings 2 in the MHNT

1 Kings 2 in the MKNFD

1 Kings 2 in the MNG

1 Kings 2 in the MNT

1 Kings 2 in the MNT2

1 Kings 2 in the MRS1T

1 Kings 2 in the NAA

1 Kings 2 in the NASB

1 Kings 2 in the NBLA

1 Kings 2 in the NBS

1 Kings 2 in the NBVTP

1 Kings 2 in the NET2

1 Kings 2 in the NIV11

1 Kings 2 in the NNT

1 Kings 2 in the NNT2

1 Kings 2 in the NNT3

1 Kings 2 in the PDDPT

1 Kings 2 in the PFNT

1 Kings 2 in the RMNT

1 Kings 2 in the SBIAS

1 Kings 2 in the SBIBS

1 Kings 2 in the SBIBS2

1 Kings 2 in the SBICS

1 Kings 2 in the SBIDS

1 Kings 2 in the SBIGS

1 Kings 2 in the SBIHS

1 Kings 2 in the SBIIS

1 Kings 2 in the SBIIS2

1 Kings 2 in the SBIIS3

1 Kings 2 in the SBIKS

1 Kings 2 in the SBIKS2

1 Kings 2 in the SBIMS

1 Kings 2 in the SBIOS

1 Kings 2 in the SBIPS

1 Kings 2 in the SBISS

1 Kings 2 in the SBITS

1 Kings 2 in the SBITS2

1 Kings 2 in the SBITS3

1 Kings 2 in the SBITS4

1 Kings 2 in the SBIUS

1 Kings 2 in the SBIVS

1 Kings 2 in the SBT

1 Kings 2 in the SBT1E

1 Kings 2 in the SCHL

1 Kings 2 in the SNT

1 Kings 2 in the SUSU

1 Kings 2 in the SUSU2

1 Kings 2 in the SYNO

1 Kings 2 in the TBIAOTANT

1 Kings 2 in the TBT1E

1 Kings 2 in the TBT1E2

1 Kings 2 in the TFTIP

1 Kings 2 in the TFTU

1 Kings 2 in the TGNTATF3T

1 Kings 2 in the THAI

1 Kings 2 in the TNFD

1 Kings 2 in the TNT

1 Kings 2 in the TNTIK

1 Kings 2 in the TNTIL

1 Kings 2 in the TNTIN

1 Kings 2 in the TNTIP

1 Kings 2 in the TNTIZ

1 Kings 2 in the TOMA

1 Kings 2 in the TTENT

1 Kings 2 in the UBG

1 Kings 2 in the UGV

1 Kings 2 in the UGV2

1 Kings 2 in the UGV3

1 Kings 2 in the VBL

1 Kings 2 in the VDCC

1 Kings 2 in the YALU

1 Kings 2 in the YAPE

1 Kings 2 in the YBVTP

1 Kings 2 in the ZBP