1 Samuel 20 (BOYCB)

1 Nígbà náà ni Dafidi sá kúrò ní Naioti ti Rama ó sì lọ sọ́dọ̀ Jonatani ó sì béèrè pé, “Kí ni mo ṣe? Kí ni ẹ̀ṣẹ̀ mi? Báwo ni mo ṣe ṣẹ baba rẹ, tí ó sì ń wá ọ̀nà láti gba ẹ̀mí mi?” 2 Jonatani dáhùn pé, “Kí a má rí i! Ìwọ kò ní kú! Wò ó baba mi kì í ṣe ohunkóhun tí ó tóbi tàbí tí ó kéré, láìfi lọ̀ mí. Èéṣe tí yóò fi fi èyí pamọ́ fún mi? Kò rí bẹ́ẹ̀.” 3 Ṣùgbọ́n Dafidi tún búra, ó sì wí pé, “Baba rẹ mọ̀ dáradára pé mo rí ojúrere ní ojú rẹ, ó sì wí fún ara rẹ̀ pé, ‘Jonatani kò gbọdọ̀ mọ èyí yóò sì bà á nínú jẹ́.’ Síbẹ̀ nítòótọ́ bí OLÚWA ti wà láààyè àti gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti wà láààyè, ìgbésẹ̀ kan ni ó wà láàrín ìyè àti ikú.” 4 Jonatani wí fún Dafidi pé, “Ohunkóhun tí ìwọ bá ń fẹ́ kí èmi kí ó ṣe, èmi yóò ṣe é fún ọ.” 5 Dafidi sì wí fún Jonatani pé, “Wò ó, ọ̀la ni oṣù tuntun, mo sì gbọdọ̀ bá ọba jẹun, ṣùgbọ́n jẹ́ kí èmi kí ó lọ láti fi ara pamọ́ lórí pápá títí di àṣálẹ́ ọjọ́ kẹta. 6 Bí ó bá sì ṣe pé baba rẹ bá fẹ́ mi kù, kí o sì wí fún un pé, ‘Dafidi fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ béèrè ààyè láti sáré lọ sí Bẹtilẹhẹmu ìlú rẹ̀ nítorí wọ́n ń ṣe ẹbọ ọdọọdún ní ibẹ̀ fún gbogbo ìdílé rẹ̀.’ 7 Tí o bá wí pé, ‘Àlàáfíà ni,’ nígbà náà, ìránṣẹ́ rẹ wà láìléwu. Ṣùgbọ́n tí ó bá bínú gidigidi, ìwọ yóò mọ̀ dájú pé ó pinnu láti ṣe ìpalára mi. 8 Ṣùgbọ́n ní tìrẹ ìwọ, fi ojúrere wo ìránṣẹ́ rẹ; nítorí tí ìwọ ti bá a dá májẹ̀mú pẹ̀lú rẹ níwájú OLÚWA. Tí mo bá jẹ̀bi, pa mí fún ara rẹ! Èéṣe tí ìwọ yóò fi fi mí lé baba rẹ lọ́wọ́?” 9 Jonatani wí pé, “Kí a má rí i! Ti mo bá ti gbọ́ tí baba mi ti pinnu láti pa ọ́ lára, ṣé èmi kò ní sọ fún ọ?” 10 Nígbà náà ni Dafidi sì wí fún Jonatani pé, “Ta ni yóò sọ fún mi tí baba rẹ̀ bá dá ọ lóhùn ní ohùn líle?” 11 Jonatani wí fún Dafidi pé, “Wá, jẹ́ kí a jáde lọ sórí pápá.” Nígbà náà wọ́n sì jáde lọ. 12 Nígbà náà ni Jonatani wí fún Dafidi pé, “Mo fi OLÚWA Ọlọ́run àwọn Israẹli búra pé, èmi yóò rí i dájú pé mo gbọ́ ti ẹnu baba mi ní ìwòyí ọ̀la tàbí ní ọ̀túnla! Bí ó bá sì ní inú dídùn sí ọ, èmi yóò ránṣẹ́ sí ọ, èmi yóò sì jẹ́ kí o mọ̀? 13 Ṣùgbọ́n tí baba mi bá fẹ́ pa ọ́ lára, kí OLÚWA kí ó ṣe bẹ́ẹ̀ àti jù bẹ́ẹ̀ lọ sí Jonatani; tí èmi kò bá jẹ́ kí o mọ̀, kí n sì jẹ́ kí o lọ ní àlàáfíà. Kí OLÚWA kí ó wà pẹ̀lú rẹ gẹ́gẹ́ bí ó ti wà pẹ̀lú baba mi. 14 Ṣùgbọ́n fi àìkùnà inú rere hàn mí bí inú rere OLÚWA, níwọ́n ìgbà tí mo bá wà láààyè kí wọ́n má ba à pa mí. 15 Má ṣe ké àánú rẹ kúrò lórí ìdílé mi títí láé. Bí OLÚWA tilẹ̀ ké gbogbo ọ̀tá Dafidi kúrò lórí ilẹ̀.” 16 Nígbà náà ni Jonatani bá ilé Dafidi dá májẹ̀mú wí pé, “OLÚWA yóò pe àwọn àti Dafidi láti ṣírò.” 17 Jonatani mú kí Dafidi tún ìbúra ṣe nítorí ìfẹ́ tí ó ní sí i, nítorí tí ó fẹ́ ẹ gẹ́gẹ́ bí ó ti fẹ́ràn ara rẹ̀. 18 Nígbà náà ni Jonatani wí fún Dafidi pé, “Lọ́la ní ibi àsè ìbẹ̀rẹ̀ oṣù tuntun, a yóò fẹ́ ọ kù, nítorí ààyè rẹ yóò ṣófo. 19 Ní ọ̀túnla lọ́wọ́ alẹ́ lọ sí ibi tí o sá pamọ́ sí nígbà tí ìṣòro yìí bẹ̀rẹ̀, kí o sì dúró níbi òkúta Eselu. 20 Èmi yóò ta ọfà mẹ́ta sí ẹ̀gbẹ́ ibẹ̀, gẹ́gẹ́ bí i pé mo ta á sí àmì ibìkan. 21 Èmi yóò rán ọmọdékùnrin kan èmi yóò wí fún un wí pé, ‘Lọ, kí o lọ wá ọfà náà.’ Tí mo bá sọ fún un wí pé, ‘Wò ó, ọfà wọ̀nyí wà ní ibi báyìí ní ẹ̀gbẹ́ ẹ̀ rẹ; kó wọn wá síbí,’ kí o sì wá, nítorí pé, gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti wà ní ààyè, o wà ní àlàáfíà; kò sí ewu. 22 Ṣùgbọ́n tí mo bá sọ fún ọmọdékùnrin náà pé, ‘Wò ó, àwọn ọfà náà ń bẹ níwájú rẹ,’ ǹjẹ́ máa bá tìrẹ lọ, nítorí OLÚWA ni ó rán ọ lọ. 23 Nípa ọ̀rọ̀ tí èmi àti ìwọ jọ sọ, rántí OLÚWA jẹ́ ẹlẹ́rìí láàrín ìwọ àti èmi títí láéláé.” 24 Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi sá pamọ́ sínú pápá. Nígbà tí àsè ìbẹ̀rẹ̀ oṣù tuntun sì dé, ọba sì jókòó láti jẹun. 25 Ọba sì jókòó gẹ́gẹ́ bí ipò o rẹ̀ ní ibi tí ó máa ń jókòó lórí ìjókòó tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ògiri, ní òdìkejì Jonatani, Abneri sì jókòó ti Saulu, ṣùgbọ́n ààyè Dafidi sì ṣófo. 26 Saulu kò sọ nǹkan kan ní ọjọ́ náà, nítorí ó rò pé, “Nǹkan kan ti ṣẹlẹ̀ sí Dafidi láti jẹ́ kí ó di aláìmọ́ lóòtítọ́ ó jẹ́ aláìmọ́.” 27 Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ kejì, ní ọjọ́ kejì oṣù, ààyè Dafidi sì tún ṣófo. Nígbà náà ni Saulu wí fún ọmọ rẹ̀ Jonatani pé, “Kí ni ó dé tí ọmọ Jese kò fi wá sí ibi oúnjẹ, lánàá àti lónìí?” 28 Jonatani sì dáhùn pé, “Dafidi bẹ̀ mí tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ fún ààyè láti lọ sí Bẹtilẹhẹmu. 29 Ó wí pé, ‘Jẹ́ kí n lọ, nítorí pé ìdílé wa ń ṣe ìrúbọ ní ìlú, àwọn ẹ̀gbọ́n ọ̀n mi sì ti pàṣẹ fún mi láti wà níbẹ̀; tí èmi bá rí ojúrere ní ojú rẹ, jẹ́ kí n lọ láti lọ rí àwọn ẹ̀gbọ́n mi.’ Ìdí nìyìí tí kò fi wá sí orí tábìlì oúnjẹ ọba.” 30 Ìbínú Saulu sì ru sí Jonatani ó sì wí fún un pé, “Ìwọ ọmọ aláìgbọ́ràn àti ọlọ̀tẹ̀ búburú yìí, ṣé èmi kò ti mọ̀ pé, ìwọ ti yan ọmọ Jese fún ìtìjú ti ara rẹ àti fún ìtìjú màmá rẹ tí ó bí ọ? 31 Níwọ́n ìgbà tí ọmọ Jese bá wà láààyè lórí ilẹ̀ ayé, a kì yóò fi ẹsẹ̀ ìwọ tàbí ti ìjọba rẹ múlẹ̀. Nísinsin yìí ránṣẹ́ kí o sì lọ mú un wá fún mi, nítorí ó gbọdọ̀ kú!” 32 Jonatani béèrè lọ́wọ́ baba rẹ̀ pé, “Èéṣe tí àwa yóò fi pa á? Kí ni ó ṣe?” 33 Ṣùgbọ́n Saulu ju ọ̀kọ̀ rẹ̀ sí Jonatani láti gún un pa. Nígbà náà ni Jonatani mọ̀ pé baba rẹ̀ mọ̀ ọ́n mọ̀ fẹ́ pa Dafidi ni. 34 Bẹ́ẹ̀ ni Jonatani sì fi ìbínú dìde kúrò ni ibi oúnjẹ, kò sì jẹun ni ọjọ́ kejì oṣù náà, inú rẹ̀ sì bàjẹ́ gidigidi fún Dafidi, nítorí pé baba rẹ̀ dójútì í. 35 Ó sì ṣe, ní òwúrọ̀ ni Jonatani jáde lọ sí oko ní àkókò tí òun àti Dafidi ti fi àdéhùn sí, ọmọdékùnrin kan sì wá pẹ̀lú rẹ̀. 36 Ó si wí fún ọmọdékùnrin rẹ̀ pé, “Sáré, kí o si wá àwọn ọfà tí èmi ó ta.” Bí ọmọdé náà sì ti ń sáré, òun sì tafà rékọjá rẹ̀. 37 Nígbà tí ọmọdékùnrin náà sì dé ibi ọfà tí Jonatani ta, Jonatani sì kọ sí ọmọdékùnrin náà ó sì wí pé, “Ọfà náà kò ha wà níwájú rẹ bi?” 38 Jonatani sì kọ sí ọmọdékùnrin náà pé, “Sáré! Yára! Má ṣe dúró!” Ọmọdékùnrin Jonatani sì ṣa àwọn ọfà náà, ó sì tọ olúwa rẹ̀ wá. 39 (Ọmọdékùnrin náà kò sì mọ̀ nǹkan; ṣùgbọ́n Jonatani àti Dafidi ni ó mọ ọ̀ràn náà.) 40 Jonatani sì fi apó àti ọrun rẹ̀ fún ọmọdékùnrin rẹ̀, ó sì wí fún un pé, “Lọ, kí o sì mú wọn lọ sí ìlú.” 41 Bí ọmọdékùnrin náà ti lọ tán, Dafidi sì dìde láti ibi ìhà gúúsù òkúta náà, ó sì wólẹ̀, ó sì tẹríba ní ìdojúbolẹ̀ lẹ́ẹ̀mẹ́ta fún Jonatani, wọ́n sì fi ẹnu ko ara wọn lẹ́nu, wọ́n sì jùmọ̀ sọkún, èkínní pẹ̀lú èkejì rẹ̀, ṣùgbọ́n Dafidi sọkún púpọ̀ jù. 42 Jonatani sì wí fún Dafidi pé, “Máa lọ ní àlàáfíà, bí o ti jẹ́ pé àwa méjèèjì tí jùmọ̀ búra ni orúkọ OLÚWA pé, ‘Ki OLÚWA ó wà láàrín èmi àti ìwọ, láàrín irú-ọmọ mi àti láàrín irú-ọmọ rẹ̀ láéláé.’ ” Òun sì dìde, ó sì lọ kúrò: Jonatani sì lọ sí ìlú.

In Other Versions

1 Samuel 20 in the ANGEFD

1 Samuel 20 in the ANTPNG2D

1 Samuel 20 in the AS21

1 Samuel 20 in the BAGH

1 Samuel 20 in the BBPNG

1 Samuel 20 in the BBT1E

1 Samuel 20 in the BDS

1 Samuel 20 in the BEV

1 Samuel 20 in the BHAD

1 Samuel 20 in the BIB

1 Samuel 20 in the BLPT

1 Samuel 20 in the BNT

1 Samuel 20 in the BNTABOOT

1 Samuel 20 in the BNTLV

1 Samuel 20 in the BOATCB

1 Samuel 20 in the BOATCB2

1 Samuel 20 in the BOBCV

1 Samuel 20 in the BOCNT

1 Samuel 20 in the BOECS

1 Samuel 20 in the BOGWICC

1 Samuel 20 in the BOHCB

1 Samuel 20 in the BOHCV

1 Samuel 20 in the BOHLNT

1 Samuel 20 in the BOHNTLTAL

1 Samuel 20 in the BOICB

1 Samuel 20 in the BOILNTAP

1 Samuel 20 in the BOITCV

1 Samuel 20 in the BOKCV

1 Samuel 20 in the BOKCV2

1 Samuel 20 in the BOKHWOG

1 Samuel 20 in the BOKSSV

1 Samuel 20 in the BOLCB

1 Samuel 20 in the BOLCB2

1 Samuel 20 in the BOMCV

1 Samuel 20 in the BONAV

1 Samuel 20 in the BONCB

1 Samuel 20 in the BONLT

1 Samuel 20 in the BONUT2

1 Samuel 20 in the BOPLNT

1 Samuel 20 in the BOSCB

1 Samuel 20 in the BOSNC

1 Samuel 20 in the BOTLNT

1 Samuel 20 in the BOVCB

1 Samuel 20 in the BPBB

1 Samuel 20 in the BPH

1 Samuel 20 in the BSB

1 Samuel 20 in the CCB

1 Samuel 20 in the CUV

1 Samuel 20 in the CUVS

1 Samuel 20 in the DBT

1 Samuel 20 in the DGDNT

1 Samuel 20 in the DHNT

1 Samuel 20 in the DNT

1 Samuel 20 in the ELBE

1 Samuel 20 in the EMTV

1 Samuel 20 in the ESV

1 Samuel 20 in the FBV

1 Samuel 20 in the FEB

1 Samuel 20 in the GGMNT

1 Samuel 20 in the GNT

1 Samuel 20 in the HARY

1 Samuel 20 in the HNT

1 Samuel 20 in the IRVA

1 Samuel 20 in the IRVB

1 Samuel 20 in the IRVG

1 Samuel 20 in the IRVH

1 Samuel 20 in the IRVK

1 Samuel 20 in the IRVM

1 Samuel 20 in the IRVM2

1 Samuel 20 in the IRVO

1 Samuel 20 in the IRVP

1 Samuel 20 in the IRVT

1 Samuel 20 in the IRVT2

1 Samuel 20 in the IRVU

1 Samuel 20 in the ISVN

1 Samuel 20 in the JSNT

1 Samuel 20 in the KAPI

1 Samuel 20 in the KBT1ETNIK

1 Samuel 20 in the KBV

1 Samuel 20 in the KJV

1 Samuel 20 in the KNFD

1 Samuel 20 in the LBA

1 Samuel 20 in the LBLA

1 Samuel 20 in the LNT

1 Samuel 20 in the LSV

1 Samuel 20 in the MAAL

1 Samuel 20 in the MBV

1 Samuel 20 in the MBV2

1 Samuel 20 in the MHNT

1 Samuel 20 in the MKNFD

1 Samuel 20 in the MNG

1 Samuel 20 in the MNT

1 Samuel 20 in the MNT2

1 Samuel 20 in the MRS1T

1 Samuel 20 in the NAA

1 Samuel 20 in the NASB

1 Samuel 20 in the NBLA

1 Samuel 20 in the NBS

1 Samuel 20 in the NBVTP

1 Samuel 20 in the NET2

1 Samuel 20 in the NIV11

1 Samuel 20 in the NNT

1 Samuel 20 in the NNT2

1 Samuel 20 in the NNT3

1 Samuel 20 in the PDDPT

1 Samuel 20 in the PFNT

1 Samuel 20 in the RMNT

1 Samuel 20 in the SBIAS

1 Samuel 20 in the SBIBS

1 Samuel 20 in the SBIBS2

1 Samuel 20 in the SBICS

1 Samuel 20 in the SBIDS

1 Samuel 20 in the SBIGS

1 Samuel 20 in the SBIHS

1 Samuel 20 in the SBIIS

1 Samuel 20 in the SBIIS2

1 Samuel 20 in the SBIIS3

1 Samuel 20 in the SBIKS

1 Samuel 20 in the SBIKS2

1 Samuel 20 in the SBIMS

1 Samuel 20 in the SBIOS

1 Samuel 20 in the SBIPS

1 Samuel 20 in the SBISS

1 Samuel 20 in the SBITS

1 Samuel 20 in the SBITS2

1 Samuel 20 in the SBITS3

1 Samuel 20 in the SBITS4

1 Samuel 20 in the SBIUS

1 Samuel 20 in the SBIVS

1 Samuel 20 in the SBT

1 Samuel 20 in the SBT1E

1 Samuel 20 in the SCHL

1 Samuel 20 in the SNT

1 Samuel 20 in the SUSU

1 Samuel 20 in the SUSU2

1 Samuel 20 in the SYNO

1 Samuel 20 in the TBIAOTANT

1 Samuel 20 in the TBT1E

1 Samuel 20 in the TBT1E2

1 Samuel 20 in the TFTIP

1 Samuel 20 in the TFTU

1 Samuel 20 in the TGNTATF3T

1 Samuel 20 in the THAI

1 Samuel 20 in the TNFD

1 Samuel 20 in the TNT

1 Samuel 20 in the TNTIK

1 Samuel 20 in the TNTIL

1 Samuel 20 in the TNTIN

1 Samuel 20 in the TNTIP

1 Samuel 20 in the TNTIZ

1 Samuel 20 in the TOMA

1 Samuel 20 in the TTENT

1 Samuel 20 in the UBG

1 Samuel 20 in the UGV

1 Samuel 20 in the UGV2

1 Samuel 20 in the UGV3

1 Samuel 20 in the VBL

1 Samuel 20 in the VDCC

1 Samuel 20 in the YALU

1 Samuel 20 in the YAPE

1 Samuel 20 in the YBVTP

1 Samuel 20 in the ZBP