Daniel 11 (BOYCB)

1 Ní ọdún kìn-ín-ní Dariusi ará Media, mo dúró láti tì í lẹ́yìn àti láti dáàbò bò ó.) 2 “Ní ìsinsin yìí, mo sọ òtítọ́ fún ọ ọba mẹ́ta yóò dìde sí i ní Persia, àti ẹ̀kẹrin tí yóò jẹ́ ọlọ́rọ̀ ju gbogbo wọn lọ. Tí ó bá ti di alágbára nípa ọrọ̀ rẹ̀, yóò sì ru gbogbo wọn sókè lòdì sí ìjọba Giriki. 3 Nígbà náà ni ọba alágbára kan yóò fi ara hàn, yóò ṣe àkóso pẹ̀lú agbára ńlá, yóò sì ṣe bí ó ti wù ú. 4 Lẹ́yìn ìgbà tí ó bá fi ara hàn tán, ìjọba rẹ̀ yóò fọ́, yóò sì pín sí mẹ́rin ní orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé, ìjọba náà kò sì ṣọ́wọ́ àwọn ìran rẹ̀ tàbí kí ó ní agbára tí ó ń lò tẹ́lẹ̀, nítorí, a ó fa ìjọba rẹ̀ tu a ó sì fi fún àwọn mìíràn. 5 “Ọba ìhà gúúsù yóò di alágbára ṣùgbọ́n ọ̀kan lára àwọn aláṣẹ rẹ̀ yóò di alágbára jù ú lọ, yóò sì ṣe àkóso ìjọba rẹ̀ pẹ̀lú agbára ńlá. 6 Lẹ́yìn ọdún púpọ̀ wọn yóò dá májẹ̀mú àlàáfíà, ọmọbìnrin ọba gúúsù yóò lọ sí ọ̀dọ̀ ọba àríwá láti bá a dá májẹ̀mú àlàáfíà, ṣùgbọ́n òun kì yóò lè di agbára apá a rẹ̀ mú, bẹ́ẹ̀ ni òun kì yóò lè dádúró, ṣùgbọ́n a ó tẹrí i rẹ̀ ba àti àwọn tí ó mú un wá, àti ọmọ tí ó bí, àti ẹni tí ó ń mu lọ́kàn le ní gbogbo àkókò wọ̀nyí. 7 “Ọ̀kan lára àwọn ìdílé e rẹ̀, ọmọbìnrin ọba gúúsù yóò dìde láti gba ipò o rẹ̀. Yóò sì kọlu ogun ọba àríwá, yóò sì wó odi alágbára; yóò bá wọn jà yóò sì borí. 8 Yóò gba òrìṣà wọn, ère dídá àti ohun èlò oníye lórí ti fàdákà àti ti wúrà, yóò sì kó wọn lọ sí Ejibiti. Fún ọdún díẹ̀ yóò fi ọba àríwá lọ́rùn sílẹ̀. 9 Nígbà náà, ni ọba àríwá yóò gbógun ti ilẹ̀ ọba, gúúsù, ṣùgbọ́n yóò padà sí Orílẹ̀-èdè, òun fúnra rẹ̀. 10 Àwọn ọmọ rẹ̀ yóò múra ogun wọn yóò kó ogun ńlá jọ, èyí tí a ó gbá lọ bí àgbàrá omi ńlá, yóò sì gbá a lọ títí dé ìlú olódi rẹ̀. 11 “Nígbà náà ni ọba gúúsù yóò jáde pẹ̀lú ìbínú, yóò sì bá ọba àríwá jà, ẹni tí yóò kó ọmọ-ogun púpọ̀ jọ, ṣùgbọ́n ọba gúúsù yóò borí i wọn. 12 Nígbà tí a bá kó ogun náà lọ, ọba gúúsù yóò kún fún agbára, yóò sì pa ẹgbẹẹgbẹ̀rún ní ìpakúpa síbẹ̀ kì yóò ṣẹ́gun. 13 Nítorí ọba àríwá yóò lọ kó ogun mìíràn jọ, tí ó pọ̀ ju ti àkọ́kọ́ lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, yóò jáde pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogun tí ó ti dira ogun fún dáradára. 14 “Ní àkókò ìgbà náà, ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò dìde sí ọba gúúsù. Àwọn ọlọ̀tẹ̀ nínú àwọn ènìyàn an rẹ̀ yóò ṣọ̀tẹ̀ ní ìmúṣẹ ìran náà, ṣùgbọ́n wọn kì yóò borí. 15 Nígbà náà ni ọba àríwá yóò wá yóò sì gbé ogun tì í, yóò sì kó ìlú olódi. Ogun ọba gúúsù kò ní ní agbára láti kọjú ìjà sí i; bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọ̀wọ́ ogun tó dára jù kò ní ní agbára láti dúró. 16 Ẹni tí ó gbóguntì í yóò máa ṣe bí ó ti wù ú, kò sì ṣí ẹni tí yóò le è dojúkọ ọ́. Yóò sì fún ara rẹ̀ ní ibùjókòó ní ilẹ̀ tí ó dára, yóò sì ní agbára láti bà á jẹ́. 17 Yóò pinnu láti wá pẹ̀lú agbára ìjọba rẹ̀, yóò sì ní májẹ̀mú àlàáfíà pẹ̀lú ọba gúúsù yóò sì fi ọmọbìnrin rẹ̀ fún un láti fẹ́ ẹ ní ìyàwó nítorí kí ó lè gba ìjọba, ṣùgbọ́n ète rẹ̀ yìí kì yóò dúró tàbí ṣe ìrànlọ́wọ́ fún un. 18 Nígbà náà ni yóò yí ara padà sí ilẹ̀ etí Òkun, yóò mú ọ̀pọ̀lọpọ̀, ṣùgbọ́n aláṣẹ kan yóò mú òpin bá àfojúdi rẹ̀, yóò sì yí àfojúdi rẹ̀ padà sí orí rẹ̀. 19 Lẹ́yìn èyí, yóò sì yí padà sí ìlú olódi ti orílẹ̀-èdè òun fúnra rẹ̀, ṣùgbọ́n yóò kọsẹ̀ yóò sì ṣubú, a kì yóò sì rí i mọ́. 20 “Arọ́pò rẹ̀ yóò rán agbowó orí kan jáde láti fi ìdí ipò ọlá ọba múlẹ̀ ṣùgbọ́n ní ìwọ̀n ọdún díẹ̀, a ó pa á run, kì yóò jẹ́ nípa ìbínú tàbí nínú ogun. 21 “Ẹni tí kò níláárí kan yóò rọ́pò rẹ̀, ẹni tí a kò tí ì fi ọlá ọba fún rí. Yóò sì gbógun sí ìjọba nígbà tí ọkàn àwọn ènìyàn balẹ̀ láìbẹ̀rù, yóò sì gbà á pẹ̀lú àrékérekè. 22 Nígbà náà, ni a ó gbà ogunlọ́gọ̀ ogun kúrò níwájú u rẹ̀, pẹ̀lú òun àti ọmọ-aládé ti májẹ̀mú náà ni a ó parun. 23 Lẹ́yìn tí ó wá ṣe ìpinnu pẹ̀lú u rẹ̀, yóò hùwà ẹ̀tàn, pẹ̀lú ìwọ̀nba ènìyàn kékeré ni yóò gba ìjọba. 24 Nígbà tí àwọn agbègbè tí ó lọ́rọ̀ gidigidi wà láìbẹ̀rù ni yóò gbóguntì wọ́n, yóò ṣe ohun tí baba rẹ̀ tàbí baba ńlá rẹ̀ kò ṣe rí, yóò pín ìkógun ẹrù àti ọrọ̀ fún àwọn ọmọ lẹ́yìn in rẹ̀. Yóò pète àti bi àwọn ìlú olódi ṣubú, ṣùgbọ́n fún ìgbà díẹ̀ ni. 25 “Pẹ̀lú ogun púpọ̀, yóò sì ru agbára rẹ̀ àti ìgboyà rẹ̀ sókè sí ọba gúúsù. Ọba gúúsù yóò dìde ogun pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ-ogun tí ó lágbára gidigidi, ṣùgbọ́n kò ní le è dúró, nítorí ọ̀tẹ̀ tí ó gbèrò sí i. 26 Àwọn tí ó jẹ nínú oúnjẹ ọba yóò gbìyànjú láti parun, a ó gbá ogun rẹ̀ dànù, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni yóò ṣubú sí ogun. 27 Àwọn ọba méjèèjì, ọkàn wọn tẹ̀ sí búburú, wọn yóò jókòó lórí tábìlì kan, wọn yóò máa parọ́ sí ara wọn, ṣùgbọ́n kò ní yọrí sí nǹkan kan nítorí òpin yóò wá ní àsìkò tí a yàn. 28 Ọba àríwá yóò padà sí ilẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ọrọ̀ púpọ̀, ṣùgbọ́n ọkàn rẹ̀ yóò lòdì sí májẹ̀mú mímọ́, yóò sì ṣiṣẹ́ lòdì sí i, yóò sì padà sí orílẹ̀-èdè òun fúnra rẹ̀. 29 “Ní àsìkò tí a yàn, yóò gbógun sí gúúsù lẹ́ẹ̀kan sí i, ṣùgbọ́n ní ìgbà yí àyọríṣí yóò yàtọ̀ sí ti ìṣáájú. 30 Nítorí pé, ọkọ̀ ojú omi àwọn ilẹ̀ etídò ìwọ̀-oòrùn yóò takò ó, ọkàn rẹ̀ yóò sì pami. Nígbà náà, ni yóò padà, yóò sì bínú sí májẹ̀mú mímọ́, yóò sì padà, yóò sì fi ojúrere hàn sí àwọn tí ó kọ májẹ̀mú mímọ́ náà. 31 “Agbára ọmọ-ogun rẹ̀ yóò dìde láti ba ohun mímọ́ ilé olódi tẹmpili jẹ́, yóò sì pa ẹbọ ojoojúmọ́ rẹ́. Nígbà náà ni wọn yóò gbé ìríra tí ó fa ìsọdahoro kalẹ̀. 32 Pẹ̀lú irú àwọn tí ń ṣe búburú sí májẹ̀mú ní yóò fi ọ̀rọ̀ ìpọ́nni mú ṣọ̀tẹ̀, ṣùgbọ́n, àwọn tí ó mọ Ọlọ́run wọn yóò mú ọkàn le. Wọn yóò sì máa ṣe iṣẹ́ agbára. 33 “Àwọn tí ó mòye yóò máa kọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀, ṣùgbọ́n fún ìgbà díẹ̀, wọn yóò máa ṣubú nípa idà tàbí kí a jó wọn tàbí ìgbèkùn tàbí nípa ìkógun. 34 Nígbà tí wọ́n bá ṣubú, wọn yóò rí ìrànlọ́wọ́ díẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn tó ṣe aláìṣòótọ́ yóò sì darapọ̀ mọ́ wọn. 35 Lára àwọn tí ó mòye yóò kọsẹ̀, nítorí kí a ba à tún wọn ṣe, wọ́n di mímọ́ àti aláìlábàwọ́n títí di ìgbà ìkẹyìn nítorí yóò sì wá ní àkókò tí a yàn. 36 “Ọba yóò ṣe bí ó ti wù ú yóò sì gbé ara rẹ̀ ga, ju gbogbo òrìṣà lọ, yóò máa sọ àwọn ọ̀rọ̀ tí kò-ṣe-é-gbọ́-létí sí Ọlọ́run àwọn Ọlọ́run, yóò sì máa yege títí àkókò ìbínú yóò fi parí, nítorí ohun tí a ti pinnu yóò ṣẹlẹ̀. 37 Òun kò ní ka òrìṣà àwọn baba rẹ̀ sí tàbí èyí tí àwọn fẹ́, òun kò ní ka nǹkan kan sí, ṣùgbọ́n yóò gbé ara rẹ̀ ga ju gbogbo wọn lọ. 38 Ṣùgbọ́n dípò wọn, yóò bu ọlá fún òrìṣà àwọn ìlú olódi: òrìṣà tí àwọn baba rẹ̀ kò mọ̀ ni yóò bu ọlá fún pẹ̀lú wúrà àti fàdákà, pẹ̀lú òkúta iyebíye àti ẹ̀bùn tí ó lówó lórí. 39 Yóò kọlu àwọn ìlú olódi tí ó lágbára pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ òrìṣà àjèjì, yóò sì bu ọláńlá fún ẹni tí ó jẹ́wọ́ rẹ̀. Yóò mú wọn ṣe alákòóso lórí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, yóò sì pín ilẹ̀ náà fún wọn gẹ́gẹ́ bí èrè. 40 “Ní ìgbà ìkẹyìn, ọba gúúsù yóò gbé ogun de sí i, ọba àríwá yóò sì jáde bí ìjì láti kọlù ú pẹ̀lú u kẹ̀kẹ́ ogun àti ẹlẹ́ṣin àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkọ̀ ojú omi. Yóò gbógun wọ orílẹ̀-èdè púpọ̀, yóò sì bo wọn mọ́lẹ̀ bí ìkún omi. 41 Bẹ́ẹ̀ ni yóò sì tún gbógun ti ilẹ̀ ológo náà pẹ̀lú, ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè yóò ṣubú, ṣùgbọ́n Edomu, Moabu àti àwọn olórí Ammoni yóò bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀. 42 Yóò lo agbára rẹ̀ lórí ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè; Ejibiti kì yóò là. 43 Yóò gba àkóso ìṣúra wúrà àti fàdákà àti gbogbo ọrọ̀ Ejibiti, pẹ̀lú ti Libia àti Kuṣi nígbà tí ó mú wọn tẹríba. 44 Ṣùgbọ́n ìròyìn láti ìlà-oòrùn àti láti ìwọ̀-oòrùn yóò mú ìdáríjì bá a, yóò sì fi ìbínú ńlá jáde lọ láti parun, àti láti pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ run pátápátá. 45 Yóò sì pàgọ́ ọ rẹ̀ láàrín Òkun kọjú sí àárín òkè mímọ́ ológo. Síbẹ̀ yóò wá sí òpin rẹ̀, ẹnìkan kò ní ràn án lọ́wọ́.

In Other Versions

Daniel 11 in the ANGEFD

Daniel 11 in the ANTPNG2D

Daniel 11 in the AS21

Daniel 11 in the BAGH

Daniel 11 in the BBPNG

Daniel 11 in the BBT1E

Daniel 11 in the BDS

Daniel 11 in the BEV

Daniel 11 in the BHAD

Daniel 11 in the BIB

Daniel 11 in the BLPT

Daniel 11 in the BNT

Daniel 11 in the BNTABOOT

Daniel 11 in the BNTLV

Daniel 11 in the BOATCB

Daniel 11 in the BOATCB2

Daniel 11 in the BOBCV

Daniel 11 in the BOCNT

Daniel 11 in the BOECS

Daniel 11 in the BOGWICC

Daniel 11 in the BOHCB

Daniel 11 in the BOHCV

Daniel 11 in the BOHLNT

Daniel 11 in the BOHNTLTAL

Daniel 11 in the BOICB

Daniel 11 in the BOILNTAP

Daniel 11 in the BOITCV

Daniel 11 in the BOKCV

Daniel 11 in the BOKCV2

Daniel 11 in the BOKHWOG

Daniel 11 in the BOKSSV

Daniel 11 in the BOLCB

Daniel 11 in the BOLCB2

Daniel 11 in the BOMCV

Daniel 11 in the BONAV

Daniel 11 in the BONCB

Daniel 11 in the BONLT

Daniel 11 in the BONUT2

Daniel 11 in the BOPLNT

Daniel 11 in the BOSCB

Daniel 11 in the BOSNC

Daniel 11 in the BOTLNT

Daniel 11 in the BOVCB

Daniel 11 in the BPBB

Daniel 11 in the BPH

Daniel 11 in the BSB

Daniel 11 in the CCB

Daniel 11 in the CUV

Daniel 11 in the CUVS

Daniel 11 in the DBT

Daniel 11 in the DGDNT

Daniel 11 in the DHNT

Daniel 11 in the DNT

Daniel 11 in the ELBE

Daniel 11 in the EMTV

Daniel 11 in the ESV

Daniel 11 in the FBV

Daniel 11 in the FEB

Daniel 11 in the GGMNT

Daniel 11 in the GNT

Daniel 11 in the HARY

Daniel 11 in the HNT

Daniel 11 in the IRVA

Daniel 11 in the IRVB

Daniel 11 in the IRVG

Daniel 11 in the IRVH

Daniel 11 in the IRVK

Daniel 11 in the IRVM

Daniel 11 in the IRVM2

Daniel 11 in the IRVO

Daniel 11 in the IRVP

Daniel 11 in the IRVT

Daniel 11 in the IRVT2

Daniel 11 in the IRVU

Daniel 11 in the ISVN

Daniel 11 in the JSNT

Daniel 11 in the KAPI

Daniel 11 in the KBT1ETNIK

Daniel 11 in the KBV

Daniel 11 in the KJV

Daniel 11 in the KNFD

Daniel 11 in the LBA

Daniel 11 in the LBLA

Daniel 11 in the LNT

Daniel 11 in the LSV

Daniel 11 in the MAAL

Daniel 11 in the MBV

Daniel 11 in the MBV2

Daniel 11 in the MHNT

Daniel 11 in the MKNFD

Daniel 11 in the MNG

Daniel 11 in the MNT

Daniel 11 in the MNT2

Daniel 11 in the MRS1T

Daniel 11 in the NAA

Daniel 11 in the NASB

Daniel 11 in the NBLA

Daniel 11 in the NBS

Daniel 11 in the NBVTP

Daniel 11 in the NET2

Daniel 11 in the NIV11

Daniel 11 in the NNT

Daniel 11 in the NNT2

Daniel 11 in the NNT3

Daniel 11 in the PDDPT

Daniel 11 in the PFNT

Daniel 11 in the RMNT

Daniel 11 in the SBIAS

Daniel 11 in the SBIBS

Daniel 11 in the SBIBS2

Daniel 11 in the SBICS

Daniel 11 in the SBIDS

Daniel 11 in the SBIGS

Daniel 11 in the SBIHS

Daniel 11 in the SBIIS

Daniel 11 in the SBIIS2

Daniel 11 in the SBIIS3

Daniel 11 in the SBIKS

Daniel 11 in the SBIKS2

Daniel 11 in the SBIMS

Daniel 11 in the SBIOS

Daniel 11 in the SBIPS

Daniel 11 in the SBISS

Daniel 11 in the SBITS

Daniel 11 in the SBITS2

Daniel 11 in the SBITS3

Daniel 11 in the SBITS4

Daniel 11 in the SBIUS

Daniel 11 in the SBIVS

Daniel 11 in the SBT

Daniel 11 in the SBT1E

Daniel 11 in the SCHL

Daniel 11 in the SNT

Daniel 11 in the SUSU

Daniel 11 in the SUSU2

Daniel 11 in the SYNO

Daniel 11 in the TBIAOTANT

Daniel 11 in the TBT1E

Daniel 11 in the TBT1E2

Daniel 11 in the TFTIP

Daniel 11 in the TFTU

Daniel 11 in the TGNTATF3T

Daniel 11 in the THAI

Daniel 11 in the TNFD

Daniel 11 in the TNT

Daniel 11 in the TNTIK

Daniel 11 in the TNTIL

Daniel 11 in the TNTIN

Daniel 11 in the TNTIP

Daniel 11 in the TNTIZ

Daniel 11 in the TOMA

Daniel 11 in the TTENT

Daniel 11 in the UBG

Daniel 11 in the UGV

Daniel 11 in the UGV2

Daniel 11 in the UGV3

Daniel 11 in the VBL

Daniel 11 in the VDCC

Daniel 11 in the YALU

Daniel 11 in the YAPE

Daniel 11 in the YBVTP

Daniel 11 in the ZBP