Ecclesiastes 8 (BOYCB)

1 Ta ni ó dàbí ọlọ́gbọ́n ènìyàn?Ta ni ó mọ ìtumọ̀ ohun gbogbo?Ọgbọ́n a máa mú ojú ènìyàn dánó sì máa ń pààrọ̀ ìrínisí rẹ̀. 2 Mo sọ wí pé, pa òfin ọba mọ́, nítorí pé, ìwọ ti ṣe ìbúra níwájú Ọlọ́run. 3 Má ṣe jẹ́ kí ojú kán ọ láti kúrò ní iwájú ọba, má ṣe dúró nínú ohun búburú, nítorí yóò ṣe ohunkóhun tí ó bá tẹ́ ẹ lọ́rùn. 4 Níwọ́n ìgbà tí ọ̀rọ̀ ọba ni àṣẹ, ta ni ó le è sọ fún un wí pé, “Kí ni ìwọ ń ṣe?” 5 Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa àṣẹ rẹ̀ mọ́, kò ní wá sí ìpalára kankan,àyà ọlọ́gbọ́n ènìyàn yóò sì mọ àsìkò tí ó tọ́ àti ọ̀nà tí yóò gbà ṣe é. 6 Ohun gbogbo ni ó ní àsìkò àti ọ̀nà tí ó tọ́ láti ṣe,ṣùgbọ́n, òsì ènìyàn pọ̀ sí orí ara rẹ̀. 7 Níwọ́n ìgbà tí kò sí ẹni tí ó mọ ọjọ́-ọ̀lá,ta ni ó le è sọ fún un ohun tí ó ń bọ̀? 8 Kò sí ẹni tí ó lágbára lórí afẹ́fẹ́ láti gbà á dúró,nítorí náà, kò sí ẹni tí ó ní agbára lórí ọjọ́ ikú rẹ̀.Bí ó ti jẹ́ wí pé kò sí ẹni tí a dá sílẹ̀ nígbà ogun,bẹ́ẹ̀ náà ni ìkà kò ní fi àwọn tí ó ń ṣe é sílẹ̀;bí ó ti jẹ́ wí pé kò sí ẹni tí a dá sílẹ̀ nígbà ogun,bẹ́ẹ̀ náà ni ìwà búburú kò le gba àwọn tí ó ń ṣe é sílẹ̀. 9 Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni mo ti rí, tí mo sì ń múlò ní ọkàn mi sí gbogbo iṣẹ́ tí a ti ṣe lábẹ́ oòrùn. Ìgbà kan wà tí ẹnìkan ń ṣe olórí àwọn tókù fún ìpalára rẹ̀. 10 Nígbà náà ni mo tún rí ìsìnkú ènìyàn búburú—àwọn tí wọ́n máa ń wá tí wọ́n sì ń lọ láti ibi mímọ́ kí wọn sì gba ìyìn ní ìlú tàbí tí wọ́n ti ṣe èyí. Eléyìí pẹ̀lú kò ní ìtumọ̀. 11 Nígbà tí a kò bá tètè ṣe ìdájọ́ fún ẹlẹ́ṣẹ̀ kíákíá, ọkàn àwọn ènìyàn a máa kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìmọ̀ láti ṣe ibi. 12 Bí ènìyàn búburú tó dẹ́ṣẹ̀ nígbà ọgọ́rùn-ún tilẹ̀ wà láààyè fún ìgbà pípẹ́, mo mọ̀ wí pé yóò dára fún ẹni tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó bẹ̀rù níwájú rẹ̀. 13 Bẹ́ẹ̀ ni kì yóò dára fún ènìyàn búburú, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fa ọjọ́ rẹ̀ gún tí ó dà bí òjìji, nítorí tí kò bẹ̀rù níwájú Ọlọ́run. 14 Ohun mìíràn tún wà tí kò ní ìtumọ̀, tí ó ń ṣẹlẹ̀ láyé olódodo tí ó ń gba ohun tí ó tọ́ sí òṣìkà àti ènìyàn búburú tí ó ń gba ohun tí ó tọ́ sí olódodo. Mo sọ wí pé eléyìí gan an kò ní ìtumọ̀. 15 Nítorí náà mo kan sáárá sí ìgbádùn ayé, nítorí pé kò sí ohun tí ó dára fún ènìyàn ní abẹ́ oòrùn ju pé kí ó jẹ, kí ó mu, kí inú rẹ̀ sì dùn lọ. Nígbà náà ni ìdùnnú yóò bá a rìn nínú iṣẹ́ ẹ rẹ̀, ní gbogbo ọjọ́ ayé ti Ọlọ́run tí fi fún un lábẹ́ oòrùn. 16 Nígbà tí mo lo ọkàn mi láti mọ ọgbọ́n àti láti wo wàhálà ènìyàn ní ayé. 17 Nígbà náà ni mo rí gbogbo ohun tí Ọlọ́run tí ṣe, kò sí ẹnìkan tí ó le è mòye ohun tí ó ń lọ lábẹ́ oòrùn. Láìbìkítà gbogbo ìyànjú rẹ̀ láti wá rí jáde, ènìyàn kò le è mọ ìtumọ̀ rẹ̀, kódà bí ọlọ́gbọ́n ènìyàn rò wí pé òun mọ̀ ọ́n, kò le è ní òye rẹ̀ ní pàtó.

In Other Versions

Ecclesiastes 8 in the ANGEFD

Ecclesiastes 8 in the ANTPNG2D

Ecclesiastes 8 in the AS21

Ecclesiastes 8 in the BAGH

Ecclesiastes 8 in the BBPNG

Ecclesiastes 8 in the BBT1E

Ecclesiastes 8 in the BDS

Ecclesiastes 8 in the BEV

Ecclesiastes 8 in the BHAD

Ecclesiastes 8 in the BIB

Ecclesiastes 8 in the BLPT

Ecclesiastes 8 in the BNT

Ecclesiastes 8 in the BNTABOOT

Ecclesiastes 8 in the BNTLV

Ecclesiastes 8 in the BOATCB

Ecclesiastes 8 in the BOATCB2

Ecclesiastes 8 in the BOBCV

Ecclesiastes 8 in the BOCNT

Ecclesiastes 8 in the BOECS

Ecclesiastes 8 in the BOGWICC

Ecclesiastes 8 in the BOHCB

Ecclesiastes 8 in the BOHCV

Ecclesiastes 8 in the BOHLNT

Ecclesiastes 8 in the BOHNTLTAL

Ecclesiastes 8 in the BOICB

Ecclesiastes 8 in the BOILNTAP

Ecclesiastes 8 in the BOITCV

Ecclesiastes 8 in the BOKCV

Ecclesiastes 8 in the BOKCV2

Ecclesiastes 8 in the BOKHWOG

Ecclesiastes 8 in the BOKSSV

Ecclesiastes 8 in the BOLCB

Ecclesiastes 8 in the BOLCB2

Ecclesiastes 8 in the BOMCV

Ecclesiastes 8 in the BONAV

Ecclesiastes 8 in the BONCB

Ecclesiastes 8 in the BONLT

Ecclesiastes 8 in the BONUT2

Ecclesiastes 8 in the BOPLNT

Ecclesiastes 8 in the BOSCB

Ecclesiastes 8 in the BOSNC

Ecclesiastes 8 in the BOTLNT

Ecclesiastes 8 in the BOVCB

Ecclesiastes 8 in the BPBB

Ecclesiastes 8 in the BPH

Ecclesiastes 8 in the BSB

Ecclesiastes 8 in the CCB

Ecclesiastes 8 in the CUV

Ecclesiastes 8 in the CUVS

Ecclesiastes 8 in the DBT

Ecclesiastes 8 in the DGDNT

Ecclesiastes 8 in the DHNT

Ecclesiastes 8 in the DNT

Ecclesiastes 8 in the ELBE

Ecclesiastes 8 in the EMTV

Ecclesiastes 8 in the ESV

Ecclesiastes 8 in the FBV

Ecclesiastes 8 in the FEB

Ecclesiastes 8 in the GGMNT

Ecclesiastes 8 in the GNT

Ecclesiastes 8 in the HARY

Ecclesiastes 8 in the HNT

Ecclesiastes 8 in the IRVA

Ecclesiastes 8 in the IRVB

Ecclesiastes 8 in the IRVG

Ecclesiastes 8 in the IRVH

Ecclesiastes 8 in the IRVK

Ecclesiastes 8 in the IRVM

Ecclesiastes 8 in the IRVM2

Ecclesiastes 8 in the IRVO

Ecclesiastes 8 in the IRVP

Ecclesiastes 8 in the IRVT

Ecclesiastes 8 in the IRVT2

Ecclesiastes 8 in the IRVU

Ecclesiastes 8 in the ISVN

Ecclesiastes 8 in the JSNT

Ecclesiastes 8 in the KAPI

Ecclesiastes 8 in the KBT1ETNIK

Ecclesiastes 8 in the KBV

Ecclesiastes 8 in the KJV

Ecclesiastes 8 in the KNFD

Ecclesiastes 8 in the LBA

Ecclesiastes 8 in the LBLA

Ecclesiastes 8 in the LNT

Ecclesiastes 8 in the LSV

Ecclesiastes 8 in the MAAL

Ecclesiastes 8 in the MBV

Ecclesiastes 8 in the MBV2

Ecclesiastes 8 in the MHNT

Ecclesiastes 8 in the MKNFD

Ecclesiastes 8 in the MNG

Ecclesiastes 8 in the MNT

Ecclesiastes 8 in the MNT2

Ecclesiastes 8 in the MRS1T

Ecclesiastes 8 in the NAA

Ecclesiastes 8 in the NASB

Ecclesiastes 8 in the NBLA

Ecclesiastes 8 in the NBS

Ecclesiastes 8 in the NBVTP

Ecclesiastes 8 in the NET2

Ecclesiastes 8 in the NIV11

Ecclesiastes 8 in the NNT

Ecclesiastes 8 in the NNT2

Ecclesiastes 8 in the NNT3

Ecclesiastes 8 in the PDDPT

Ecclesiastes 8 in the PFNT

Ecclesiastes 8 in the RMNT

Ecclesiastes 8 in the SBIAS

Ecclesiastes 8 in the SBIBS

Ecclesiastes 8 in the SBIBS2

Ecclesiastes 8 in the SBICS

Ecclesiastes 8 in the SBIDS

Ecclesiastes 8 in the SBIGS

Ecclesiastes 8 in the SBIHS

Ecclesiastes 8 in the SBIIS

Ecclesiastes 8 in the SBIIS2

Ecclesiastes 8 in the SBIIS3

Ecclesiastes 8 in the SBIKS

Ecclesiastes 8 in the SBIKS2

Ecclesiastes 8 in the SBIMS

Ecclesiastes 8 in the SBIOS

Ecclesiastes 8 in the SBIPS

Ecclesiastes 8 in the SBISS

Ecclesiastes 8 in the SBITS

Ecclesiastes 8 in the SBITS2

Ecclesiastes 8 in the SBITS3

Ecclesiastes 8 in the SBITS4

Ecclesiastes 8 in the SBIUS

Ecclesiastes 8 in the SBIVS

Ecclesiastes 8 in the SBT

Ecclesiastes 8 in the SBT1E

Ecclesiastes 8 in the SCHL

Ecclesiastes 8 in the SNT

Ecclesiastes 8 in the SUSU

Ecclesiastes 8 in the SUSU2

Ecclesiastes 8 in the SYNO

Ecclesiastes 8 in the TBIAOTANT

Ecclesiastes 8 in the TBT1E

Ecclesiastes 8 in the TBT1E2

Ecclesiastes 8 in the TFTIP

Ecclesiastes 8 in the TFTU

Ecclesiastes 8 in the TGNTATF3T

Ecclesiastes 8 in the THAI

Ecclesiastes 8 in the TNFD

Ecclesiastes 8 in the TNT

Ecclesiastes 8 in the TNTIK

Ecclesiastes 8 in the TNTIL

Ecclesiastes 8 in the TNTIN

Ecclesiastes 8 in the TNTIP

Ecclesiastes 8 in the TNTIZ

Ecclesiastes 8 in the TOMA

Ecclesiastes 8 in the TTENT

Ecclesiastes 8 in the UBG

Ecclesiastes 8 in the UGV

Ecclesiastes 8 in the UGV2

Ecclesiastes 8 in the UGV3

Ecclesiastes 8 in the VBL

Ecclesiastes 8 in the VDCC

Ecclesiastes 8 in the YALU

Ecclesiastes 8 in the YAPE

Ecclesiastes 8 in the YBVTP

Ecclesiastes 8 in the ZBP