Esther 9 (BOYCB)

1 Ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kejìlá, oṣù Addari, tí ó yẹ kí a mú àṣẹ tí ọba pa wá sí ìmúṣẹ. Ní ọjọ́ yìí ni ọ̀tá àwọn Júù rò pé àwọn yóò borí i wọn, ṣùgbọ́n nísinsin yìí a ti yìí padà, àwọn Júù sì na ọwọ́ agbára tó ga lórí àwọn tí ó kórìíra wọn. 2 Àwọn Júù péjọ ní àwọn ìlú u wọn ní gbogbo agbègbè ọba Ahaswerusi láti kọlu àwọn tó ń wá ìparun wọn. Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè dojúkọ wọ́n, nítorí gbogbo àwọn ènìyàn ìlú tókù ń bẹ̀rù u wọn. 3 Gbogbo àwọn ọlọ́lá ìgbèríko, àwọn alákòóso, àwọn baálẹ̀ àti àwọn onídàájọ́ ọba ran àwọn Júù lọ́wọ́, nítorí wọ́n bẹ̀rù u Mordekai. 4 Mordekai sì jẹ́ ẹni pàtàkì ní ààfin ọba, òkìkí rẹ̀ sì tàn jákèjádò àwọn ìgbèríko, ó sì ní agbára kún agbára. 5 Àwọn Júù sì gé gbogbo àwọn ọ̀tá a wọn lulẹ̀ pẹ̀lú idà, wọ́n pa wọ́n, wọ́n sì run wọ́n, wọ́n sì ṣe ohun tí ó wù wọ́n sí àwọn tí ó kórìíra wọn. 6 Ní ilé ìṣọ́ ti Susa, àwọn Júù pa ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) ọkùnrin run. 7 Wọ́n sì tún pa Parṣandata, Dalfoni, Aspata, 8 Porata, Adalia, Aridata, 9 Parmaṣta, Arisai, Aridai àti Faisata. 10 Àwọn ọmọkùnrin mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tí wọ́n jẹ́ ọmọ Hamani, ọmọ Hammedata, ọ̀tá àwọn Júù. Ṣùgbọ́n wọn kò fi ọwọ́ wọn lé ìkógun un wọn. 11 Ní ọjọ́ náà gan an ni a mú iye àwọn tí a pa ní ilé ìṣọ́ ti Susa wá fún ọba. 12 Ọba sì sọ fún Esteri ayaba pé, “Àwọn Júù ti pa ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) ọkùnrin àti àwọn ọmọkùnrin mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tí i ṣe ọmọ Hamani ní ilé ìṣọ́ Susa run. Kí ni wọ́n ṣe ní gbogbo ìgbèríko ọba tókù? Báyìí kí ni ẹ̀bẹ̀ rẹ? A ó fi fún ọ. Kí ni ìbéèrè rẹ? A ó sì tún fi fún ọ.” 13 Esteri sì dáhùn pé, “Bí ó bá tẹ́ ọba lọ́rùn, fún àwọn Júù tí ó wà ní Susa ní àṣẹ láti ṣe gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe ní òní kí wọn ṣe bákan náà ní ọ̀la, kí a sì so àwọn ọmọkùnrin Hamani mẹ́wẹ̀ẹ̀wá náà rọ̀ sórí igi.” 14 Nítorí náà ọba pàṣẹ pé kí a ṣe bẹ́ẹ̀. A sì gbé àṣẹ kan jáde ní Susa, wọ́n sì so àwọn ọmọkùnrin mẹ́wẹ̀ẹ̀wá Hamani kọ́. 15 Àwọn Júù tí ó wà ní Susa sì péjọ ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Addari, wọ́n sì pa ọ̀ọ́dúnrún (300) ọkùnrin ní Susa, ṣùgbọ́n wọn kò fi ọwọ́ wọn lé ìkógun un wọn. 16 Lákokò yìí, àwọn tókù nínú àwọn Júù tí wọ́n wà ní agbègbè ọba náà tún kó ara wọn jọ láti dáàbò bo ara wọn kí wọn sì sinmi lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá a wọn. Wọ́n sì pa ẹgbàá mẹ́tàdínlógójì ó lé ẹgbẹ̀rin (75,000) àwọn tí ó kórìíra wọn ṣùgbọ́n wọn kò fi ọwọ́ wọn lé ìkógun un wọn. 17 Èyí ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù Addari, wọ́n sì sinmi ní ọjọ́ kẹrìnlá, wọ́n sì ṣe ọjọ́ náà ní ọjọ́ àsè àti ayọ̀. 18 Àwọn Júù tí ó wà ní Susa, kó ara wọn jọ ní ọjọ́ kẹtàlá àti ọjọ́ kẹrìnlá, nígbà tí ó sì di ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún wọ́n sinmi wọ́n sì ṣe ọjọ́ náà ní ọjọ́ àsè àti ayọ̀. 19 Nítorí náà ni àwọn Júù tí wọ́n ń gbé ní ìletò ṣe pa ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Addari mọ́ gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ ayọ̀ àti ọjọ́ àsè, ọjọ́ tí wọ́n ń fún ara wọn ní ẹ̀bùn. 20 Mordekai ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí, ó sì kọ ìwé ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn Júù jákèjádò àgbáyé ọba Ahaswerusi, tí ó wà ní tòsí àti àwọn tí ó wà ní jìnnà réré, 21 láti lè máa ṣe àjọyọ̀ ní ọjọ́ kẹrìnlá àti ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù Addari ní ọdọọdún. 22 gẹ́gẹ́ bí àkókò tí àwọn Júù gba ìsinmi kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá a wọn, àti bí oṣù tí ìbànújẹ́ ẹ wọn yí padà di ayọ̀ àti tí ọjọ́ ọ̀fọ̀ wọn di ọjọ́ àjọyọ̀. Ó kọ ọ́ sí wọn láti máa pa ọjọ́ náà mọ́ gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ àsè àti ọjọ́ ayọ̀ kí wọn sì máa fi oúnjẹ fún ara wọn, kí wọn sì máa fi ẹ̀bùn fún àwọn aláìní. 23 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn Júù gbà láti máa ṣe àjọyọ̀ tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀, wọ́n ń ṣe bí Mordekai ti kọ̀wé sí wọn. 24 Nítorí Hamani ọmọ Hammedata, ará Agagi, ọ̀tá gbogbo àwọn Júù, ti gbèrò sí àwọn Júù láti pa wọ́n run, ó sì ti di puri (èyí tí í ṣe ìbò) fún ìsọdahoro àti ìparun wọn. 25 Ṣùgbọ́n nígbà tí Esteri sọ nípa ìṣọ̀tẹ̀ náà fún ọba, ó kọ̀wé àṣẹ kan jáde pé kí ète búburú tí Hamani ti pa sí àwọn Júù kí ó padà sí orí òun fúnra rẹ̀, àti pé kí a gbé òun àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ kọ́ sórí igi. 26 (Nítorí náà a pe àwọn ọjọ́ wọ̀nyí ní Purimu, láti ara ọ̀rọ̀ puri). Nítorí ohun gbogbo tí a kọ sínú ìwé yìí àti nítorí ohun tí wọ́n ti rí àti ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí wọn, 27 àwọn Júù fi lélẹ̀, wọ́n sì gbà á gẹ́gẹ́ bí ìlànà fún ara wọn àti fún irú àwọn ọmọ wọn àti gbogbo àwọn tí ó darapọ̀ mọ́ wọn, kò sì ní kúrò, wọn yóò sì máa pa àwọn ọjọ́ méjèèjì yìí mọ́ ní gbogbo ọdún, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ àti àkókò tí a yàn. 28 A gbọdọ̀ máa ṣe ìrántí àwọn ọjọ́ wọ̀nyí kí a sì máa pa wọ́n mọ́ ní ìrandíran ní gbogbo ìdílé, àti ní gbogbo ìgbèríko àti ní gbogbo ìlú. A gbọdọ̀ máa ṣe àwọn ọjọ́ Purimu wọ̀nyí ní àárín àwọn Júù, bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ di ohun ìgbàgbé láàrín irú àwọn ọmọ wọn. 29 Bẹ́ẹ̀ ni Esteri ayaba, ọmọbìnrin Abihaili, pẹ̀lú Mordekai ará a Júù, kọ̀wé pẹ̀lú àṣẹ láti fi ìdí ìwé kejì nípa Purimu yìí múlẹ̀. 30 Mordekai sì kọ ìwé ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn Júù, sí ìgbèríko mẹ́tàdínláàádóje (127) ní ilẹ̀ ọba Ahaswerusi ní ọ̀rọ̀ àlàáfíà àti òtítọ́. 31 Láti fi ìdí àwọn ọjọ́ ọ Purimu yìí múlẹ̀ ní àkókò tí wọ́n yàn, gẹ́gẹ́ bí Mordekai ará Juda, àti Esteri ayaba ti pa á láṣẹ fún wọn, àti bí wọ́n ṣe fi lélẹ̀ fún ara wọn àti irú àwọn ọmọ wọn ní ìbámu pẹ̀lú àkókò àwẹ̀ àti ẹkún wọn. 32 Àṣẹ Esteri sì fi ìdí ìlànà Purimu wọ̀nyí múlẹ̀, a sì kọ ọ́ sínú ìwé àkọsílẹ̀.

In Other Versions

Esther 9 in the ANGEFD

Esther 9 in the ANTPNG2D

Esther 9 in the AS21

Esther 9 in the BAGH

Esther 9 in the BBPNG

Esther 9 in the BBT1E

Esther 9 in the BDS

Esther 9 in the BEV

Esther 9 in the BHAD

Esther 9 in the BIB

Esther 9 in the BLPT

Esther 9 in the BNT

Esther 9 in the BNTABOOT

Esther 9 in the BNTLV

Esther 9 in the BOATCB

Esther 9 in the BOATCB2

Esther 9 in the BOBCV

Esther 9 in the BOCNT

Esther 9 in the BOECS

Esther 9 in the BOGWICC

Esther 9 in the BOHCB

Esther 9 in the BOHCV

Esther 9 in the BOHLNT

Esther 9 in the BOHNTLTAL

Esther 9 in the BOICB

Esther 9 in the BOILNTAP

Esther 9 in the BOITCV

Esther 9 in the BOKCV

Esther 9 in the BOKCV2

Esther 9 in the BOKHWOG

Esther 9 in the BOKSSV

Esther 9 in the BOLCB

Esther 9 in the BOLCB2

Esther 9 in the BOMCV

Esther 9 in the BONAV

Esther 9 in the BONCB

Esther 9 in the BONLT

Esther 9 in the BONUT2

Esther 9 in the BOPLNT

Esther 9 in the BOSCB

Esther 9 in the BOSNC

Esther 9 in the BOTLNT

Esther 9 in the BOVCB

Esther 9 in the BPBB

Esther 9 in the BPH

Esther 9 in the BSB

Esther 9 in the CCB

Esther 9 in the CUV

Esther 9 in the CUVS

Esther 9 in the DBT

Esther 9 in the DGDNT

Esther 9 in the DHNT

Esther 9 in the DNT

Esther 9 in the ELBE

Esther 9 in the EMTV

Esther 9 in the ESV

Esther 9 in the FBV

Esther 9 in the FEB

Esther 9 in the GGMNT

Esther 9 in the GNT

Esther 9 in the HARY

Esther 9 in the HNT

Esther 9 in the IRVA

Esther 9 in the IRVB

Esther 9 in the IRVG

Esther 9 in the IRVH

Esther 9 in the IRVK

Esther 9 in the IRVM

Esther 9 in the IRVM2

Esther 9 in the IRVO

Esther 9 in the IRVP

Esther 9 in the IRVT

Esther 9 in the IRVT2

Esther 9 in the IRVU

Esther 9 in the ISVN

Esther 9 in the JSNT

Esther 9 in the KAPI

Esther 9 in the KBT1ETNIK

Esther 9 in the KBV

Esther 9 in the KJV

Esther 9 in the KNFD

Esther 9 in the LBA

Esther 9 in the LBLA

Esther 9 in the LNT

Esther 9 in the LSV

Esther 9 in the MAAL

Esther 9 in the MBV

Esther 9 in the MBV2

Esther 9 in the MHNT

Esther 9 in the MKNFD

Esther 9 in the MNG

Esther 9 in the MNT

Esther 9 in the MNT2

Esther 9 in the MRS1T

Esther 9 in the NAA

Esther 9 in the NASB

Esther 9 in the NBLA

Esther 9 in the NBS

Esther 9 in the NBVTP

Esther 9 in the NET2

Esther 9 in the NIV11

Esther 9 in the NNT

Esther 9 in the NNT2

Esther 9 in the NNT3

Esther 9 in the PDDPT

Esther 9 in the PFNT

Esther 9 in the RMNT

Esther 9 in the SBIAS

Esther 9 in the SBIBS

Esther 9 in the SBIBS2

Esther 9 in the SBICS

Esther 9 in the SBIDS

Esther 9 in the SBIGS

Esther 9 in the SBIHS

Esther 9 in the SBIIS

Esther 9 in the SBIIS2

Esther 9 in the SBIIS3

Esther 9 in the SBIKS

Esther 9 in the SBIKS2

Esther 9 in the SBIMS

Esther 9 in the SBIOS

Esther 9 in the SBIPS

Esther 9 in the SBISS

Esther 9 in the SBITS

Esther 9 in the SBITS2

Esther 9 in the SBITS3

Esther 9 in the SBITS4

Esther 9 in the SBIUS

Esther 9 in the SBIVS

Esther 9 in the SBT

Esther 9 in the SBT1E

Esther 9 in the SCHL

Esther 9 in the SNT

Esther 9 in the SUSU

Esther 9 in the SUSU2

Esther 9 in the SYNO

Esther 9 in the TBIAOTANT

Esther 9 in the TBT1E

Esther 9 in the TBT1E2

Esther 9 in the TFTIP

Esther 9 in the TFTU

Esther 9 in the TGNTATF3T

Esther 9 in the THAI

Esther 9 in the TNFD

Esther 9 in the TNT

Esther 9 in the TNTIK

Esther 9 in the TNTIL

Esther 9 in the TNTIN

Esther 9 in the TNTIP

Esther 9 in the TNTIZ

Esther 9 in the TOMA

Esther 9 in the TTENT

Esther 9 in the UBG

Esther 9 in the UGV

Esther 9 in the UGV2

Esther 9 in the UGV3

Esther 9 in the VBL

Esther 9 in the VDCC

Esther 9 in the YALU

Esther 9 in the YAPE

Esther 9 in the YBVTP

Esther 9 in the ZBP