Exodus 31 (BOYCB)
1 OLÚWA wí fún Mose pé, 2 “Wò ó, Èmi ti yan Besaleli ọmọ Uri, ọmọ Huri, ti ẹ̀yà Juda, 3 Èmi sì ti fi Ẹ̀mí Ọlọ́run kún un pẹ̀lú ọgbọ́n, òye àti ìmọ̀ ní gbogbo onírúurú iṣẹ́ ọnà. 4 Láti ṣe aláràbarà iṣẹ́ ní wúrà, fàdákà àti idẹ, 5 láti gbẹ́ òkúta àti láti tò wọ́n, láti ṣiṣẹ́ ní igi, àti láti ṣiṣẹ́ ní gbogbo onírúurú iṣẹ́ ọnà. 6 Síwájú sí i, èmi ti yan Oholiabu ọmọ Ahisamaki, ti ẹ̀yà Dani, láti ràn án lọ́wọ́. “Bákan náà, Èmi ti fi ọgbọ́n fún gbogbo àwọn oníṣẹ́-ọnà láti ṣe ohun gbogbo tí mo pàṣẹ fún ọ: 7 “àgọ́ àjọ náà,àpótí ẹ̀rí pẹ̀lú ìtẹ́ àánú tí ó wà lórí rẹ̀,àti gbogbo ohun èlò àgọ́ náà, 8 tábìlì àti ohun èlò rẹ̀,ọ̀pá fìtílà tí ó jẹ́ kìkì wúrà àti gbogbo ohun èlò rẹ̀,pẹpẹ tùràrí, 9 pẹpẹ ẹbọ sísun àti gbogbo ohun èlò rẹ̀,agbada pẹ̀lú ẹsẹ̀ rẹ̀, 10 àti aṣọ híhun pẹ̀lú,papọ̀ pẹ̀lú aṣọ mímọ́ fún Aaroni àlùfáààti aṣọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ bí àlùfáà, 11 òróró ìtasórí àti tùràrí olóòórùn dídùn fún Ibi Mímọ́. “Kí wọ́n ṣe wọ́n gẹ́gẹ́ bí mo ṣe pàṣẹ fún ọ.” 12 OLÚWA wí fún Mose pé, 13 “Kí ìwọ kí ó sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Ẹ̀yin gbọdọ̀ máa pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́. Èyí ni yóò jẹ́ àmì láàrín Èmi àti ẹ̀yin fún ìrandíran tó ń bọ̀, nítorí kí ẹ̀yin lè mọ̀ pé Èmi ni OLÚWA, ẹni tí ó yà yín sí mímọ́. 14 “ ‘Nítorí náà, kí ẹ̀yin kí ó máa pa ọjọ́ ìsinmi mọ́, nítorí mímọ́ ni fún un yín. Ẹnikẹ́ni tí ó bá bà á jẹ́, ni a yóò pa; ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ kankan ní ọjọ́ náà ni a yóò gé kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ. 15 Ọjọ́ mẹ́fà ni kí ẹ fi ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n ọjọ́ keje ní ọjọ́ ìsinmi tí ẹ̀yin yóò fi sinmi, mímọ́ ni fún OLÚWA. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣiṣẹ́ ní ọjọ́ ìsinmi ni a ó pa nítòótọ́. 16 Nítorí náà ni àwọn ọmọ Israẹli yóò ṣe máa pa ọjọ́ ìsinmi mọ́, ẹ máa ṣe àkíyèsí rẹ̀ dé ìrandíran tó ń bọ̀ bí i májẹ̀mú títí láé. 17 Yóò jẹ́ àmì láàrín Èmi àti àwọn ọmọ Israẹli títí láé, nítorí ní ọjọ́ mẹ́fà ni OLÚWA dá ọ̀run àti ayé, àti ní ọjọ́ keje ni ó fi iṣẹ́ sílẹ̀, ó sì sinmi.’ ” 18 Nígbà tí OLÚWA parí ọ̀rọ̀ sísọ fún Mose lórí òkè Sinai, ó fún un ní òkúta wàláà ẹ̀rí méjì, òkúta wàláà òkúta tí a fi ìka Ọlọ́run kọ.
In Other Versions
Exodus 31 in the ANGEFD
Exodus 31 in the ANTPNG2D
Exodus 31 in the AS21
Exodus 31 in the BAGH
Exodus 31 in the BBPNG
Exodus 31 in the BBT1E
Exodus 31 in the BDS
Exodus 31 in the BEV
Exodus 31 in the BHAD
Exodus 31 in the BIB
Exodus 31 in the BLPT
Exodus 31 in the BNT
Exodus 31 in the BNTABOOT
Exodus 31 in the BNTLV
Exodus 31 in the BOATCB
Exodus 31 in the BOATCB2
Exodus 31 in the BOBCV
Exodus 31 in the BOCNT
Exodus 31 in the BOECS
Exodus 31 in the BOGWICC
Exodus 31 in the BOHCB
Exodus 31 in the BOHCV
Exodus 31 in the BOHLNT
Exodus 31 in the BOHNTLTAL
Exodus 31 in the BOICB
Exodus 31 in the BOILNTAP
Exodus 31 in the BOITCV
Exodus 31 in the BOKCV
Exodus 31 in the BOKCV2
Exodus 31 in the BOKHWOG
Exodus 31 in the BOKSSV
Exodus 31 in the BOLCB
Exodus 31 in the BOLCB2
Exodus 31 in the BOMCV
Exodus 31 in the BONAV
Exodus 31 in the BONCB
Exodus 31 in the BONLT
Exodus 31 in the BONUT2
Exodus 31 in the BOPLNT
Exodus 31 in the BOSCB
Exodus 31 in the BOSNC
Exodus 31 in the BOTLNT
Exodus 31 in the BOVCB
Exodus 31 in the BPBB
Exodus 31 in the BPH
Exodus 31 in the BSB
Exodus 31 in the CCB
Exodus 31 in the CUV
Exodus 31 in the CUVS
Exodus 31 in the DBT
Exodus 31 in the DGDNT
Exodus 31 in the DHNT
Exodus 31 in the DNT
Exodus 31 in the ELBE
Exodus 31 in the EMTV
Exodus 31 in the ESV
Exodus 31 in the FBV
Exodus 31 in the FEB
Exodus 31 in the GGMNT
Exodus 31 in the GNT
Exodus 31 in the HARY
Exodus 31 in the HNT
Exodus 31 in the IRVA
Exodus 31 in the IRVB
Exodus 31 in the IRVG
Exodus 31 in the IRVH
Exodus 31 in the IRVK
Exodus 31 in the IRVM
Exodus 31 in the IRVM2
Exodus 31 in the IRVO
Exodus 31 in the IRVP
Exodus 31 in the IRVT
Exodus 31 in the IRVT2
Exodus 31 in the IRVU
Exodus 31 in the ISVN
Exodus 31 in the JSNT
Exodus 31 in the KAPI
Exodus 31 in the KBT1ETNIK
Exodus 31 in the KBV
Exodus 31 in the KJV
Exodus 31 in the KNFD
Exodus 31 in the LBA
Exodus 31 in the LBLA
Exodus 31 in the LNT
Exodus 31 in the LSV
Exodus 31 in the MAAL
Exodus 31 in the MBV
Exodus 31 in the MBV2
Exodus 31 in the MHNT
Exodus 31 in the MKNFD
Exodus 31 in the MNG
Exodus 31 in the MNT
Exodus 31 in the MNT2
Exodus 31 in the MRS1T
Exodus 31 in the NAA
Exodus 31 in the NASB
Exodus 31 in the NBLA
Exodus 31 in the NBS
Exodus 31 in the NBVTP
Exodus 31 in the NET2
Exodus 31 in the NIV11
Exodus 31 in the NNT
Exodus 31 in the NNT2
Exodus 31 in the NNT3
Exodus 31 in the PDDPT
Exodus 31 in the PFNT
Exodus 31 in the RMNT
Exodus 31 in the SBIAS
Exodus 31 in the SBIBS
Exodus 31 in the SBIBS2
Exodus 31 in the SBICS
Exodus 31 in the SBIDS
Exodus 31 in the SBIGS
Exodus 31 in the SBIHS
Exodus 31 in the SBIIS
Exodus 31 in the SBIIS2
Exodus 31 in the SBIIS3
Exodus 31 in the SBIKS
Exodus 31 in the SBIKS2
Exodus 31 in the SBIMS
Exodus 31 in the SBIOS
Exodus 31 in the SBIPS
Exodus 31 in the SBISS
Exodus 31 in the SBITS
Exodus 31 in the SBITS2
Exodus 31 in the SBITS3
Exodus 31 in the SBITS4
Exodus 31 in the SBIUS
Exodus 31 in the SBIVS
Exodus 31 in the SBT
Exodus 31 in the SBT1E
Exodus 31 in the SCHL
Exodus 31 in the SNT
Exodus 31 in the SUSU
Exodus 31 in the SUSU2
Exodus 31 in the SYNO
Exodus 31 in the TBIAOTANT
Exodus 31 in the TBT1E
Exodus 31 in the TBT1E2
Exodus 31 in the TFTIP
Exodus 31 in the TFTU
Exodus 31 in the TGNTATF3T
Exodus 31 in the THAI
Exodus 31 in the TNFD
Exodus 31 in the TNT
Exodus 31 in the TNTIK
Exodus 31 in the TNTIL
Exodus 31 in the TNTIN
Exodus 31 in the TNTIP
Exodus 31 in the TNTIZ
Exodus 31 in the TOMA
Exodus 31 in the TTENT
Exodus 31 in the UBG
Exodus 31 in the UGV
Exodus 31 in the UGV2
Exodus 31 in the UGV3
Exodus 31 in the VBL
Exodus 31 in the VDCC
Exodus 31 in the YALU
Exodus 31 in the YAPE
Exodus 31 in the YBVTP
Exodus 31 in the ZBP