Genesis 13 (BOYCB)
1 Abramu sì gòkè láti Ejibiti lọ sí ìhà gúúsù, pẹ̀lú aya rẹ̀ àti ohun gbogbo tí ó ní àti Lọti pẹ̀lú. 2 Abramu sì ti di ọlọ́rọ̀ gidigidi; ní ẹran ọ̀sìn, ó ní fàdákà àti wúrà. 3 Láti gúúsù, ó ń lọ láti ibìkan sí ibòmíràn títí ó fi dé ilẹ̀ Beteli, ní ibi tí àgọ́ rẹ̀ ti wà ní ìṣáájú rí, lágbedeméjì Beteli àti Ai. 4 Ní ibi pẹpẹ tí ó ti tẹ́ síbẹ̀ ní ìṣáájú, níbẹ̀ ni Abramu sì ń ké pe orúkọ OLÚWA. 5 Àti Lọti pẹ̀lú, tí ó ń bá Abramu rìn kiri, ní agbo ẹran, ọ̀wọ́ ẹran àti àgọ́. 6 Ṣùgbọ́n ilẹ̀ náà kò le gbà wọ́n tí wọ́n bá ń gbé pọ̀, nítorí, ohun ìní wọn pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, dé bi wí pé wọn kò le è gbé pọ̀. 7 Èdè-àìyedè sì bẹ̀rẹ̀ láàrín àwọn darandaran Abramu àti ti Lọti. Àwọn ará Kenaani àti àwọn ará Peresi sì ń gbé ní ilẹ̀ náà nígbà náà. 8 Abramu sì wí fún Lọti pé, “Èmi bẹ̀ ọ́, má ṣe jẹ́ kí èdè-àìyedè kí ó wà láàrín èmi àti ìrẹ, àti láàrín àwọn darandaran wa, nítorí pé ẹbí kan ni àwa ṣe. 9 Gbogbo ilẹ̀ ha kọ́ nìyí níwájú rẹ? Jẹ́ kí a pínyà. Bí ìwọ bá lọ sí apá ọ̀tún, èmi yóò lọ sí apá òsì, bí ó sì ṣe òsì ni ìwọ lọ, èmi yóò lọ sí apá ọ̀tún.” 10 Lọti sì gbójú sókè, ó sì ri wí pé gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jordani ni omi rin dáradára bí ọgbà OLÚWA, bí ilẹ̀ Ejibiti, ní ọ̀nà Soari. (Èyí ní ìṣáájú kí OLÚWA tó pa Sodomu àti Gomorra run.) 11 Nítorí náà Lọti yan gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jordani yìí fún ara rẹ̀, ó sì ń lọ sí ọ̀nà ìlà-oòrùn. Òun àti Abramu sì pínyà. 12 Abramu ń gbé ni ilẹ̀ Kenaani, Lọti sì jókòó ní ìlú agbègbè àfonífojì náà, ó sì pàgọ́ rẹ̀ títí dé Sodomu. 13 Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin Sodomu jẹ́ ènìyàn búburú, wọn sì ń dẹ́ṣẹ̀ gidigidi ni iwájú OLÚWA. 14 OLÚWA sì wí fún Abramu lẹ́yìn ìpinyà òun àti Lọti pé, “Gbé ojú rẹ sókè nísinsin yìí, kí o sì wò láti ibi tí o gbé wà a nì lọ sí ìhà àríwá àti sí ìhà gúúsù, sí ìlà-oòrùn àti sí ìwọ̀ rẹ̀. 15 Gbogbo ilẹ̀ tí ìwọ ń wò o nì ni èmi ó fi fún ọ àti irú-ọmọ rẹ láéláé. 16 Èmi yóò mú kí irú-ọmọ rẹ kí ó pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí ó bá ṣe pé ẹnikẹ́ni bá le è ka erùpẹ̀ ilẹ̀, nígbà náà ni yóò tó lè ka irú-ọmọ rẹ. 17 Dìde, rìn òró àti ìbú ilẹ̀ náà já, nítorí ìwọ ni Èmi yóò fi fún.” 18 Nígbà náà ni Abramu kó àgọ́ rẹ̀, ó sì wá, ó sì jókòó ní ẹ̀gbẹ́ igi ńlá igbó Mamre, tí ó wà ní Hebroni. Níbẹ̀ ni ó gbé tẹ́ pẹpẹ kan sí fún OLÚWA.
In Other Versions
Genesis 13 in the ANGEFD
Genesis 13 in the ANTPNG2D
Genesis 13 in the AS21
Genesis 13 in the BAGH
Genesis 13 in the BBPNG
Genesis 13 in the BBT1E
Genesis 13 in the BDS
Genesis 13 in the BEV
Genesis 13 in the BHAD
Genesis 13 in the BIB
Genesis 13 in the BLPT
Genesis 13 in the BNT
Genesis 13 in the BNTABOOT
Genesis 13 in the BNTLV
Genesis 13 in the BOATCB
Genesis 13 in the BOATCB2
Genesis 13 in the BOBCV
Genesis 13 in the BOCNT
Genesis 13 in the BOECS
Genesis 13 in the BOGWICC
Genesis 13 in the BOHCB
Genesis 13 in the BOHCV
Genesis 13 in the BOHLNT
Genesis 13 in the BOHNTLTAL
Genesis 13 in the BOICB
Genesis 13 in the BOILNTAP
Genesis 13 in the BOITCV
Genesis 13 in the BOKCV
Genesis 13 in the BOKCV2
Genesis 13 in the BOKHWOG
Genesis 13 in the BOKSSV
Genesis 13 in the BOLCB
Genesis 13 in the BOLCB2
Genesis 13 in the BOMCV
Genesis 13 in the BONAV
Genesis 13 in the BONCB
Genesis 13 in the BONLT
Genesis 13 in the BONUT2
Genesis 13 in the BOPLNT
Genesis 13 in the BOSCB
Genesis 13 in the BOSNC
Genesis 13 in the BOTLNT
Genesis 13 in the BOVCB
Genesis 13 in the BPBB
Genesis 13 in the BPH
Genesis 13 in the BSB
Genesis 13 in the CCB
Genesis 13 in the CUV
Genesis 13 in the CUVS
Genesis 13 in the DBT
Genesis 13 in the DGDNT
Genesis 13 in the DHNT
Genesis 13 in the DNT
Genesis 13 in the ELBE
Genesis 13 in the EMTV
Genesis 13 in the ESV
Genesis 13 in the FBV
Genesis 13 in the FEB
Genesis 13 in the GGMNT
Genesis 13 in the GNT
Genesis 13 in the HARY
Genesis 13 in the HNT
Genesis 13 in the IRVA
Genesis 13 in the IRVB
Genesis 13 in the IRVG
Genesis 13 in the IRVH
Genesis 13 in the IRVK
Genesis 13 in the IRVM
Genesis 13 in the IRVM2
Genesis 13 in the IRVO
Genesis 13 in the IRVP
Genesis 13 in the IRVT
Genesis 13 in the IRVT2
Genesis 13 in the IRVU
Genesis 13 in the ISVN
Genesis 13 in the JSNT
Genesis 13 in the KAPI
Genesis 13 in the KBT1ETNIK
Genesis 13 in the KBV
Genesis 13 in the KJV
Genesis 13 in the KNFD
Genesis 13 in the LBA
Genesis 13 in the LBLA
Genesis 13 in the LNT
Genesis 13 in the LSV
Genesis 13 in the MAAL
Genesis 13 in the MBV
Genesis 13 in the MBV2
Genesis 13 in the MHNT
Genesis 13 in the MKNFD
Genesis 13 in the MNG
Genesis 13 in the MNT
Genesis 13 in the MNT2
Genesis 13 in the MRS1T
Genesis 13 in the NAA
Genesis 13 in the NASB
Genesis 13 in the NBLA
Genesis 13 in the NBS
Genesis 13 in the NBVTP
Genesis 13 in the NET2
Genesis 13 in the NIV11
Genesis 13 in the NNT
Genesis 13 in the NNT2
Genesis 13 in the NNT3
Genesis 13 in the PDDPT
Genesis 13 in the PFNT
Genesis 13 in the RMNT
Genesis 13 in the SBIAS
Genesis 13 in the SBIBS
Genesis 13 in the SBIBS2
Genesis 13 in the SBICS
Genesis 13 in the SBIDS
Genesis 13 in the SBIGS
Genesis 13 in the SBIHS
Genesis 13 in the SBIIS
Genesis 13 in the SBIIS2
Genesis 13 in the SBIIS3
Genesis 13 in the SBIKS
Genesis 13 in the SBIKS2
Genesis 13 in the SBIMS
Genesis 13 in the SBIOS
Genesis 13 in the SBIPS
Genesis 13 in the SBISS
Genesis 13 in the SBITS
Genesis 13 in the SBITS2
Genesis 13 in the SBITS3
Genesis 13 in the SBITS4
Genesis 13 in the SBIUS
Genesis 13 in the SBIVS
Genesis 13 in the SBT
Genesis 13 in the SBT1E
Genesis 13 in the SCHL
Genesis 13 in the SNT
Genesis 13 in the SUSU
Genesis 13 in the SUSU2
Genesis 13 in the SYNO
Genesis 13 in the TBIAOTANT
Genesis 13 in the TBT1E
Genesis 13 in the TBT1E2
Genesis 13 in the TFTIP
Genesis 13 in the TFTU
Genesis 13 in the TGNTATF3T
Genesis 13 in the THAI
Genesis 13 in the TNFD
Genesis 13 in the TNT
Genesis 13 in the TNTIK
Genesis 13 in the TNTIL
Genesis 13 in the TNTIN
Genesis 13 in the TNTIP
Genesis 13 in the TNTIZ
Genesis 13 in the TOMA
Genesis 13 in the TTENT
Genesis 13 in the UBG
Genesis 13 in the UGV
Genesis 13 in the UGV2
Genesis 13 in the UGV3
Genesis 13 in the VBL
Genesis 13 in the VDCC
Genesis 13 in the YALU
Genesis 13 in the YAPE
Genesis 13 in the YBVTP
Genesis 13 in the ZBP