Judges 12 (BOYCB)
1 Àwọn ọkùnrin Efraimu pe àwọn ológun wọn jáde, wọ́n sì rékọjá sí ìhà àríwá, wọ́n sì bi Jefta pé, “Èéṣe tí o fi lọ bá àwọn ará Ammoni jagun láì ké sí wa láti bá ọ lọ? Àwa yóò sun ilé rẹ mọ́ ọ lórí.” 2 Jefta dáhùn pé, “Èmi àti àwọn ènìyàn ní ìyọnu ńlá pẹ̀lú àwọn ará Ammoni, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo pè yín, ẹ̀yin kò gbà mí sílẹ̀ ní ọwọ́ wọn. 3 Nígbà tí mo rí i pé ẹ̀yin kò gbà mí, mo fi ẹ̀mí mi wéwu. Mó sì gòkè lọ láti bá àwọn ará Ammoni jà, OLÚWA sì fún mi ní ìṣẹ́gun lórí wọn, èéṣe báyìí tí ẹ fi dìde wá lónìí láti bá mi jà?” 4 Nígbà náà ni Jefta kó gbogbo ọkùnrin Gileadi jọ, ó sì bá Efraimu jà. Àwọn ọkùnrin Gileadi sì kọlù Efraimu, nítorí wọ́n ti sọtẹ́lẹ̀ pé, “Ẹ̀yin ará Gileadi jẹ́ àsáwọ̀ àwọn ará Efraimu àti ti Manase.” 5 Àwọn ará Gileadi gba à bá wọ odò Jordani tí wọ́n máa gbà lọ sí Efraimu, nígbàkígbà tí àwọn ará Efraimu bá wí pé, “Jẹ́ kí ń sálọ sí òkè,” lọ́hùn ún àwọn ará Gileadi yóò bi í pé, “Ṣé ará Efraimu ni ìwọ ń ṣe?” Tí ó bá wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́,” 6 wọ́n ó wí fún un pé, “Ó dá à wí pé ‘Ṣibolẹti.’ ” Tí ó bá ní, “Sibolẹti,” torí pé kò ní mọ̀ ọ́n pé dáradára, wọ́n á mú un wọn, a sì pa á ni à bá wọ odò Jordani. Àwọn ará Efraimu tí wọn pa ní àkókò yìí jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìlélógójì (42,000) ọkùnrin. 7 Jefta ṣe ìdájọ́ Israẹli ní ọdún mẹ́fà. Lẹ́yìn náà Jefta ará Gileadi kú, wọ́n sì sin ín sí ọ̀kan nínú àwọn ìlú Gileadi. 8 Lẹ́yìn Jefta, Ibsani ará Bẹtilẹhẹmu ṣe ìdájọ́ àwọn ọmọ Israẹli. 9 Ó ní ọgbọ̀n ọmọkùnrin àti ọgbọ̀n ọmọbìnrin fún àwọn tí kì í ṣe ẹ̀yà rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìyàwó, ó sì fẹ́ ọgbọ̀n àwọn ọmọbìnrin fún àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin lára àwọn tí kì í ṣe ẹ̀yà rẹ̀. Ibsani ṣe ìdájọ́ Israẹli fún ọdún méje. 10 Lẹ́yìn náà ni Ibsani kú, wọ́n sì sin ín sí Bẹtilẹhẹmu. 11 Lẹ́yìn rẹ̀, Eloni ti ẹ̀yà Sebuluni ṣe àkóso Israẹli fún ọdún mẹ́wàá. 12 Eloni sì kú, wọ́n sì sin ín sí Aijaloni ní ilẹ̀ Sebuluni. 13 Lẹ́yìn rẹ̀ ni Abdoni ọmọ Hileli tí Piratoni n ṣe àkóso Israẹli. 14 Òun ní ogójì ọmọkùnrin àti ọgbọ̀n ọmọ ọmọ àwọn tí ó ń gun àádọ́rin kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Ó ṣe ìdájọ́ Israẹli ní ọdún mẹ́jọ. 15 Abdoni ọmọ Hileli sì kú, wọ́n sin ín sí Piratoni ní ilé Efraimu ní ìlú òkè àwọn ará Amaleki.
In Other Versions
Judges 12 in the ANGEFD
Judges 12 in the ANTPNG2D
Judges 12 in the AS21
Judges 12 in the BAGH
Judges 12 in the BBPNG
Judges 12 in the BBT1E
Judges 12 in the BDS
Judges 12 in the BEV
Judges 12 in the BHAD
Judges 12 in the BIB
Judges 12 in the BLPT
Judges 12 in the BNT
Judges 12 in the BNTABOOT
Judges 12 in the BNTLV
Judges 12 in the BOATCB
Judges 12 in the BOATCB2
Judges 12 in the BOBCV
Judges 12 in the BOCNT
Judges 12 in the BOECS
Judges 12 in the BOGWICC
Judges 12 in the BOHCB
Judges 12 in the BOHCV
Judges 12 in the BOHLNT
Judges 12 in the BOHNTLTAL
Judges 12 in the BOICB
Judges 12 in the BOILNTAP
Judges 12 in the BOITCV
Judges 12 in the BOKCV
Judges 12 in the BOKCV2
Judges 12 in the BOKHWOG
Judges 12 in the BOKSSV
Judges 12 in the BOLCB
Judges 12 in the BOLCB2
Judges 12 in the BOMCV
Judges 12 in the BONAV
Judges 12 in the BONCB
Judges 12 in the BONLT
Judges 12 in the BONUT2
Judges 12 in the BOPLNT
Judges 12 in the BOSCB
Judges 12 in the BOSNC
Judges 12 in the BOTLNT
Judges 12 in the BOVCB
Judges 12 in the BPBB
Judges 12 in the BPH
Judges 12 in the BSB
Judges 12 in the CCB
Judges 12 in the CUV
Judges 12 in the CUVS
Judges 12 in the DBT
Judges 12 in the DGDNT
Judges 12 in the DHNT
Judges 12 in the DNT
Judges 12 in the ELBE
Judges 12 in the EMTV
Judges 12 in the ESV
Judges 12 in the FBV
Judges 12 in the FEB
Judges 12 in the GGMNT
Judges 12 in the GNT
Judges 12 in the HARY
Judges 12 in the HNT
Judges 12 in the IRVA
Judges 12 in the IRVB
Judges 12 in the IRVG
Judges 12 in the IRVH
Judges 12 in the IRVK
Judges 12 in the IRVM
Judges 12 in the IRVM2
Judges 12 in the IRVO
Judges 12 in the IRVP
Judges 12 in the IRVT
Judges 12 in the IRVT2
Judges 12 in the IRVU
Judges 12 in the ISVN
Judges 12 in the JSNT
Judges 12 in the KAPI
Judges 12 in the KBT1ETNIK
Judges 12 in the KBV
Judges 12 in the KJV
Judges 12 in the KNFD
Judges 12 in the LBA
Judges 12 in the LBLA
Judges 12 in the LNT
Judges 12 in the LSV
Judges 12 in the MAAL
Judges 12 in the MBV
Judges 12 in the MBV2
Judges 12 in the MHNT
Judges 12 in the MKNFD
Judges 12 in the MNG
Judges 12 in the MNT
Judges 12 in the MNT2
Judges 12 in the MRS1T
Judges 12 in the NAA
Judges 12 in the NASB
Judges 12 in the NBLA
Judges 12 in the NBS
Judges 12 in the NBVTP
Judges 12 in the NET2
Judges 12 in the NIV11
Judges 12 in the NNT
Judges 12 in the NNT2
Judges 12 in the NNT3
Judges 12 in the PDDPT
Judges 12 in the PFNT
Judges 12 in the RMNT
Judges 12 in the SBIAS
Judges 12 in the SBIBS
Judges 12 in the SBIBS2
Judges 12 in the SBICS
Judges 12 in the SBIDS
Judges 12 in the SBIGS
Judges 12 in the SBIHS
Judges 12 in the SBIIS
Judges 12 in the SBIIS2
Judges 12 in the SBIIS3
Judges 12 in the SBIKS
Judges 12 in the SBIKS2
Judges 12 in the SBIMS
Judges 12 in the SBIOS
Judges 12 in the SBIPS
Judges 12 in the SBISS
Judges 12 in the SBITS
Judges 12 in the SBITS2
Judges 12 in the SBITS3
Judges 12 in the SBITS4
Judges 12 in the SBIUS
Judges 12 in the SBIVS
Judges 12 in the SBT
Judges 12 in the SBT1E
Judges 12 in the SCHL
Judges 12 in the SNT
Judges 12 in the SUSU
Judges 12 in the SUSU2
Judges 12 in the SYNO
Judges 12 in the TBIAOTANT
Judges 12 in the TBT1E
Judges 12 in the TBT1E2
Judges 12 in the TFTIP
Judges 12 in the TFTU
Judges 12 in the TGNTATF3T
Judges 12 in the THAI
Judges 12 in the TNFD
Judges 12 in the TNT
Judges 12 in the TNTIK
Judges 12 in the TNTIL
Judges 12 in the TNTIN
Judges 12 in the TNTIP
Judges 12 in the TNTIZ
Judges 12 in the TOMA
Judges 12 in the TTENT
Judges 12 in the UBG
Judges 12 in the UGV
Judges 12 in the UGV2
Judges 12 in the UGV3
Judges 12 in the VBL
Judges 12 in the VDCC
Judges 12 in the YALU
Judges 12 in the YAPE
Judges 12 in the YBVTP
Judges 12 in the ZBP