Judges 17 (BOYCB)
1 Nígbà náà ni ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mika láti agbègbè òkè Efraimu 2 sọ fún ìyá rẹ̀ pé, “Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀fà ṣékélì fàdákà èyí tí wọ́n jí mọ́ ọ lọ́wọ́, àti nípa èyí tí mo gbọ́ tí ìwọ ń ṣẹ́ èpè. Kíyèsi fàdákà náà wà ní ọ̀dọ̀ mi, èmi ni mo kó o.”Nígbà náà ni ìyá rẹ̀ dáhùn pé, “Kí OLÚWA bùkún ọ ọmọ mi!” 3 Nígbà tí ó da ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀fà ṣékélì fàdákà náà padà fún ìyá rẹ̀, ìyá rẹ̀ dáhùn pé, “Èmi ti fi òtítọ́ inú ya sílífà náà sọ́tọ̀ sí OLÚWA fún ọmọ mi láti fi dá ère dídá àti ère gbígbẹ́. Èmi yóò dá a padà fún ọ.” 4 Nítorí náà òun dá sílífà náà padà fún ìyá rẹ̀, ìyá rẹ̀ sì mú igba ṣékélì fàdákà, ó sì fún alágbẹ̀dẹ fàdákà ẹni tí ó fi wọ́n rọ ère fínfín àti ère dídà. Wọ́n sì kó wọn sí ilé Mika. 5 Ọkùnrin náà, Mika sì ní ojúbọ kan. Òun sì ra ẹ̀wù efodu kan, ó sì ṣe àwọn ère kan, ó sì fi ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin ṣe àlùfáà rẹ̀. 6 Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì àwọn ọmọ Israẹli kò ní ọba; olúkúlùkù ṣe bí ó ti rò pé ó tọ́ ní ojú ara rẹ́. 7 Ọ̀dọ́mọkùnrin kan sì ti Bẹtilẹhẹmu ti Juda wá, tí í ṣe ìdílé Juda, ẹni tí í ṣe ẹ̀yà Lefi, òun sì ṣe àtìpó níbẹ̀, 8 ọkùnrin náà sì ti ìlú Bẹtilẹhẹmu ti Juda lọ, láti ṣe àtìpó ní ibikíbi tí ó bá rí. Ní ojú ọ̀nà àjò rẹ̀, ó dé ilẹ̀ Mika nínú àwọn ilẹ̀ òkè Efraimu. 9 Mika bi í pé, “Níbo ni ó ti ń bọ̀?”Ó dáhùn pé, “Ọmọ Lefi ni mí láti Bẹtilẹhẹmu Juda, mo sì ń wá ibi tí èmi yóò máa gbé.” 10 Mika sì sọ fún un wí pé, “Dúró lọ́dọ̀ mi kí ìwọ sì jẹ́ baba mi àti àlùfáà fún mi, èmi ó sì máa fún ọ ní ṣékélì mẹ́wàá fàdákà ní ọdọọdún, pẹ̀lú aṣọ àti oúnjẹ rẹ̀.” 11 Ọmọ Lefi náà sì gbà láti máa bá a gbé, ọ̀dọ́mọkùnrin náà sì dàbí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀. 12 Nígbà náà ni Mika ya ará Lefi náà sí mímọ́, ọ̀dọ́mọkùnrin náà sì di àlùfáà rẹ̀, ó sì ń gbé ilé rẹ̀. 13 Mika sì wí pé, “Báyìí, èmi mọ̀ pé OLÚWA yóò ṣe mi ní oore nítorí pé mo ní ọmọ Lefi ní àlùfáà mi.”
In Other Versions
Judges 17 in the ANGEFD
Judges 17 in the ANTPNG2D
Judges 17 in the AS21
Judges 17 in the BAGH
Judges 17 in the BBPNG
Judges 17 in the BBT1E
Judges 17 in the BDS
Judges 17 in the BEV
Judges 17 in the BHAD
Judges 17 in the BIB
Judges 17 in the BLPT
Judges 17 in the BNT
Judges 17 in the BNTABOOT
Judges 17 in the BNTLV
Judges 17 in the BOATCB
Judges 17 in the BOATCB2
Judges 17 in the BOBCV
Judges 17 in the BOCNT
Judges 17 in the BOECS
Judges 17 in the BOGWICC
Judges 17 in the BOHCB
Judges 17 in the BOHCV
Judges 17 in the BOHLNT
Judges 17 in the BOHNTLTAL
Judges 17 in the BOICB
Judges 17 in the BOILNTAP
Judges 17 in the BOITCV
Judges 17 in the BOKCV
Judges 17 in the BOKCV2
Judges 17 in the BOKHWOG
Judges 17 in the BOKSSV
Judges 17 in the BOLCB
Judges 17 in the BOLCB2
Judges 17 in the BOMCV
Judges 17 in the BONAV
Judges 17 in the BONCB
Judges 17 in the BONLT
Judges 17 in the BONUT2
Judges 17 in the BOPLNT
Judges 17 in the BOSCB
Judges 17 in the BOSNC
Judges 17 in the BOTLNT
Judges 17 in the BOVCB
Judges 17 in the BPBB
Judges 17 in the BPH
Judges 17 in the BSB
Judges 17 in the CCB
Judges 17 in the CUV
Judges 17 in the CUVS
Judges 17 in the DBT
Judges 17 in the DGDNT
Judges 17 in the DHNT
Judges 17 in the DNT
Judges 17 in the ELBE
Judges 17 in the EMTV
Judges 17 in the ESV
Judges 17 in the FBV
Judges 17 in the FEB
Judges 17 in the GGMNT
Judges 17 in the GNT
Judges 17 in the HARY
Judges 17 in the HNT
Judges 17 in the IRVA
Judges 17 in the IRVB
Judges 17 in the IRVG
Judges 17 in the IRVH
Judges 17 in the IRVK
Judges 17 in the IRVM
Judges 17 in the IRVM2
Judges 17 in the IRVO
Judges 17 in the IRVP
Judges 17 in the IRVT
Judges 17 in the IRVT2
Judges 17 in the IRVU
Judges 17 in the ISVN
Judges 17 in the JSNT
Judges 17 in the KAPI
Judges 17 in the KBT1ETNIK
Judges 17 in the KBV
Judges 17 in the KJV
Judges 17 in the KNFD
Judges 17 in the LBA
Judges 17 in the LBLA
Judges 17 in the LNT
Judges 17 in the LSV
Judges 17 in the MAAL
Judges 17 in the MBV
Judges 17 in the MBV2
Judges 17 in the MHNT
Judges 17 in the MKNFD
Judges 17 in the MNG
Judges 17 in the MNT
Judges 17 in the MNT2
Judges 17 in the MRS1T
Judges 17 in the NAA
Judges 17 in the NASB
Judges 17 in the NBLA
Judges 17 in the NBS
Judges 17 in the NBVTP
Judges 17 in the NET2
Judges 17 in the NIV11
Judges 17 in the NNT
Judges 17 in the NNT2
Judges 17 in the NNT3
Judges 17 in the PDDPT
Judges 17 in the PFNT
Judges 17 in the RMNT
Judges 17 in the SBIAS
Judges 17 in the SBIBS
Judges 17 in the SBIBS2
Judges 17 in the SBICS
Judges 17 in the SBIDS
Judges 17 in the SBIGS
Judges 17 in the SBIHS
Judges 17 in the SBIIS
Judges 17 in the SBIIS2
Judges 17 in the SBIIS3
Judges 17 in the SBIKS
Judges 17 in the SBIKS2
Judges 17 in the SBIMS
Judges 17 in the SBIOS
Judges 17 in the SBIPS
Judges 17 in the SBISS
Judges 17 in the SBITS
Judges 17 in the SBITS2
Judges 17 in the SBITS3
Judges 17 in the SBITS4
Judges 17 in the SBIUS
Judges 17 in the SBIVS
Judges 17 in the SBT
Judges 17 in the SBT1E
Judges 17 in the SCHL
Judges 17 in the SNT
Judges 17 in the SUSU
Judges 17 in the SUSU2
Judges 17 in the SYNO
Judges 17 in the TBIAOTANT
Judges 17 in the TBT1E
Judges 17 in the TBT1E2
Judges 17 in the TFTIP
Judges 17 in the TFTU
Judges 17 in the TGNTATF3T
Judges 17 in the THAI
Judges 17 in the TNFD
Judges 17 in the TNT
Judges 17 in the TNTIK
Judges 17 in the TNTIL
Judges 17 in the TNTIN
Judges 17 in the TNTIP
Judges 17 in the TNTIZ
Judges 17 in the TOMA
Judges 17 in the TTENT
Judges 17 in the UBG
Judges 17 in the UGV
Judges 17 in the UGV2
Judges 17 in the UGV3
Judges 17 in the VBL
Judges 17 in the VDCC
Judges 17 in the YALU
Judges 17 in the YAPE
Judges 17 in the YBVTP
Judges 17 in the ZBP