Psalms 134 (BOYCB)
undefined Orin ìgòkè. 1 Ẹ kíyèsi i, ẹ fi ìbùkún fún OLÚWA,gbogbo ẹ̀yin ìránṣẹ́ OLÚWA,tí ó dúró ní ilé OLÚWA ní òru. 2 Ẹ gbé ọwọ́ yín sókè sí ibi mímọ́,kí ẹ sì fi ìbùkún fún OLÚWA. 3 OLÚWA tí ó dá ọ̀run òun ayé,kí ó bùsi i fún ọ láti Sioni wá.