Psalms 147 (BOYCB)
1 Ẹ fi ìyìn fún OLÚWA. Nítorí ohun rere ni láti máa kọrin ìyìn sí Ọlọ́run wa,ó yẹ láti kọrin ìyìn sí i! 2 OLÚWA kọ́ Jerusalẹmu;Ó kó àwọn Israẹli tí a lé sọnù jọ. 3 Ó wo àwọn tí ọkàn wọ́n bàjẹ́ sànó sì di ọgbẹ́ wọ́n. 4 Ó ka iye àwọn ìràwọ̀ó sì pe ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní orúkọ. 5 Títóbi ni Olúwa wa ó sì pọ̀ ní agbáraòye rẹ̀ kò sì ní òpin. 6 OLÚWA wa pẹ̀lú àwọn onírẹ̀lẹ̀bẹ́ẹ̀ ni ó rẹ̀ àwọn ènìyàn búburú sílẹ̀. 7 Fi ọpẹ́ kọrin sí OLÚWAfi ohun èlò orin olókùn yin Ọlọ́run. 8 Ó fi ìkùùkuu bo àwọ̀ sánmọ̀ó rọ òjò sí orílẹ̀ ayéó mú kí koríko hù lórí àwọn òkè 9 Ó pèsè oúnjẹ fún àwọn ẹrankoàti fún àwọn ọmọ ẹyẹ ìwò ní ìgbà tí wọ́n bá ń ké. 10 Òun kò ní inú dídùn nínú agbára ẹṣin,bẹ́ẹ̀ ni Òun kò ní ayọ̀ sí ẹ̀ṣẹ̀ ọkùnrin 11 OLÚWA ni ayọ̀ nínú àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,sí àwọn tí ó ní ìrètí nínú àánú rẹ̀. 12 Yin OLÚWA, ìwọ Jerusalẹmu;yin Ọlọ́run rẹ, ìwọ Sioni. 13 Nítorí tí ó ti mú ọ̀pá ìdábùú ibodè rẹ̀ lágbára,Òun sì ti bùkún fún àwọn ọmọ rẹ̀ nínú rẹ 14 Òun jẹ́ kí àlàáfíà wà ní àwọn ẹnu ibodè rẹ̀,òun sì fi jéró dáradára tẹ́ ọ lọ́rùn. 15 Òun sì rán àṣẹ rẹ̀ sí ayéọ̀rọ̀ rẹ̀ sáré tete. 16 Ó fi yìnyín fún ni bi irun àgùntànó sì fọ́n ìrì dídì ká bí eérú 17 Ó rọ òjò yìnyín rẹ̀ bí òkúta wẹ́wẹ́ta ni ó lè dúró níwájú òtútù rẹ̀ 18 Ó rán ọ̀rọ̀ rẹ̀ jáde ó sì mú wọn yọ̀ó mú kí afẹ́fẹ́ rẹ̀ fẹ́ó sì mú odò rẹ̀ sàn. 19 Ó sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ di mí mọ̀ fún Jakọbuàwọn òfin àti ìlànà rẹ̀ fún Israẹli. 20 Òun kó tí ṣe irú èyí sí orílẹ̀-èdè kan rí, bí ó ṣe ti ìdájọ́ rẹ̀wọn ko mọ òfin rẹ̀. Ẹ fi ìyìn fún OLÚWA.