Psalms 36 (BOYCB)
undefined Fún adarí orin. Ti Dafidi ìránṣẹ́ OLÚWA. 1 Ìré-òfin-kọjá ènìyàn búburújẹ́ kí n mọ̀ nínú ọkàn mi pé,ìbẹ̀rù Ọlọ́run kò síníwájú wọn. 2 Nítorí pé wọ́n pọ́n ara wọn ní ojú ara wọntítí tí a kò fi le rí ẹ̀ṣẹ̀ wọn láti kórìíra. 3 Ọ̀rọ̀ ẹnu wọn ni ẹ̀ṣẹ̀ òhun ẹ̀tàn;wọ́n ti fi ọgbọ́n àti ṣíṣe rere sílẹ̀. 4 Wọ́n gbìmọ̀ ìwà ìkà nígbà tí wọ́n wà lórí ibùsùn wọn:wọ́n gba ọ̀nà tí kò dárawọn kò sì kọ ọ̀nà ibi sílẹ̀. 5 Ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ rẹ, ìwọ OLÚWA, ó ga dé ọ̀run,òtítọ́ ọ̀ rẹ ga dé àwọsánmọ̀. 6 Òdodo rẹ dàbí àwọn òkè Ọlọ́run,àwọn ìdájọ́ rẹ dàbí ibú ńlá;ìwọ gba ẹranko àti ènìyàn là, OLÚWA. 7 Báwo ni ìṣeun ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ rẹ ti tó! Ọlọ́run!Kí gbogbo ọmọ ènìyàn le sá sí abẹ́ òjìji ìyẹ́ rẹ. 8 Àsè ilé rẹ yóò tẹ́ wọn lọ́rùn gidigidi;ìwọ yóò sì mú wọn mu nínú odò inú dídùn rẹ. 9 Nítorí pé pẹ̀lú rẹ ni orísun ìyè wà:nínú ìmọ́lẹ̀ rẹ ni àwa yóò rí ìmọ́lẹ̀. 10 Mú ìṣeun ìfẹ́ ẹ̀ rẹ sí àwọn tí ó mọ̀ ọ́nàti ìgbàlà rẹ sí àwọn tí ó ní ìdúró ṣinṣin ọkàn! 11 Má ṣe jẹ́ kí ẹsẹ̀ agbéraga kí ó wá sí orí mi,kí o má sì jẹ́ kí ọwọ́ àwọn ènìyàn búburú sí mi ní ipò. 12 Níbẹ̀ ni àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ gbé ṣubú sí:a rẹ̀ wọ́n sílẹ̀, wọn kì yóò le è dìde!