1 Chronicles 27 (BOYCB)

1 Wọ̀nyí ni ìwé àkójọ orúkọ àwọn ọmọ Israẹli, àwọn olórí àwọn ìdílé, àwọn balógun ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti àwọn balógun ọ̀rọ̀ọ̀rún àti àwọn ìjòyè wọn. Tí ó n sin ọba nínú gbogbo ohun tí ó kan ìpín àwọn ọmọ-ogun tí ó wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ní oṣooṣù ní gbogbo ọdún. Ìpín kọ̀ọ̀kan jẹ́ ẹgbàá méjìlá (24,000) ọkùnrin. 2 Ní ti alákòóso lórí ìpín kìn-ín-ní fún oṣù kìn-ín-ní jẹ́ Jaṣobeamu ọmọ Sabdieli àwọn ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ní ó wà ní abẹ́ ìpín tirẹ̀. 3 Ó jẹ́ ìran ọmọ Peresi àti olóyè fún gbogbo àwọn ìjòyè ológun fún oṣù kìn-ín-ní. 4 Alákòóso fún ìpín àwọn ọmọ-ogun fún oṣù kejì jẹ́ Dodai ará Ahohi; Mikloti jẹ́ olórí ìpín tirẹ̀. Ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ni ó wà ní ìpín tirẹ̀. 5 Olórí àwọn ọmọ-ogun ẹlẹ́ẹ̀kẹta fún oṣù kẹta jẹ́ Benaiah ọmọ Jehoiada àlùfáà. Ó jẹ́ olóyè, àwọn ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ní ó wà ní ìpín tirẹ̀. 6 Èyí ni Benaiah náà tí ó jẹ́ ọkùnrin ńlá láàrín àwọn ọgbọ̀n àti lórí àwọn ọgbọ̀n. Ọmọ rẹ̀ Amisabadi jẹ́ alákòóso lórí ìpín tirẹ̀. 7 Ẹlẹ́ẹ̀kẹrin fún oṣù kẹrin, jẹ́ Asaheli arákùnrin Joabu: ọmọ rẹ̀ Sebadiah jẹ́ arọ́pò rẹ̀. Ẹgbàá méjìlá (24,000) ọkùnrin ni ó wà ní ìpín rẹ̀. 8 Ẹ̀karùnún fún oṣù karùn-ún, jẹ́ olórí Ṣamhuti ará Israhi. Ẹgbàá méjìlá (24,000) ọkùnrin ní ó wà ní ìpín tirẹ̀. 9 Ẹ̀kẹfà fún oṣù kẹfà jẹ́ Ira ọmọ Ikẹsi, ará Tekoi. Ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ni ó wà ní ìpín rẹ̀. 10 Èkeje fún oṣù keje jẹ́ Helesi ará Peloni, ará Efraimu. Ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ni o wà ní ìpín rẹ̀. 11 Ẹ̀kẹjọ fún oṣù kẹjọ jẹ́ Sibekai ará Huṣati, ará Sera ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ni ó wà ní ìpín rẹ̀. 12 Ẹ̀kẹsànán fún oṣù kẹsànán jẹ́. Abieseri ará Anatoti, ará Benjamini ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ni ó wà ní ìpín rẹ̀. 13 Ẹ̀kẹwàá fún oṣù kẹwàá jẹ́ Maharai ará Netofa, ará Sera ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ni ó wà ní ìpín rẹ̀. 14 Ìkọkànlá fún oṣù kọkànlá jẹ́ Benaiah ará Piratoni ará Efraimu ọkùnrin ẹgbàá méjìlá (24,000) ni ó wà ní ìpín tirẹ̀. 15 Èkejìlá fún oṣù kejìlá jẹ́ Heldai ará Netofa láti ìdílé Otnieli. Ẹgbàá méjìlá (24,000) ọkùnrin ni ó wà ní ìpín tirẹ̀. 16 Àwọn ìjòyè lórí àwọn ẹ̀yà tí Israẹli: lórí àwọn ará Reubeni: Elieseri ọmọ Sikri;lórí àwọn ọmọ Simeoni: Ṣefatia ọmọ Maaka; 17 lórí Lefi: Haṣabiah ọmọ Kemueli;lórí Aaroni: Sadoku; 18 lórí Juda: Elihu arákùnrin Dafidi;lórí Isakari: Omri ọmọ Mikaeli; 19 lórí Sebuluni: Iṣmaiah ọmọ Obadiah;lórí Naftali: Jerimoti ọmọ Asrieli; 20 lórí àwọn ará Efraimu: Hosea ọmọ Asasiah;lórí ààbọ̀ ẹ̀yà Manase: Joẹli ọmọ Pedaiah; 21 lórí ààbọ̀ ẹ̀yà Manase ní Gileadi: Iddo ọmọ Sekariah;lórí Benjamini: Jaasieli ọmọ Abneri; 22 lórí Dani: Asareeli ọmọ Jerohamu. Wọ̀nyí ni àwọn ìjòyè lórí ẹ̀yà Israẹli. 23 Dafidi kò kọ iye àwọn ọkùnrin náà ní ogún ọdún sẹ́yìn tàbí dín nítorí OLÚWA ti ṣe ìlérí láti ṣe Israẹli gẹ́gẹ́ bí iye ìràwọ̀ ojú ọ̀run. 24 Joabu ọmọ Seruiah bẹ̀rẹ̀ sí ní kà wọ́n, ṣùgbọ́n kò parí kíkà wọ́n nítorí, ìbínú dé sórí àwọn Israẹli nípasẹ̀ kíka iye àti iye náà, a kò kọ ọ́ sínú ìwé ìtàn ayé ti ọba Dafidi. 25 Asmafeti ọmọ Adieli wà ní ìdí ilé ìṣúra ti ọba.Jonatani ọmọ Ussiah wà ní ìdí ilé ìṣúra ní iwájú agbègbè nínú àwọn ìlú, àwọn ìletò àti àwọn ilé ìṣọ́. 26 Esri ọmọ Kelubu wà ní ìdí àwọn òṣìṣẹ́ lórí pápá, tí wọ́n ń ko ilẹ̀ náà. 27 Ṣimei ará Ramoti wà ní ìdí àwọn ọgbà àjàrà.Sabdi ará Sifmi wà ní ìdí mímú jáde ti èso àjàrà fún ọpọ́n ńlá tí a ń fi ọ̀tún èso àjàrà sí. 28 Baali-Hanani ará Gederi wà ní ìdí olifi àti àwọn igi sikamore ní apá ìhà ìwọ̀-oòrùn àwọn ní ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀tẹ́lẹ̀.Joaṣi wà ní ìdí fífún ni ní òróró olifi. 29 Ṣitrai ará Ṣaroni wà ní ìdí fífi ọwọ́ ẹran jẹ oko ní Ṣaroni.Ṣafati ọmọ Adlai wà ní ìdí àwọn ọ̀wọ́ ẹran ní àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀. 30 Obili ará Iṣmaeli wà ní ìdí àwọn ìbákasẹ.Jehdeiah ará Meronoti wà ní ìdí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. 31 Jasisi ará Hagari wà ní ìdí àwọn agbo ẹran.Gbogbo wọ̀nyí ni àwọn oníṣẹ́ tí wọ́n wà ní ìdí ẹrù ọba Dafidi. 32 Jonatani, arákùnrin Dafidi jẹ́ olùdámọ̀ràn, ọkùnrin onímọ̀ àti akọ̀wé.Jehieli ọmọ Hakmoni bojútó àwọn ọmọ ọba. 33 Ahitofeli jẹ́ olùdámọ̀ràn ọba.Huṣai ará Arki jẹ́ ọ̀rẹ́ ọba. 34 (Jehoiada ọmọ Benaiah àti nípasẹ̀ Abiatari jẹ ọba rọ́pò Ahitofeli.)Joabu jẹ́ olórí ọmọ-ogun ọba.

In Other Versions

1 Chronicles 27 in the ANGEFD

1 Chronicles 27 in the ANTPNG2D

1 Chronicles 27 in the AS21

1 Chronicles 27 in the BAGH

1 Chronicles 27 in the BBPNG

1 Chronicles 27 in the BBT1E

1 Chronicles 27 in the BDS

1 Chronicles 27 in the BEV

1 Chronicles 27 in the BHAD

1 Chronicles 27 in the BIB

1 Chronicles 27 in the BLPT

1 Chronicles 27 in the BNT

1 Chronicles 27 in the BNTABOOT

1 Chronicles 27 in the BNTLV

1 Chronicles 27 in the BOATCB

1 Chronicles 27 in the BOATCB2

1 Chronicles 27 in the BOBCV

1 Chronicles 27 in the BOCNT

1 Chronicles 27 in the BOECS

1 Chronicles 27 in the BOGWICC

1 Chronicles 27 in the BOHCB

1 Chronicles 27 in the BOHCV

1 Chronicles 27 in the BOHLNT

1 Chronicles 27 in the BOHNTLTAL

1 Chronicles 27 in the BOICB

1 Chronicles 27 in the BOILNTAP

1 Chronicles 27 in the BOITCV

1 Chronicles 27 in the BOKCV

1 Chronicles 27 in the BOKCV2

1 Chronicles 27 in the BOKHWOG

1 Chronicles 27 in the BOKSSV

1 Chronicles 27 in the BOLCB

1 Chronicles 27 in the BOLCB2

1 Chronicles 27 in the BOMCV

1 Chronicles 27 in the BONAV

1 Chronicles 27 in the BONCB

1 Chronicles 27 in the BONLT

1 Chronicles 27 in the BONUT2

1 Chronicles 27 in the BOPLNT

1 Chronicles 27 in the BOSCB

1 Chronicles 27 in the BOSNC

1 Chronicles 27 in the BOTLNT

1 Chronicles 27 in the BOVCB

1 Chronicles 27 in the BPBB

1 Chronicles 27 in the BPH

1 Chronicles 27 in the BSB

1 Chronicles 27 in the CCB

1 Chronicles 27 in the CUV

1 Chronicles 27 in the CUVS

1 Chronicles 27 in the DBT

1 Chronicles 27 in the DGDNT

1 Chronicles 27 in the DHNT

1 Chronicles 27 in the DNT

1 Chronicles 27 in the ELBE

1 Chronicles 27 in the EMTV

1 Chronicles 27 in the ESV

1 Chronicles 27 in the FBV

1 Chronicles 27 in the FEB

1 Chronicles 27 in the GGMNT

1 Chronicles 27 in the GNT

1 Chronicles 27 in the HARY

1 Chronicles 27 in the HNT

1 Chronicles 27 in the IRVA

1 Chronicles 27 in the IRVB

1 Chronicles 27 in the IRVG

1 Chronicles 27 in the IRVH

1 Chronicles 27 in the IRVK

1 Chronicles 27 in the IRVM

1 Chronicles 27 in the IRVM2

1 Chronicles 27 in the IRVO

1 Chronicles 27 in the IRVP

1 Chronicles 27 in the IRVT

1 Chronicles 27 in the IRVT2

1 Chronicles 27 in the IRVU

1 Chronicles 27 in the ISVN

1 Chronicles 27 in the JSNT

1 Chronicles 27 in the KAPI

1 Chronicles 27 in the KBT1ETNIK

1 Chronicles 27 in the KBV

1 Chronicles 27 in the KJV

1 Chronicles 27 in the KNFD

1 Chronicles 27 in the LBA

1 Chronicles 27 in the LBLA

1 Chronicles 27 in the LNT

1 Chronicles 27 in the LSV

1 Chronicles 27 in the MAAL

1 Chronicles 27 in the MBV

1 Chronicles 27 in the MBV2

1 Chronicles 27 in the MHNT

1 Chronicles 27 in the MKNFD

1 Chronicles 27 in the MNG

1 Chronicles 27 in the MNT

1 Chronicles 27 in the MNT2

1 Chronicles 27 in the MRS1T

1 Chronicles 27 in the NAA

1 Chronicles 27 in the NASB

1 Chronicles 27 in the NBLA

1 Chronicles 27 in the NBS

1 Chronicles 27 in the NBVTP

1 Chronicles 27 in the NET2

1 Chronicles 27 in the NIV11

1 Chronicles 27 in the NNT

1 Chronicles 27 in the NNT2

1 Chronicles 27 in the NNT3

1 Chronicles 27 in the PDDPT

1 Chronicles 27 in the PFNT

1 Chronicles 27 in the RMNT

1 Chronicles 27 in the SBIAS

1 Chronicles 27 in the SBIBS

1 Chronicles 27 in the SBIBS2

1 Chronicles 27 in the SBICS

1 Chronicles 27 in the SBIDS

1 Chronicles 27 in the SBIGS

1 Chronicles 27 in the SBIHS

1 Chronicles 27 in the SBIIS

1 Chronicles 27 in the SBIIS2

1 Chronicles 27 in the SBIIS3

1 Chronicles 27 in the SBIKS

1 Chronicles 27 in the SBIKS2

1 Chronicles 27 in the SBIMS

1 Chronicles 27 in the SBIOS

1 Chronicles 27 in the SBIPS

1 Chronicles 27 in the SBISS

1 Chronicles 27 in the SBITS

1 Chronicles 27 in the SBITS2

1 Chronicles 27 in the SBITS3

1 Chronicles 27 in the SBITS4

1 Chronicles 27 in the SBIUS

1 Chronicles 27 in the SBIVS

1 Chronicles 27 in the SBT

1 Chronicles 27 in the SBT1E

1 Chronicles 27 in the SCHL

1 Chronicles 27 in the SNT

1 Chronicles 27 in the SUSU

1 Chronicles 27 in the SUSU2

1 Chronicles 27 in the SYNO

1 Chronicles 27 in the TBIAOTANT

1 Chronicles 27 in the TBT1E

1 Chronicles 27 in the TBT1E2

1 Chronicles 27 in the TFTIP

1 Chronicles 27 in the TFTU

1 Chronicles 27 in the TGNTATF3T

1 Chronicles 27 in the THAI

1 Chronicles 27 in the TNFD

1 Chronicles 27 in the TNT

1 Chronicles 27 in the TNTIK

1 Chronicles 27 in the TNTIL

1 Chronicles 27 in the TNTIN

1 Chronicles 27 in the TNTIP

1 Chronicles 27 in the TNTIZ

1 Chronicles 27 in the TOMA

1 Chronicles 27 in the TTENT

1 Chronicles 27 in the UBG

1 Chronicles 27 in the UGV

1 Chronicles 27 in the UGV2

1 Chronicles 27 in the UGV3

1 Chronicles 27 in the VBL

1 Chronicles 27 in the VDCC

1 Chronicles 27 in the YALU

1 Chronicles 27 in the YAPE

1 Chronicles 27 in the YBVTP

1 Chronicles 27 in the ZBP