1 Kings 3 (BOYCB)

1 Solomoni sì bá Farao ọba Ejibiti dá àna, ó sì fẹ́ ọmọbìnrin rẹ̀ ní ìyàwó. Ó sì mú un wá sí ìlú Dafidi títí tí ó fi parí kíkọ́ ààfin rẹ̀ àti tẹmpili OLÚWA, àti odi tí ó yí Jerusalẹmu ká. 2 Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn ènìyàn ṣì ń rú ẹbọ ní ibi gíga, nítorí a kò tí ì kọ́ ilé fún orúkọ OLÚWA títí di ìgbà náà 3 Solomoni sì fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn sí OLÚWA nípa rírìn gẹ́gẹ́ bí òfin Dafidi baba rẹ̀, àti pé, ó rú ẹbọ, ó sì fi tùràrí jóná ní ibi gíga. 4 Ọba sì lọ sí Gibeoni láti rú ẹbọ, nítorí ibẹ̀ ni ibi gíga tí ó ṣe pàtàkì jù, Solomoni sì rú ẹgbẹ̀rún (1,000) ọrẹ ẹbọ sísun lórí pẹpẹ. 5 Ní Gibeoni, OLÚWA fi ara han Solomoni lójú àlá ní òru, Ọlọ́run sì wí pé, “Béèrè fún ohunkóhun tí o bá ń fẹ́ kí èmi ó fi fún ọ.” 6 Solomoni sì dáhùn wí pé, “O ti fi inú rere oore ńlá hàn sí ìránṣẹ́ rẹ, Dafidi baba mi, nítorí ó jẹ́ olóòtítọ́ sí ọ àti olódodo àti ẹni tí ó ní ọkàn ìdúró ṣinṣin. Ìwọ sì tẹ̀síwájú nínú oore ńlá yìí fún un, ìwọ sì ti fún un ní ọmọkùnrin láti jókòó lórí ìtẹ́ rẹ ní gbogbo ọjọ́. 7 “Nísinsin yìí, OLÚWA Ọlọ́run mi, o ti mú ìránṣẹ́ rẹ jẹ ọba ní ipò Dafidi baba mi. Ṣùgbọ́n ọmọ kékeré ni mí, èmi kò sì mọ jíjáde àti wíwọlé mi. 8 Ìránṣẹ́ rẹ nìyí láàrín àwọn ènìyàn tí o ti yàn, àwọn ènìyàn ńlá, wọ́n pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí a kò sì lè kà wọ́n tàbí mọye wọn. 9 Nítorí náà fi ọkàn ìmòye fún ìránṣẹ́ rẹ láti le ṣàkóso àwọn ènìyàn rẹ àti láti mọ ìyàtọ̀ láàrín rere àti búburú. Nítorí ta ni ó lè ṣe àkóso àwọn ènìyàn ńlá rẹ yìí?” 10 Inú Olúwa sì dùn pé Solomoni béèrè nǹkan yìí. 11 Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún un pé, “Nítorí tí ìwọ ti béèrè fún èyí, tí kì í ṣe ẹ̀mí gígùn tàbí ọrọ̀ fún ara rẹ, tàbí béèrè fún ikú àwọn ọ̀tá rẹ, ṣùgbọ́n fún òye láti mọ ẹjọ́ dá, 12 èmi yóò ṣe ohun tí ìwọ ti béèrè. Èmi yóò fún ọ ní ọgbọ́n àti ọkàn ìmòye, tó bẹ́ẹ̀ tí kò fi ní sí ẹnìkan tí ó dàbí rẹ ṣáájú rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kì yóò dìde tí yóò dàbí rẹ lẹ́yìn rẹ. 13 Síwájú sí i, èmi yóò fi ohun tí ìwọ kò béèrè fún ọ: ọrọ̀ àti ọlá ní gbogbo ayé rẹ, tí kì yóò sí ẹnìkan nínú àwọn ọba tí yóò dàbí rẹ. 14 Àti bí ìwọ bá rìn ní ọ̀nà mi, tí o sì pa òfin àti àṣẹ mi mọ́ bí Dafidi baba rẹ ti ṣe, èmi yóò fún ọ ní ẹ̀mí gígùn.” 15 Solomoni jí: ó sì mọ̀ pé àlá ni.Ó sì padà sí Jerusalẹmu, ó sì dúró níwájú àpótí ẹ̀rí OLÚWA, ó sì rú ẹbọ sísun àti ẹbọ àlàáfíà. Nígbà náà ni ó ṣe àsè fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. 16 Lẹ́yìn náà ni àwọn obìnrin alágbèrè méjì wá sọ́dọ̀ ọba, wọ́n sì dúró níwájú rẹ̀. 17 Ọ̀kan nínú wọn sì wí pé, “Olúwa mi, èmi àti obìnrin yìí ń gbé nínú ilé kan. Èmi sì bí ọmọ ní ilé pẹ̀lú rẹ̀. 18 Ní ọjọ́ kẹta lẹ́yìn ìgbà tí mo bímọ tan, obìnrin yìí sì bímọ pẹ̀lú. A sì nìkan dá wà; kò sí àlejò ní ilé bí kò ṣe àwa méjèèjì nìkan. 19 “Ní òru, ọmọ obìnrin yìí kú nítorí tí ó sùn lé e. 20 Nígbà náà ni ó sì dìde ní ọ̀gànjọ́, ó sì gbé ọmọ tèmi lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi, nígbà tí èmi ìránṣẹ́ rẹ̀ ti sùn lọ. Ó sì tẹ́ ẹ sí àyà rẹ̀, ó sì tẹ́ òkú ọmọ tirẹ̀ sí àyà mi. 21 Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, mo sì dìde láti fi ọmú fún ọmọ mi: ó sì ti kú! Ṣùgbọ́n, nígbà tí mo sì wò ó fín ní òwúrọ̀, mo sì rí i pé kì í ṣe ọmọ mi tí mo bí.” 22 Obìnrin kejì sì wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́! Èyí alààyè ni ọmọ mi, èyí òkú ni ọmọ tirẹ̀.” Èyí òkú ni tirẹ̀; èyí alààyè ni tèmi.Ṣùgbọ́n èyí àkọ́kọ́ tún wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́! Èyí òkú ni tìrẹ; èyí alààyè ni tèmi.” Báyìí ni wọ́n sì ń jiyàn níwájú ọba. 23 Ọba sì wí pé, “Ẹni yìí wí pé, ‘Ọmọ mi ni ó wà láààyè, ọmọ tirẹ̀ ni ó kú,’ nígbà tí ẹni èkejì náà ń wí pé, ‘Bẹ́ẹ̀ kọ́! Ọmọ tirẹ̀ ni ó kú, ọmọ tèmi ni ó wà láààyè.’ ” 24 Nígbà náà ni ọba wí pé, “Ẹ mú idà fún mi wá.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì mú idà wá fún ọba. 25 Ọba sì pàṣẹ pé, “Ẹ gé alààyè ọmọ sí méjì, kí ẹ sì mú ìdajì fún ọ̀kan, àti ìdajì fún èkejì.” 26 Obìnrin tí ọmọ tirẹ̀ wà láààyè sì kún fún àánú fún ọmọ rẹ̀, ó sì wí fún ọba pé, “Jọ̀wọ́, olúwa mi, ẹ fún un ní alààyè ọmọ! Ẹ má ṣe pa á!”Ṣùgbọ́n obìnrin èkejì sì wí pé, “Kì yóò jẹ́ tèmi tàbí tìrẹ. Ẹ gé e sí méjì!” 27 Nígbà náà ni ọba dáhùn, ó wí pé, “Ẹ fi alààyè ọmọ fún obìnrin àkọ́kọ́. Ẹ má ṣe pa á: òun ni ìyá rẹ̀.” 28 Nígbà tí gbogbo Israẹli gbọ́ ìdájọ́ tí ọba ṣe, wọ́n sì bẹ̀rù níwájú ọba, nítorí wọ́n ti rí í pé ó ní ọgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run láti ṣe ìdájọ́.

In Other Versions

1 Kings 3 in the ANGEFD

1 Kings 3 in the ANTPNG2D

1 Kings 3 in the AS21

1 Kings 3 in the BAGH

1 Kings 3 in the BBPNG

1 Kings 3 in the BBT1E

1 Kings 3 in the BDS

1 Kings 3 in the BEV

1 Kings 3 in the BHAD

1 Kings 3 in the BIB

1 Kings 3 in the BLPT

1 Kings 3 in the BNT

1 Kings 3 in the BNTABOOT

1 Kings 3 in the BNTLV

1 Kings 3 in the BOATCB

1 Kings 3 in the BOATCB2

1 Kings 3 in the BOBCV

1 Kings 3 in the BOCNT

1 Kings 3 in the BOECS

1 Kings 3 in the BOGWICC

1 Kings 3 in the BOHCB

1 Kings 3 in the BOHCV

1 Kings 3 in the BOHLNT

1 Kings 3 in the BOHNTLTAL

1 Kings 3 in the BOICB

1 Kings 3 in the BOILNTAP

1 Kings 3 in the BOITCV

1 Kings 3 in the BOKCV

1 Kings 3 in the BOKCV2

1 Kings 3 in the BOKHWOG

1 Kings 3 in the BOKSSV

1 Kings 3 in the BOLCB

1 Kings 3 in the BOLCB2

1 Kings 3 in the BOMCV

1 Kings 3 in the BONAV

1 Kings 3 in the BONCB

1 Kings 3 in the BONLT

1 Kings 3 in the BONUT2

1 Kings 3 in the BOPLNT

1 Kings 3 in the BOSCB

1 Kings 3 in the BOSNC

1 Kings 3 in the BOTLNT

1 Kings 3 in the BOVCB

1 Kings 3 in the BPBB

1 Kings 3 in the BPH

1 Kings 3 in the BSB

1 Kings 3 in the CCB

1 Kings 3 in the CUV

1 Kings 3 in the CUVS

1 Kings 3 in the DBT

1 Kings 3 in the DGDNT

1 Kings 3 in the DHNT

1 Kings 3 in the DNT

1 Kings 3 in the ELBE

1 Kings 3 in the EMTV

1 Kings 3 in the ESV

1 Kings 3 in the FBV

1 Kings 3 in the FEB

1 Kings 3 in the GGMNT

1 Kings 3 in the GNT

1 Kings 3 in the HARY

1 Kings 3 in the HNT

1 Kings 3 in the IRVA

1 Kings 3 in the IRVB

1 Kings 3 in the IRVG

1 Kings 3 in the IRVH

1 Kings 3 in the IRVK

1 Kings 3 in the IRVM

1 Kings 3 in the IRVM2

1 Kings 3 in the IRVO

1 Kings 3 in the IRVP

1 Kings 3 in the IRVT

1 Kings 3 in the IRVT2

1 Kings 3 in the IRVU

1 Kings 3 in the ISVN

1 Kings 3 in the JSNT

1 Kings 3 in the KAPI

1 Kings 3 in the KBT1ETNIK

1 Kings 3 in the KBV

1 Kings 3 in the KJV

1 Kings 3 in the KNFD

1 Kings 3 in the LBA

1 Kings 3 in the LBLA

1 Kings 3 in the LNT

1 Kings 3 in the LSV

1 Kings 3 in the MAAL

1 Kings 3 in the MBV

1 Kings 3 in the MBV2

1 Kings 3 in the MHNT

1 Kings 3 in the MKNFD

1 Kings 3 in the MNG

1 Kings 3 in the MNT

1 Kings 3 in the MNT2

1 Kings 3 in the MRS1T

1 Kings 3 in the NAA

1 Kings 3 in the NASB

1 Kings 3 in the NBLA

1 Kings 3 in the NBS

1 Kings 3 in the NBVTP

1 Kings 3 in the NET2

1 Kings 3 in the NIV11

1 Kings 3 in the NNT

1 Kings 3 in the NNT2

1 Kings 3 in the NNT3

1 Kings 3 in the PDDPT

1 Kings 3 in the PFNT

1 Kings 3 in the RMNT

1 Kings 3 in the SBIAS

1 Kings 3 in the SBIBS

1 Kings 3 in the SBIBS2

1 Kings 3 in the SBICS

1 Kings 3 in the SBIDS

1 Kings 3 in the SBIGS

1 Kings 3 in the SBIHS

1 Kings 3 in the SBIIS

1 Kings 3 in the SBIIS2

1 Kings 3 in the SBIIS3

1 Kings 3 in the SBIKS

1 Kings 3 in the SBIKS2

1 Kings 3 in the SBIMS

1 Kings 3 in the SBIOS

1 Kings 3 in the SBIPS

1 Kings 3 in the SBISS

1 Kings 3 in the SBITS

1 Kings 3 in the SBITS2

1 Kings 3 in the SBITS3

1 Kings 3 in the SBITS4

1 Kings 3 in the SBIUS

1 Kings 3 in the SBIVS

1 Kings 3 in the SBT

1 Kings 3 in the SBT1E

1 Kings 3 in the SCHL

1 Kings 3 in the SNT

1 Kings 3 in the SUSU

1 Kings 3 in the SUSU2

1 Kings 3 in the SYNO

1 Kings 3 in the TBIAOTANT

1 Kings 3 in the TBT1E

1 Kings 3 in the TBT1E2

1 Kings 3 in the TFTIP

1 Kings 3 in the TFTU

1 Kings 3 in the TGNTATF3T

1 Kings 3 in the THAI

1 Kings 3 in the TNFD

1 Kings 3 in the TNT

1 Kings 3 in the TNTIK

1 Kings 3 in the TNTIL

1 Kings 3 in the TNTIN

1 Kings 3 in the TNTIP

1 Kings 3 in the TNTIZ

1 Kings 3 in the TOMA

1 Kings 3 in the TTENT

1 Kings 3 in the UBG

1 Kings 3 in the UGV

1 Kings 3 in the UGV2

1 Kings 3 in the UGV3

1 Kings 3 in the VBL

1 Kings 3 in the VDCC

1 Kings 3 in the YALU

1 Kings 3 in the YAPE

1 Kings 3 in the YBVTP

1 Kings 3 in the ZBP