1 Samuel 23 (BOYCB)

1 Wọ́n sì wí fún Dafidi pé, “Sá wò ó, àwọn ará Filistini ń bá ará Keila jagun, wọ́n sì ja àwọn ilẹ̀ ìpakà lólè.” 2 Dafidi sì béèrè lọ́dọ̀ OLÚWA pé, “Ṣé kí èmi ó lọ kọlu àwọn ará Filistini wọ̀nyí bí?” OLÚWA sì wí fún Dafidi pé, “Lọ kí o sì kọlu àwọn ará Filistini kí o sì gba Keila sílẹ̀.” 3 Àwọn ọmọkùnrin tí ó wà lọ́dọ̀ Dafidi sì wí fún un pé, “Wò ó, àwa ń bẹ̀rù níhìn-ín yìí ní Juda; ǹjẹ́ yóò ti rí nígbà ti àwa bá dé Keila láti fi ojú ko ogun àwọn ara Filistini?” 4 Dafidi sì tún béèrè lọ́dọ̀ OLÚWA. OLÚWA sì dá a lóhùn, ó sì wí pé, “Dìde, kí o sọ̀kalẹ̀ lọ sí Keila, nítorí pé èmi ó fi àwọn ará Filistini náà lé ọ lọ́wọ́.” 5 Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì lọ sí Keila, wọ́n sì bá àwọn ará Filistini jà, wọ́n sì kó ohun ọ̀sìn wọn, wọ́n sì fi ìparun ńlá pa wọ́n. Dafidi sì gba àwọn ará Keila sílẹ̀. 6 Ó sì ṣe, nígbà tí Abiatari ọmọ Ahimeleki fi sá tọ Dafidi lọ ní Keila, ó sọ̀kalẹ̀ òun pẹ̀lú efodu kan lọ́wọ́ rẹ̀. 7 A sì sọ fún Saulu pé Dafidi wá sí Keila. Saulu sì wí pé, “Ọlọ́run ti fi í lé mi lọ́wọ́; nítorí tí ó ti sé ara rẹ̀ mọ́ ní ti wíwá tí ó wá sí ìlú tí ó ní ìlẹ̀kùn àti kẹrẹ.” 8 Saulu sì pe gbogbo àwọn ènìyàn náà jọ sí ogun, láti sọ̀kalẹ̀ lọ sí Keila, láti ká Dafidi mọ́ àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀. 9 Dafidi sì mọ̀ pé Saulu ti gbèrò búburú sí òun; ó sì wí fún Abiatari àlùfáà náà pé, “Mú efodu náà wá níhìn-ín yìí!” 10 Dafidi sì wí pé, “OLÚWA Ọlọ́run Israẹli, lóòótọ́ ni ìránṣẹ́ rẹ ti gbọ́ pé Saulu ń wá ọ̀nà láti wá sí Keila, láti wá fọ́ ìlú náà nítorí mi. 11 Àwọn àgbà ìlú Keila yóò fi mí lé e lọ́wọ́ bí? Saulu yóò ha sọ̀kalẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ rẹ ti gbọ́ bí?” OLÚWA Ọlọ́run Israẹli, èmi bẹ̀ ọ́, wí fún ìránṣẹ́ rẹ. OLÚWA sì wí pé, “Yóò sọ̀kalẹ̀ wá.” 12 Dafidi sì wí pé, “Àwọn àgbà ìlú Keila yóò fi èmi àti àwọn ọmọkùnrin mi lé Saulu lọ́wọ́ bí?” OLÚWA sì wí pé, “Wọn ó fi ọ́ lé wọn lọ́wọ́.” 13 Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ tí wọ́n tó ẹgbẹ̀ta (600) ènìyàn sì dìde, wọ́n lọ kúrò ní Keila, wọ́n sì lọ sí ibikíbi tí wọ́n lè rìn lọ. A sì wí fún Saulu pé, “Dafidi ti sá kúrò ní Keila; kò sì lọ sí Keila mọ́.” 14 Dafidi sì ń gbé ní aginjù, níbi tí ó ti sá pamọ́ sí, ó sì ń gbé níbi òkè ńlá kan ní aginjù Sifi. Saulu sì ń wá a lójoojúmọ́, ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò fi lé e lọ́wọ́. 15 Nígbà tí Dafidi wà ní Horeṣi ní aginjù Sifi, Dafidi sì rí i pé, Saulu ti jáde láti wá ẹ̀mí òun kiri. 16 Jonatani ọmọ Saulu sì dìde, ó sì tọ Dafidi lọ nínú igbó Horeṣi, ó sì gbà á ní ìyànjú nípa ti Ọlọ́run. 17 Òun sì wí fún un pé, “Má ṣe bẹ̀rù, nítorí tí ọwọ́ Saulu baba mi kì yóò tẹ̀ ọ́. Ìwọ ni yóò jẹ ọba lórí Israẹli, èmi ni yóò sì ṣe ibìkejì rẹ. Saulu baba mi mọ̀ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.” 18 Àwọn méjèèjì sì ṣe àdéhùn níwájú OLÚWA; Dafidi sì jókòó nínú igbó Horeṣi. Jonatani sì lọ sí ilé rẹ̀. 19 Àwọn ará Sifi sì gòkè tọ Saulu wá sí Gibeah, wọ́n sì wí pé, “Ṣé Dafidi ti fi ara rẹ̀ pamọ́ sọ́dọ̀ wa ní ibi gíga ìsápamọ́sí ní Horeṣi, ní òkè Hakila, tí ó wà níhà gúúsù ti Jeṣimoni. 20 Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ọba, sọ̀kalẹ̀ wá gẹ́gẹ́ bi gbogbo ìfẹ́ tí ó wà ní ọkàn rẹ láti sọ̀kalẹ̀: ipa tí àwa ní láti fi lé ọba lọ́wọ́.” 21 Saulu sì wí pé, “Alábùkún fún ni ẹ̀yin nípa OLÚWA; nítorí pé ẹ̀yin ti káàánú fún mi. 22 Lọ, èmi bẹ̀ yín, ẹ tún múra, kí ẹ sì mọ̀ ki ẹ si rí ibi tí ẹsẹ̀ rẹ̀ gbé wà, àti ẹni tí ó rí níbẹ̀: nítorí tí a ti sọ fún mi pé, ọgbọ́n ni ó ń lò jọjọ. 23 Ẹ sì wò, kí ẹ sì mọ ibi ìsápamọ́ tí ó máa ń sá pamọ́ sí, kí ẹ sì tún padà tọ̀ mí wá, kí èmi lè mọ̀ dájú; èmi ó sì bá yín lọ: yóò sì ṣe bí ó bá wà ní ilẹ̀ Israẹli, èmi ó sì wá a ní àwárí nínú gbogbo ẹgbẹ̀rún Juda!” 24 Wọ́n sì dìde, wọ́n sì ṣáájú Saulu lọ sí Sifi, ṣùgbọ́n Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ wà ní aginjù Maoni, ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ níhà gúúsù ti Jeṣimoni. 25 Saulu àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì lọ ń wá a. Wọ́n sì sọ fún Dafidi: ó sì sọ̀kalẹ̀ wá sí ibi òkúta kan, ó sì jókòó ní aginjù ti Maoni. Saulu sì gbọ́, ó sì lépa Dafidi ní aginjù Maoni. 26 Saulu sì ń rin apá kan òkè kan, Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ ní apá kejì òkè náà. Dafidi sì yára láti sá kúrò níwájú Saulu; nítorí pé Saulu àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ ti rọ̀gbà yí Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ ká láti mú wọn. 27 Ṣùgbọ́n oníṣẹ́ kan sì tọ Saulu wá ó sì wí pé, “Ìwọ yára kí o sì wá, nítorí tí àwọn Filistini ti gbé ogun ti ilẹ̀ wa.” 28 Saulu sì padà kúrò ní lílépa Dafidi, ó sì lọ pàdé àwọn Filistini nítorí náà ni wọ́n sì ṣe ń pe ibẹ̀ náà ní Selahamalekoti (èyí tí ó túmọ̀ sí “Òkúta Ìpinyà”). 29 Dafidi sì gòkè láti ibẹ̀ lọ, ó sì jókòó níbi tí ó sá pamọ́ sí ní En-Gedi.

In Other Versions

1 Samuel 23 in the ANGEFD

1 Samuel 23 in the ANTPNG2D

1 Samuel 23 in the AS21

1 Samuel 23 in the BAGH

1 Samuel 23 in the BBPNG

1 Samuel 23 in the BBT1E

1 Samuel 23 in the BDS

1 Samuel 23 in the BEV

1 Samuel 23 in the BHAD

1 Samuel 23 in the BIB

1 Samuel 23 in the BLPT

1 Samuel 23 in the BNT

1 Samuel 23 in the BNTABOOT

1 Samuel 23 in the BNTLV

1 Samuel 23 in the BOATCB

1 Samuel 23 in the BOATCB2

1 Samuel 23 in the BOBCV

1 Samuel 23 in the BOCNT

1 Samuel 23 in the BOECS

1 Samuel 23 in the BOGWICC

1 Samuel 23 in the BOHCB

1 Samuel 23 in the BOHCV

1 Samuel 23 in the BOHLNT

1 Samuel 23 in the BOHNTLTAL

1 Samuel 23 in the BOICB

1 Samuel 23 in the BOILNTAP

1 Samuel 23 in the BOITCV

1 Samuel 23 in the BOKCV

1 Samuel 23 in the BOKCV2

1 Samuel 23 in the BOKHWOG

1 Samuel 23 in the BOKSSV

1 Samuel 23 in the BOLCB

1 Samuel 23 in the BOLCB2

1 Samuel 23 in the BOMCV

1 Samuel 23 in the BONAV

1 Samuel 23 in the BONCB

1 Samuel 23 in the BONLT

1 Samuel 23 in the BONUT2

1 Samuel 23 in the BOPLNT

1 Samuel 23 in the BOSCB

1 Samuel 23 in the BOSNC

1 Samuel 23 in the BOTLNT

1 Samuel 23 in the BOVCB

1 Samuel 23 in the BPBB

1 Samuel 23 in the BPH

1 Samuel 23 in the BSB

1 Samuel 23 in the CCB

1 Samuel 23 in the CUV

1 Samuel 23 in the CUVS

1 Samuel 23 in the DBT

1 Samuel 23 in the DGDNT

1 Samuel 23 in the DHNT

1 Samuel 23 in the DNT

1 Samuel 23 in the ELBE

1 Samuel 23 in the EMTV

1 Samuel 23 in the ESV

1 Samuel 23 in the FBV

1 Samuel 23 in the FEB

1 Samuel 23 in the GGMNT

1 Samuel 23 in the GNT

1 Samuel 23 in the HARY

1 Samuel 23 in the HNT

1 Samuel 23 in the IRVA

1 Samuel 23 in the IRVB

1 Samuel 23 in the IRVG

1 Samuel 23 in the IRVH

1 Samuel 23 in the IRVK

1 Samuel 23 in the IRVM

1 Samuel 23 in the IRVM2

1 Samuel 23 in the IRVO

1 Samuel 23 in the IRVP

1 Samuel 23 in the IRVT

1 Samuel 23 in the IRVT2

1 Samuel 23 in the IRVU

1 Samuel 23 in the ISVN

1 Samuel 23 in the JSNT

1 Samuel 23 in the KAPI

1 Samuel 23 in the KBT1ETNIK

1 Samuel 23 in the KBV

1 Samuel 23 in the KJV

1 Samuel 23 in the KNFD

1 Samuel 23 in the LBA

1 Samuel 23 in the LBLA

1 Samuel 23 in the LNT

1 Samuel 23 in the LSV

1 Samuel 23 in the MAAL

1 Samuel 23 in the MBV

1 Samuel 23 in the MBV2

1 Samuel 23 in the MHNT

1 Samuel 23 in the MKNFD

1 Samuel 23 in the MNG

1 Samuel 23 in the MNT

1 Samuel 23 in the MNT2

1 Samuel 23 in the MRS1T

1 Samuel 23 in the NAA

1 Samuel 23 in the NASB

1 Samuel 23 in the NBLA

1 Samuel 23 in the NBS

1 Samuel 23 in the NBVTP

1 Samuel 23 in the NET2

1 Samuel 23 in the NIV11

1 Samuel 23 in the NNT

1 Samuel 23 in the NNT2

1 Samuel 23 in the NNT3

1 Samuel 23 in the PDDPT

1 Samuel 23 in the PFNT

1 Samuel 23 in the RMNT

1 Samuel 23 in the SBIAS

1 Samuel 23 in the SBIBS

1 Samuel 23 in the SBIBS2

1 Samuel 23 in the SBICS

1 Samuel 23 in the SBIDS

1 Samuel 23 in the SBIGS

1 Samuel 23 in the SBIHS

1 Samuel 23 in the SBIIS

1 Samuel 23 in the SBIIS2

1 Samuel 23 in the SBIIS3

1 Samuel 23 in the SBIKS

1 Samuel 23 in the SBIKS2

1 Samuel 23 in the SBIMS

1 Samuel 23 in the SBIOS

1 Samuel 23 in the SBIPS

1 Samuel 23 in the SBISS

1 Samuel 23 in the SBITS

1 Samuel 23 in the SBITS2

1 Samuel 23 in the SBITS3

1 Samuel 23 in the SBITS4

1 Samuel 23 in the SBIUS

1 Samuel 23 in the SBIVS

1 Samuel 23 in the SBT

1 Samuel 23 in the SBT1E

1 Samuel 23 in the SCHL

1 Samuel 23 in the SNT

1 Samuel 23 in the SUSU

1 Samuel 23 in the SUSU2

1 Samuel 23 in the SYNO

1 Samuel 23 in the TBIAOTANT

1 Samuel 23 in the TBT1E

1 Samuel 23 in the TBT1E2

1 Samuel 23 in the TFTIP

1 Samuel 23 in the TFTU

1 Samuel 23 in the TGNTATF3T

1 Samuel 23 in the THAI

1 Samuel 23 in the TNFD

1 Samuel 23 in the TNT

1 Samuel 23 in the TNTIK

1 Samuel 23 in the TNTIL

1 Samuel 23 in the TNTIN

1 Samuel 23 in the TNTIP

1 Samuel 23 in the TNTIZ

1 Samuel 23 in the TOMA

1 Samuel 23 in the TTENT

1 Samuel 23 in the UBG

1 Samuel 23 in the UGV

1 Samuel 23 in the UGV2

1 Samuel 23 in the UGV3

1 Samuel 23 in the VBL

1 Samuel 23 in the VDCC

1 Samuel 23 in the YALU

1 Samuel 23 in the YAPE

1 Samuel 23 in the YBVTP

1 Samuel 23 in the ZBP