Ezekiel 40 (BOYCB)

1 Ní ọdún kẹẹdọ́gbọ̀n tí a ti wà ni oko ẹrú wa, ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún, ni oṣù kẹwàá ọdún kẹrìnlá lẹ́yìn ìṣubú ìlú ńlá náà ní ọjọ́ náà gan an ọwọ́ OLÚWA ń bẹ̀ lára mi, òun sì mú mi lọ síbẹ̀. 2 Nínú ìran Ọlọ́run, ó mú mí lọ sí ilẹ̀ Israẹli, ó sì gbé mi lọ sí orí òkè gíga fíofío. Ní ẹ̀gbẹ́ gúúsù ọ̀pọ̀ ilé tó wà níbẹ̀ dàbí ìlú ńlá. 3 Ó mú mi lọ síbẹ̀, mo sì rí ọkùnrin kan tí ìrírí rẹ̀ dàbí ìrí baba; ó dúró ni ẹnu-ọ̀nà pẹ̀lú okùn aṣọ ọ̀gbọ̀ funfun àti ọ̀pá ìwọnlẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀. 4 Ọkùnrin náà sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, wò pẹ̀lú ojú rẹ kí o sì gbọ́ pẹ̀lú etí rẹ, kí ó sì fi ara balẹ̀ sì gbogbo ohun tí mo máa fihàn ọ, nítorí ìdí nìyí tí a fi mú ọ wá síyìn-ín. Sọ gbogbo ohun tí ó bá rí fún ilé Israẹli.” 5 Mo rí ògiri tí ó yí agbègbè ibi mí mọ̀ po. Gígùn ọ̀pá ìwọnlẹ̀ tí ó wà ní ọwọ́ ọkùnrin náà sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà, ọ̀kọ̀ọ̀kan sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan àti ìlàsí mẹ́rin ẹsẹ̀ bàtà. Ó wọn ògiri náà; ó jẹ́ ìwọ̀nyí ọ̀pá náà ni nínípọn, ó sì jẹ́ ọ̀pá kan ní gíga. 6 Lẹ́yìn náà ni ó wá lọ sí ẹnu-ọ̀nà òde tí ó kọjú sí ìlà-oòrùn. Ó gun àtẹ̀gùn rẹ̀, o sì wọn ìloro ẹnu-ọ̀nà ilé; ó jẹ́ ọ̀pá kan ní jíjìn. 7 Yàrá kéékèèké sì jẹ ọ̀pá kan ni gígùn àti ọ̀pá kan ní ibú, ìgbéró ògiri àárín yàrá kéékèèké náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ni nínípọn. Ìloro ẹnu-ọ̀nà náà tí ó kángun sí àtẹ̀wọ ẹnu-ọ̀nà náà tó kọjú sì tẹmpili jẹ́ ọ̀pá kan ní jíjìn. 8 Lẹ́yìn náà, ó wọ̀n ògiri àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà: 9 Ó jẹ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́jọ ní jíjìn àtẹ́rígbà rẹ̀ sì jẹ ìgbọ̀nwọ́ méjì ní nínípọn. Ògiri àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà kọjú sí tẹmpili. 10 Ní ẹnu-ọ̀nà ìlà-oòrùn ni àwọn yàrá kéékèèké mẹ́ta wà ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan: mẹ́tẹ̀ẹ̀ta kọ̀ jú sí ara wọn, ojú ìgbéró ògiri ni ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan jẹ́ bákan náà ní wíwọ̀n. 11 Lẹ́yìn náà ó wọn ìbú à bá wọ ẹnu-ọ̀nà náà; ó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá, gígùn rẹ̀ sì jẹ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́tàlá. 12 Ní iwájú ọ̀kọ̀ọ̀kan yàrá kéékèèké kọ̀ọ̀kan ní ògiri tí gíga rẹ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan wà, ẹ̀gbẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àwọn yàrá kéékèèké sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà. 13 Lẹ́yìn náà, ó wọn ẹnu-ọ̀nà láti òkè ẹ̀yìn ògiri yàrá kéékèèké kan títí dé òkè ìdojúkọ ọ̀kan; jíjìn sí ara wọn jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n láti odi kan tí ó ṣí sílẹ̀ sí ìdojúkọ ọ̀kan. 14 Ó sí ṣe àtẹ́rígbà ọlọ́gọ́ta ìgbọ̀nwọ́, àní títí dé àtẹ́rígbà ògiri àgbàlá, yí ẹnu-ọ̀nà ká. 15 Láti iwájú ẹnu-ọ̀nà àbáwọlé títí dé ìparí yàrá kéékèèké náà àti àwọn ìgbéró ògiri nínú ẹnu-ọ̀nà ní a gbé dá jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́. 16 Ni a tẹ nínú yíká; àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà ní fèrèsé tóóró tí ó wọ inú yíká. Àwọn ògiri wọn ní inú ni a fi pákó tẹ yíká láti ilẹ̀ dé òkè fèrèsé àti láti fèrèsé dé òrùlé. 17 Lẹ́yìn náà ó mú mi lọ sí ojú òde àgbàlá. Níbẹ̀ mo rí yàrá díẹ̀ àti pèpéle tí a kọ́ yí àgbàlá ká; ọgbọ̀n yàrá wà lẹ́gbẹ̀ pèpéle náà. 18 O ṣe ààlà sí ẹ̀gbẹ́ àwọn ẹnu-ọ̀nà, ìbú rẹ̀ sì jẹ́ bákan náà pẹ̀lú gígùn rẹ̀: èyí jẹ́ pèpéle tí ìsàlẹ̀. 19 Lẹ́yìn náà, o wọn jíjìnnà rẹ̀ láti inú ìsàlẹ̀ ẹnu-ọ̀nà títí dé àgbàlá tí inú; ó jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ni ìhà ìlà-oòrùn àti tí àríwá. 20 Lẹ́yìn náà, ó wọn gígùn àti ibú ẹnu-ọ̀nà tí ó dojúkọ àríwá, à bá wọ àgbàlá. 21 Àwọn yàrá kéékèèké rẹ̀ mẹ́ta ni ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan ìgbéró ògiri rẹ̀ àti àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà jẹ́ bákan náà ni wíwọ̀n gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ẹnu-ọ̀nà àkọ́kọ́. Ó jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn, ó sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ni ìbú. 22 Ojú ihò rẹ̀, àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ àti igi ọ̀pẹ tí í ṣe ọ̀ṣọ́ rẹ̀ ni wọn kàn gẹ́gẹ́ bí tí àwọn ẹnu-ọ̀nà tí ó dojúkọ ìlà-oòrùn. Àtẹ̀gùn méje ní ó dé ibẹ̀, pẹ̀lú àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà òdìkejì wọn. 23 Ẹnu-ọ̀nà kan sí àgbàlá ti inú ni ìdojúkọ ẹnu-ọ̀nà àríwá, gẹ́gẹ́ bí o ṣe wà ní ìlà-oòrùn. Ó wọ́n láti ẹnu-ọ̀nà sí ìdojúkọ ọ̀kan; ó jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́. 24 Lẹ́yìn náà, o mú mi lọ sí ìhà gúúsù, mo sì rí ẹnu-ọ̀nà tí ó dojúkọ gúúsù. Ó wọn àtẹ́rígbà àti ògiri àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà, wọ́n jẹ́ bákan náà bí ti àwọn tí o kù. 25 Ẹnu-ọ̀nà àti àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà ni ojú ihò tóóró yí po, gẹ́gẹ́ bí ojú ihò ti àwọn tókù. Ó jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ní ìbú. 26 Àtẹ̀gùn méje ní ń bẹ láti bá gun òkè rẹ̀, àti àwọn ìloro rẹ̀ sì ń bẹ níwájú wọn; Ó ní igi ọ̀pẹ tí a fi ṣe ọ̀ṣọ́ rẹ̀ ni ojú ìgbéró ògiri ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan. 27 Àgbàlá ti inú náà ní ẹnu-ọ̀nà yìí sí ẹnu-ọ̀nà ìta ni ìhà gúúsù; o jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́. 28 Lẹ́yìn náà, o mú mi lọ sí àgbàlá ti inú láti ẹnu-ọ̀nà gúúsù, ó ní ìwọ̀n kan náà ẹnu-ọ̀nà gúúsù; ó ní ìwọ̀n kan náà pẹ̀lú àwọn tí ó kù. 29 Àwọn yàrá kéékèèké rẹ̀, àwọn ìgbéró ògiri rẹ̀ àti àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà jẹ́ bákan náà pẹ̀lú àwọn tí ó kù. Ẹnu-ọ̀nà náà àti àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ ní ihò ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ gbogbo. 30 (Àwọn àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà tí ó yí àgbàlá po jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ni ìbú àti ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ni jíjìn). 31 Àtẹ̀wọ ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ tí ó dojúkọ ògiri àgbàlá tí ìta, igi ọ̀pẹ ṣe ọ̀ṣọ́ sí àwọn àtẹ́rígbà rẹ̀, àtẹ̀gùn mẹ́jọ ní ó lọ sì òkè sí i. 32 Lẹ́yìn náà, ó mú mi lọ sí àgbàlá tí inú ni ìhà ìlà-oòrùn, ó sì wọn ẹnu-ọ̀nà; ó ní ìwọ̀n kan náà pẹ̀lú àwọn tí ó kù. 33 Àwọn yàrá kéékèèké rẹ̀, ìgbéró ògiri rẹ̀ àti àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ ní ìwọ̀n kan náà pẹ̀lú àwọn tí ó kù. Ẹnu-ọ̀nà náà àti àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà ni ihò yí po. Ó jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ni ìbú. 34 Àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ dojúkọ ògiri àgbàlá tí ìta; àwọn igi ọ̀pẹ ṣe ọ̀ṣọ́ sí àtẹ́rígbà ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì, àtẹ̀gùn mẹ́jọ sì lọ sókè rẹ̀. 35 Gẹ́gẹ́ bí àwọn yàrá kéékèèké rẹ̀ ṣe rí. Àwọn ìgbéró ògiri rẹ̀ àti àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà, ó sì ní àwọn ihò yí i po. O jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ní ìbú. 36 Àwọn yàrá ẹ̀ṣọ́ rẹ̀ àwọn ògiri òpó rẹ̀ àti ìloro rẹ̀, àti fèrèsé rẹ̀ yíká: gígùn rẹ̀ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́, àti ìbú rẹ̀ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n. 37 Àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ dojúkọ ògiri àgbàlá ìta; àwọn igi ọ̀pẹ ṣe ọ̀ṣọ́ sí àwọn àtẹ́rígbà rẹ̀ ni ẹ̀gbẹ́ méjèèjì, àtẹ̀gùn mẹ́jọ ní ó so mọ́ ọn lókè. 38 Yàrá kan pẹ̀lú ìlẹ̀kùn wà ní ẹ̀gbẹ́ ògiri àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà ní ọ̀kọ̀ọ̀kan ẹnu-ọ̀nà inú, níbi tí wọn tí ń fọ àwọn ẹbọ sísun. 39 Ní àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà tí ẹnu-ọ̀nà ni tẹmpili méjì wà ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan, lórí èyí tí a ti ń pa ọrẹ ẹbọ sísun, ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹbọ ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀. 40 Ní ẹ̀gbẹ́ ògiri ìta àtẹ̀wọ ẹnu-ọ̀nà tí ẹnu-ọ̀nà, tí ó súnmọ́ àwọn àtẹ̀gùn ní àbáwọlé tí ẹnu-ọ̀nà àríwá ni tẹmpili méjì wà, ní ẹ̀gbẹ́ kejì tí àtẹ̀gùn ní tẹmpili méjì wà. 41 Nítorí náà, tẹmpili mẹ́rin ni ó wà ní ẹ̀gbẹ́ kan ẹnu-ọ̀nà, mẹ́rin sì wà ní ẹ̀gbẹ́ kejì tẹmpili, mẹ́jọ ni gbogbo rẹ̀ lórí èyí ni a ti ń pa ohun ìrúbọ. 42 Tẹmpili mẹ́rin tí à fi òkúta ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ sì tún wà fún ẹbọ sísun, ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan àti ààbọ̀ ni gígùn, ìgbọ̀nwọ́ kan àti ààbọ̀ ní ìbú àti ìgbọ̀nwọ́ kan ni gíga. Ní orí rẹ̀ ni a kó àwọn ohun èlò fún pípa, ọrẹ ẹbọ sísun àti àwọn ìrúbọ tí ó kù sí. 43 Ìlọ́po méjì ohun èlò bí àmúga tí o ní ìwọ̀ tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìbú ọwọ́ ní gígùn, ni a so mọ́ ara ògiri yíká. Àwọn tẹmpili náà wa fún ẹran ohun ìrúbọ. 44 Lẹ́yìn náà ó wọn àgbàlá, ó jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, ó sì jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ní ìbú. Pẹpẹ sì wà ní iwájú tẹmpili. 45 Ó sì wí fún mi pé, “Yàrá yìí, tí iwájú rẹ̀ wà níhà gúúsù, wà fún àwọn àlùfáà, àwọn ti n bojútó ilé náà. 46 Iyàrá ti iwájú rẹ̀ ti o wà níhà àríwá, wà fún àwọn àlùfáà, àwọn ti ń bojútó pẹpẹ náà, àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Sadoku nínú àwọn ọmọ Lefi, tí wọ́n ń súnmọ́ OLÚWA láti ṣe ìránṣẹ́ fún un.” 47 Ó sì wọn àgbàlá náà, ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn, ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ni ìbú, igun mẹ́rin lọ́gbọọgba, àti pẹpẹ ti ń bẹ níwájú ilé náà. 48 Ó mú mi lọ sí àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà tẹmpili, ó sì wọn àwọn àtẹ́rígbà àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà; wọ́n jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní ìbú, ẹ̀gbẹ́ méjèèjì rẹ̀. Fífẹ̀ àbáwọlé jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rìnlá, ìgbéró àwọn ògiri náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ta ní ìbú ní ẹ̀gbẹ́ ògiri méjèèjì. 49 Àtẹ̀wọ ẹnu-ọ̀nà jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́ ní ìbú, àti ìgbọ̀nwọ́ méjìlá láti iwájú dé ẹ̀yìn. Láti ara àtẹ̀gùn ní a ti ń dé ibẹ̀ àwọn òpó sì wà ni ẹ̀gbẹ́ ògiri kọ̀ọ̀kan àwọn àtẹ́rígbà náà.

In Other Versions

Ezekiel 40 in the ANGEFD

Ezekiel 40 in the ANTPNG2D

Ezekiel 40 in the AS21

Ezekiel 40 in the BAGH

Ezekiel 40 in the BBPNG

Ezekiel 40 in the BBT1E

Ezekiel 40 in the BDS

Ezekiel 40 in the BEV

Ezekiel 40 in the BHAD

Ezekiel 40 in the BIB

Ezekiel 40 in the BLPT

Ezekiel 40 in the BNT

Ezekiel 40 in the BNTABOOT

Ezekiel 40 in the BNTLV

Ezekiel 40 in the BOATCB

Ezekiel 40 in the BOATCB2

Ezekiel 40 in the BOBCV

Ezekiel 40 in the BOCNT

Ezekiel 40 in the BOECS

Ezekiel 40 in the BOGWICC

Ezekiel 40 in the BOHCB

Ezekiel 40 in the BOHCV

Ezekiel 40 in the BOHLNT

Ezekiel 40 in the BOHNTLTAL

Ezekiel 40 in the BOICB

Ezekiel 40 in the BOILNTAP

Ezekiel 40 in the BOITCV

Ezekiel 40 in the BOKCV

Ezekiel 40 in the BOKCV2

Ezekiel 40 in the BOKHWOG

Ezekiel 40 in the BOKSSV

Ezekiel 40 in the BOLCB

Ezekiel 40 in the BOLCB2

Ezekiel 40 in the BOMCV

Ezekiel 40 in the BONAV

Ezekiel 40 in the BONCB

Ezekiel 40 in the BONLT

Ezekiel 40 in the BONUT2

Ezekiel 40 in the BOPLNT

Ezekiel 40 in the BOSCB

Ezekiel 40 in the BOSNC

Ezekiel 40 in the BOTLNT

Ezekiel 40 in the BOVCB

Ezekiel 40 in the BPBB

Ezekiel 40 in the BPH

Ezekiel 40 in the BSB

Ezekiel 40 in the CCB

Ezekiel 40 in the CUV

Ezekiel 40 in the CUVS

Ezekiel 40 in the DBT

Ezekiel 40 in the DGDNT

Ezekiel 40 in the DHNT

Ezekiel 40 in the DNT

Ezekiel 40 in the ELBE

Ezekiel 40 in the EMTV

Ezekiel 40 in the ESV

Ezekiel 40 in the FBV

Ezekiel 40 in the FEB

Ezekiel 40 in the GGMNT

Ezekiel 40 in the GNT

Ezekiel 40 in the HARY

Ezekiel 40 in the HNT

Ezekiel 40 in the IRVA

Ezekiel 40 in the IRVB

Ezekiel 40 in the IRVG

Ezekiel 40 in the IRVH

Ezekiel 40 in the IRVK

Ezekiel 40 in the IRVM

Ezekiel 40 in the IRVM2

Ezekiel 40 in the IRVO

Ezekiel 40 in the IRVP

Ezekiel 40 in the IRVT

Ezekiel 40 in the IRVT2

Ezekiel 40 in the IRVU

Ezekiel 40 in the ISVN

Ezekiel 40 in the JSNT

Ezekiel 40 in the KAPI

Ezekiel 40 in the KBT1ETNIK

Ezekiel 40 in the KBV

Ezekiel 40 in the KJV

Ezekiel 40 in the KNFD

Ezekiel 40 in the LBA

Ezekiel 40 in the LBLA

Ezekiel 40 in the LNT

Ezekiel 40 in the LSV

Ezekiel 40 in the MAAL

Ezekiel 40 in the MBV

Ezekiel 40 in the MBV2

Ezekiel 40 in the MHNT

Ezekiel 40 in the MKNFD

Ezekiel 40 in the MNG

Ezekiel 40 in the MNT

Ezekiel 40 in the MNT2

Ezekiel 40 in the MRS1T

Ezekiel 40 in the NAA

Ezekiel 40 in the NASB

Ezekiel 40 in the NBLA

Ezekiel 40 in the NBS

Ezekiel 40 in the NBVTP

Ezekiel 40 in the NET2

Ezekiel 40 in the NIV11

Ezekiel 40 in the NNT

Ezekiel 40 in the NNT2

Ezekiel 40 in the NNT3

Ezekiel 40 in the PDDPT

Ezekiel 40 in the PFNT

Ezekiel 40 in the RMNT

Ezekiel 40 in the SBIAS

Ezekiel 40 in the SBIBS

Ezekiel 40 in the SBIBS2

Ezekiel 40 in the SBICS

Ezekiel 40 in the SBIDS

Ezekiel 40 in the SBIGS

Ezekiel 40 in the SBIHS

Ezekiel 40 in the SBIIS

Ezekiel 40 in the SBIIS2

Ezekiel 40 in the SBIIS3

Ezekiel 40 in the SBIKS

Ezekiel 40 in the SBIKS2

Ezekiel 40 in the SBIMS

Ezekiel 40 in the SBIOS

Ezekiel 40 in the SBIPS

Ezekiel 40 in the SBISS

Ezekiel 40 in the SBITS

Ezekiel 40 in the SBITS2

Ezekiel 40 in the SBITS3

Ezekiel 40 in the SBITS4

Ezekiel 40 in the SBIUS

Ezekiel 40 in the SBIVS

Ezekiel 40 in the SBT

Ezekiel 40 in the SBT1E

Ezekiel 40 in the SCHL

Ezekiel 40 in the SNT

Ezekiel 40 in the SUSU

Ezekiel 40 in the SUSU2

Ezekiel 40 in the SYNO

Ezekiel 40 in the TBIAOTANT

Ezekiel 40 in the TBT1E

Ezekiel 40 in the TBT1E2

Ezekiel 40 in the TFTIP

Ezekiel 40 in the TFTU

Ezekiel 40 in the TGNTATF3T

Ezekiel 40 in the THAI

Ezekiel 40 in the TNFD

Ezekiel 40 in the TNT

Ezekiel 40 in the TNTIK

Ezekiel 40 in the TNTIL

Ezekiel 40 in the TNTIN

Ezekiel 40 in the TNTIP

Ezekiel 40 in the TNTIZ

Ezekiel 40 in the TOMA

Ezekiel 40 in the TTENT

Ezekiel 40 in the UBG

Ezekiel 40 in the UGV

Ezekiel 40 in the UGV2

Ezekiel 40 in the UGV3

Ezekiel 40 in the VBL

Ezekiel 40 in the VDCC

Ezekiel 40 in the YALU

Ezekiel 40 in the YAPE

Ezekiel 40 in the YBVTP

Ezekiel 40 in the ZBP