Genesis 16 (BOYCB)

1 Sarai, aya Abramu kò bímọ fún un, ṣùgbọ́n ó ní ọmọ ọ̀dọ̀ obìnrin ará Ejibiti kan tí ń jẹ́ Hagari. 2 Nítorí náà, Sarai wí fún Abramu pé, “Kíyèsi i OLÚWA ti sé mi ní inú, èmi kò sì bímọ, wọlé tọ ọmọ ọ̀dọ̀ mi lọ, bóyá èmi yóò le ti ipasẹ̀ rẹ̀ ní ọmọ.”Abramu sì gba ohun tí Sarai sọ. 3 Lẹ́yìn ọdún mẹ́wàá tí Abramu ti ń gbé ni Kenaani ni Sarai mú ọmọbìnrin, ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ Hagari, tí í ṣe ará Ejibiti fún Abramu ọkọ rẹ̀ láti fi ṣe aya. 4 Abramu sì bá Hagari lòpọ̀, ó sì lóyún.Nígbà tí ó sì ti mọ̀ pé òun lóyún, ó bẹ̀rẹ̀ sì ní kẹ́gàn ọ̀gá rẹ̀. 5 Nígbà náà ni Sarai wí fún Abramu pé, “Ìwọ ni ó jẹ́ kí ẹ̀gbin yìí máa jẹ mí, mo fa ọmọ ọ̀dọ̀ mi lé ọ lọ́wọ́, nígbà tí ó sì rí i pé òun lóyún, mo di ẹni ẹ̀gàn ní ojú rẹ̀. Kí OLÚWA kí ó ṣe ìdájọ́ láàrín tèmi tìrẹ.” 6 Abramu dáhùn pé, “Ìwọ ló ni ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ, ṣe ohunkóhun tí ó bá tọ́ ní ojú rẹ sí i.” Nígbà náà ni Sarai fi ìyà jẹ Hagari, ó sì sálọ. 7 Angẹli OLÚWA sì rí Hagari ní ẹ̀gbẹ́ ìsun omi ní ijù, ìsun omi tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà tí ó lọ sí Ṣuri. 8 Ó sì wí pé, “Hagari, ìránṣẹ́ Sarai, níbo ni o ti ń bọ̀, níbo sì ni ìwọ ń lọ?”Ó sì dáhùn pé, “Mo ń sálọ kúrò lọ́dọ̀ ọ̀gá mi Sarai ni.” 9 Angẹli OLÚWA sì wí fún un pé, “Padà lọ sí ọ̀dọ̀ ọ̀gá rẹ kí o sì tẹríba fún un.” 10 Angẹli OLÚWA náà sì fi kún fún un pé, “Èmi yóò sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá, ìran rẹ kì yóò sì lóǹkà.” 11 Angẹli OLÚWA náà sì wí fún un pé,“Ìwọ ti lóyún,ìwọ yóò sì bí ọmọkùnrin kan.Ìwọ yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Iṣmaeli,nítorí tí OLÚWA ti rí ìpọ́njú rẹ. 12 Òun yóò jẹ́ oníjàgídíjàgan ènìyànọwọ́ rẹ̀ yóò wà lára ènìyàn gbogbo,ọwọ́ ènìyàn gbogbo yóò sì wà lára rẹ̀,yóò sì máa gbé ní ìkanrapẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀.” 13 Ó sì pe orúkọ OLÚWA tí o bá sọ̀rọ̀ ní, “Ìwọ ni Ọlọ́run tí ó rí mi,” nítorí tí ó wí pé, “Mo ti ri ẹni tí ó rí mi báyìí.” 14 Nítorí náà ni a ṣe ń pe kànga náà ní Beeri-Lahai-Roi; kànga ẹni alààyè tí ó rí mi. Ó wà ní agbede-méjì Kadeṣi àti Beredi. 15 Hagari sì bí ọmọkùnrin kan fún Abramu, Abramu sì pe orúkọ rẹ̀ ní Iṣmaeli. 16 Abramu jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìndínláàádọ́rùn-ún nígbà tí Hagari bí Iṣmaeli fún un.

In Other Versions

Genesis 16 in the ANGEFD

Genesis 16 in the ANTPNG2D

Genesis 16 in the AS21

Genesis 16 in the BAGH

Genesis 16 in the BBPNG

Genesis 16 in the BBT1E

Genesis 16 in the BDS

Genesis 16 in the BEV

Genesis 16 in the BHAD

Genesis 16 in the BIB

Genesis 16 in the BLPT

Genesis 16 in the BNT

Genesis 16 in the BNTABOOT

Genesis 16 in the BNTLV

Genesis 16 in the BOATCB

Genesis 16 in the BOATCB2

Genesis 16 in the BOBCV

Genesis 16 in the BOCNT

Genesis 16 in the BOECS

Genesis 16 in the BOGWICC

Genesis 16 in the BOHCB

Genesis 16 in the BOHCV

Genesis 16 in the BOHLNT

Genesis 16 in the BOHNTLTAL

Genesis 16 in the BOICB

Genesis 16 in the BOILNTAP

Genesis 16 in the BOITCV

Genesis 16 in the BOKCV

Genesis 16 in the BOKCV2

Genesis 16 in the BOKHWOG

Genesis 16 in the BOKSSV

Genesis 16 in the BOLCB

Genesis 16 in the BOLCB2

Genesis 16 in the BOMCV

Genesis 16 in the BONAV

Genesis 16 in the BONCB

Genesis 16 in the BONLT

Genesis 16 in the BONUT2

Genesis 16 in the BOPLNT

Genesis 16 in the BOSCB

Genesis 16 in the BOSNC

Genesis 16 in the BOTLNT

Genesis 16 in the BOVCB

Genesis 16 in the BPBB

Genesis 16 in the BPH

Genesis 16 in the BSB

Genesis 16 in the CCB

Genesis 16 in the CUV

Genesis 16 in the CUVS

Genesis 16 in the DBT

Genesis 16 in the DGDNT

Genesis 16 in the DHNT

Genesis 16 in the DNT

Genesis 16 in the ELBE

Genesis 16 in the EMTV

Genesis 16 in the ESV

Genesis 16 in the FBV

Genesis 16 in the FEB

Genesis 16 in the GGMNT

Genesis 16 in the GNT

Genesis 16 in the HARY

Genesis 16 in the HNT

Genesis 16 in the IRVA

Genesis 16 in the IRVB

Genesis 16 in the IRVG

Genesis 16 in the IRVH

Genesis 16 in the IRVK

Genesis 16 in the IRVM

Genesis 16 in the IRVM2

Genesis 16 in the IRVO

Genesis 16 in the IRVP

Genesis 16 in the IRVT

Genesis 16 in the IRVT2

Genesis 16 in the IRVU

Genesis 16 in the ISVN

Genesis 16 in the JSNT

Genesis 16 in the KAPI

Genesis 16 in the KBT1ETNIK

Genesis 16 in the KBV

Genesis 16 in the KJV

Genesis 16 in the KNFD

Genesis 16 in the LBA

Genesis 16 in the LBLA

Genesis 16 in the LNT

Genesis 16 in the LSV

Genesis 16 in the MAAL

Genesis 16 in the MBV

Genesis 16 in the MBV2

Genesis 16 in the MHNT

Genesis 16 in the MKNFD

Genesis 16 in the MNG

Genesis 16 in the MNT

Genesis 16 in the MNT2

Genesis 16 in the MRS1T

Genesis 16 in the NAA

Genesis 16 in the NASB

Genesis 16 in the NBLA

Genesis 16 in the NBS

Genesis 16 in the NBVTP

Genesis 16 in the NET2

Genesis 16 in the NIV11

Genesis 16 in the NNT

Genesis 16 in the NNT2

Genesis 16 in the NNT3

Genesis 16 in the PDDPT

Genesis 16 in the PFNT

Genesis 16 in the RMNT

Genesis 16 in the SBIAS

Genesis 16 in the SBIBS

Genesis 16 in the SBIBS2

Genesis 16 in the SBICS

Genesis 16 in the SBIDS

Genesis 16 in the SBIGS

Genesis 16 in the SBIHS

Genesis 16 in the SBIIS

Genesis 16 in the SBIIS2

Genesis 16 in the SBIIS3

Genesis 16 in the SBIKS

Genesis 16 in the SBIKS2

Genesis 16 in the SBIMS

Genesis 16 in the SBIOS

Genesis 16 in the SBIPS

Genesis 16 in the SBISS

Genesis 16 in the SBITS

Genesis 16 in the SBITS2

Genesis 16 in the SBITS3

Genesis 16 in the SBITS4

Genesis 16 in the SBIUS

Genesis 16 in the SBIVS

Genesis 16 in the SBT

Genesis 16 in the SBT1E

Genesis 16 in the SCHL

Genesis 16 in the SNT

Genesis 16 in the SUSU

Genesis 16 in the SUSU2

Genesis 16 in the SYNO

Genesis 16 in the TBIAOTANT

Genesis 16 in the TBT1E

Genesis 16 in the TBT1E2

Genesis 16 in the TFTIP

Genesis 16 in the TFTU

Genesis 16 in the TGNTATF3T

Genesis 16 in the THAI

Genesis 16 in the TNFD

Genesis 16 in the TNT

Genesis 16 in the TNTIK

Genesis 16 in the TNTIL

Genesis 16 in the TNTIN

Genesis 16 in the TNTIP

Genesis 16 in the TNTIZ

Genesis 16 in the TOMA

Genesis 16 in the TTENT

Genesis 16 in the UBG

Genesis 16 in the UGV

Genesis 16 in the UGV2

Genesis 16 in the UGV3

Genesis 16 in the VBL

Genesis 16 in the VDCC

Genesis 16 in the YALU

Genesis 16 in the YAPE

Genesis 16 in the YBVTP

Genesis 16 in the ZBP