Genesis 7 (BOYCB)
1 Nígbà náà ni OLÚWA wí fún Noa pé, “Wọ inú ọkọ̀ lọ ìwọ àti gbogbo ìdílé rẹ, nítorí ìwọ nìkan ni mo rí bí olódodo nínú ìran yìí. 2 Mú méje méje nínú àwọn ẹran tí ó mọ́, akọ àti abo, mú méjì méjì takọ tabo nínú àwọn ẹran aláìmọ́. 3 Sì mú méje méje pẹ̀lú nínú onírúurú ẹyẹ, takọ tabo ni kí o mú wọn, wọlé sínú ọkọ̀ pẹ̀lú rẹ, kí á ba à lè pa wọ́n mọ́ láààyè ní gbogbo ayé. 4 Nítorí ní ọjọ́ méje sí ìhín, èmi yóò rọ òjò sórí ilẹ̀ fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru, èmi yóò sì pa gbogbo ohun alààyè tí mo ti dá run kúrò lórí ilẹ̀.” 5 Noa sì ṣe ohun gbogbo tí OLÚWA pàṣẹ fún un. 6 Noa jẹ́ ọmọ ẹgbẹ̀ta (600) ọdún nígbà tí ìkún omi dé sórí ilẹ̀. 7 Noa àti ìyàwó rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn aya ọmọ rẹ̀ sì wọ inú ọkọ láti sá àsálà fún ìkún omi. 8 Méjì méjì ni àwọn ẹran tí ó mọ́ àti aláìmọ́, ti ẹyẹ àti ti gbogbo àwọn ẹ̀dá afàyàfà, 9 akọ àti abo ni wọ́n wọlé pẹ̀lú Noa sínú ọkọ̀ bí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún Noa. 10 Lẹ́yìn ọjọ́ keje, ìkún omi sì dé sí ayé. 11 Ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kejì, tí Noa pé ọmọ ẹgbẹ̀ta (600) ọdún, ni gbogbo ìsun ibú ya, fèrèsé ìṣàn omi ọ̀run sì ṣí sílẹ̀. 12 Òjò àrọ̀ìrọ̀dá sì rọ̀ fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru. 13 Ní ọjọ́ tí ìkún omi yóò bẹ̀rẹ̀ gan an ni Noa àti Ṣemu, Hamu àti Jafeti pẹ̀lú aya Noa àti aya àwọn ọmọ rẹ̀ wọ inú ọkọ̀. 14 Wọ́n mú ẹranko igbó àti ohun ọ̀sìn ní onírúurú wọn, àwọn ẹ̀dá afàyàfà àti ẹyẹ àti àwọn ohun abìyẹ́ ni onírúurú wọn. 15 Méjì méjì ni gbogbo ẹ̀dá tí ó ní èémí ìyè nínú wọlé pẹ̀lú Noa sínú ọkọ̀. 16 Gbogbo wọ́n wọlé ní takọ tabo bí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún Noa, OLÚWA sì tì wọn mọ́ inú ọkọ̀. 17 Òjò náà sì rọ̀ ní àrọ̀ìrọ̀dá fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru, ọkọ̀ náà sì ń léfòó lórí omi, kúrò lórí ilẹ̀ bí omi náà ti ń pọ̀ sí i. 18 Bí omi náà ti ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ náà ni ọkọ̀ náà sì ń léfòó lójú omi. 19 Omi náà pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ó bo gbogbo àwọn òkè gíga tí ó wà lábẹ́ ọ̀run. 20 Omi náà kún bo àwọn òkè, bí ìwọ̀n ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún. 21 Gbogbo ohun alààyè tí ó wà lórí ilẹ̀ parun: ẹyẹ, ohun ọ̀sìn, ẹranko igbó, àwọn ẹ̀dá afàyàfà àti ènìyàn. 22 Gbogbo ohun tí ó wà lórí ìyàngbẹ ilẹ̀ tó ní èémí ìyè ní ihò imú wọn ni ó kú. 23 Gbogbo ohun alààyè tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé ni a parẹ́: ènìyàn àti ẹranko, àwọn ohun tí ń rìn nílẹ̀, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run pátápátá ló ṣègbé. Noa àti àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ọkọ̀ ni ó ṣẹ́kù. 24 Omi náà sì bo ilẹ̀ fún àádọ́jọ ọjọ́.
In Other Versions
Genesis 7 in the ANGEFD
Genesis 7 in the ANTPNG2D
Genesis 7 in the AS21
Genesis 7 in the BAGH
Genesis 7 in the BBPNG
Genesis 7 in the BBT1E
Genesis 7 in the BDS
Genesis 7 in the BEV
Genesis 7 in the BHAD
Genesis 7 in the BIB
Genesis 7 in the BLPT
Genesis 7 in the BNT
Genesis 7 in the BNTABOOT
Genesis 7 in the BNTLV
Genesis 7 in the BOATCB
Genesis 7 in the BOATCB2
Genesis 7 in the BOBCV
Genesis 7 in the BOCNT
Genesis 7 in the BOECS
Genesis 7 in the BOGWICC
Genesis 7 in the BOHCB
Genesis 7 in the BOHCV
Genesis 7 in the BOHLNT
Genesis 7 in the BOHNTLTAL
Genesis 7 in the BOICB
Genesis 7 in the BOILNTAP
Genesis 7 in the BOITCV
Genesis 7 in the BOKCV
Genesis 7 in the BOKCV2
Genesis 7 in the BOKHWOG
Genesis 7 in the BOKSSV
Genesis 7 in the BOLCB
Genesis 7 in the BOLCB2
Genesis 7 in the BOMCV
Genesis 7 in the BONAV
Genesis 7 in the BONCB
Genesis 7 in the BONLT
Genesis 7 in the BONUT2
Genesis 7 in the BOPLNT
Genesis 7 in the BOSCB
Genesis 7 in the BOSNC
Genesis 7 in the BOTLNT
Genesis 7 in the BOVCB
Genesis 7 in the BPBB
Genesis 7 in the BPH
Genesis 7 in the BSB
Genesis 7 in the CCB
Genesis 7 in the CUV
Genesis 7 in the CUVS
Genesis 7 in the DBT
Genesis 7 in the DGDNT
Genesis 7 in the DHNT
Genesis 7 in the DNT
Genesis 7 in the ELBE
Genesis 7 in the EMTV
Genesis 7 in the ESV
Genesis 7 in the FBV
Genesis 7 in the FEB
Genesis 7 in the GGMNT
Genesis 7 in the GNT
Genesis 7 in the HARY
Genesis 7 in the HNT
Genesis 7 in the IRVA
Genesis 7 in the IRVB
Genesis 7 in the IRVG
Genesis 7 in the IRVH
Genesis 7 in the IRVK
Genesis 7 in the IRVM
Genesis 7 in the IRVM2
Genesis 7 in the IRVO
Genesis 7 in the IRVP
Genesis 7 in the IRVT
Genesis 7 in the IRVT2
Genesis 7 in the IRVU
Genesis 7 in the ISVN
Genesis 7 in the JSNT
Genesis 7 in the KAPI
Genesis 7 in the KBT1ETNIK
Genesis 7 in the KBV
Genesis 7 in the KJV
Genesis 7 in the KNFD
Genesis 7 in the LBA
Genesis 7 in the LBLA
Genesis 7 in the LNT
Genesis 7 in the LSV
Genesis 7 in the MAAL
Genesis 7 in the MBV
Genesis 7 in the MBV2
Genesis 7 in the MHNT
Genesis 7 in the MKNFD
Genesis 7 in the MNG
Genesis 7 in the MNT
Genesis 7 in the MNT2
Genesis 7 in the MRS1T
Genesis 7 in the NAA
Genesis 7 in the NASB
Genesis 7 in the NBLA
Genesis 7 in the NBS
Genesis 7 in the NBVTP
Genesis 7 in the NET2
Genesis 7 in the NIV11
Genesis 7 in the NNT
Genesis 7 in the NNT2
Genesis 7 in the NNT3
Genesis 7 in the PDDPT
Genesis 7 in the PFNT
Genesis 7 in the RMNT
Genesis 7 in the SBIAS
Genesis 7 in the SBIBS
Genesis 7 in the SBIBS2
Genesis 7 in the SBICS
Genesis 7 in the SBIDS
Genesis 7 in the SBIGS
Genesis 7 in the SBIHS
Genesis 7 in the SBIIS
Genesis 7 in the SBIIS2
Genesis 7 in the SBIIS3
Genesis 7 in the SBIKS
Genesis 7 in the SBIKS2
Genesis 7 in the SBIMS
Genesis 7 in the SBIOS
Genesis 7 in the SBIPS
Genesis 7 in the SBISS
Genesis 7 in the SBITS
Genesis 7 in the SBITS2
Genesis 7 in the SBITS3
Genesis 7 in the SBITS4
Genesis 7 in the SBIUS
Genesis 7 in the SBIVS
Genesis 7 in the SBT
Genesis 7 in the SBT1E
Genesis 7 in the SCHL
Genesis 7 in the SNT
Genesis 7 in the SUSU
Genesis 7 in the SUSU2
Genesis 7 in the SYNO
Genesis 7 in the TBIAOTANT
Genesis 7 in the TBT1E
Genesis 7 in the TBT1E2
Genesis 7 in the TFTIP
Genesis 7 in the TFTU
Genesis 7 in the TGNTATF3T
Genesis 7 in the THAI
Genesis 7 in the TNFD
Genesis 7 in the TNT
Genesis 7 in the TNTIK
Genesis 7 in the TNTIL
Genesis 7 in the TNTIN
Genesis 7 in the TNTIP
Genesis 7 in the TNTIZ
Genesis 7 in the TOMA
Genesis 7 in the TTENT
Genesis 7 in the UBG
Genesis 7 in the UGV
Genesis 7 in the UGV2
Genesis 7 in the UGV3
Genesis 7 in the VBL
Genesis 7 in the VDCC
Genesis 7 in the YALU
Genesis 7 in the YAPE
Genesis 7 in the YBVTP
Genesis 7 in the ZBP