Judges 4 (BOYCB)

1 Lẹ́yìn ikú Ehudu, àwọn ènìyàn Israẹli sì tún ṣẹ̀, wọ́n ṣe ohun tí ó burú ní ojú OLÚWA. 2 Nítorí náà OLÚWA jẹ́ kí Jabini, ọba àwọn Kenaani, ẹni tí ó jẹ ọba ní Hasori, ṣẹ́gun wọn. Orúkọ olórí ogun rẹ̀ ni Sisera ẹni tí ń gbé Haroseti-Hagoyimu. 3 Nítorí tí ó ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún (900) kẹ̀kẹ́ ogun irin, ó sì ń pọ́n Israẹli lójú gidigidi fún ogún ọdún, Israẹli ké pe OLÚWA fún ìrànlọ́wọ́. 4 Debora, wòlíì obìnrin, aya Lapidoti ni olórí àti aṣíwájú àwọn ará Israẹli ní àsìkò náà. 5 Òun a máa jókòó ṣe ìdájọ́ ní abẹ́ igi ọ̀pẹ tí a sọ orúkọ rẹ̀ ní ọ̀pẹ Debora láàrín Rama àti Beteli ní ilẹ̀ òkè Efraimu, àwọn ará Israẹli a sì máa wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti yanjú èdè-àìyedè tí wọ́n bá ní sí ara wọn, tàbí láti gbọ́ ohùn OLÚWA láti ẹnu rẹ̀. 6 Ní ọjọ́ kan, ó ránṣẹ́ pe Baraki ọmọ Abinoamu, ẹni tí ń gbé ní Kedeṣi ní ilẹ̀ Naftali, ó sì wí fún un pé, “OLÚWA, Ọlọ́run Israẹli pa á ní àṣẹ fún un pé, ‘Kí ó kó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) àwọn akọni ọkùnrin jọ láti ẹ̀yà Naftali àti ẹ̀yà Sebuluni bí ẹgbẹ́ ogun, kí o sì síwájú wọn lọ sí òkè Tabori. 7 Èmi yóò sì fa Sisera olórí ogun Jabini, pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ ogun rẹ àti àwọn ogun rẹ, sí odò Kiṣoni èmi yóò sì fi lé ọ lọ́wọ́ ìwọ yóò sì ṣẹ́gun wọn níbẹ̀.’ ” 8 Baraki sì dá a lóhùn pé, “Èmi yóò lọ tí ìwọ ó bá bá mi lọ, ṣùgbọ́n tí ìwọ kì yóò bá bá mi lọ, èmi kì yóò lọ.” 9 Debora dá a lóhùn pé, “ó dára, èmi yóò bá ọ lọ. Ṣùgbọ́n ọlá ìṣẹ́gun tí o ń lọ yìí kò ní jẹ́ tìrẹ, nítorí OLÚWA yóò fi Sisera lé obìnrin lọ́wọ́,” báyìí Debora bá Baraki lọ sí Kedeṣi. 10 Nígbà tí Baraki pe ẹ̀yà Sebuluni àti ẹ̀yà Naftali sí Kedeṣi ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) akíkanjú ọkùnrin ogun tẹ̀lé e, Debora pẹ̀lú bá wọn lọ. 11 Ǹjẹ́ Heberi ọmọ Keni, ti ya ara rẹ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọmọ Keni, àní àwọn ọmọ Hobabu, àna Mose, ó sì pa àgọ́ rẹ̀ títí dé ibi igi óákù Saananimu, tí ó wà ni agbègbè Kedeṣi. 12 Nígbà tí a sọ fún Sisera pé Baraki ọmọ Abinoamu ti kó ogun jọ sí òkè Tabori, 13 Sisera kó gbogbo kẹ̀kẹ́ ogun irin rẹ̀ tí ṣe ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún (900) àti gbogbo àwọn ọmọ-ogun tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, láti Haroseti tí àwọn orílẹ̀-èdè wá sí odò Kiṣoni. 14 Debora sì wí fún Baraki pé, “Lọ! Lónìí ni OLÚWA fi Sisera lé ọ lọ́wọ́, OLÚWA ti lọ síwájú rẹ.” Baraki sì síwájú, àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) sì tẹ̀lé e lẹ́yìn, wọ́n sì kọjá sí òkè Tabori. 15 OLÚWA sì mú ìdàrúdàpọ̀ wá sí àárín ogun Sisera, OLÚWA sì fi ojú idà ṣẹ́gun Sisera àti àwọn oníkẹ̀kẹ́ ogun àti ọmọ-ogun orí ilẹ̀ ní iwájú Baraki. Sisera sì sọ̀kalẹ̀ lórí kẹ̀kẹ́-ẹṣin rẹ̀ ó sì fi ẹsẹ̀ sálọ. 16 Baraki àti àwọn ogun rẹ̀ sì lé àwọn ọ̀tá náà, àwọn ọmọ-ogun orílẹ̀ àti àwọn kẹ̀kẹ́ ogun wọn títí dé Haroseti ti àwọn orílẹ̀-èdè, gbogbo ogun Sisera sì ti ojú idà ṣubú, kò sí ọ̀kan tí ó lè sálà tàbí tí ó wà láààyè. 17 Ṣùgbọ́n Sisera ti fi ẹsẹ̀ sálọ sí àgọ́ Jaeli aya Heberi ẹ̀yà Keni: nítorí ìbá dá ọ̀rẹ́ àlàáfíà wà láàrín Jabini ọba Hasori àti ìdílé Heberi ti ẹ̀yà Keni. 18 Jaeli sì jáde síta láti pàdé Sisera, ó sì wí fún un pé, “Wọlé sínú àgọ́ mi, OLÚWA mi, wọlé wá má ṣe bẹ̀rù nítorí pé ààbò ń bẹ fún ọ.” Ó sì yà sínú àgọ́ rẹ̀, ó sì fi aṣọ bò ó. 19 Sisera wí pé, “Òrùngbẹ ń gbẹ́ mí, jọ̀wọ́ fún mi ní omi mu.” Ó sì ṣí awọ wàrà kan, ó sì fún un mu ó sì tún daṣọ bò ó padà. 20 Sisera sọ fún Jaeli pé, “Kí ó dúró ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́, àti pé bí ẹnikẹ́ni bá béèrè bóyá òun wà níbẹ̀ kí ó sọ pé, ‘Kò sí ẹnìkankan ní ibẹ̀.’ ” 21 Ṣùgbọ́n Jaeli ìyàwó Heberi mú ìṣó àgọ́ tí ó mú àti òòlù ní ọwọ́ rẹ̀, ó sì yọ́ wọ inú ibi tí ó sùn, nígbà tí ó ti sùn fọnfọn, nígbà náà ni ó kan ìṣó náà mọ́ òkè ìpéǹpéjú rẹ̀, ó sì wọlé ṣinṣin, ó sì kú. 22 Nígbà tí Baraki dé bí ó ti ń lépa Sisera, Jaeli láti pàdé rẹ̀, wá, èmi yóò fi ẹni tí ìwọ ń wá hàn ọ́, báyìí ni ó tẹ̀lé e wọ inú àgọ́ lọ, kíyèsi Sisera dùbúlẹ̀ síbẹ̀ pẹ̀lú ìṣó àgọ́ ní agbárí rẹ̀ tí a ti kàn mọ́lẹ̀ ṣinṣin tí ó sì ti kú. 23 Ní ọjọ́ náà ni Ọlọ́run ṣẹ́gun Jabini ọba àwọn ará Kenaani ní iwájú àwọn ẹ̀yà Israẹli. 24 Ọwọ́ àwọn ọmọ Israẹli sì le, ó sì ń lágbára síwájú àti síwájú sí i lára Jabini ọba Kenaani, títí wọ́n fi run òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀.

In Other Versions

Judges 4 in the ANGEFD

Judges 4 in the ANTPNG2D

Judges 4 in the AS21

Judges 4 in the BAGH

Judges 4 in the BBPNG

Judges 4 in the BBT1E

Judges 4 in the BDS

Judges 4 in the BEV

Judges 4 in the BHAD

Judges 4 in the BIB

Judges 4 in the BLPT

Judges 4 in the BNT

Judges 4 in the BNTABOOT

Judges 4 in the BNTLV

Judges 4 in the BOATCB

Judges 4 in the BOATCB2

Judges 4 in the BOBCV

Judges 4 in the BOCNT

Judges 4 in the BOECS

Judges 4 in the BOGWICC

Judges 4 in the BOHCB

Judges 4 in the BOHCV

Judges 4 in the BOHLNT

Judges 4 in the BOHNTLTAL

Judges 4 in the BOICB

Judges 4 in the BOILNTAP

Judges 4 in the BOITCV

Judges 4 in the BOKCV

Judges 4 in the BOKCV2

Judges 4 in the BOKHWOG

Judges 4 in the BOKSSV

Judges 4 in the BOLCB

Judges 4 in the BOLCB2

Judges 4 in the BOMCV

Judges 4 in the BONAV

Judges 4 in the BONCB

Judges 4 in the BONLT

Judges 4 in the BONUT2

Judges 4 in the BOPLNT

Judges 4 in the BOSCB

Judges 4 in the BOSNC

Judges 4 in the BOTLNT

Judges 4 in the BOVCB

Judges 4 in the BPBB

Judges 4 in the BPH

Judges 4 in the BSB

Judges 4 in the CCB

Judges 4 in the CUV

Judges 4 in the CUVS

Judges 4 in the DBT

Judges 4 in the DGDNT

Judges 4 in the DHNT

Judges 4 in the DNT

Judges 4 in the ELBE

Judges 4 in the EMTV

Judges 4 in the ESV

Judges 4 in the FBV

Judges 4 in the FEB

Judges 4 in the GGMNT

Judges 4 in the GNT

Judges 4 in the HARY

Judges 4 in the HNT

Judges 4 in the IRVA

Judges 4 in the IRVB

Judges 4 in the IRVG

Judges 4 in the IRVH

Judges 4 in the IRVK

Judges 4 in the IRVM

Judges 4 in the IRVM2

Judges 4 in the IRVO

Judges 4 in the IRVP

Judges 4 in the IRVT

Judges 4 in the IRVT2

Judges 4 in the IRVU

Judges 4 in the ISVN

Judges 4 in the JSNT

Judges 4 in the KAPI

Judges 4 in the KBT1ETNIK

Judges 4 in the KBV

Judges 4 in the KJV

Judges 4 in the KNFD

Judges 4 in the LBA

Judges 4 in the LBLA

Judges 4 in the LNT

Judges 4 in the LSV

Judges 4 in the MAAL

Judges 4 in the MBV

Judges 4 in the MBV2

Judges 4 in the MHNT

Judges 4 in the MKNFD

Judges 4 in the MNG

Judges 4 in the MNT

Judges 4 in the MNT2

Judges 4 in the MRS1T

Judges 4 in the NAA

Judges 4 in the NASB

Judges 4 in the NBLA

Judges 4 in the NBS

Judges 4 in the NBVTP

Judges 4 in the NET2

Judges 4 in the NIV11

Judges 4 in the NNT

Judges 4 in the NNT2

Judges 4 in the NNT3

Judges 4 in the PDDPT

Judges 4 in the PFNT

Judges 4 in the RMNT

Judges 4 in the SBIAS

Judges 4 in the SBIBS

Judges 4 in the SBIBS2

Judges 4 in the SBICS

Judges 4 in the SBIDS

Judges 4 in the SBIGS

Judges 4 in the SBIHS

Judges 4 in the SBIIS

Judges 4 in the SBIIS2

Judges 4 in the SBIIS3

Judges 4 in the SBIKS

Judges 4 in the SBIKS2

Judges 4 in the SBIMS

Judges 4 in the SBIOS

Judges 4 in the SBIPS

Judges 4 in the SBISS

Judges 4 in the SBITS

Judges 4 in the SBITS2

Judges 4 in the SBITS3

Judges 4 in the SBITS4

Judges 4 in the SBIUS

Judges 4 in the SBIVS

Judges 4 in the SBT

Judges 4 in the SBT1E

Judges 4 in the SCHL

Judges 4 in the SNT

Judges 4 in the SUSU

Judges 4 in the SUSU2

Judges 4 in the SYNO

Judges 4 in the TBIAOTANT

Judges 4 in the TBT1E

Judges 4 in the TBT1E2

Judges 4 in the TFTIP

Judges 4 in the TFTU

Judges 4 in the TGNTATF3T

Judges 4 in the THAI

Judges 4 in the TNFD

Judges 4 in the TNT

Judges 4 in the TNTIK

Judges 4 in the TNTIL

Judges 4 in the TNTIN

Judges 4 in the TNTIP

Judges 4 in the TNTIZ

Judges 4 in the TOMA

Judges 4 in the TTENT

Judges 4 in the UBG

Judges 4 in the UGV

Judges 4 in the UGV2

Judges 4 in the UGV3

Judges 4 in the VBL

Judges 4 in the VDCC

Judges 4 in the YALU

Judges 4 in the YAPE

Judges 4 in the YBVTP

Judges 4 in the ZBP