Job 2 (BOYCB)
1 Ó sì tún di ọjọ́ kan nígbà tí àwọn ọmọ Ọlọ́run wá síwájú OLÚWA, Satani sì wá pẹ̀lú wọn láti pe níwájú OLÚWA. 2 OLÚWA sì bi Satani pé, “Níbo ni ìwọ ti wá?”Satani sì dá OLÚWA lóhùn pé, “Láti lọ síwá sẹ́yìn lórí ilẹ̀ ayé àti ní ìrìnkèrindò nínú rẹ̀.” 3 OLÚWA sì wí fún Satani pé, “Ìwọ ha kíyèsi Jobu ìránṣẹ́ mi, pé, kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ̀ ní ayé, ọkùnrin tí ń ṣe olóòtítọ́ tí ó sì dúró ṣinṣin, ẹni tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó sì kórìíra ìwà búburú, bẹ́ẹ̀ ni ó sì di ìwà òtítọ́ rẹ̀ mu ṣinṣin, bí ìwọ tilẹ̀ ti dẹ mí sí i láti run ún láìnídìí.” 4 Satani sì dá OLÚWA lóhùn wí pé, “Awọ fún awọ; àní ohun gbogbo tí ènìyàn ní, òun ni yóò fi ra ẹ̀mí rẹ̀. 5 Ṣùgbọ́n nawọ́ rẹ nísinsin yìí, kí ó tọ́ egungun rẹ̀ àti ara rẹ̀, bí kì yóò sì bọ́hùn ní ojú rẹ.” 6 OLÚWA sì wí fún Satani pé, “Wò ó, ó ń bẹ ní ìkáwọ́ rẹ, ṣùgbọ́n dá ẹ̀mí rẹ̀ sí.” 7 Bẹ́ẹ̀ ni Satani jáde lọ kúrò níwájú OLÚWA, ó sì sọ Jobu ní oówo kíkankíkan láti àtẹ́lẹsẹ̀ títí dé àtàrí rẹ̀. 8 Ó sì mú àpáàdì, ó fi ń họ ara rẹ̀, ó sì jókòó nínú eérú. 9 Nígbà náà ni aya rẹ̀ wí fún un pé, “Ìwọ di ìwà òtítọ́ mú síbẹ̀! Bú Ọlọ́run, kí ó sì kú!” 10 Ṣùgbọ́n ó dá a lóhùn pé, “Ìwọ sọ̀rọ̀ bí ọ̀kan lára àwọn aṣiwèrè obìnrin ti í sọ̀rọ̀; há bà! Àwa yóò ha gba ìre lọ́wọ́ Ọlọ́run, kí a má sì gba ibi?”Nínú gbogbo èyí, Jobu kò fi ètè rẹ̀ ṣẹ̀. 11 Nígbà tí àwọn ọ̀rẹ́ Jobu mẹ́ta gbúròó gbogbo ibi tí ó bá a, wọ́n wá, olúkúlùkù láti ibùjókòó rẹ̀; Elifasi, ara Temani àti Bilidadi, ará Ṣuhi, àti Sofari, ará Naama: nítorí pé wọ́n ti dájọ́ ìpàdé pọ̀ láti bá a ṣọ̀fọ̀, àti láti ṣìpẹ̀ fún un. 12 Nígbà tí wọ́n gbójú wọn wò ní òkèrè réré, tí wọ́n kò sì mọ̀ ọ́n, wọ́n gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sọkún: olúkúlùkù sì fa aṣọ ìgúnwà rẹ̀ ya, wọ́n sì ku erùpẹ̀ sí ojú ọ̀run, wọ́n sì tẹ́ orí gbà á. 13 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n jókòó tì í ní inú erùpẹ̀ ní ọjọ́ méje ti ọ̀sán ti òru, ẹnikẹ́ni kò sì bá a sọ ọ̀rọ̀ kan, nítorí tí wọ́n ti rí i pé ìbànújẹ́ rẹ̀ pọ̀ jọjọ.
In Other Versions
Job 2 in the ANGEFD
Job 2 in the ANTPNG2D
Job 2 in the AS21
Job 2 in the BAGH
Job 2 in the BBPNG
Job 2 in the BBT1E
Job 2 in the BDS
Job 2 in the BEV
Job 2 in the BHAD
Job 2 in the BIB
Job 2 in the BLPT
Job 2 in the BNT
Job 2 in the BNTABOOT
Job 2 in the BNTLV
Job 2 in the BOATCB
Job 2 in the BOATCB2
Job 2 in the BOBCV
Job 2 in the BOCNT
Job 2 in the BOECS
Job 2 in the BOGWICC
Job 2 in the BOHCB
Job 2 in the BOHCV
Job 2 in the BOHLNT
Job 2 in the BOHNTLTAL
Job 2 in the BOICB
Job 2 in the BOILNTAP
Job 2 in the BOITCV
Job 2 in the BOKCV
Job 2 in the BOKCV2
Job 2 in the BOKHWOG
Job 2 in the BOKSSV
Job 2 in the BOLCB
Job 2 in the BOLCB2
Job 2 in the BOMCV
Job 2 in the BONAV
Job 2 in the BONCB
Job 2 in the BONLT
Job 2 in the BONUT2
Job 2 in the BOPLNT
Job 2 in the BOSCB
Job 2 in the BOSNC
Job 2 in the BOTLNT
Job 2 in the BOVCB
Job 2 in the BPBB
Job 2 in the BPH
Job 2 in the BSB
Job 2 in the CCB
Job 2 in the CUV
Job 2 in the CUVS
Job 2 in the DBT
Job 2 in the DGDNT
Job 2 in the DHNT
Job 2 in the DNT
Job 2 in the ELBE
Job 2 in the EMTV
Job 2 in the ESV
Job 2 in the FBV
Job 2 in the FEB
Job 2 in the GGMNT
Job 2 in the GNT
Job 2 in the HARY
Job 2 in the HNT
Job 2 in the IRVA
Job 2 in the IRVB
Job 2 in the IRVG
Job 2 in the IRVH
Job 2 in the IRVK
Job 2 in the IRVM
Job 2 in the IRVM2
Job 2 in the IRVO
Job 2 in the IRVP
Job 2 in the IRVT
Job 2 in the IRVT2
Job 2 in the IRVU
Job 2 in the ISVN
Job 2 in the JSNT
Job 2 in the KAPI
Job 2 in the KBT1ETNIK
Job 2 in the KBV
Job 2 in the KJV
Job 2 in the KNFD
Job 2 in the LBA
Job 2 in the LBLA
Job 2 in the LNT
Job 2 in the LSV
Job 2 in the MAAL
Job 2 in the MBV
Job 2 in the MBV2
Job 2 in the MHNT
Job 2 in the MKNFD
Job 2 in the MNG
Job 2 in the MNT
Job 2 in the MNT2
Job 2 in the MRS1T
Job 2 in the NAA
Job 2 in the NASB
Job 2 in the NBLA
Job 2 in the NBS
Job 2 in the NBVTP
Job 2 in the NET2
Job 2 in the NIV11
Job 2 in the NNT
Job 2 in the NNT2
Job 2 in the NNT3
Job 2 in the PDDPT
Job 2 in the PFNT
Job 2 in the RMNT
Job 2 in the SBIAS
Job 2 in the SBIBS
Job 2 in the SBIBS2
Job 2 in the SBICS
Job 2 in the SBIDS
Job 2 in the SBIGS
Job 2 in the SBIHS
Job 2 in the SBIIS
Job 2 in the SBIIS2
Job 2 in the SBIIS3
Job 2 in the SBIKS
Job 2 in the SBIKS2
Job 2 in the SBIMS
Job 2 in the SBIOS
Job 2 in the SBIPS
Job 2 in the SBISS
Job 2 in the SBITS
Job 2 in the SBITS2
Job 2 in the SBITS3
Job 2 in the SBITS4
Job 2 in the SBIUS
Job 2 in the SBIVS
Job 2 in the SBT
Job 2 in the SBT1E
Job 2 in the SCHL
Job 2 in the SNT
Job 2 in the SUSU
Job 2 in the SUSU2
Job 2 in the SYNO
Job 2 in the TBIAOTANT
Job 2 in the TBT1E
Job 2 in the TBT1E2
Job 2 in the TFTIP
Job 2 in the TFTU
Job 2 in the TGNTATF3T
Job 2 in the THAI
Job 2 in the TNFD
Job 2 in the TNT
Job 2 in the TNTIK
Job 2 in the TNTIL
Job 2 in the TNTIN
Job 2 in the TNTIP
Job 2 in the TNTIZ
Job 2 in the TOMA
Job 2 in the TTENT
Job 2 in the UBG
Job 2 in the UGV
Job 2 in the UGV2
Job 2 in the UGV3
Job 2 in the VBL
Job 2 in the VDCC
Job 2 in the YALU
Job 2 in the YAPE
Job 2 in the YBVTP
Job 2 in the ZBP