Leviticus 17 (BOYCB)

1 OLÚWA sọ fún Mose pé, 2 “Sọ fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli: ‘Ohun tí OLÚWA pàṣẹ nìyí, 3 bí ẹnikẹ́ni nínú ìdílé Israẹli bá pa màlúù tàbí ọ̀dọ́-àgùntàn tàbí àgbò nínú ibùdó tàbí bí ó bá pa á lẹ́yìn ibùdó 4 tí kò sì mú un wá sí ibi àgọ́ ìpàdé láti fi rú ẹbọ sí OLÚWA níwájú àgọ́ ìpàdé, ẹ̀bi ìtàjẹ̀ sílẹ̀ ni kí ẹ kà sí ẹni náà lọ́rùn: torí pé ó ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, ẹni náà ni a ó sì gé kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀. 5 Èyí rí bẹ́ẹ̀ kí àwọn ọmọ Israẹli le è máa mú ẹbọ wọn tí wọn ti rú ní ìta gbangba wá sí iwájú OLÚWA: wọ́n gbọdọ̀ mú un wá síwájú àlùfáà àní sí OLÚWA ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, kí wọ́n sì rú wọn gẹ́gẹ́ bí ẹbọ àlàáfíà sí OLÚWA. 6 Àlùfáà náà yóò sì fi ẹ̀jẹ̀ náà wọ́n ibi pẹpẹ OLÚWA ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, yóò sì sun ọ̀rá rẹ̀ ní òórùn dídùn sí OLÚWA. 7 Nítorí náà, kí wọn má ṣe rú ẹbọ wọn sí ère ẹranko mọ́, nínú èyí tí wọ́n ti ṣe àgbèrè tọ̀ lọ. Èyí yóò sì jẹ́ ìlànà títí láé láti ìran dé ìran wọn tí ń bọ̀.’ 8 “Kí ó sọ fún wọn pé, ‘Ọkùnrin yówù kí ó jẹ́ ní ìdílé Israẹli tàbí ti àwọn àlejò tí ń gbé láàrín wọn tí ó bá rú ẹbọ sísun tàbí ṣe ẹbọ 9 tí kò sì mú un wá sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé láti fi rú ẹbọ sí OLÚWA irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni a ó gé kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀. 10 “ ‘Bí ẹnikẹ́ni bá jẹ ẹ̀jẹ̀ yálà nínú ìdílé Israẹli tàbí àwọn àlejò tí ń gbé láàrín wọn, Èmi yóò bínú sí irú ẹni náà tí ó jẹ ẹ̀jẹ̀, èmi yóò sì gé e kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀. 11 Nítorí pé nínú ẹ̀jẹ̀ ni ẹ̀mí ẹ̀dá wà, èmi sì ti fi fún yín lórí pẹpẹ fún ètùtù ọkàn yín: nítorí pé ẹ̀jẹ̀ ni a fi ń ṣe ètùtù fún ẹ̀mí ènìyàn. 12 Ìdí nìyí tí mo fi sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ọ̀kankan nínú yín kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni àlejò kan tí ń ṣe àtìpó nínú yín kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀. 13 “ ‘Ẹnikẹ́ni yálà nínú àwọn ọmọ Israẹli tàbí àlejò tí ń gbé láàrín wọn, tí ó bá pa ẹranko tàbí ẹyẹ tí ó yẹ fún jíjẹ gbọdọ̀ ro ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀ kí ó sì bò ó mọ́lẹ̀. 14 Torí pé ẹ̀mí gbogbo ẹ̀dá ni ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, torí náà ni mo fi kìlọ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli pé wọn kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ ohun abẹ̀mí kankan, torí pé nínú ẹ̀jẹ̀ ohun abẹ̀mí wọ̀nyí ni ẹ̀mí wọn wà, ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ẹ́ ni a ó gé kúrò. 15 “ ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ohun tí ó kú sílẹ̀ fúnra rẹ̀, tàbí èyí tí ẹranko búburú pa kálẹ̀ yálà onílé tàbí àlejò, ó ní láti fọ aṣọ rẹ̀. Kí ó sì fi omi wẹ ara rẹ̀, yóò sì wà ní ipò àìmọ́ títí di àṣálẹ́ lẹ́yìn èyí ni yóò tó di mímọ́. 16 Ṣùgbọ́n bí ó bá kọ̀ láti wẹ ara rẹ̀ tí kò sì fọ aṣọ rẹ̀ náà: ẹ̀bi rẹ̀ yóò wà lórí ara rẹ̀.’ ”

In Other Versions

Leviticus 17 in the ANGEFD

Leviticus 17 in the ANTPNG2D

Leviticus 17 in the AS21

Leviticus 17 in the BAGH

Leviticus 17 in the BBPNG

Leviticus 17 in the BBT1E

Leviticus 17 in the BDS

Leviticus 17 in the BEV

Leviticus 17 in the BHAD

Leviticus 17 in the BIB

Leviticus 17 in the BLPT

Leviticus 17 in the BNT

Leviticus 17 in the BNTABOOT

Leviticus 17 in the BNTLV

Leviticus 17 in the BOATCB

Leviticus 17 in the BOATCB2

Leviticus 17 in the BOBCV

Leviticus 17 in the BOCNT

Leviticus 17 in the BOECS

Leviticus 17 in the BOGWICC

Leviticus 17 in the BOHCB

Leviticus 17 in the BOHCV

Leviticus 17 in the BOHLNT

Leviticus 17 in the BOHNTLTAL

Leviticus 17 in the BOICB

Leviticus 17 in the BOILNTAP

Leviticus 17 in the BOITCV

Leviticus 17 in the BOKCV

Leviticus 17 in the BOKCV2

Leviticus 17 in the BOKHWOG

Leviticus 17 in the BOKSSV

Leviticus 17 in the BOLCB

Leviticus 17 in the BOLCB2

Leviticus 17 in the BOMCV

Leviticus 17 in the BONAV

Leviticus 17 in the BONCB

Leviticus 17 in the BONLT

Leviticus 17 in the BONUT2

Leviticus 17 in the BOPLNT

Leviticus 17 in the BOSCB

Leviticus 17 in the BOSNC

Leviticus 17 in the BOTLNT

Leviticus 17 in the BOVCB

Leviticus 17 in the BPBB

Leviticus 17 in the BPH

Leviticus 17 in the BSB

Leviticus 17 in the CCB

Leviticus 17 in the CUV

Leviticus 17 in the CUVS

Leviticus 17 in the DBT

Leviticus 17 in the DGDNT

Leviticus 17 in the DHNT

Leviticus 17 in the DNT

Leviticus 17 in the ELBE

Leviticus 17 in the EMTV

Leviticus 17 in the ESV

Leviticus 17 in the FBV

Leviticus 17 in the FEB

Leviticus 17 in the GGMNT

Leviticus 17 in the GNT

Leviticus 17 in the HARY

Leviticus 17 in the HNT

Leviticus 17 in the IRVA

Leviticus 17 in the IRVB

Leviticus 17 in the IRVG

Leviticus 17 in the IRVH

Leviticus 17 in the IRVK

Leviticus 17 in the IRVM

Leviticus 17 in the IRVM2

Leviticus 17 in the IRVO

Leviticus 17 in the IRVP

Leviticus 17 in the IRVT

Leviticus 17 in the IRVT2

Leviticus 17 in the IRVU

Leviticus 17 in the ISVN

Leviticus 17 in the JSNT

Leviticus 17 in the KAPI

Leviticus 17 in the KBT1ETNIK

Leviticus 17 in the KBV

Leviticus 17 in the KJV

Leviticus 17 in the KNFD

Leviticus 17 in the LBA

Leviticus 17 in the LBLA

Leviticus 17 in the LNT

Leviticus 17 in the LSV

Leviticus 17 in the MAAL

Leviticus 17 in the MBV

Leviticus 17 in the MBV2

Leviticus 17 in the MHNT

Leviticus 17 in the MKNFD

Leviticus 17 in the MNG

Leviticus 17 in the MNT

Leviticus 17 in the MNT2

Leviticus 17 in the MRS1T

Leviticus 17 in the NAA

Leviticus 17 in the NASB

Leviticus 17 in the NBLA

Leviticus 17 in the NBS

Leviticus 17 in the NBVTP

Leviticus 17 in the NET2

Leviticus 17 in the NIV11

Leviticus 17 in the NNT

Leviticus 17 in the NNT2

Leviticus 17 in the NNT3

Leviticus 17 in the PDDPT

Leviticus 17 in the PFNT

Leviticus 17 in the RMNT

Leviticus 17 in the SBIAS

Leviticus 17 in the SBIBS

Leviticus 17 in the SBIBS2

Leviticus 17 in the SBICS

Leviticus 17 in the SBIDS

Leviticus 17 in the SBIGS

Leviticus 17 in the SBIHS

Leviticus 17 in the SBIIS

Leviticus 17 in the SBIIS2

Leviticus 17 in the SBIIS3

Leviticus 17 in the SBIKS

Leviticus 17 in the SBIKS2

Leviticus 17 in the SBIMS

Leviticus 17 in the SBIOS

Leviticus 17 in the SBIPS

Leviticus 17 in the SBISS

Leviticus 17 in the SBITS

Leviticus 17 in the SBITS2

Leviticus 17 in the SBITS3

Leviticus 17 in the SBITS4

Leviticus 17 in the SBIUS

Leviticus 17 in the SBIVS

Leviticus 17 in the SBT

Leviticus 17 in the SBT1E

Leviticus 17 in the SCHL

Leviticus 17 in the SNT

Leviticus 17 in the SUSU

Leviticus 17 in the SUSU2

Leviticus 17 in the SYNO

Leviticus 17 in the TBIAOTANT

Leviticus 17 in the TBT1E

Leviticus 17 in the TBT1E2

Leviticus 17 in the TFTIP

Leviticus 17 in the TFTU

Leviticus 17 in the TGNTATF3T

Leviticus 17 in the THAI

Leviticus 17 in the TNFD

Leviticus 17 in the TNT

Leviticus 17 in the TNTIK

Leviticus 17 in the TNTIL

Leviticus 17 in the TNTIN

Leviticus 17 in the TNTIP

Leviticus 17 in the TNTIZ

Leviticus 17 in the TOMA

Leviticus 17 in the TTENT

Leviticus 17 in the UBG

Leviticus 17 in the UGV

Leviticus 17 in the UGV2

Leviticus 17 in the UGV3

Leviticus 17 in the VBL

Leviticus 17 in the VDCC

Leviticus 17 in the YALU

Leviticus 17 in the YAPE

Leviticus 17 in the YBVTP

Leviticus 17 in the ZBP