Leviticus 24 (BOYCB)
1 OLÚWA sọ fún Mose pé, 2 “Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli láti mú òróró tí ó mọ́ tí a fún láti ara olifi wá láti fi tan iná, kí fìtílà lè máa jò láì kú. 3 Lẹ́yìn aṣọ ìkélé ti ibi àpótí ẹ̀rí tí ó wà ní inú àgọ́ ìpàdé, ni kí Aaroni ti tan iná náà níwájú OLÚWA, láti ìrọ̀lẹ́ di àárọ̀ lójoojúmọ́. Èyí yóò jẹ́ ìlànà ayérayé fún àwọn ìran tí ń bọ̀. 4 Àwọn Àtùpà tí wọ́n wà lórí ojúlówó ọ̀pá fìtílà tí a fi wúrà ṣe níwájú OLÚWA ni kí ó máa jó lójoojúmọ́. 5 “Mú ìyẹ̀fun dáradára, kí o sì ṣe ìṣù àkàrà méjìlá, kí o lo ìdá méjì nínú mẹ́wàá òsùwọ̀n efa (èyí jẹ́ lita mẹ́rin ààbọ̀) fún ìṣù kọ̀ọ̀kan. 6 Tò wọ́n sí ọ̀nà ìlà méjì, mẹ́fà mẹ́fà ní ìlà kọ̀ọ̀kan lórí tábìlì tí a fi ojúlówó wúrà bọ̀. Èyí tí ó wà níwájú OLÚWA. 7 Ẹ fi ojúlówó tùràrí sí ọnà kọ̀ọ̀kan, gẹ́gẹ́ bí ìpín ìrántí láti dípò àkàrà, àti láti jẹ ẹbọ sísun sí OLÚWA. 8 Àkàrà yìí ni kí ẹ gbé wá síwájú OLÚWA nígbàkígbà, lọ́ṣọ̀ọ̀ṣẹ̀, nítorí tí àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí májẹ̀mú ayérayé. 9 Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ ló ni í. Wọ́n gbọdọ̀ jẹ ẹ́ ní ibi mímọ́ torí pé ó jẹ́ ipa tí ó mọ́ jùlọ ti ìpín wọn ojoojúmọ́ nínú ọrẹ tí a fi iná ṣe sí OLÚWA.” 10 Ọmọkùnrin kan wà tí ìyá rẹ̀ jẹ́ ọmọ Israẹli baba rẹ̀ sì jẹ́ ará Ejibiti. Ó jáde lọ láàrín àwọn ọmọ Israẹli, ìjà sì ṣẹlẹ̀ nínú àgọ́ láàrín òun àti ọmọ Israẹli kan. 11 Ọmọkùnrin arábìnrin Israẹli náà sọ̀rọ̀-òdì sí orúkọ OLÚWA pẹ̀lú èpè, wọ́n sì mú un tọ Mose wá. (Orúkọ ìyá rẹ̀ ní Ṣelomiti, ọmọbìnrin Debiri, ti ẹ̀yà Dani.) 12 Wọ́n fi í sínú túbú kí OLÚWA to sọ ohun tí wọn yóò ṣe fún wọn. 13 OLÚWA sì sọ fún Mose pé, 14 “Mú asọ̀rọ̀-òdì náà jáde wá sẹ́yìn àgọ́, kí gbogbo àwọn tí ó gbọ́ pé ó ṣépè gbé ọwọ́ wọn lórí ọkùnrin náà láti fihàn pé ó jẹ̀bi. Lẹ́yìn náà ni kí gbogbo àpéjọpọ̀, sọ ọ́ ní òkúta pa. 15 Sọ fún àwọn ará Israẹli pé, ‘Bí ẹnikẹ́ni bá ṣépè lé Ọlọ́run rẹ̀, yóò jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. 16 Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀-òdì sí orúkọ OLÚWA ni kí ẹ pa, kí gbogbo àpéjọpọ̀ sọ ọ́ ní òkúta pa, yálà àlejò ni tàbí ọmọ bíbí Israẹli, bí ó bá ti sọ̀rọ̀-òdì sí orúkọ OLÚWA, pípa ni kí ẹ pa á. 17 “ ‘Ẹni tí ó bá gba ẹ̀mí ènìyàn pípa ni kí ẹ pa á. 18 Ẹni tí ó bá gba ẹ̀mí ẹran ọ̀sìn ẹlòmíràn, kí ó dá a padà—ẹ̀mí dípò ẹ̀mí. 19 Bí ẹnìkan bá pa ẹnìkejì rẹ̀ lára, ohunkóhun tí ó ṣe ni kí ẹ ṣe sí i. 20 Ẹ̀yà fún ẹ̀yà, ojú fún ojú, eyín fún eyín; bí òun ti ṣe àbùkù sí ara ènìyàn, bẹ́ẹ̀ ni kí a ṣe sí i. 21 Ẹni tí ó bá sì lu ẹran pa, kí ó sán an padà; ẹni tí ó bá sì lu ènìyàn pa, a ó pa á. 22 Òfin kan náà ló wà fún àlejò àti fún ọmọ Israẹli. Èmi ni OLÚWA Ọlọ́run yín.’ ” 23 Nígbà náà ni Mose sọ fún àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì mú asọ̀rọ̀-òdì náà lọ sí ẹ̀yìn àgọ́, wọ́n sì sọ ọ́ ní òkúta pa. Àwọn ọmọ Israẹli sì ṣe ohun tí OLÚWA pàṣẹ fún Mose.
In Other Versions
Leviticus 24 in the ANGEFD
Leviticus 24 in the ANTPNG2D
Leviticus 24 in the AS21
Leviticus 24 in the BAGH
Leviticus 24 in the BBPNG
Leviticus 24 in the BBT1E
Leviticus 24 in the BDS
Leviticus 24 in the BEV
Leviticus 24 in the BHAD
Leviticus 24 in the BIB
Leviticus 24 in the BLPT
Leviticus 24 in the BNT
Leviticus 24 in the BNTABOOT
Leviticus 24 in the BNTLV
Leviticus 24 in the BOATCB
Leviticus 24 in the BOATCB2
Leviticus 24 in the BOBCV
Leviticus 24 in the BOCNT
Leviticus 24 in the BOECS
Leviticus 24 in the BOGWICC
Leviticus 24 in the BOHCB
Leviticus 24 in the BOHCV
Leviticus 24 in the BOHLNT
Leviticus 24 in the BOHNTLTAL
Leviticus 24 in the BOICB
Leviticus 24 in the BOILNTAP
Leviticus 24 in the BOITCV
Leviticus 24 in the BOKCV
Leviticus 24 in the BOKCV2
Leviticus 24 in the BOKHWOG
Leviticus 24 in the BOKSSV
Leviticus 24 in the BOLCB
Leviticus 24 in the BOLCB2
Leviticus 24 in the BOMCV
Leviticus 24 in the BONAV
Leviticus 24 in the BONCB
Leviticus 24 in the BONLT
Leviticus 24 in the BONUT2
Leviticus 24 in the BOPLNT
Leviticus 24 in the BOSCB
Leviticus 24 in the BOSNC
Leviticus 24 in the BOTLNT
Leviticus 24 in the BOVCB
Leviticus 24 in the BPBB
Leviticus 24 in the BPH
Leviticus 24 in the BSB
Leviticus 24 in the CCB
Leviticus 24 in the CUV
Leviticus 24 in the CUVS
Leviticus 24 in the DBT
Leviticus 24 in the DGDNT
Leviticus 24 in the DHNT
Leviticus 24 in the DNT
Leviticus 24 in the ELBE
Leviticus 24 in the EMTV
Leviticus 24 in the ESV
Leviticus 24 in the FBV
Leviticus 24 in the FEB
Leviticus 24 in the GGMNT
Leviticus 24 in the GNT
Leviticus 24 in the HARY
Leviticus 24 in the HNT
Leviticus 24 in the IRVA
Leviticus 24 in the IRVB
Leviticus 24 in the IRVG
Leviticus 24 in the IRVH
Leviticus 24 in the IRVK
Leviticus 24 in the IRVM
Leviticus 24 in the IRVM2
Leviticus 24 in the IRVO
Leviticus 24 in the IRVP
Leviticus 24 in the IRVT
Leviticus 24 in the IRVT2
Leviticus 24 in the IRVU
Leviticus 24 in the ISVN
Leviticus 24 in the JSNT
Leviticus 24 in the KAPI
Leviticus 24 in the KBT1ETNIK
Leviticus 24 in the KBV
Leviticus 24 in the KJV
Leviticus 24 in the KNFD
Leviticus 24 in the LBA
Leviticus 24 in the LBLA
Leviticus 24 in the LNT
Leviticus 24 in the LSV
Leviticus 24 in the MAAL
Leviticus 24 in the MBV
Leviticus 24 in the MBV2
Leviticus 24 in the MHNT
Leviticus 24 in the MKNFD
Leviticus 24 in the MNG
Leviticus 24 in the MNT
Leviticus 24 in the MNT2
Leviticus 24 in the MRS1T
Leviticus 24 in the NAA
Leviticus 24 in the NASB
Leviticus 24 in the NBLA
Leviticus 24 in the NBS
Leviticus 24 in the NBVTP
Leviticus 24 in the NET2
Leviticus 24 in the NIV11
Leviticus 24 in the NNT
Leviticus 24 in the NNT2
Leviticus 24 in the NNT3
Leviticus 24 in the PDDPT
Leviticus 24 in the PFNT
Leviticus 24 in the RMNT
Leviticus 24 in the SBIAS
Leviticus 24 in the SBIBS
Leviticus 24 in the SBIBS2
Leviticus 24 in the SBICS
Leviticus 24 in the SBIDS
Leviticus 24 in the SBIGS
Leviticus 24 in the SBIHS
Leviticus 24 in the SBIIS
Leviticus 24 in the SBIIS2
Leviticus 24 in the SBIIS3
Leviticus 24 in the SBIKS
Leviticus 24 in the SBIKS2
Leviticus 24 in the SBIMS
Leviticus 24 in the SBIOS
Leviticus 24 in the SBIPS
Leviticus 24 in the SBISS
Leviticus 24 in the SBITS
Leviticus 24 in the SBITS2
Leviticus 24 in the SBITS3
Leviticus 24 in the SBITS4
Leviticus 24 in the SBIUS
Leviticus 24 in the SBIVS
Leviticus 24 in the SBT
Leviticus 24 in the SBT1E
Leviticus 24 in the SCHL
Leviticus 24 in the SNT
Leviticus 24 in the SUSU
Leviticus 24 in the SUSU2
Leviticus 24 in the SYNO
Leviticus 24 in the TBIAOTANT
Leviticus 24 in the TBT1E
Leviticus 24 in the TBT1E2
Leviticus 24 in the TFTIP
Leviticus 24 in the TFTU
Leviticus 24 in the TGNTATF3T
Leviticus 24 in the THAI
Leviticus 24 in the TNFD
Leviticus 24 in the TNT
Leviticus 24 in the TNTIK
Leviticus 24 in the TNTIL
Leviticus 24 in the TNTIN
Leviticus 24 in the TNTIP
Leviticus 24 in the TNTIZ
Leviticus 24 in the TOMA
Leviticus 24 in the TTENT
Leviticus 24 in the UBG
Leviticus 24 in the UGV
Leviticus 24 in the UGV2
Leviticus 24 in the UGV3
Leviticus 24 in the VBL
Leviticus 24 in the VDCC
Leviticus 24 in the YALU
Leviticus 24 in the YAPE
Leviticus 24 in the YBVTP
Leviticus 24 in the ZBP