Psalms 113 (BOYCB)
1 Ẹ máa yin OLÚWA. Yìn ín ẹ̀yin ìránṣẹ́ OLÚWA,ẹ yin orúkọ OLÚWA. 2 Fi ìbùkún fún orúkọ OLÚWA látiìsinsin yìí lọ àti títí láéláé. 3 Láti ìlà-oòrùn títí dé ìwọ̀ rẹ̀orúkọ OLÚWA ni kí a máa yìn. 4 OLÚWA ga lórí gbogbo orílẹ̀-èdè,àti ògo rẹ̀ lórí àwọn ọ̀run. 5 Ta ló dàbí OLÚWA Ọlọ́run wa,tí ó gbé ní ibi gíga. 6 Tí ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ láti wòòun tí ó ń bẹ lọ́run, àti nínú ayé! 7 Ó gbé òtòṣì dìde láti inú erùpẹ̀,àti pé ó gbé aláìní sókè láti inú ààtàn wá. 8 Kí ó le mú un jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládéàní pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládé àwọn ènìyàn rẹ̀. 9 Ó mú àgàn obìnrin gbé inú ilé,àti láti jẹ́ aláyọ̀ ìyá fún àwọn ọmọ rẹ̀. Ẹ yin OLÚWA.