Psalms 99 (BOYCB)
1 OLÚWA jẹ ọba;jẹ́ kí ayé kí ó wárìrìÓ jókòó lórí ìtẹ́ kérúbùjẹ́ kí ayé kí ó wárìrì. 2 OLÚWA tóbi ní Sioni;Ó sì ga jù gbogbo orílẹ̀-èdè lọ. 3 Kí wọ́n sì yin orúkọ rẹ̀ tí ó tóbití ó ni ẹ̀rù, Mímọ́ ni Òun. 4 Ọba náà ní agbára, ó sì fẹ́ òdodo,ìwọ fi ìdí àìṣègbè múlẹ̀;ìwọ ṣe ohun tí ó tọ́ àti ohun tí ó yẹ nínú Jakọbu. 5 Gbígbéga ni OLÚWA Ọlọ́run waẹ foríbalẹ̀ níbi ẹsẹ̀ rẹ̀; ó jẹ́ mímọ́. 6 Mose àti Aaroni wà nínú àwọn àlùfáà rẹ̀Samuẹli wà nínú àwọn tí ó ń ké pe orúkọ rẹ̀wọ́n ké pe OLÚWA, ó sì dá wọn lóhùn. 7 Ó sọ̀rọ̀ sí wọn nínú ọ̀wọ́n àwọsánmọ̀,wọ́n pa ẹ̀rí rẹ̀ mọ́ àti ìlànà tí ó fún wọn. 8 OLÚWA Ọlọ́run wa, ó dá wọn lóhùn;ó jẹ́ Ọlọ́run tí ó ń dáríjì àwọn ọmọ Israẹliìwọ tí ó ń fi ìyà àìṣedéédéé wọn jẹ wọ́n. 9 Gbígbéga ni OLÚWA Ọlọ́run wakí a sìn ín ní òkè mímọ́ rẹ̀nítorí OLÚWA Ọlọ́run wa jẹ́ mímọ́.