1 Samuel 16 (BOYCB)

1 OLÚWA sọ fún Samuẹli pé, “Yóò ha ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò máa dárò Saulu, nígbà tí ó jẹ́ pé mo ti kọ̀ ọ́ ní ọba lórí Israẹli? Rọ òróró kún inú ìwo rẹ, kí o sì mú ọ̀nà rẹ pọ̀n, Èmi rán ọ sí Jese ará Bẹtilẹhẹmu. Èmi ti yan ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ láti jẹ ọba.” 2 Ṣùgbọ́n Samuẹli wí pé, “Báwo ni èmi yóò ṣe lọ? Bí Saulu bá gbọ́ nípa rẹ̀, yóò pa mi.” OLÚWA wí pé, “Mú abo ẹgbọrọ màlúù kan pẹ̀lú rẹ, kí o sì wí pé, ‘Èmi wá láti wá rú ẹbọ sí OLÚWA.’ 3 Pe Jese wá sí ibi ìrúbọ náà, Èmi yóò sì fi ohun tí ìwọ yóò ṣe hàn ọ́. Ìwọ yóò fi òróró yàn fún mi, ẹni tí èmi bá fihàn ọ́.” 4 Samuẹli ṣe ohun tí OLÚWA sọ. Nígbà tí ó dé Bẹtilẹhẹmu, àyà gbogbo àgbàgbà ìlú já, nígbà tí wọ́n pàdé rẹ̀. Wọ́n béèrè pé, “Ṣé àlàáfíà ní ìwọ bá wá?” 5 Samuẹli sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni àlàáfíà ni; mo wá láti wá rú ẹbọ sí OLÚWA. Ẹ ya ara yín sí mímọ́, kí ẹ sì wá rú ẹbọ pẹ̀lú mi.” Nígbà náà ni ó sì ya Jese sí mímọ́ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀, ó sì pè wọ́n wá sí ibi ìrúbọ náà. 6 Nígbà tí wọ́n dé, Samuẹli rí Eliabu, ó rò nínú ara rẹ̀ pé lóòótọ́ ẹni òróró OLÚWA dúró níbí níwájú OLÚWA. 7 Ṣùgbọ́n OLÚWA sọ fún Samuẹli pé, “Má ṣe wo ti ìrísí rẹ̀ tàbí ti gíga rẹ̀, nítorí èmi ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀. OLÚWA kì í wo ohun tí ènìyàn máa ń wò. Ènìyàn máa ń wo òde ara ṣùgbọ́n OLÚWA máa ń wo ọkàn.” 8 Nígbà náà ni Jese pe Abinadabu, ó sì jẹ́ kí ó rìn kọjá ní iwájú Samuẹli. Ṣùgbọ́n Samuẹli wí pé, “OLÚWA kò yan ẹni yìí.” 9 Jese sì jẹ́ kí Ṣamma rìn kọjá ní iwájú Samuẹli, ṣùgbọ́n Samuẹli wí pé, “OLÚWA kò yan ẹni yìí náà.” 10 Jese jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ̀ méje rìn kọjá ní iwájú Samuẹli ṣùgbọ́n Samuẹli sọ fún un pé, “OLÚWA kò yan àwọn wọ̀nyí.” 11 Nígbà náà ni ó béèrè lọ́wọ́ Jese pé, “Ṣé èyí ni gbogbo àwọn ọmọ rẹ?”Jese dáhùn pé, “Ó ku àbíkẹ́yìn wọn, ó ń tọ́jú agbo àgùntàn.”Samuẹli sì wí pé, “Rán ìránṣẹ́ lọ pè é wá; àwa kò ní jókòó títí òun yóò fi dé.” 12 Ó sì ránṣẹ́ sí i, wọ́n sì mú un wọlé wá, ó jẹ́ ẹni tó mọ́ra, àwọ̀ ara rẹ̀ dùn ún wò, ó jẹ́ arẹwà gidigidi.Nígbà náà ni OLÚWA wí pé, “Dìde kí o sì fi òróró yàn án, òun ni ẹni náà.” 13 Nígbà náà ni Samuẹli mú ìwo òróró, ó sì ta á sí i ní orí ní iwájú àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀, láti ọjọ́ náà lọ, Ẹ̀mí Mímọ́ OLÚWA wá sí orí Dafidi nínú agbára. Samuẹli sì lọ sí Rama. 14 Nísinsin yìí, ẹ̀mí OLÚWA ti kúrò lára Saulu, ẹ̀mí búburú láti ọ̀dọ̀ OLÚWA sì ń yọ ọ́ lẹ́nu. 15 Àwọn ìránṣẹ́ Saulu sì wí fún un pé, “Wò ó, ẹ̀mí búburú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá ń yọ ọ́ lẹ́nu. 16 Jẹ́ kí olúwa wa pàṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ó wà níhìn-ín láti wa ẹnìkan tí ó lè fi dùùrù kọrin. Yóò sì ṣe é nígbà tí ẹ̀mí búburú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bá bà lé ọ, ìwọ yóò sì sàn.” 17 Nígbà náà ni Saulu wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ wá ẹnìkan tí ó lè kọrin dáradára kí ẹ sì mú u wá fún mi.” 18 Ọ̀kan nínú ìránṣẹ́ náà dáhùn pé, “Èmi ti ri ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Jese ti Bẹtilẹhẹmu tí ó mọ orin kọ, ó jẹ́ alágbára àti ológun. Ó ní ọgbọ́n ọ̀rọ̀ òun sì dára ní wíwò. OLÚWA sì wà pẹ̀lú u rẹ̀.” 19 Saulu sì rán oníṣẹ́ sí Jese wí pé, “Rán Dafidi ọmọ rẹ sí mi, ẹni tí ó ń ṣọ́ àgùntàn.” 20 Jese sì mú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ti a di ẹrù lé àti ìgò ọtí wáìnì àti ọmọ ewúrẹ́; ó sì rán wọn nípa ọwọ́ Dafidi ọmọ rẹ̀ sí Saulu. 21 Dafidi sì tọ Saulu lọ, ó sì dúró níwájú rẹ̀, òun sì fẹ́ ẹ gidigidi, Dafidi sì wá di ọ̀kan nínú àwọn tí ń ru ìhámọ́ra rẹ̀. 22 Nígbà náà ni Saulu ránṣẹ́ sí Jese pé, “Jẹ́ kí Dafidi dúró níwájú mi, nítorí tí ó wù mí.” 23 Ó sì ṣe, nígbà tí ẹ̀mí búburú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá bá dé sí Saulu, Dafidi a sì fi ọwọ́ rẹ̀ kọrin lára dùùrù: a sì san fún Saulu, ara rẹ̀ a sì dá; ẹ̀mí búburú náà a sì fi sílẹ̀.

In Other Versions

1 Samuel 16 in the ANGEFD

1 Samuel 16 in the ANTPNG2D

1 Samuel 16 in the AS21

1 Samuel 16 in the BAGH

1 Samuel 16 in the BBPNG

1 Samuel 16 in the BBT1E

1 Samuel 16 in the BDS

1 Samuel 16 in the BEV

1 Samuel 16 in the BHAD

1 Samuel 16 in the BIB

1 Samuel 16 in the BLPT

1 Samuel 16 in the BNT

1 Samuel 16 in the BNTABOOT

1 Samuel 16 in the BNTLV

1 Samuel 16 in the BOATCB

1 Samuel 16 in the BOATCB2

1 Samuel 16 in the BOBCV

1 Samuel 16 in the BOCNT

1 Samuel 16 in the BOECS

1 Samuel 16 in the BOGWICC

1 Samuel 16 in the BOHCB

1 Samuel 16 in the BOHCV

1 Samuel 16 in the BOHLNT

1 Samuel 16 in the BOHNTLTAL

1 Samuel 16 in the BOICB

1 Samuel 16 in the BOILNTAP

1 Samuel 16 in the BOITCV

1 Samuel 16 in the BOKCV

1 Samuel 16 in the BOKCV2

1 Samuel 16 in the BOKHWOG

1 Samuel 16 in the BOKSSV

1 Samuel 16 in the BOLCB

1 Samuel 16 in the BOLCB2

1 Samuel 16 in the BOMCV

1 Samuel 16 in the BONAV

1 Samuel 16 in the BONCB

1 Samuel 16 in the BONLT

1 Samuel 16 in the BONUT2

1 Samuel 16 in the BOPLNT

1 Samuel 16 in the BOSCB

1 Samuel 16 in the BOSNC

1 Samuel 16 in the BOTLNT

1 Samuel 16 in the BOVCB

1 Samuel 16 in the BPBB

1 Samuel 16 in the BPH

1 Samuel 16 in the BSB

1 Samuel 16 in the CCB

1 Samuel 16 in the CUV

1 Samuel 16 in the CUVS

1 Samuel 16 in the DBT

1 Samuel 16 in the DGDNT

1 Samuel 16 in the DHNT

1 Samuel 16 in the DNT

1 Samuel 16 in the ELBE

1 Samuel 16 in the EMTV

1 Samuel 16 in the ESV

1 Samuel 16 in the FBV

1 Samuel 16 in the FEB

1 Samuel 16 in the GGMNT

1 Samuel 16 in the GNT

1 Samuel 16 in the HARY

1 Samuel 16 in the HNT

1 Samuel 16 in the IRVA

1 Samuel 16 in the IRVB

1 Samuel 16 in the IRVG

1 Samuel 16 in the IRVH

1 Samuel 16 in the IRVK

1 Samuel 16 in the IRVM

1 Samuel 16 in the IRVM2

1 Samuel 16 in the IRVO

1 Samuel 16 in the IRVP

1 Samuel 16 in the IRVT

1 Samuel 16 in the IRVT2

1 Samuel 16 in the IRVU

1 Samuel 16 in the ISVN

1 Samuel 16 in the JSNT

1 Samuel 16 in the KAPI

1 Samuel 16 in the KBT1ETNIK

1 Samuel 16 in the KBV

1 Samuel 16 in the KJV

1 Samuel 16 in the KNFD

1 Samuel 16 in the LBA

1 Samuel 16 in the LBLA

1 Samuel 16 in the LNT

1 Samuel 16 in the LSV

1 Samuel 16 in the MAAL

1 Samuel 16 in the MBV

1 Samuel 16 in the MBV2

1 Samuel 16 in the MHNT

1 Samuel 16 in the MKNFD

1 Samuel 16 in the MNG

1 Samuel 16 in the MNT

1 Samuel 16 in the MNT2

1 Samuel 16 in the MRS1T

1 Samuel 16 in the NAA

1 Samuel 16 in the NASB

1 Samuel 16 in the NBLA

1 Samuel 16 in the NBS

1 Samuel 16 in the NBVTP

1 Samuel 16 in the NET2

1 Samuel 16 in the NIV11

1 Samuel 16 in the NNT

1 Samuel 16 in the NNT2

1 Samuel 16 in the NNT3

1 Samuel 16 in the PDDPT

1 Samuel 16 in the PFNT

1 Samuel 16 in the RMNT

1 Samuel 16 in the SBIAS

1 Samuel 16 in the SBIBS

1 Samuel 16 in the SBIBS2

1 Samuel 16 in the SBICS

1 Samuel 16 in the SBIDS

1 Samuel 16 in the SBIGS

1 Samuel 16 in the SBIHS

1 Samuel 16 in the SBIIS

1 Samuel 16 in the SBIIS2

1 Samuel 16 in the SBIIS3

1 Samuel 16 in the SBIKS

1 Samuel 16 in the SBIKS2

1 Samuel 16 in the SBIMS

1 Samuel 16 in the SBIOS

1 Samuel 16 in the SBIPS

1 Samuel 16 in the SBISS

1 Samuel 16 in the SBITS

1 Samuel 16 in the SBITS2

1 Samuel 16 in the SBITS3

1 Samuel 16 in the SBITS4

1 Samuel 16 in the SBIUS

1 Samuel 16 in the SBIVS

1 Samuel 16 in the SBT

1 Samuel 16 in the SBT1E

1 Samuel 16 in the SCHL

1 Samuel 16 in the SNT

1 Samuel 16 in the SUSU

1 Samuel 16 in the SUSU2

1 Samuel 16 in the SYNO

1 Samuel 16 in the TBIAOTANT

1 Samuel 16 in the TBT1E

1 Samuel 16 in the TBT1E2

1 Samuel 16 in the TFTIP

1 Samuel 16 in the TFTU

1 Samuel 16 in the TGNTATF3T

1 Samuel 16 in the THAI

1 Samuel 16 in the TNFD

1 Samuel 16 in the TNT

1 Samuel 16 in the TNTIK

1 Samuel 16 in the TNTIL

1 Samuel 16 in the TNTIN

1 Samuel 16 in the TNTIP

1 Samuel 16 in the TNTIZ

1 Samuel 16 in the TOMA

1 Samuel 16 in the TTENT

1 Samuel 16 in the UBG

1 Samuel 16 in the UGV

1 Samuel 16 in the UGV2

1 Samuel 16 in the UGV3

1 Samuel 16 in the VBL

1 Samuel 16 in the VDCC

1 Samuel 16 in the YALU

1 Samuel 16 in the YAPE

1 Samuel 16 in the YBVTP

1 Samuel 16 in the ZBP