2 Chronicles 11 (BOYCB)

1 Nígbà tí Rehoboamu dé Jerusalẹmu, ó kó ilé Juda àti Benjamini jọ, ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án (180,000) ènìyàn tí a yàn, tí wọ́n jẹ́ ológun, láti bá Israẹli jà kí ó lè mú ìjọba náà padà bọ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀. 2 Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ OLÚWA tọ Ṣemaiah ènìyàn Ọlọ́run wá wí pé, 3 “Wí fún Rehoboamu ọmọ Solomoni ọba Juda, sí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ní Juda àti Benjamini, 4 ‘Èyí ní ohun tí OLÚWA wí. Ẹ má ṣe gòkè lọ láti lọ jà pẹ̀lú arákùnrin yín, ẹ lọ sílé, gbogbo yín, nítorí ti ìṣe mi nìyí.’ ” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n tẹ̀lé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n sì padà sẹ́yìn láti yan lọ dojúkọ Jeroboamu. 5 Rehoboamu ń gbe ní Jerusalẹmu ó sì kọ́ àwọn ìlú fún olódi ní Juda. 6 Bẹtilẹhẹmu, Etamu, Tekoa, 7 Beti-Suri, Soko, Adullamu, 8 Gati, Meraṣa Sifi, 9 Adoraimu, Lakiṣi, Aseka 10 Sora, Aijaloni, àti Hebroni. Wọ̀nyí ni àwọn ìlú ìdáàbòbò ní Juda àti Benjamini. 11 Ó sì mú àwọn ìlú olódi lágbára, ó sì fi àwọn balógun sínú wọn àti àkójọ oúnjẹ, àti òróró àti ọtí wáìnì. 12 Àti ní olúkúlùkù ìlú ni ó fi asà àti ọ̀kọ̀ sí, ó sì mú wọn lágbára gidigidi, ó sì ní Juda àti Benjamini lábẹ́ rẹ̀. 13 Àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi, láti gbogbo ẹ̀yà wọn jákèjádò Israẹli wà ní ẹ̀bá rẹ̀. 14 Àwọn ará Lefi fi ìgbèríko sílẹ̀, wọ́n sì wá sí Juda àti Jerusalẹmu nítorí Jeroboamu àti àwọn ọmọ rẹ̀, ti kọ̀ wọ́n sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn àlùfáà OLÚWA. 15 Ó sì yan àwọn àlùfáà tirẹ̀ fún àwọn ibi gíga wọ̀n-ọn-nì, àti fún àwọn ère òbúkọ, àti fún ẹgbọrọ màlúù tí ó ṣe. 16 Àwọn tó wá láti gbogbo ẹ̀yà Israẹli tí wọ́n fi ọkàn wọn fún wíwá OLÚWA, Ọlọ́run Israẹli, tẹ̀lé àwọn ará Lefi lọ sí Jerusalẹmu láti lọ rú ẹbọ sí OLÚWA Ọlọ́run baba a wọn. 17 Ó fún ìjọba Juda ní agbára, ó sì ti Rehoboamu ọmọ Solomoni lẹ́yìn fún ọdún mẹ́ta nítorí ọdún mẹ́ta ni wọ́n fi rìn ní ọ̀nà ti Dafidi àti Solomoni ní àkókò yí. 18 Rehoboamu fẹ́ Mahalati tí ó jẹ́ ọmọbìnrin ti ọmọkùnrin Dafidi Jerimoti bi àti ti Abihaili, ọmọbìnrin ti ọmọkùnrin Jese Eliabu bí. 19 Ó bí àwọn ọmọ fún un: Jeuṣi, Ṣemariah àti Sahamu. 20 Nígbà náà, ó fẹ́ Maaka ọmọbìnrin Absalomu, tí ó bí Abijah fún Attai, Sisa àti Ṣelomiti. 21 Rehoboamu fẹ́ràn Maaka ọmọbìnrin Absalomu ju èyíkéyìí nínú àwọn ìyàwó rẹ̀ àti àwọn àlè rẹ̀ lọ. Ní gbogbo rẹ̀, ó ní ìyàwó méjìdínlógún àti ọgọ́ta àlè ọmọkùnrin méjìdínlọ́gbọ̀n àti ọgọ́ta ọmọbìnrin. 22 Rehoboamu yan Abijah ọmọ Maaka láti jẹ́ olóyè ọmọ-aládé láàrín àwọn arákùnrin rẹ̀, kí ó ba à lè ṣe é ní ọba. 23 Ó hùwà ọlọ́gbọ́n, nípa fí fọ́n díẹ̀ nínú àwọn ọmọ rẹ̀ jákèjádò ká àwọn agbègbè Juda àti Benjamini àti sí gbogbo àwọn ìlú ńlá olódi. Ó fún wọn ní ọ̀pọ̀ ohun tí wọ́n fẹ́, ó sì fẹ́ ọ̀pọ̀ ìyàwó fún wọn.

In Other Versions

2 Chronicles 11 in the ANGEFD

2 Chronicles 11 in the ANTPNG2D

2 Chronicles 11 in the AS21

2 Chronicles 11 in the BAGH

2 Chronicles 11 in the BBPNG

2 Chronicles 11 in the BBT1E

2 Chronicles 11 in the BDS

2 Chronicles 11 in the BEV

2 Chronicles 11 in the BHAD

2 Chronicles 11 in the BIB

2 Chronicles 11 in the BLPT

2 Chronicles 11 in the BNT

2 Chronicles 11 in the BNTABOOT

2 Chronicles 11 in the BNTLV

2 Chronicles 11 in the BOATCB

2 Chronicles 11 in the BOATCB2

2 Chronicles 11 in the BOBCV

2 Chronicles 11 in the BOCNT

2 Chronicles 11 in the BOECS

2 Chronicles 11 in the BOGWICC

2 Chronicles 11 in the BOHCB

2 Chronicles 11 in the BOHCV

2 Chronicles 11 in the BOHLNT

2 Chronicles 11 in the BOHNTLTAL

2 Chronicles 11 in the BOICB

2 Chronicles 11 in the BOILNTAP

2 Chronicles 11 in the BOITCV

2 Chronicles 11 in the BOKCV

2 Chronicles 11 in the BOKCV2

2 Chronicles 11 in the BOKHWOG

2 Chronicles 11 in the BOKSSV

2 Chronicles 11 in the BOLCB

2 Chronicles 11 in the BOLCB2

2 Chronicles 11 in the BOMCV

2 Chronicles 11 in the BONAV

2 Chronicles 11 in the BONCB

2 Chronicles 11 in the BONLT

2 Chronicles 11 in the BONUT2

2 Chronicles 11 in the BOPLNT

2 Chronicles 11 in the BOSCB

2 Chronicles 11 in the BOSNC

2 Chronicles 11 in the BOTLNT

2 Chronicles 11 in the BOVCB

2 Chronicles 11 in the BPBB

2 Chronicles 11 in the BPH

2 Chronicles 11 in the BSB

2 Chronicles 11 in the CCB

2 Chronicles 11 in the CUV

2 Chronicles 11 in the CUVS

2 Chronicles 11 in the DBT

2 Chronicles 11 in the DGDNT

2 Chronicles 11 in the DHNT

2 Chronicles 11 in the DNT

2 Chronicles 11 in the ELBE

2 Chronicles 11 in the EMTV

2 Chronicles 11 in the ESV

2 Chronicles 11 in the FBV

2 Chronicles 11 in the FEB

2 Chronicles 11 in the GGMNT

2 Chronicles 11 in the GNT

2 Chronicles 11 in the HARY

2 Chronicles 11 in the HNT

2 Chronicles 11 in the IRVA

2 Chronicles 11 in the IRVB

2 Chronicles 11 in the IRVG

2 Chronicles 11 in the IRVH

2 Chronicles 11 in the IRVK

2 Chronicles 11 in the IRVM

2 Chronicles 11 in the IRVM2

2 Chronicles 11 in the IRVO

2 Chronicles 11 in the IRVP

2 Chronicles 11 in the IRVT

2 Chronicles 11 in the IRVT2

2 Chronicles 11 in the IRVU

2 Chronicles 11 in the ISVN

2 Chronicles 11 in the JSNT

2 Chronicles 11 in the KAPI

2 Chronicles 11 in the KBT1ETNIK

2 Chronicles 11 in the KBV

2 Chronicles 11 in the KJV

2 Chronicles 11 in the KNFD

2 Chronicles 11 in the LBA

2 Chronicles 11 in the LBLA

2 Chronicles 11 in the LNT

2 Chronicles 11 in the LSV

2 Chronicles 11 in the MAAL

2 Chronicles 11 in the MBV

2 Chronicles 11 in the MBV2

2 Chronicles 11 in the MHNT

2 Chronicles 11 in the MKNFD

2 Chronicles 11 in the MNG

2 Chronicles 11 in the MNT

2 Chronicles 11 in the MNT2

2 Chronicles 11 in the MRS1T

2 Chronicles 11 in the NAA

2 Chronicles 11 in the NASB

2 Chronicles 11 in the NBLA

2 Chronicles 11 in the NBS

2 Chronicles 11 in the NBVTP

2 Chronicles 11 in the NET2

2 Chronicles 11 in the NIV11

2 Chronicles 11 in the NNT

2 Chronicles 11 in the NNT2

2 Chronicles 11 in the NNT3

2 Chronicles 11 in the PDDPT

2 Chronicles 11 in the PFNT

2 Chronicles 11 in the RMNT

2 Chronicles 11 in the SBIAS

2 Chronicles 11 in the SBIBS

2 Chronicles 11 in the SBIBS2

2 Chronicles 11 in the SBICS

2 Chronicles 11 in the SBIDS

2 Chronicles 11 in the SBIGS

2 Chronicles 11 in the SBIHS

2 Chronicles 11 in the SBIIS

2 Chronicles 11 in the SBIIS2

2 Chronicles 11 in the SBIIS3

2 Chronicles 11 in the SBIKS

2 Chronicles 11 in the SBIKS2

2 Chronicles 11 in the SBIMS

2 Chronicles 11 in the SBIOS

2 Chronicles 11 in the SBIPS

2 Chronicles 11 in the SBISS

2 Chronicles 11 in the SBITS

2 Chronicles 11 in the SBITS2

2 Chronicles 11 in the SBITS3

2 Chronicles 11 in the SBITS4

2 Chronicles 11 in the SBIUS

2 Chronicles 11 in the SBIVS

2 Chronicles 11 in the SBT

2 Chronicles 11 in the SBT1E

2 Chronicles 11 in the SCHL

2 Chronicles 11 in the SNT

2 Chronicles 11 in the SUSU

2 Chronicles 11 in the SUSU2

2 Chronicles 11 in the SYNO

2 Chronicles 11 in the TBIAOTANT

2 Chronicles 11 in the TBT1E

2 Chronicles 11 in the TBT1E2

2 Chronicles 11 in the TFTIP

2 Chronicles 11 in the TFTU

2 Chronicles 11 in the TGNTATF3T

2 Chronicles 11 in the THAI

2 Chronicles 11 in the TNFD

2 Chronicles 11 in the TNT

2 Chronicles 11 in the TNTIK

2 Chronicles 11 in the TNTIL

2 Chronicles 11 in the TNTIN

2 Chronicles 11 in the TNTIP

2 Chronicles 11 in the TNTIZ

2 Chronicles 11 in the TOMA

2 Chronicles 11 in the TTENT

2 Chronicles 11 in the UBG

2 Chronicles 11 in the UGV

2 Chronicles 11 in the UGV2

2 Chronicles 11 in the UGV3

2 Chronicles 11 in the VBL

2 Chronicles 11 in the VDCC

2 Chronicles 11 in the YALU

2 Chronicles 11 in the YAPE

2 Chronicles 11 in the YBVTP

2 Chronicles 11 in the ZBP