2 Kings 13 (BOYCB)
1 Ní ọdún kẹtàlélógún ti Joaṣi ọmọ ọba Ahasiah ti Juda, Jehoahasi ọmọ Jehu di ọba Israẹli ní Samaria. Ó sì jẹ ọba fún ọdún mẹ́tàdínlógún. 2 Ó ṣe búburú níwájú OLÚWA nípa títẹ̀lé ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu ọmọ Nebati, èyí tí ó ti fa Israẹli láti dá, kò sì yípadà kúrò nínú wọn. 3 Bẹ́ẹ̀ ni ìbínú OLÚWA ru sí àwọn ọmọ Israẹli, àti fún ìgbà pípẹ́, ó fi wọ́n pamọ́ sí abẹ́ agbára ọba Hasaeli ọba Siria àti Beni-Hadadi ọmọ rẹ̀. 4 Nígbà náà Jehoahasi kígbe ó wá ojúrere OLÚWA, OLÚWA sì tẹ́tí sí i. Nítorí ó rí bí ọba Siria ti ń ni Israẹli lára gidigidi. 5 OLÚWA pèsè olùgbàlà fún Israẹli, wọ́n sì sá kúrò lọ́wọ́ agbára Siria. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli gbé nínú ilé ara wọn gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti wà tẹ́lẹ̀. 6 Ṣùgbọ́n wọn kò yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ ilé Jeroboamu, èyí tí ó ti fa Israẹli láti dá, wọ́n tẹ̀síwájú nínú rẹ̀, ère òrìṣà Aṣerah sì wà síbẹ̀ ní Samaria pẹ̀lú. 7 Kò sí ohùn kan tí wọ́n fi sílẹ̀ ní ti ọmọ-ogun Jehoahasi àyàfi àádọ́ta ọkùnrin ẹlẹ́ṣin, kẹ̀kẹ́ mẹ́wàá, àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ọmọ-ogun ẹlẹ́ṣẹ̀, nítorí ọba Siria ti pa ìyókù run, ó sì ṣe wọ́n bí eruku nígbà pípa ọkà. 8 Fún ti ìyókù ìṣe Jehoahasi fún ìgbà, tí ó fi jẹ ọba, gbogbo ohun tí ó ṣe àti àṣeyọrí rẹ̀ ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Israẹli? 9 Jehoahasi pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀. A sì sin ín sí Samaria. Jehoaṣi ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba. 10 Ní ọdún kẹtàdínlógójì tí Joaṣi ọba Juda, Jehoaṣi ọmọ Jehoahasi di ọba Israẹli ní Samaria ó sì jẹ ọba fún ọdún mẹ́rìndínlógún. 11 Ó ṣe búburú ní ojú OLÚWA, kò sì yípadà kúrò nínú ọ̀kankan nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu ọmọ Nebati èyí tí ó ti ti Israẹli láti fà. Ó sì tẹ̀síwájú nínú wọn. 12 Fún ti ìyókù iṣẹ́ Jehoaṣi fún ìgbà tí ó fi jẹ ọba, gbogbo ohun tí ó ṣe, pẹ̀lú àṣeyọrí rẹ̀ pẹ̀lú ogun rẹ̀ sí Amasiah ọba Juda, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Israẹli? 13 Jehoaṣi sinmi pẹ̀lú àwọn baba a rẹ̀. Jeroboamu sì rọ́pò rẹ̀ lórí ìtẹ́. A sin Jehoaṣi sí Samaria pẹ̀lú àwọn ọba Israẹli. 14 Nísinsin yìí, Eliṣa ń jìyà lọ́wọ́ àìsàn, lọ́wọ́ èyí tí ó sì kú. Jehoaṣi ọba Israẹli lọ láti lọ wò ó, ó sì sọkún lórí rẹ̀. “Baba mi! Baba mi!” Ó sọkún. “Àwọn kẹ̀kẹ́ àti àwọn ọkùnrin ẹlẹ́ṣin Israẹli!” 15 Eliṣa wí pé, “Mú ọrun kan àti àwọn ọfà,” ó sì ṣe bẹ́ẹ̀. 16 “Mú ọrun ní ọwọ́ rẹ.” Ó wí fún ọba Israẹli. Nígbà tí ó ti mú u, Eliṣa mú ọwọ́ rẹ̀ lé ọwọ́ ọba. 17 “Ṣí fèrèsé apá ìlà-oòrùn,” ó wí, pẹ̀lú ó sì ṣí i: “Ta á!” Eliṣa wí, ó sì ta á. “Ọfà ìṣẹ́gun OLÚWA; ọfà ìṣẹ́gun lórí Siria!” Eliṣa kéde. “Ìwọ yóò pa àwọn ará Siria run pátápátá ní Afeki.” 18 Nígbà náà ó wí pé, “Mú àwọn ọfà náà,” ọba sì mú wọn. Eliṣa wí fún un pé, “Lu ilẹ̀.” Ó lù ú lẹ́ẹ̀mẹ́ta, ó sì dáwọ́ dúró. 19 Ènìyàn Ọlọ́run sì bínú sí i, ó sì wí pé, “Ìwọ kò bá ti lu ilẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀márùn ún tàbí ní ẹ̀ẹ̀mẹ́fà, nígbà náà, ìwọ kò bá ti ṣẹ́gun Siria àti pa á run pátápátá ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ìwọ yóò ṣẹ́gun rẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀mẹ́ta péré.” 20 Eliṣa kú a sì sin ín.Ẹgbẹ́ àwọn ará Moabu máa ń wọ orílẹ̀-èdè ní gbogbo àmọ́dún. 21 Bí àwọn ọmọ Israẹli kan ti ń sin òkú ọkùnrin kan, lójijì wọ́n rí ẹgbẹ́ àwọn oníjadì, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ju òkú ọkùnrin náà sínú ibojì Eliṣa. Nígbà tí ara ọkùnrin náà kan egungun Eliṣa, ó padà wá sí ayé, ó sì dúró ní ẹsẹ̀ rẹ̀. 22 Hasaeli ọba Siria ni Israẹli lára ní gbogbo àkókò tí Jehoahasi fi jẹ ọba. 23 Ṣùgbọ́n OLÚWA ṣàánú fún wọn ó sì ní ìyọ́nú, ó sì fiyèsí wọn nítorí májẹ̀mú rẹ̀ pẹ̀lú Abrahamu, Isaaki àti Jakọbu. Títí di ọjọ́ òní, kì í ṣe ìfẹ́ inú rẹ̀ láti pa wọ́n run tàbí lé wọn lọ níwájú rẹ̀. 24 Hasaeli ọba Siria kú, Beni-Hadadi ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba. 25 Nígbà náà, Jehoaṣi ọmọ Jehoahasi gbà padà kúrò lọ́wọ́ Beni-Hadadi ọmọ Hasaeli àwọn ìlú tí ó ti gbà nínú ogun látọ̀dọ̀ baba rẹ̀ Jehoahasi. Ní ẹ̀ẹ̀mẹta, Jehoaṣi ṣẹ́gun rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó gba ìlú àwọn ọmọ Israẹli padà.
In Other Versions
2 Kings 13 in the ANGEFD
2 Kings 13 in the ANTPNG2D
2 Kings 13 in the AS21
2 Kings 13 in the BAGH
2 Kings 13 in the BBPNG
2 Kings 13 in the BBT1E
2 Kings 13 in the BDS
2 Kings 13 in the BEV
2 Kings 13 in the BHAD
2 Kings 13 in the BIB
2 Kings 13 in the BLPT
2 Kings 13 in the BNT
2 Kings 13 in the BNTABOOT
2 Kings 13 in the BNTLV
2 Kings 13 in the BOATCB
2 Kings 13 in the BOATCB2
2 Kings 13 in the BOBCV
2 Kings 13 in the BOCNT
2 Kings 13 in the BOECS
2 Kings 13 in the BOGWICC
2 Kings 13 in the BOHCB
2 Kings 13 in the BOHCV
2 Kings 13 in the BOHLNT
2 Kings 13 in the BOHNTLTAL
2 Kings 13 in the BOICB
2 Kings 13 in the BOILNTAP
2 Kings 13 in the BOITCV
2 Kings 13 in the BOKCV
2 Kings 13 in the BOKCV2
2 Kings 13 in the BOKHWOG
2 Kings 13 in the BOKSSV
2 Kings 13 in the BOLCB
2 Kings 13 in the BOLCB2
2 Kings 13 in the BOMCV
2 Kings 13 in the BONAV
2 Kings 13 in the BONCB
2 Kings 13 in the BONLT
2 Kings 13 in the BONUT2
2 Kings 13 in the BOPLNT
2 Kings 13 in the BOSCB
2 Kings 13 in the BOSNC
2 Kings 13 in the BOTLNT
2 Kings 13 in the BOVCB
2 Kings 13 in the BPBB
2 Kings 13 in the BPH
2 Kings 13 in the BSB
2 Kings 13 in the CCB
2 Kings 13 in the CUV
2 Kings 13 in the CUVS
2 Kings 13 in the DBT
2 Kings 13 in the DGDNT
2 Kings 13 in the DHNT
2 Kings 13 in the DNT
2 Kings 13 in the ELBE
2 Kings 13 in the EMTV
2 Kings 13 in the ESV
2 Kings 13 in the FBV
2 Kings 13 in the FEB
2 Kings 13 in the GGMNT
2 Kings 13 in the GNT
2 Kings 13 in the HARY
2 Kings 13 in the HNT
2 Kings 13 in the IRVA
2 Kings 13 in the IRVB
2 Kings 13 in the IRVG
2 Kings 13 in the IRVH
2 Kings 13 in the IRVK
2 Kings 13 in the IRVM
2 Kings 13 in the IRVM2
2 Kings 13 in the IRVO
2 Kings 13 in the IRVP
2 Kings 13 in the IRVT
2 Kings 13 in the IRVT2
2 Kings 13 in the IRVU
2 Kings 13 in the ISVN
2 Kings 13 in the JSNT
2 Kings 13 in the KAPI
2 Kings 13 in the KBT1ETNIK
2 Kings 13 in the KBV
2 Kings 13 in the KJV
2 Kings 13 in the KNFD
2 Kings 13 in the LBA
2 Kings 13 in the LBLA
2 Kings 13 in the LNT
2 Kings 13 in the LSV
2 Kings 13 in the MAAL
2 Kings 13 in the MBV
2 Kings 13 in the MBV2
2 Kings 13 in the MHNT
2 Kings 13 in the MKNFD
2 Kings 13 in the MNG
2 Kings 13 in the MNT
2 Kings 13 in the MNT2
2 Kings 13 in the MRS1T
2 Kings 13 in the NAA
2 Kings 13 in the NASB
2 Kings 13 in the NBLA
2 Kings 13 in the NBS
2 Kings 13 in the NBVTP
2 Kings 13 in the NET2
2 Kings 13 in the NIV11
2 Kings 13 in the NNT
2 Kings 13 in the NNT2
2 Kings 13 in the NNT3
2 Kings 13 in the PDDPT
2 Kings 13 in the PFNT
2 Kings 13 in the RMNT
2 Kings 13 in the SBIAS
2 Kings 13 in the SBIBS
2 Kings 13 in the SBIBS2
2 Kings 13 in the SBICS
2 Kings 13 in the SBIDS
2 Kings 13 in the SBIGS
2 Kings 13 in the SBIHS
2 Kings 13 in the SBIIS
2 Kings 13 in the SBIIS2
2 Kings 13 in the SBIIS3
2 Kings 13 in the SBIKS
2 Kings 13 in the SBIKS2
2 Kings 13 in the SBIMS
2 Kings 13 in the SBIOS
2 Kings 13 in the SBIPS
2 Kings 13 in the SBISS
2 Kings 13 in the SBITS
2 Kings 13 in the SBITS2
2 Kings 13 in the SBITS3
2 Kings 13 in the SBITS4
2 Kings 13 in the SBIUS
2 Kings 13 in the SBIVS
2 Kings 13 in the SBT
2 Kings 13 in the SBT1E
2 Kings 13 in the SCHL
2 Kings 13 in the SNT
2 Kings 13 in the SUSU
2 Kings 13 in the SUSU2
2 Kings 13 in the SYNO
2 Kings 13 in the TBIAOTANT
2 Kings 13 in the TBT1E
2 Kings 13 in the TBT1E2
2 Kings 13 in the TFTIP
2 Kings 13 in the TFTU
2 Kings 13 in the TGNTATF3T
2 Kings 13 in the THAI
2 Kings 13 in the TNFD
2 Kings 13 in the TNT
2 Kings 13 in the TNTIK
2 Kings 13 in the TNTIL
2 Kings 13 in the TNTIN
2 Kings 13 in the TNTIP
2 Kings 13 in the TNTIZ
2 Kings 13 in the TOMA
2 Kings 13 in the TTENT
2 Kings 13 in the UBG
2 Kings 13 in the UGV
2 Kings 13 in the UGV2
2 Kings 13 in the UGV3
2 Kings 13 in the VBL
2 Kings 13 in the VDCC
2 Kings 13 in the YALU
2 Kings 13 in the YAPE
2 Kings 13 in the YBVTP
2 Kings 13 in the ZBP