Esther 3 (BOYCB)
1 Lẹ́yìn àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí, ọba Ahaswerusi dá Hamani ọmọ Hammedata, ará Agagi lọ́lá, ọba gbé e ga, ó si fún un ní àga ọlá tí ó ju ti gbogbo àwọn ọlọ́lá tókù lọ. 2 Gbogbo àwọn ìjòyè ọba tí ó wà ní ẹnu-ọ̀nà ọba wọn kúnlẹ̀ wọ́n sì fi ọlá fun Hamani, nítorí ọba ti pàṣẹ èyí nípa tirẹ̀. Ṣùgbọ́n Mordekai kò ní kúnlẹ̀ tàbí bu ọlá fún un. 3 Nígbà náà ni àwọn ìjòyè ọba tí ó wà ní ẹnu-ọ̀nà béèrè lọ́wọ́ Mordekai pé, “Èéṣe tí ìwọ kò ṣe pa àṣẹ ọba mọ́.” 4 Ní ojoojúmọ́ ni wọ́n máa n sọ fún un ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, wọ́n sọ fún Hamani nípa rẹ̀ láti wò ó bóyá ó lè gba irú ìwà tí Mordekai ń hù yìí, nítorí tí ó ti sọ fún wọn pé Júù ni òun. 5 Nígbà tí Hamani rí i pé Mordekai kò ní kúnlẹ̀ tàbí bu ọlá fún òun, ó bínú. 6 Síbẹ̀ kò mọ irú ènìyàn tí Mordekai jẹ́, ó kẹ́gàn láti pa Mordekai nìkan. Dípò bẹ́ẹ̀ Hamani ń wá láti pa gbogbo ènìyàn Mordekai run, àwọn Júù jákèjádò gbogbo ìjọba Ahaswerusi. 7 Ní ọdún kejìlá ọba Ahaswerusi, ní oṣù kìn-ín-ní, èyí ni oṣù Nisani, wọ́n da puri (èyí tí í ṣe, ìbò) ní iwájú Hamani láti yan ọjọ́ kan àti oṣù, ìbò náà sì wáyé ní oṣù kejìlá, oṣù Addari. 8 Nígbà náà ni Hamani sọ fún ọba Ahaswerusi pé, “Àwọn ènìyàn kan wà tí wọ́n fọ́nká tí wọ́n sì túká ní ara àwọn ènìyàn ní gbogbo àgbáyé ìjọba rẹ̀ tí ìṣe wọn yàtọ̀ sí ti gbogbo àwọn tókù tí wọn kò sì pa òfin ọba mọ́; èyí kì í ṣe ìfẹ́ ọba láti gbà fún wọn bẹ́ẹ̀. 9 Tí ó bá tẹ́ ọba lọ́rùn, kí a gbé òfin kan jáde tí yóò pa wọ́n run, èmi yóò sì fi ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) tálẹ́ǹtì fàdákà sínú ìṣúra ọba fún àwọn ọkùnrin tí wọn o ṣe iṣẹ́ náà.” 10 Nítorí náà, ọba sì bọ́ òrùka èdìdì tí ó wà ní ìka rẹ̀, ó sì fi fún Hamani ọmọ Hammedata, ará Agagi, ọ̀tá àwọn Júù. 11 Ọba sọ fún Hamani pé, “Pa owó náà mọ́, kí o sì ṣe ohun tí ó wù ọ́ fún àwọn ènìyàn náà.” 12 Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹtàlá oṣù kìn-ín-ní àkọ́kọ́, wọ́n pe àwọn akọ̀wé ọba jọ. Wọ́n kọ ọ́ ní ìlànà bí ìgbèríko kọ̀ọ̀kan ṣe ń kọ̀wé, ó kọ̀wé sí àwọn ènìyàn kọ̀ọ̀kan ní èdè wọn gbogbo èyí tí Hamani ti pàṣẹ sí àwọn akọ̀wé ọba, sí baálẹ̀ ìgbèríko kọ̀ọ̀kan àti àwọn ọlọ́lá àwọn onírúurú ènìyàn. A kọ èyí ní orúkọ ọba Ahaswerusi fúnra rẹ̀ ó sì fi òrùka ọba ṣe èdìdì i rẹ̀. 13 A sì fi ìwé náà ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn ìgbèríko ọba pẹ̀lú àṣẹ láti parun, láti pa gbogbo àwọn Júù èwe àti àgbà, obìnrin àti àwọn ọmọ wẹ́wẹ́—ní ọjọ́ kan kí wọn sì parẹ́, ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kejìlá, oṣù Addari kí a sì kó àwọn ohun ìní wọn. 14 Kí ẹ mú àdàkọ ìwé náà kí a tẹ̀ ẹ́ jáde bí òfin ní gbogbo ìgbèríko kí ó sì di mí mọ̀ fún àwọn ènìyàn ìlú nítorí kí wọ́n le múra fún ọjọ́ náà. 15 Àwọn ìránṣẹ́ náà sì jáde, wọ́n tẹ̀síwájú nípa àṣẹ ọba, ìkéde náà sì jáde ní ilé ìṣọ́ ti Susa. Ọba àti Hamani jókòó wọ́n ń mu, ṣùgbọ́n ìlú Susa wà nínú ìdààmú.
In Other Versions
Esther 3 in the ANGEFD
Esther 3 in the ANTPNG2D
Esther 3 in the AS21
Esther 3 in the BAGH
Esther 3 in the BBPNG
Esther 3 in the BBT1E
Esther 3 in the BDS
Esther 3 in the BEV
Esther 3 in the BHAD
Esther 3 in the BIB
Esther 3 in the BLPT
Esther 3 in the BNT
Esther 3 in the BNTABOOT
Esther 3 in the BNTLV
Esther 3 in the BOATCB
Esther 3 in the BOATCB2
Esther 3 in the BOBCV
Esther 3 in the BOCNT
Esther 3 in the BOECS
Esther 3 in the BOGWICC
Esther 3 in the BOHCB
Esther 3 in the BOHCV
Esther 3 in the BOHLNT
Esther 3 in the BOHNTLTAL
Esther 3 in the BOICB
Esther 3 in the BOILNTAP
Esther 3 in the BOITCV
Esther 3 in the BOKCV
Esther 3 in the BOKCV2
Esther 3 in the BOKHWOG
Esther 3 in the BOKSSV
Esther 3 in the BOLCB
Esther 3 in the BOLCB2
Esther 3 in the BOMCV
Esther 3 in the BONAV
Esther 3 in the BONCB
Esther 3 in the BONLT
Esther 3 in the BONUT2
Esther 3 in the BOPLNT
Esther 3 in the BOSCB
Esther 3 in the BOSNC
Esther 3 in the BOTLNT
Esther 3 in the BOVCB
Esther 3 in the BPBB
Esther 3 in the BPH
Esther 3 in the BSB
Esther 3 in the CCB
Esther 3 in the CUV
Esther 3 in the CUVS
Esther 3 in the DBT
Esther 3 in the DGDNT
Esther 3 in the DHNT
Esther 3 in the DNT
Esther 3 in the ELBE
Esther 3 in the EMTV
Esther 3 in the ESV
Esther 3 in the FBV
Esther 3 in the FEB
Esther 3 in the GGMNT
Esther 3 in the GNT
Esther 3 in the HARY
Esther 3 in the HNT
Esther 3 in the IRVA
Esther 3 in the IRVB
Esther 3 in the IRVG
Esther 3 in the IRVH
Esther 3 in the IRVK
Esther 3 in the IRVM
Esther 3 in the IRVM2
Esther 3 in the IRVO
Esther 3 in the IRVP
Esther 3 in the IRVT
Esther 3 in the IRVT2
Esther 3 in the IRVU
Esther 3 in the ISVN
Esther 3 in the JSNT
Esther 3 in the KAPI
Esther 3 in the KBT1ETNIK
Esther 3 in the KBV
Esther 3 in the KJV
Esther 3 in the KNFD
Esther 3 in the LBA
Esther 3 in the LBLA
Esther 3 in the LNT
Esther 3 in the LSV
Esther 3 in the MAAL
Esther 3 in the MBV
Esther 3 in the MBV2
Esther 3 in the MHNT
Esther 3 in the MKNFD
Esther 3 in the MNG
Esther 3 in the MNT
Esther 3 in the MNT2
Esther 3 in the MRS1T
Esther 3 in the NAA
Esther 3 in the NASB
Esther 3 in the NBLA
Esther 3 in the NBS
Esther 3 in the NBVTP
Esther 3 in the NET2
Esther 3 in the NIV11
Esther 3 in the NNT
Esther 3 in the NNT2
Esther 3 in the NNT3
Esther 3 in the PDDPT
Esther 3 in the PFNT
Esther 3 in the RMNT
Esther 3 in the SBIAS
Esther 3 in the SBIBS
Esther 3 in the SBIBS2
Esther 3 in the SBICS
Esther 3 in the SBIDS
Esther 3 in the SBIGS
Esther 3 in the SBIHS
Esther 3 in the SBIIS
Esther 3 in the SBIIS2
Esther 3 in the SBIIS3
Esther 3 in the SBIKS
Esther 3 in the SBIKS2
Esther 3 in the SBIMS
Esther 3 in the SBIOS
Esther 3 in the SBIPS
Esther 3 in the SBISS
Esther 3 in the SBITS
Esther 3 in the SBITS2
Esther 3 in the SBITS3
Esther 3 in the SBITS4
Esther 3 in the SBIUS
Esther 3 in the SBIVS
Esther 3 in the SBT
Esther 3 in the SBT1E
Esther 3 in the SCHL
Esther 3 in the SNT
Esther 3 in the SUSU
Esther 3 in the SUSU2
Esther 3 in the SYNO
Esther 3 in the TBIAOTANT
Esther 3 in the TBT1E
Esther 3 in the TBT1E2
Esther 3 in the TFTIP
Esther 3 in the TFTU
Esther 3 in the TGNTATF3T
Esther 3 in the THAI
Esther 3 in the TNFD
Esther 3 in the TNT
Esther 3 in the TNTIK
Esther 3 in the TNTIL
Esther 3 in the TNTIN
Esther 3 in the TNTIP
Esther 3 in the TNTIZ
Esther 3 in the TOMA
Esther 3 in the TTENT
Esther 3 in the UBG
Esther 3 in the UGV
Esther 3 in the UGV2
Esther 3 in the UGV3
Esther 3 in the VBL
Esther 3 in the VDCC
Esther 3 in the YALU
Esther 3 in the YAPE
Esther 3 in the YBVTP
Esther 3 in the ZBP