Exodus 17 (BOYCB)
1 Gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli si gbéra láti jáde kúrò láti aginjù Sini wọ́n ń lọ láti ibi kan de ibi kan gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti pàṣẹ. Wọ́n pàgọ́ sí Refidimu, ṣùgbọ́n kò sí omi fún àwọn ènìyàn láti mú. 2 Àwọn ènìyàn sì sọ̀ fún Mose, wọ́n wí pé, “Fún wa ni omi mu.”Mose dá wọn lóhùn wí pé, “Èéṣe ti ẹ̀yin fi ń bá mi jà? Èéṣe ti ẹ̀yin fi ń dán OLÚWA wò?” 3 Ṣùgbọ́n òǹgbẹ ń gbẹ àwọn ènìyàn, wọ́n sì ń kùn sí Mose, wọ́n wí pé, “Èéṣe tí ìwọ fi mú wa jáde kúrò ní Ejibiti láti mú kí òǹgbẹ pa àwa, àwọn ọmọ wa àti ohun ọ̀sìn wa ku fún òǹgbẹ.” 4 Nígbà náà ni Mose gbé ohùn rẹ̀ sókè sí OLÚWA pé, “Kí ni kí èmi kí ó ṣe fún àwọn ènìyàn yìí? Wọ́n múra tan láti sọ mi ni òkúta.” 5 OLÚWA sì dá Mose lóhùn pé, “Máa lọ síwájú àwọn ènìyàn, mú nínú àwọn àgbàgbà Israẹli pẹ̀lú rẹ, mú ọ̀pá tí ìwọ fi lu odò Naili lọ́wọ́ kí ó sì máa lọ. 6 Èmi yóò dúró ni ibẹ̀ dè ọ ni orí àpáta ni Horebu. Ìwọ ó sì lu àpáta, omi yóò sì jáde nínú rẹ̀ fún àwọn ènìyàn láti mu.” Mose sì ṣe bẹ́ẹ̀ ni iwájú àwọn àgbàgbà Israẹli. 7 Ó sì sọ orúkọ ibẹ̀ ni Massa àti Meriba, nítorí àwọn ọmọ Israẹli sọ̀, wọ́n sì dán OLÚWA wò, wọ́n wí pé, “Ǹjẹ́ OLÚWA ń bẹ láàrín wa tàbí kò sí?” 8 Àwọn ara Amaleki jáde, wọ́n sì dìde ogun sí àwọn ọmọ Israẹli ni Refidimu. 9 Mose sì sọ fún Joṣua pé, “Yàn lára àwọn ọkùnrin fún wa, kí wọn ó sì jáde lọ bá àwọn ará Amaleki jà. Ní ọ̀la, èmi yóò dúró ni orí òkè pẹ̀lú ọ̀pá Ọlọ́run ní ọwọ́ mi.” 10 Joṣua ṣe bí Mose ti wí fún un, ó sì bá àwọn ará Amaleki jagun; nígbà tí Mose, Aaroni àti Huri lọ sí orí òkè náà. 11 Níwọ́n ìgbà tí Mose bá gbé apá rẹ̀ sókè, Israẹli n borí ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá sì rẹ apá rẹ̀ sílẹ̀, Amaleki a sì borí. 12 Ṣùgbọ́n apá ń ro Mose, wọ́n mú òkúta, wọ́n sì fi sí abẹ́ rẹ̀, ó sì jókòó lé òkúta náà; Aaroni àti Huri sì mu ní apá rẹ̀, ọ̀kan ní apá ọ̀tún àti èkejì ni apá òsì; apá rẹ̀ méjèèjì sì dúró gangan títí di ìgbà ti oòrùn wọ. 13 Joṣua sì fi ojú idà ṣẹ́gun àwọn ará Amaleki. 14 OLÚWA sì sọ fun Mose pé. “Kọ èyí sì inú ìwé fún ìrántí, kí o sì sọ fún Joṣua pẹ̀lú; nítorí èmi yóò pa ìrántí Amaleki run pátápátá kúrò lábẹ́ ọ̀run.” 15 Mose sì tẹ́ pẹpẹ kan, ó sì sọ orúkọ pẹpẹ náà ní OLÚWA ni Àsíá mi. 16 Ó wí pé, “A gbé ọwọ́ sókè sí ìtẹ́ OLÚWA. OLÚWA yóò bá Amaleki jagun láti ìran dé ìran.”
In Other Versions
Exodus 17 in the ANGEFD
Exodus 17 in the ANTPNG2D
Exodus 17 in the AS21
Exodus 17 in the BAGH
Exodus 17 in the BBPNG
Exodus 17 in the BBT1E
Exodus 17 in the BDS
Exodus 17 in the BEV
Exodus 17 in the BHAD
Exodus 17 in the BIB
Exodus 17 in the BLPT
Exodus 17 in the BNT
Exodus 17 in the BNTABOOT
Exodus 17 in the BNTLV
Exodus 17 in the BOATCB
Exodus 17 in the BOATCB2
Exodus 17 in the BOBCV
Exodus 17 in the BOCNT
Exodus 17 in the BOECS
Exodus 17 in the BOGWICC
Exodus 17 in the BOHCB
Exodus 17 in the BOHCV
Exodus 17 in the BOHLNT
Exodus 17 in the BOHNTLTAL
Exodus 17 in the BOICB
Exodus 17 in the BOILNTAP
Exodus 17 in the BOITCV
Exodus 17 in the BOKCV
Exodus 17 in the BOKCV2
Exodus 17 in the BOKHWOG
Exodus 17 in the BOKSSV
Exodus 17 in the BOLCB
Exodus 17 in the BOLCB2
Exodus 17 in the BOMCV
Exodus 17 in the BONAV
Exodus 17 in the BONCB
Exodus 17 in the BONLT
Exodus 17 in the BONUT2
Exodus 17 in the BOPLNT
Exodus 17 in the BOSCB
Exodus 17 in the BOSNC
Exodus 17 in the BOTLNT
Exodus 17 in the BOVCB
Exodus 17 in the BPBB
Exodus 17 in the BPH
Exodus 17 in the BSB
Exodus 17 in the CCB
Exodus 17 in the CUV
Exodus 17 in the CUVS
Exodus 17 in the DBT
Exodus 17 in the DGDNT
Exodus 17 in the DHNT
Exodus 17 in the DNT
Exodus 17 in the ELBE
Exodus 17 in the EMTV
Exodus 17 in the ESV
Exodus 17 in the FBV
Exodus 17 in the FEB
Exodus 17 in the GGMNT
Exodus 17 in the GNT
Exodus 17 in the HARY
Exodus 17 in the HNT
Exodus 17 in the IRVA
Exodus 17 in the IRVB
Exodus 17 in the IRVG
Exodus 17 in the IRVH
Exodus 17 in the IRVK
Exodus 17 in the IRVM
Exodus 17 in the IRVM2
Exodus 17 in the IRVO
Exodus 17 in the IRVP
Exodus 17 in the IRVT
Exodus 17 in the IRVT2
Exodus 17 in the IRVU
Exodus 17 in the ISVN
Exodus 17 in the JSNT
Exodus 17 in the KAPI
Exodus 17 in the KBT1ETNIK
Exodus 17 in the KBV
Exodus 17 in the KJV
Exodus 17 in the KNFD
Exodus 17 in the LBA
Exodus 17 in the LBLA
Exodus 17 in the LNT
Exodus 17 in the LSV
Exodus 17 in the MAAL
Exodus 17 in the MBV
Exodus 17 in the MBV2
Exodus 17 in the MHNT
Exodus 17 in the MKNFD
Exodus 17 in the MNG
Exodus 17 in the MNT
Exodus 17 in the MNT2
Exodus 17 in the MRS1T
Exodus 17 in the NAA
Exodus 17 in the NASB
Exodus 17 in the NBLA
Exodus 17 in the NBS
Exodus 17 in the NBVTP
Exodus 17 in the NET2
Exodus 17 in the NIV11
Exodus 17 in the NNT
Exodus 17 in the NNT2
Exodus 17 in the NNT3
Exodus 17 in the PDDPT
Exodus 17 in the PFNT
Exodus 17 in the RMNT
Exodus 17 in the SBIAS
Exodus 17 in the SBIBS
Exodus 17 in the SBIBS2
Exodus 17 in the SBICS
Exodus 17 in the SBIDS
Exodus 17 in the SBIGS
Exodus 17 in the SBIHS
Exodus 17 in the SBIIS
Exodus 17 in the SBIIS2
Exodus 17 in the SBIIS3
Exodus 17 in the SBIKS
Exodus 17 in the SBIKS2
Exodus 17 in the SBIMS
Exodus 17 in the SBIOS
Exodus 17 in the SBIPS
Exodus 17 in the SBISS
Exodus 17 in the SBITS
Exodus 17 in the SBITS2
Exodus 17 in the SBITS3
Exodus 17 in the SBITS4
Exodus 17 in the SBIUS
Exodus 17 in the SBIVS
Exodus 17 in the SBT
Exodus 17 in the SBT1E
Exodus 17 in the SCHL
Exodus 17 in the SNT
Exodus 17 in the SUSU
Exodus 17 in the SUSU2
Exodus 17 in the SYNO
Exodus 17 in the TBIAOTANT
Exodus 17 in the TBT1E
Exodus 17 in the TBT1E2
Exodus 17 in the TFTIP
Exodus 17 in the TFTU
Exodus 17 in the TGNTATF3T
Exodus 17 in the THAI
Exodus 17 in the TNFD
Exodus 17 in the TNT
Exodus 17 in the TNTIK
Exodus 17 in the TNTIL
Exodus 17 in the TNTIN
Exodus 17 in the TNTIP
Exodus 17 in the TNTIZ
Exodus 17 in the TOMA
Exodus 17 in the TTENT
Exodus 17 in the UBG
Exodus 17 in the UGV
Exodus 17 in the UGV2
Exodus 17 in the UGV3
Exodus 17 in the VBL
Exodus 17 in the VDCC
Exodus 17 in the YALU
Exodus 17 in the YAPE
Exodus 17 in the YBVTP
Exodus 17 in the ZBP