Ezekiel 28 (BOYCB)
1 Ọ̀rọ̀ OLÚWA tún tọ̀ mí wá wí pé: 2 “Ọmọ ènìyàn, sọ fún ọmọ-aládé Tire pé, ‘Báyìí ní OLÚWA Olódùmarè wí:“ ‘Nítorí tí ọkàn rẹ gbé sókè sí mi,ìwọ wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run;Èmi jókòó sí orí ìtẹ́ òrìṣà,ní àárín gbùngbùn Òkun.”Ṣùgbọ́n ènìyàn ni ọ́, kì i ṣe òrìṣà,bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ìwọ rò pé ìwọ gbọ́n bí Ọlọ́run. 3 Ìwọ gbọ́n ju Daniẹli lọ bí?Ṣé kò sí àṣírí kan tí ó pamọ́ fún ọ? 4 Pẹ̀lú ọgbọ́n àti ìmọ̀ rẹ,ìwọ tí jèrè ọrọ̀ fún ara rẹ,àti àkójọpọ̀ wúrà àti fàdákà,nínú àwọn ilé ìṣúra rẹ. 5 Nípa ọgbọ́n rẹ ńlá àti nípa òwò rẹ,ìwọ ti sọ ọrọ̀ rẹ di púpọ̀,àti nítorí ọrọ̀ rẹ di púpọ̀,ọkàn rẹ gbé sókè,nítorí ọrọ̀ rẹ. 6 “ ‘Nítorí náà èyí yìí ní OLÚWA Olódùmarè wí:“ ‘Nítorí pé ìwọ rò pé o gbọ́n,pé ìwọ gbọ́n bí Ọlọ́run. 7 Èmi yóò mú kí àwọn àjèjì dìde sí ọ,ẹlẹ́rù nínú àwọn orílẹ̀-èdè;wọn yóò yọ idà wọn sí ọ,ẹwà rẹ àti ọgbọ́n rẹ,wọn yóò sì ba dídán rẹ̀ jẹ́. 8 Wọn yóò mú ọ sọ̀kalẹ̀ wá sínú ihò,ìwọ yóò sì kú ikú gbígbóná,àwọn tí a pa ní àárín Òkun. 9 Ṣé ìwọ yóò wá wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run,”ní ojú àwọn tí ó pa ọ́?Ìwọ yóò jẹ́ ènìyàn, kì í ṣe Ọlọ́run,ní ọwọ́ àwọn ti yóò pa ọ́. 10 Ìwọ yóò kú ikú aláìkọlà,ní ọwọ́ àwọn àjèjì.Èmi ni ó ti sọ ọ́, ní OLÚWA Olódùmarè wí.’ ” 11 Ọ̀rọ̀ OLÚWA tún tọ̀ mí wá wí pé: 12 “Ọmọ ènìyàn, pohùnréré ẹkún sórí ọba Tire kí ó sì sọ fún un pé: ‘Èyí yìí ni ohun tí OLÚWA Olódùmarè wí:“ ‘Ìwọ jẹ́ àpẹẹrẹ ìjẹ́pípé náà,o kún fún ọgbọ́n,o sì pé ní ẹwà. 13 Ìwọ ti wà ní Edeni, ọgbà Ọlọ́run;onírúurú òkúta oníyebíye ni ìbora rẹ;sardiu, topasi àti diamọndi, berili, óníkìsì,àti jasperi, safire, emeradi,turikuose, àti karbunkili, àti wúrà,ìpilẹ̀ṣẹ̀ rẹ àti àwọn òkè rẹ ní a dà,láti ara wúrà,ní ọjọ́ tí á dá ọ ní a pèsè wọn. 14 A fi àmì òróró yàn ọ́ gẹ́gẹ́ bí olùtọ́jú kérúbù,torí èyí ni mo fi yàn ọ́.Ìwọ wà lórí òkè mímọ́ Ọlọ́run;ìwọ rìn ni àárín òkúta a mú bí iná. 15 Ìwọ pé ní ọ̀nà rẹ,láti ọjọ́ tí a ti dá ọ,títí a fi rí àìṣedéédéé ní inú rẹ. 16 Nípa ìtànkálẹ̀ òwò rẹ,ìwọ kún fún ìwà ipá;ìwọ sì dẹ́ṣẹ̀.Nítorí náà ni mo ṣe sọ ọ nù,bí ohun àìlọ́wọ̀ kúrò lórí òkè Ọlọ́run.Èmi sì pa ọ run,ìwọ kérúbù, tí ó bọ́ kúrò ní àárín òkúta a mú bí iná. 17 Ọkàn rẹ gbéraga,nítorí ẹwà rẹ.Ìwọ sì ba ọgbọ́n rẹ jẹ́,nítorí dídára rẹ.Nítorí náà mo le ọ sórí ayé;mo sọ ọ di awòojú níwájú àwọn ọba. 18 Nípa ẹ̀ṣẹ̀ púpọ̀ rẹ àti òwò àìṣòótọ́ rẹ,ìwọ ti ba àwọn ibi mímọ́ rẹ jẹ́.Nítorí náà mo mú kí iná jáde wá,láti inú rẹ, yóò sì jó ọ run,èmi yóò sì sọ ọ́ di eérú lórí ilẹ̀,lójú gbogbo àwọn tí ó ń wò ọ́. 19 Gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó mọ̀ ọ́n,ní ẹnu ń yà sí ọ;ìwọ yóò sì jẹ́ ẹ̀rù,ìwọ kì yóò sì ṣí mọ́ láéláé.’ ” 20 Ọ̀rọ̀ OLÚWA tún tọ̀ mí wá wí pé: 21 “Ọmọ ènìyàn, kọ ojú sí Sidoni; kí o sì sọtẹ́lẹ̀ sí i, 22 kí ó sì wí pé, ‘Báyìí ni OLÚWA Olódùmarè wí:“ ‘Èmi lòdì sí ọ, ìwọ Sidoni,a ó sì ṣe mí lógo láàrín rẹ.Wọn yóò mọ̀ pé èmi ní OLÚWA,nígbà tí mo bá mú ìdájọ́ mi ṣẹ nínú rẹ,tí a sì yá mí sí mímọ́ nínú rẹ. 23 Èmi yóò sì rán àjàkálẹ̀-ààrùn sínú rẹ,èmi yóò sì mú kí ẹ̀jẹ̀ sàn ní ìgboro rẹ,ẹni ti á pa yóò ṣubú ní àárín rẹ,pẹ̀lú idà lára rẹ ní gbogbo ẹ̀gbẹ́,nígbà náà wọn yóò mọ̀ wí pé èmi ni OLÚWA. 24 “ ‘Kì yóò sì ṣí ẹ̀gún tí ń gun ni ní ilẹ̀ Israẹli mọ́, tàbí ẹ̀gún bíbani nínú jẹ́ ti gbogbo àwọn tí wọn wà ní àyíká wọn, tí wọ́n sì ń fi ojú yẹpẹrẹ wò wọ́n, nígbà náà ni wọn yóò mọ́ wí pé èmi ni OLÚWA Olódùmarè. 25 “ ‘Èyí yìí ní OLÚWA Olódùmarè wí: Nígbà tí èmi yóò bá sa àwọn ènìyàn Israẹli jọ kúrò ní gbogbo orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti fọ́nká sí, tí a ó sì yà mí sí mímọ́ láàrín wọn lójú àwọn aláìkọlà. Nígbà náà ni wọn yóò gbé ní ilẹ̀ àwọn tìkálára wọn, èyí tí mo fún ìránṣẹ́ mi Jakọbu. 26 Wọn yóò sì máa gbé ní inú rẹ̀ ní àìléwu, wọn yóò sì kọ́lé, wọn yóò sì gbin ọgbà àjàrà; nítòótọ́ wọn yóò wà ní ìbàlẹ̀ àyà, nígbà tí èmi bá ti mú ìdájọ́ mi ṣẹ̀ sí ara àwọn tí ń ṣátá wọn ní gbogbo àyíká wọn. Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé, Èmi ni OLÚWA Ọlọ́run wọn.’ ”
In Other Versions
Ezekiel 28 in the ANGEFD
Ezekiel 28 in the ANTPNG2D
Ezekiel 28 in the AS21
Ezekiel 28 in the BAGH
Ezekiel 28 in the BBPNG
Ezekiel 28 in the BBT1E
Ezekiel 28 in the BDS
Ezekiel 28 in the BEV
Ezekiel 28 in the BHAD
Ezekiel 28 in the BIB
Ezekiel 28 in the BLPT
Ezekiel 28 in the BNT
Ezekiel 28 in the BNTABOOT
Ezekiel 28 in the BNTLV
Ezekiel 28 in the BOATCB
Ezekiel 28 in the BOATCB2
Ezekiel 28 in the BOBCV
Ezekiel 28 in the BOCNT
Ezekiel 28 in the BOECS
Ezekiel 28 in the BOGWICC
Ezekiel 28 in the BOHCB
Ezekiel 28 in the BOHCV
Ezekiel 28 in the BOHLNT
Ezekiel 28 in the BOHNTLTAL
Ezekiel 28 in the BOICB
Ezekiel 28 in the BOILNTAP
Ezekiel 28 in the BOITCV
Ezekiel 28 in the BOKCV
Ezekiel 28 in the BOKCV2
Ezekiel 28 in the BOKHWOG
Ezekiel 28 in the BOKSSV
Ezekiel 28 in the BOLCB
Ezekiel 28 in the BOLCB2
Ezekiel 28 in the BOMCV
Ezekiel 28 in the BONAV
Ezekiel 28 in the BONCB
Ezekiel 28 in the BONLT
Ezekiel 28 in the BONUT2
Ezekiel 28 in the BOPLNT
Ezekiel 28 in the BOSCB
Ezekiel 28 in the BOSNC
Ezekiel 28 in the BOTLNT
Ezekiel 28 in the BOVCB
Ezekiel 28 in the BPBB
Ezekiel 28 in the BPH
Ezekiel 28 in the BSB
Ezekiel 28 in the CCB
Ezekiel 28 in the CUV
Ezekiel 28 in the CUVS
Ezekiel 28 in the DBT
Ezekiel 28 in the DGDNT
Ezekiel 28 in the DHNT
Ezekiel 28 in the DNT
Ezekiel 28 in the ELBE
Ezekiel 28 in the EMTV
Ezekiel 28 in the ESV
Ezekiel 28 in the FBV
Ezekiel 28 in the FEB
Ezekiel 28 in the GGMNT
Ezekiel 28 in the GNT
Ezekiel 28 in the HARY
Ezekiel 28 in the HNT
Ezekiel 28 in the IRVA
Ezekiel 28 in the IRVB
Ezekiel 28 in the IRVG
Ezekiel 28 in the IRVH
Ezekiel 28 in the IRVK
Ezekiel 28 in the IRVM
Ezekiel 28 in the IRVM2
Ezekiel 28 in the IRVO
Ezekiel 28 in the IRVP
Ezekiel 28 in the IRVT
Ezekiel 28 in the IRVT2
Ezekiel 28 in the IRVU
Ezekiel 28 in the ISVN
Ezekiel 28 in the JSNT
Ezekiel 28 in the KAPI
Ezekiel 28 in the KBT1ETNIK
Ezekiel 28 in the KBV
Ezekiel 28 in the KJV
Ezekiel 28 in the KNFD
Ezekiel 28 in the LBA
Ezekiel 28 in the LBLA
Ezekiel 28 in the LNT
Ezekiel 28 in the LSV
Ezekiel 28 in the MAAL
Ezekiel 28 in the MBV
Ezekiel 28 in the MBV2
Ezekiel 28 in the MHNT
Ezekiel 28 in the MKNFD
Ezekiel 28 in the MNG
Ezekiel 28 in the MNT
Ezekiel 28 in the MNT2
Ezekiel 28 in the MRS1T
Ezekiel 28 in the NAA
Ezekiel 28 in the NASB
Ezekiel 28 in the NBLA
Ezekiel 28 in the NBS
Ezekiel 28 in the NBVTP
Ezekiel 28 in the NET2
Ezekiel 28 in the NIV11
Ezekiel 28 in the NNT
Ezekiel 28 in the NNT2
Ezekiel 28 in the NNT3
Ezekiel 28 in the PDDPT
Ezekiel 28 in the PFNT
Ezekiel 28 in the RMNT
Ezekiel 28 in the SBIAS
Ezekiel 28 in the SBIBS
Ezekiel 28 in the SBIBS2
Ezekiel 28 in the SBICS
Ezekiel 28 in the SBIDS
Ezekiel 28 in the SBIGS
Ezekiel 28 in the SBIHS
Ezekiel 28 in the SBIIS
Ezekiel 28 in the SBIIS2
Ezekiel 28 in the SBIIS3
Ezekiel 28 in the SBIKS
Ezekiel 28 in the SBIKS2
Ezekiel 28 in the SBIMS
Ezekiel 28 in the SBIOS
Ezekiel 28 in the SBIPS
Ezekiel 28 in the SBISS
Ezekiel 28 in the SBITS
Ezekiel 28 in the SBITS2
Ezekiel 28 in the SBITS3
Ezekiel 28 in the SBITS4
Ezekiel 28 in the SBIUS
Ezekiel 28 in the SBIVS
Ezekiel 28 in the SBT
Ezekiel 28 in the SBT1E
Ezekiel 28 in the SCHL
Ezekiel 28 in the SNT
Ezekiel 28 in the SUSU
Ezekiel 28 in the SUSU2
Ezekiel 28 in the SYNO
Ezekiel 28 in the TBIAOTANT
Ezekiel 28 in the TBT1E
Ezekiel 28 in the TBT1E2
Ezekiel 28 in the TFTIP
Ezekiel 28 in the TFTU
Ezekiel 28 in the TGNTATF3T
Ezekiel 28 in the THAI
Ezekiel 28 in the TNFD
Ezekiel 28 in the TNT
Ezekiel 28 in the TNTIK
Ezekiel 28 in the TNTIL
Ezekiel 28 in the TNTIN
Ezekiel 28 in the TNTIP
Ezekiel 28 in the TNTIZ
Ezekiel 28 in the TOMA
Ezekiel 28 in the TTENT
Ezekiel 28 in the UBG
Ezekiel 28 in the UGV
Ezekiel 28 in the UGV2
Ezekiel 28 in the UGV3
Ezekiel 28 in the VBL
Ezekiel 28 in the VDCC
Ezekiel 28 in the YALU
Ezekiel 28 in the YAPE
Ezekiel 28 in the YBVTP
Ezekiel 28 in the ZBP