Genesis 15 (BOYCB)

1 Lẹ́yìn èyí, ọ̀rọ̀ OLÚWA tọ Abramu wá lójú ìran pé,“Abramu má ṣe bẹ̀rù.Èmi ni ààbò rẹ,Èmi sì ni èrè ńlá rẹ.” 2 Ṣùgbọ́n Abramu wí pé, “OLÚWA Olódùmarè, kí ni ìwọ yóò fi fún mi níwọ̀n ìgbà tí èmi kò bímọ, Elieseri ará Damasku ni yóò sì jogún mi,” 3 Abramu sì tún tẹ̀síwájú pé, “Ìwọ kò fún mi ní ọmọ, nítorí náà ẹrú nínú ilé mi sì ni yóò jẹ́ àrólé mi.” 4 Ọ̀rọ̀ OLÚWA sì tún tọ̀ ọ́ wá pé, “Ọkùnrin yìí kọ́ ni yóò jẹ́ àrólé rẹ bí kò ṣe ọmọ tí ìwọ bí fúnra rẹ̀ ni yóò jẹ́ àrólé rẹ.” 5 OLÚWA sì mú Abramu jáde sí ìta ó sì wí fún un pé, “Gbé ojú sókè sí ọ̀run kí o sì ka àwọn ìràwọ̀ bí ó bá ṣe pé ìwọ le è kà wọ́n.” Ó sì wí fun un pé, “Nítorí náà, báyìí ni irú-ọmọ rẹ yóò rí.” 6 Abramu gba OLÚWA gbọ́, a sì kà á sí òdodo fún un. 7 Ó sì tún wí fún un pé, “Èmi ni OLÚWA tí ó mú ọ jáde láti Uri ti Kaldea láti fún ọ ní ilẹ̀ yìí láti jogún.” 8 Ṣùgbọ́n Abramu wí pé, “OLÚWA Olódùmarè, báwo ni mo ṣe lè mọ̀ pé ilẹ̀ náà yóò jẹ́ ohun ìní mi?” 9 Nítorí náà, OLÚWA wí fún un pé, “Mú abo màlúù, ewúrẹ́ àti àgbò ọlọ́dún mẹ́ta mẹ́ta wá, àti àdàbà kan àti ọmọ ẹyẹlé kan.” 10 Abramu sì mú gbogbo nǹkan wọ̀nyí wá, ó sì là wọ́n sí méjì méjì, ó sì fi ẹ̀là èkínní kọjú sí èkejì, ṣùgbọ́n kò la àwọn ẹyẹ ní tiwọn. 11 Àwọn ẹyẹ igún sì ń wá sórí òkú ẹran náà, Abramu sì ń lé wọn. 12 Bí oòrùn ti ń wọ̀, Abramu sùn lọ fọnfọn, òkùnkùn biribiri tí ó kún fún ẹ̀rù sì bò ó. 13 Nígbà náà ni OLÚWA wí fún Abramu pé, “Mọ èyí dájú pé, irú-ọmọ rẹ yóò ṣe àtìpó ní ilẹ̀ àjèjì, wọn ó sì sọ wọn di ẹrú, wọn ó sì pọ́n wọn lójú fún irinwó (400) ọdún. 14 Ṣùgbọ́n orílẹ̀-èdè náà tí wọn yóò máa sìn, ni èmi ó dá lẹ́jọ́, lẹ́yìn náà ni wọn ó sì jáde pẹ̀lú ọrọ̀ púpọ̀. 15 Ṣùgbọ́n ìwọ yóò tọ àwọn baba rẹ lọ ni àlàáfíà, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ yóò sì di arúgbó kí a tó gbé ọ sin. 16 Ní ìran kẹrin àwọn ìran rẹ yóò padà wá sí ibi. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ará Amori kò ì tí ì kún òsùwọ̀n.” 17 Nígbà tí oòrùn wọ̀ tí ilẹ̀ sì ṣú, ìkòkò iná tí ń ṣèéfín àti ọwọ́ iná sì ń kọjá láàrín ẹ̀là ẹran náà. 18 Ní ọjọ́ náà gan an ni OLÚWA dá májẹ̀mú pẹ̀lú Abramu, ó sì wí pé, “Àwọn ìran rẹ ni èmi yóò fi ilẹ̀ yìí fún, láti odò Ejibiti dé odò ńlá Eufurate: 19 ilẹ̀ àwọn ará Keni, àti ti ará Kenissiti, àti ará Kadmoni, 20 àti ti ará Hiti, àti ti ará Peresi, àti ti ará Refaimu. 21 Àti ti ará Amori, àti ti ará Kenaani, àti ti ará Girgaṣi àti ti ará Jebusi.”

In Other Versions

Genesis 15 in the ANGEFD

Genesis 15 in the ANTPNG2D

Genesis 15 in the AS21

Genesis 15 in the BAGH

Genesis 15 in the BBPNG

Genesis 15 in the BBT1E

Genesis 15 in the BDS

Genesis 15 in the BEV

Genesis 15 in the BHAD

Genesis 15 in the BIB

Genesis 15 in the BLPT

Genesis 15 in the BNT

Genesis 15 in the BNTABOOT

Genesis 15 in the BNTLV

Genesis 15 in the BOATCB

Genesis 15 in the BOATCB2

Genesis 15 in the BOBCV

Genesis 15 in the BOCNT

Genesis 15 in the BOECS

Genesis 15 in the BOGWICC

Genesis 15 in the BOHCB

Genesis 15 in the BOHCV

Genesis 15 in the BOHLNT

Genesis 15 in the BOHNTLTAL

Genesis 15 in the BOICB

Genesis 15 in the BOILNTAP

Genesis 15 in the BOITCV

Genesis 15 in the BOKCV

Genesis 15 in the BOKCV2

Genesis 15 in the BOKHWOG

Genesis 15 in the BOKSSV

Genesis 15 in the BOLCB

Genesis 15 in the BOLCB2

Genesis 15 in the BOMCV

Genesis 15 in the BONAV

Genesis 15 in the BONCB

Genesis 15 in the BONLT

Genesis 15 in the BONUT2

Genesis 15 in the BOPLNT

Genesis 15 in the BOSCB

Genesis 15 in the BOSNC

Genesis 15 in the BOTLNT

Genesis 15 in the BOVCB

Genesis 15 in the BPBB

Genesis 15 in the BPH

Genesis 15 in the BSB

Genesis 15 in the CCB

Genesis 15 in the CUV

Genesis 15 in the CUVS

Genesis 15 in the DBT

Genesis 15 in the DGDNT

Genesis 15 in the DHNT

Genesis 15 in the DNT

Genesis 15 in the ELBE

Genesis 15 in the EMTV

Genesis 15 in the ESV

Genesis 15 in the FBV

Genesis 15 in the FEB

Genesis 15 in the GGMNT

Genesis 15 in the GNT

Genesis 15 in the HARY

Genesis 15 in the HNT

Genesis 15 in the IRVA

Genesis 15 in the IRVB

Genesis 15 in the IRVG

Genesis 15 in the IRVH

Genesis 15 in the IRVK

Genesis 15 in the IRVM

Genesis 15 in the IRVM2

Genesis 15 in the IRVO

Genesis 15 in the IRVP

Genesis 15 in the IRVT

Genesis 15 in the IRVT2

Genesis 15 in the IRVU

Genesis 15 in the ISVN

Genesis 15 in the JSNT

Genesis 15 in the KAPI

Genesis 15 in the KBT1ETNIK

Genesis 15 in the KBV

Genesis 15 in the KJV

Genesis 15 in the KNFD

Genesis 15 in the LBA

Genesis 15 in the LBLA

Genesis 15 in the LNT

Genesis 15 in the LSV

Genesis 15 in the MAAL

Genesis 15 in the MBV

Genesis 15 in the MBV2

Genesis 15 in the MHNT

Genesis 15 in the MKNFD

Genesis 15 in the MNG

Genesis 15 in the MNT

Genesis 15 in the MNT2

Genesis 15 in the MRS1T

Genesis 15 in the NAA

Genesis 15 in the NASB

Genesis 15 in the NBLA

Genesis 15 in the NBS

Genesis 15 in the NBVTP

Genesis 15 in the NET2

Genesis 15 in the NIV11

Genesis 15 in the NNT

Genesis 15 in the NNT2

Genesis 15 in the NNT3

Genesis 15 in the PDDPT

Genesis 15 in the PFNT

Genesis 15 in the RMNT

Genesis 15 in the SBIAS

Genesis 15 in the SBIBS

Genesis 15 in the SBIBS2

Genesis 15 in the SBICS

Genesis 15 in the SBIDS

Genesis 15 in the SBIGS

Genesis 15 in the SBIHS

Genesis 15 in the SBIIS

Genesis 15 in the SBIIS2

Genesis 15 in the SBIIS3

Genesis 15 in the SBIKS

Genesis 15 in the SBIKS2

Genesis 15 in the SBIMS

Genesis 15 in the SBIOS

Genesis 15 in the SBIPS

Genesis 15 in the SBISS

Genesis 15 in the SBITS

Genesis 15 in the SBITS2

Genesis 15 in the SBITS3

Genesis 15 in the SBITS4

Genesis 15 in the SBIUS

Genesis 15 in the SBIVS

Genesis 15 in the SBT

Genesis 15 in the SBT1E

Genesis 15 in the SCHL

Genesis 15 in the SNT

Genesis 15 in the SUSU

Genesis 15 in the SUSU2

Genesis 15 in the SYNO

Genesis 15 in the TBIAOTANT

Genesis 15 in the TBT1E

Genesis 15 in the TBT1E2

Genesis 15 in the TFTIP

Genesis 15 in the TFTU

Genesis 15 in the TGNTATF3T

Genesis 15 in the THAI

Genesis 15 in the TNFD

Genesis 15 in the TNT

Genesis 15 in the TNTIK

Genesis 15 in the TNTIL

Genesis 15 in the TNTIN

Genesis 15 in the TNTIP

Genesis 15 in the TNTIZ

Genesis 15 in the TOMA

Genesis 15 in the TTENT

Genesis 15 in the UBG

Genesis 15 in the UGV

Genesis 15 in the UGV2

Genesis 15 in the UGV3

Genesis 15 in the VBL

Genesis 15 in the VDCC

Genesis 15 in the YALU

Genesis 15 in the YAPE

Genesis 15 in the YBVTP

Genesis 15 in the ZBP