Genesis 20 (BOYCB)

1 Abrahamu sì kó kúrò níbẹ̀ lọ sí ìhà gúúsù ó sì ń gbé ní agbede-méjì Kadeṣi àti Ṣuri; ó sì gbé ní ìlú Gerari fún ìgbà díẹ̀. 2 Abrahamu sì sọ ní ti Sara aya rẹ̀ níbẹ̀ pé, “Arábìnrin mi ni.” Abimeleki ọba Gerari sì ránṣẹ́ mú Sara wá sí ààfin rẹ̀. 3 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run tọ Abimeleki wá ní ojú àlá lọ́jọ́ kan, ó sì wí fún un pé, “Kíyèsi, kò sí ohun tí o fi sàn ju òkú lọ, nítorí obìnrin tí ìwọ mú sọ́dọ̀ n nì, aya ẹni kan ní íṣe.” 4 Ṣùgbọ́n Abimeleki kò tí ìbá obìnrin náà lòpọ̀, nítorí náà ó wí pé, “Olúwa ìwọ yóò run orílẹ̀-èdè aláìlẹ́bi bí? 5 Ǹjẹ́ òun kò sọ fún mi pé, ‘Arábìnrin mi ni,’ obìnrin náà pẹ̀lú sì sọ pé, ‘Arákùnrin mí ni’? Ní òtítọ́ pẹ̀lú ọkàn mímọ́ àti ọwọ́ mímọ́, ni mo ṣe èyí.” 6 Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún un nínú àlá náà pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, mo mọ̀ pé pẹ̀lú òtítọ́ inú ni ìwọ ṣe èyí, èyí ni mo fi pa ọ́ mọ́ tí ń kò jẹ́ kí o ṣẹ̀ sí mi. Ìdí nìyí tí n kò fi jẹ́ kí o ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú obìnrin náà. 7 Nísinsin yìí, dá aya ọkùnrin náà padà, nítorí pé wòlíì ni, yóò sì gbàdúrà fún ọ, ìwọ yóò sì yè. Ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá dá a padà, mọ̀ dájú pé ìwọ àti gbogbo ẹni tí í ṣe tìrẹ yóò kú.” 8 Ní òwúrọ̀ kùtùkùtù ọjọ́ kejì, Abimeleki pe gbogbo àwọn ìjòyè rẹ̀. Nígbà tí ó sì sọ gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún wọn, ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi. 9 Nígbà náà ni Abimeleki pe Abrahamu ó sì wí fún un pé, “Èwo ni èyí tí ìwọ ṣe sí wa yìí? Ẹ̀ṣẹ̀ wo ni mo ṣẹ̀ ọ́ tí ìwọ fi mú ìdálẹ́bi ńlá wá sí orí èmi àti ìjọba mi? Kò yẹ kí ìwọ hu irú ìwà yìí sí mi.” 10 Abimeleki sì bi Abrahamu pé, “Kín ló dé tí ìwọ fi ṣe èyí?” 11 Abrahamu sì dáhùn pé, “Mo ṣe èyí nítorí mo rò nínú ara mi pé, ẹ̀yin tí ẹ wà níhìn-ín, ẹ kò bẹ̀rù Ọlọ́run, pé, ẹ sì le pa mí nítorí aya mi. 12 Yàtọ̀ fún ìyẹn, òtítọ́ ni pé arábìnrin mi ni. Ọmọ baba kan ni wá, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, a kì í ṣe ọmọ ìyá kan. Mo sì fẹ́ ẹ ní aya. 13 Nígbà tí Ọlọ́run sì mú mi rìn kiri kúrò ní ilé baba mi, mo wí fún un pé, ‘Èyí ni ọ̀nà tí ó lè gbà fihàn pé ó fẹ́ràn mi. Gbogbo ibi tí a bá dé máa sọ pé, “Arákùnrin rẹ ni mí.” ’ ” 14 Nígbà náà ni Abimeleki mú àgùntàn àti màlúù wá, àti ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin, ó sì kó wọn fún Abrahamu, ó sì dá Sara aya rẹ̀ padà fún un. 15 Abimeleki sì tún wí fún un pé, “Gbogbo ilẹ̀ mí nìyí níwájú rẹ, máa gbé ní ibikíbi tí o fẹ́ níbẹ̀.” 16 Abimeleki sì wí fún Sara pé, “Mo fi ẹgbẹ̀rún (1,000) owó ẹyọ fàdákà fún arákùnrin rẹ. Èyí ni owó ìtánràn ẹ̀ṣẹ̀ mi sí ọ níwájú gbogbo ẹni tí ó wà pẹ̀lú rẹ àti pé, a dá ọ láre pátápátá.” 17 Nígbà náà, Abrahamu gbàdúrà sí Ọlọ́run, Ọlọ́run sì wo Abimeleki àti aya rẹ̀ àti àwọn ẹrúbìnrin rẹ̀ sàn. Wọ́n sì tún ń bímọ, 18 nítorí OLÚWA ti sé gbogbo ará ilé Abimeleki nínú nítorí Sara aya Abrahamu.

In Other Versions

Genesis 20 in the ANGEFD

Genesis 20 in the ANTPNG2D

Genesis 20 in the AS21

Genesis 20 in the BAGH

Genesis 20 in the BBPNG

Genesis 20 in the BBT1E

Genesis 20 in the BDS

Genesis 20 in the BEV

Genesis 20 in the BHAD

Genesis 20 in the BIB

Genesis 20 in the BLPT

Genesis 20 in the BNT

Genesis 20 in the BNTABOOT

Genesis 20 in the BNTLV

Genesis 20 in the BOATCB

Genesis 20 in the BOATCB2

Genesis 20 in the BOBCV

Genesis 20 in the BOCNT

Genesis 20 in the BOECS

Genesis 20 in the BOGWICC

Genesis 20 in the BOHCB

Genesis 20 in the BOHCV

Genesis 20 in the BOHLNT

Genesis 20 in the BOHNTLTAL

Genesis 20 in the BOICB

Genesis 20 in the BOILNTAP

Genesis 20 in the BOITCV

Genesis 20 in the BOKCV

Genesis 20 in the BOKCV2

Genesis 20 in the BOKHWOG

Genesis 20 in the BOKSSV

Genesis 20 in the BOLCB

Genesis 20 in the BOLCB2

Genesis 20 in the BOMCV

Genesis 20 in the BONAV

Genesis 20 in the BONCB

Genesis 20 in the BONLT

Genesis 20 in the BONUT2

Genesis 20 in the BOPLNT

Genesis 20 in the BOSCB

Genesis 20 in the BOSNC

Genesis 20 in the BOTLNT

Genesis 20 in the BOVCB

Genesis 20 in the BPBB

Genesis 20 in the BPH

Genesis 20 in the BSB

Genesis 20 in the CCB

Genesis 20 in the CUV

Genesis 20 in the CUVS

Genesis 20 in the DBT

Genesis 20 in the DGDNT

Genesis 20 in the DHNT

Genesis 20 in the DNT

Genesis 20 in the ELBE

Genesis 20 in the EMTV

Genesis 20 in the ESV

Genesis 20 in the FBV

Genesis 20 in the FEB

Genesis 20 in the GGMNT

Genesis 20 in the GNT

Genesis 20 in the HARY

Genesis 20 in the HNT

Genesis 20 in the IRVA

Genesis 20 in the IRVB

Genesis 20 in the IRVG

Genesis 20 in the IRVH

Genesis 20 in the IRVK

Genesis 20 in the IRVM

Genesis 20 in the IRVM2

Genesis 20 in the IRVO

Genesis 20 in the IRVP

Genesis 20 in the IRVT

Genesis 20 in the IRVT2

Genesis 20 in the IRVU

Genesis 20 in the ISVN

Genesis 20 in the JSNT

Genesis 20 in the KAPI

Genesis 20 in the KBT1ETNIK

Genesis 20 in the KBV

Genesis 20 in the KJV

Genesis 20 in the KNFD

Genesis 20 in the LBA

Genesis 20 in the LBLA

Genesis 20 in the LNT

Genesis 20 in the LSV

Genesis 20 in the MAAL

Genesis 20 in the MBV

Genesis 20 in the MBV2

Genesis 20 in the MHNT

Genesis 20 in the MKNFD

Genesis 20 in the MNG

Genesis 20 in the MNT

Genesis 20 in the MNT2

Genesis 20 in the MRS1T

Genesis 20 in the NAA

Genesis 20 in the NASB

Genesis 20 in the NBLA

Genesis 20 in the NBS

Genesis 20 in the NBVTP

Genesis 20 in the NET2

Genesis 20 in the NIV11

Genesis 20 in the NNT

Genesis 20 in the NNT2

Genesis 20 in the NNT3

Genesis 20 in the PDDPT

Genesis 20 in the PFNT

Genesis 20 in the RMNT

Genesis 20 in the SBIAS

Genesis 20 in the SBIBS

Genesis 20 in the SBIBS2

Genesis 20 in the SBICS

Genesis 20 in the SBIDS

Genesis 20 in the SBIGS

Genesis 20 in the SBIHS

Genesis 20 in the SBIIS

Genesis 20 in the SBIIS2

Genesis 20 in the SBIIS3

Genesis 20 in the SBIKS

Genesis 20 in the SBIKS2

Genesis 20 in the SBIMS

Genesis 20 in the SBIOS

Genesis 20 in the SBIPS

Genesis 20 in the SBISS

Genesis 20 in the SBITS

Genesis 20 in the SBITS2

Genesis 20 in the SBITS3

Genesis 20 in the SBITS4

Genesis 20 in the SBIUS

Genesis 20 in the SBIVS

Genesis 20 in the SBT

Genesis 20 in the SBT1E

Genesis 20 in the SCHL

Genesis 20 in the SNT

Genesis 20 in the SUSU

Genesis 20 in the SUSU2

Genesis 20 in the SYNO

Genesis 20 in the TBIAOTANT

Genesis 20 in the TBT1E

Genesis 20 in the TBT1E2

Genesis 20 in the TFTIP

Genesis 20 in the TFTU

Genesis 20 in the TGNTATF3T

Genesis 20 in the THAI

Genesis 20 in the TNFD

Genesis 20 in the TNT

Genesis 20 in the TNTIK

Genesis 20 in the TNTIL

Genesis 20 in the TNTIN

Genesis 20 in the TNTIP

Genesis 20 in the TNTIZ

Genesis 20 in the TOMA

Genesis 20 in the TTENT

Genesis 20 in the UBG

Genesis 20 in the UGV

Genesis 20 in the UGV2

Genesis 20 in the UGV3

Genesis 20 in the VBL

Genesis 20 in the VDCC

Genesis 20 in the YALU

Genesis 20 in the YAPE

Genesis 20 in the YBVTP

Genesis 20 in the ZBP