Genesis 44 (BOYCB)

1 Nígbà náà ni Josẹfu pàṣẹ fún ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Di oúnjẹ kún inú àpò àwọn ọkùnrin náà tó ìwọ̀n èyí tí wọ́n le rù, kí o sì mú owó olúkúlùkù àwọn ọkùnrin náà padà sí ẹnu àpò rẹ̀. 2 Nígbà náà ni kí o mú kọ́ọ̀bù idẹ mi sí ẹnu àpò èyí tí ó jẹ́ àbíkẹ́yìn nínú wọn pẹ̀lú owó tí ó fi ra ọkà,” ó sì ṣe bí Josẹfu ti sọ. 3 Bí ilẹ̀ ti ń mọ́, wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò wọn padà lọ pẹ̀lú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn. 4 Wọn kò tí ì rìn jìnnà sí ìlú náà tí Josẹfu fi wí fún ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Lépa àwọn ọkùnrin náà, nígbà tí o bá sì bá wọn, kí o wí pé, ‘Èéṣe ti ẹ fi búburú san rere? 5 Èyí ha kọ́ ni kọ́ọ̀bù tí olúwa mi ń lò fún ohun mímu tí ó sì tún ń fi í ṣe àyẹ̀wò? Ohun tí ẹ ṣe yìí burú púpọ̀.’ ” 6 Nígbà tí ó sì bá wọn, o sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún wọn. 7 Ṣùgbọ́n wọ́n dá a lóhùn pé, “Kí ló dé tí olúwa mi sọ irú nǹkan wọ̀nyí? Ká má rí i! Àwọn ìránṣẹ́ rẹ kò le ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀! 8 A tilẹ̀ mú owó tí a rí lẹ́nu àpò wa padà tọ̀ ọ́ wá láti ilẹ̀ Kenaani. Nítorí náà èéṣe tí àwa yóò fi jí wúrà tàbí idẹ ní ilé olúwa à rẹ? 9 Bí a bá rí i lọ́wọ́ èyíkéyìí nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ, kíkú ni yóò kú, àwọn tí ó kù yóò sì di ẹrú fún olúwa à rẹ.” 10 Ó wí pé, “Ó dára, kí ó rí bí ẹ ti ṣe sọ. Ẹnikẹ́ni tí mo bá rí i lọ́wọ́ rẹ̀ yóò di ẹrú mi. Ẹ̀yin tí ó kù yóò sì wà láìlẹ́bi.” 11 Olúkúlùkù wọn yára sọ àpò rẹ̀ kalẹ̀, wọ́n sì tú u. 12 Nígbà náà ni ìránṣẹ́ náà bẹ̀rẹ̀ sí ní í wá a, bẹ̀rẹ̀ láti orí ẹ̀gbọ́n títí lọ sórí àbúrò pátápátá. Ó sì rí kọ́ọ̀bù náà nínú àpò ti Benjamini. 13 Nígbà tí wọ́n rí èyí, wọ́n fa aṣọ wọn ya, wọ́n sì banújẹ́ gidigidi, wọn tún ẹrù wọn dì sórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, wọ́n sì padà sí inú ìlú. 14 Josẹfu sì wà nínú ilé nígbà tí Juda àti àwọn arákùnrin rẹ̀ wọlé wá. Gbogbo wọn sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀. 15 Josẹfu wí fún wọn pé, “Èwo ni èyí tí ẹ ṣe yìí? Ṣe ẹ kò mọ pé, ènìyàn bí èmi le è rí ìdí nǹkan nípa ṣíṣe àyẹ̀wò?” 16 Juda dáhùn pé, “Kí ni à bá sọ fún olúwa mi? Báwo ni a ṣe lè wẹ ara wa mọ́? Ọlọ́run ti tú àṣírí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, a ti di ẹrú olúwa à mi báyìí àwa fúnra wa àti ẹni náà tí a rí kọ́ọ̀bù lọ́wọ́ rẹ̀.” 17 Ṣùgbọ́n Josẹfu dáhùn pé, “Ká má rí i pé mo ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀! Ẹni tí a bá kọ́ọ̀bù mi lọ́wọ́ rẹ̀ nìkan ni yóò di ẹrú mi, ẹ̀yin tí ó kù, ẹ máa lọ sọ́dọ̀ baba yín ní àlàáfíà.” 18 Nígbà náà ni Juda súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé, “Jọ̀wọ́ olúwa mi, jẹ́ kí ìránṣẹ́ rẹ kí ó sọ ọ̀rọ̀ kan fún olúwa mi, má ṣe bínú sí ìránṣẹ́ rẹ bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ìwọ pẹ̀lú láṣẹ bí i ti Farao. 19 Olúwa mi béèrè lọ́wọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, ‘Ǹjẹ́ ó ní baba tàbí arákùnrin?’ 20 Àwa sì wí fún olúwa mi pé, ‘A ni baba tí ó ti darúgbó, ọmọkùnrin kan sì wà pẹ̀lú tí a bí fún un ní ọjọ́ ogbó rẹ̀. Ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ti kú, òun nìkan sì ni ó kù nínú àwọn ọmọ ìyá rẹ̀, baba rẹ̀ sì fẹ́ràn án rẹ̀.’ 21 “Nígbà náà ni ó sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, ‘Ẹ mu un tọ̀ mí wá kí n le fojú ara mi rí i.’ 22 A sì sọ fún olúwa à mi pé, ‘Ọmọkùnrin náà kò le è fi baba rẹ̀ sílẹ̀, bí ó bá dán an wò baba rẹ̀ yóò kú.’ 23 Ṣùgbọ́n ìwọ wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, ‘Ẹ má ṣe padà tọ̀ mí wá àyàfi bí àbíkẹ́yìn yín bá bá yín wá.’ 24 Nígbà tí a padà lọ sọ́dọ̀ baba wa, tí í ṣe ìránṣẹ́ rẹ, a sọ ohun tí olúwa à mi wí fún un. 25 “Nígbà náà ni baba wa wí pé, ‘Ẹ padà lọ láti lọ ra oúnjẹ díẹ̀ wá.’ 26 Ṣùgbọ́n a wí pe, ‘Àwa kò le è padà lọ, àyàfi bí àbúrò wa pátápátá yóò bá bá wa lọ. A kò le è rí ojú ọkùnrin náà àyàfi tí àbúrò wa bá lọ pẹ̀lú wa.’ 27 “Baba mi, ìránṣẹ́ rẹ wí fún wa pé, ‘Ẹ mọ̀ pé ìyàwó mi bí ọmọkùnrin méjì fún mi. 28 Ọ̀kan nínú wọn lọ kúrò lọ́dọ̀ mi, mo sì wí pé, “Dájúdájú a ti fà á ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ.” N kò sì tí ì ri láti ọjọ́ náà. 29 Tí ẹ bá tún mú èyí lọ, kúrò lọ́dọ̀ mi, tí ohunkóhun bá ṣe é, ìbànújẹ́ ni ẹ ó fi mú ewú orí mi lọ sí ipò òkú.’ 30 “Nítorí náà, bí a bá padà tọ baba wa lọ láìsí ọmọ náà pẹ̀lú wa nígbà tí a mọ̀ pé, ọmọ náà ni ẹ̀mí baba wa. 31 Tí ó bá ri pé ọmọkùnrin náà kò wá pẹ̀lú wa, yóò kùú. Àwọn ìránṣẹ́ rẹ yóò wá mú baba wa tòun ti ewú orí lọ sí ipò òkú ní ìbànújẹ́. 32 Ìránṣẹ́ rẹ ló ṣe onídùúró fún ààbò ọmọ náà lọ́dọ̀ baba mi. Mo wí pé, ‘Bí n kò bá mú un padà tọ̀ ọ́ wá, baba mi, èmi ó ru ẹ̀bi rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé mi!’ 33 “Nítorí náà, jẹ́ kí ìránṣẹ́ rẹ kí ó dúró ní ìhín lọ́dọ̀ olúwa à mi bí ẹrú dípò ọmọ náà. Kí ọmọ náà bá àwọn arákùnrin rẹ̀ padà. 34 Báwo ni mo ṣe lè padà tọ baba mi lọ láì bá ṣe pé ọmọ náà wà pẹ̀lú mi? Rárá, èmi kò fẹ́ kí n rí ìbànújẹ́ tí yóò dé bá baba mi.”

In Other Versions

Genesis 44 in the ANGEFD

Genesis 44 in the ANTPNG2D

Genesis 44 in the AS21

Genesis 44 in the BAGH

Genesis 44 in the BBPNG

Genesis 44 in the BBT1E

Genesis 44 in the BDS

Genesis 44 in the BEV

Genesis 44 in the BHAD

Genesis 44 in the BIB

Genesis 44 in the BLPT

Genesis 44 in the BNT

Genesis 44 in the BNTABOOT

Genesis 44 in the BNTLV

Genesis 44 in the BOATCB

Genesis 44 in the BOATCB2

Genesis 44 in the BOBCV

Genesis 44 in the BOCNT

Genesis 44 in the BOECS

Genesis 44 in the BOGWICC

Genesis 44 in the BOHCB

Genesis 44 in the BOHCV

Genesis 44 in the BOHLNT

Genesis 44 in the BOHNTLTAL

Genesis 44 in the BOICB

Genesis 44 in the BOILNTAP

Genesis 44 in the BOITCV

Genesis 44 in the BOKCV

Genesis 44 in the BOKCV2

Genesis 44 in the BOKHWOG

Genesis 44 in the BOKSSV

Genesis 44 in the BOLCB

Genesis 44 in the BOLCB2

Genesis 44 in the BOMCV

Genesis 44 in the BONAV

Genesis 44 in the BONCB

Genesis 44 in the BONLT

Genesis 44 in the BONUT2

Genesis 44 in the BOPLNT

Genesis 44 in the BOSCB

Genesis 44 in the BOSNC

Genesis 44 in the BOTLNT

Genesis 44 in the BOVCB

Genesis 44 in the BPBB

Genesis 44 in the BPH

Genesis 44 in the BSB

Genesis 44 in the CCB

Genesis 44 in the CUV

Genesis 44 in the CUVS

Genesis 44 in the DBT

Genesis 44 in the DGDNT

Genesis 44 in the DHNT

Genesis 44 in the DNT

Genesis 44 in the ELBE

Genesis 44 in the EMTV

Genesis 44 in the ESV

Genesis 44 in the FBV

Genesis 44 in the FEB

Genesis 44 in the GGMNT

Genesis 44 in the GNT

Genesis 44 in the HARY

Genesis 44 in the HNT

Genesis 44 in the IRVA

Genesis 44 in the IRVB

Genesis 44 in the IRVG

Genesis 44 in the IRVH

Genesis 44 in the IRVK

Genesis 44 in the IRVM

Genesis 44 in the IRVM2

Genesis 44 in the IRVO

Genesis 44 in the IRVP

Genesis 44 in the IRVT

Genesis 44 in the IRVT2

Genesis 44 in the IRVU

Genesis 44 in the ISVN

Genesis 44 in the JSNT

Genesis 44 in the KAPI

Genesis 44 in the KBT1ETNIK

Genesis 44 in the KBV

Genesis 44 in the KJV

Genesis 44 in the KNFD

Genesis 44 in the LBA

Genesis 44 in the LBLA

Genesis 44 in the LNT

Genesis 44 in the LSV

Genesis 44 in the MAAL

Genesis 44 in the MBV

Genesis 44 in the MBV2

Genesis 44 in the MHNT

Genesis 44 in the MKNFD

Genesis 44 in the MNG

Genesis 44 in the MNT

Genesis 44 in the MNT2

Genesis 44 in the MRS1T

Genesis 44 in the NAA

Genesis 44 in the NASB

Genesis 44 in the NBLA

Genesis 44 in the NBS

Genesis 44 in the NBVTP

Genesis 44 in the NET2

Genesis 44 in the NIV11

Genesis 44 in the NNT

Genesis 44 in the NNT2

Genesis 44 in the NNT3

Genesis 44 in the PDDPT

Genesis 44 in the PFNT

Genesis 44 in the RMNT

Genesis 44 in the SBIAS

Genesis 44 in the SBIBS

Genesis 44 in the SBIBS2

Genesis 44 in the SBICS

Genesis 44 in the SBIDS

Genesis 44 in the SBIGS

Genesis 44 in the SBIHS

Genesis 44 in the SBIIS

Genesis 44 in the SBIIS2

Genesis 44 in the SBIIS3

Genesis 44 in the SBIKS

Genesis 44 in the SBIKS2

Genesis 44 in the SBIMS

Genesis 44 in the SBIOS

Genesis 44 in the SBIPS

Genesis 44 in the SBISS

Genesis 44 in the SBITS

Genesis 44 in the SBITS2

Genesis 44 in the SBITS3

Genesis 44 in the SBITS4

Genesis 44 in the SBIUS

Genesis 44 in the SBIVS

Genesis 44 in the SBT

Genesis 44 in the SBT1E

Genesis 44 in the SCHL

Genesis 44 in the SNT

Genesis 44 in the SUSU

Genesis 44 in the SUSU2

Genesis 44 in the SYNO

Genesis 44 in the TBIAOTANT

Genesis 44 in the TBT1E

Genesis 44 in the TBT1E2

Genesis 44 in the TFTIP

Genesis 44 in the TFTU

Genesis 44 in the TGNTATF3T

Genesis 44 in the THAI

Genesis 44 in the TNFD

Genesis 44 in the TNT

Genesis 44 in the TNTIK

Genesis 44 in the TNTIL

Genesis 44 in the TNTIN

Genesis 44 in the TNTIP

Genesis 44 in the TNTIZ

Genesis 44 in the TOMA

Genesis 44 in the TTENT

Genesis 44 in the UBG

Genesis 44 in the UGV

Genesis 44 in the UGV2

Genesis 44 in the UGV3

Genesis 44 in the VBL

Genesis 44 in the VDCC

Genesis 44 in the YALU

Genesis 44 in the YAPE

Genesis 44 in the YBVTP

Genesis 44 in the ZBP