Genesis 48 (BOYCB)
1 Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀ si, a wí fún Josẹfu pé, “Baba rẹ ń ṣàìsàn,” nítorí náà, ó mú àwọn ọmọ rẹ̀ méjèèjì, Manase àti Efraimu lọ́wọ́ lọ pẹ̀lú rẹ̀. 2 Nígbà tí a sọ fún Jakọbu pé, “Josẹfu ọmọ rẹ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ,” Israẹli rọ́jú dìde jókòó lórí ibùsùn rẹ̀. 3 Jakọbu wí fún Josẹfu pé, “El-Ṣaddai, fi ara hàn mí ní Lusi ní ilẹ̀ Kenaani, níbẹ̀ ni ó sì ti súre fún mi. 4 Ó sì wí fún mi pé, ‘Èmi yóò mú kí o bí sí i, ìwọ yóò sì pọ̀ sí i, èmi yóò sì sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá, èmi yóò sì fún ìwọ àti irú-ọmọ rẹ lẹ́yìn rẹ ní ilẹ̀ yìí gẹ́gẹ́ bí ohun ìní ayérayé.’ 5 “Nítorí náà báyìí, àwọn ọmọ rẹ méjèèjì tí a bí fún ọ ní ilẹ̀ Ejibiti, kí èmi kí ó tó tọ̀ ọ́ wá ní ìhín, ni mo sọ di ọmọ mi fúnra mi. Manase àti Efraimu yóò jẹ́ tèmi gẹ́gẹ́ bí Reubeni àti Simeoni ti jẹ́ tèmi. 6 Àwọn ọmọ mìíràn tí ìwọ bá bí lẹ́yìn wọn yóò jẹ́ ọmọ rẹ. Ní ilẹ̀ tí wọn yóò jogún, orúkọ arákùnrin wọn ni a ó máa fi pè wọ́n. 7 Bí mo ti ń padà láti Padani, Rakeli kú ní ọ̀nà nígbà tí ó ṣì wà ní ilẹ̀ Kenaani, èyí tó mú ìbànújẹ́ bá mi, níbi tí kò jìnnà sí Efrata. Nítorí náà èmí sì sin ín sí ẹ̀bá ọ̀nà tí ó lọ sí Efrata” (tí ṣe Bẹtilẹhẹmu). 8 Nígbà tí Israẹli rí àwọn ọmọ Josẹfu, ó béèrè wí pé, “Àwọn wo nìyí?” 9 Josẹfu fún baba rẹ̀ lésì pé, “Wọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin tí Ọlọ́run ti fi fún mi ní ìhín.”Nígbà náà ni Israẹli wí pé, “Kó wọn wá sí ọ̀dọ̀ mi kí èmi kí ó ba à le súre fún wọn.” 10 Báyìí, ojú Israẹli ti ń di bàìbàì nítorí ogbó, agbára káká sì ni ó fi ń ríran. Josẹfu sì kó àwọn ọmọ rẹ̀ súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀, baba rẹ̀ fẹnukò wọ́n ni ẹnu, ó sì dì mọ́ wọn. 11 Israẹli wí fún Josẹfu pé, “Èmi kò lérò rárá pé, mo tún le rí ojú rẹ mọ́ láéláé, ṣùgbọ́n Ọlọ́run tún fún mi ní àǹfààní, mo sì tún rí àwọn ọmọ rẹ pẹ̀lú.” 12 Nígbà náà ni Josẹfu kó àwọn ọmọ náà kúrò ní orí eékún baba rẹ̀, ó wólẹ̀, ó sì tẹríba. 13 Josẹfu sì mú àwọn méjèèjì, Efraimu ni o fi sí ọwọ́ ọ̀tún òun tìkára rẹ̀, èyí tí í ṣe ọwọ́ òsì fún Israẹli, ó sì fi Manase sí ọwọ́ òsì ara rẹ̀, èyí tí ó bọ́ sí ọwọ́ ọ̀tún Israẹli. 14 Israẹli sì na ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ jáde, ó sì gbe lé Efraimu lórí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ni àbúrò, ó sì fi ọwọ́ rẹ̀ tàsé ara wọn, ó sì na ọwọ́ òsì lé Manase lórí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Manase ni àkọ́bí. 15 Nígbà náà ni ó súre fún Josẹfu wí pé,“Ǹjẹ́ kí Ọlọ́run, ẹni tí baba miAbrahamu àti Isaaki rìn níwájú rẹ̀,Ọlọ́run tí ó ti jẹ́ olùtọ́jú àti aláàbòmi ní gbogbo ọjọ́ ayé mi títí di òní, 16 Angẹli tí ó dá mi ní ìdè kúrò lọ́wọ́ gbogbo ewu,kí ó súre fún àwọn ọmọkùnrin wọ̀nyí.Kí a máa fi orúkọ mi pè wọ́n àti orúkọ àwọn baba miAbrahamu àti Isaaki,kí wọn kí ó sì pọ̀ sí i lọ́pọ̀lọ́pọ̀lórí ilẹ̀ ayé.” 17 Nígbà tí Josẹfu rí i pé baba òun gbé ọwọ́ ọ̀tún lé Efraimu lórí, inú rẹ̀ bàjẹ́, ó sì gbá ọwọ́ baba rẹ̀ mú láti gbé ọwọ́ rẹ̀ kúrò lórí Efraimu lọ sí orí Manase. 18 Josẹfu wí fun pé, “Rárá, baba mi, èyí ni àkọ́bí, orí rẹ̀ ni kí ìwọ kí o gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ lé.” 19 Ṣùgbọ́n baba rẹ̀ kò gbà, ó wí pé, “Mo mọ̀, ọmọ mi, mo mọ̀. Òun náà yóò di orílẹ̀-èdè, òun náà yóò sì di ńlá. Ṣùgbọ́n àbúrò rẹ̀ yóò di ẹni ńlá jù ú lọ, irú-ọmọ rẹ yóò sì di ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè.” 20 Ó súre fún wọn lọ́jọ́ náà pé,“Ní orúkọ yín ni Israẹli yóò máa súre yìí pé,‘Kí Ọlọ́run ṣe ọ́ bí i ti Efraimu àti Manase.’ ”Ó sì gbé Efraimu gẹ́gẹ́ bí ẹ̀gbọ́n sí Manase. 21 Nígbà náà ni Israẹli wí fún Josẹfu pé, “Ọjọ́ ikú mi súnmọ́ etílé, ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò wà pẹ̀lú yín, yóò sì mú un yín padà sí ilẹ̀ àwọn baba yín. 22 Pẹ̀lúpẹ̀lú èmi yóò fún ọ ní ìpín kan ju ti àwọn arákùnrin rẹ lọ. Ilẹ̀ tí mo fi idà àti ọ̀kọ̀ mi gbà lọ́wọ́ àwọn ará Amori.”
In Other Versions
Genesis 48 in the ANGEFD
Genesis 48 in the ANTPNG2D
Genesis 48 in the AS21
Genesis 48 in the BAGH
Genesis 48 in the BBPNG
Genesis 48 in the BBT1E
Genesis 48 in the BDS
Genesis 48 in the BEV
Genesis 48 in the BHAD
Genesis 48 in the BIB
Genesis 48 in the BLPT
Genesis 48 in the BNT
Genesis 48 in the BNTABOOT
Genesis 48 in the BNTLV
Genesis 48 in the BOATCB
Genesis 48 in the BOATCB2
Genesis 48 in the BOBCV
Genesis 48 in the BOCNT
Genesis 48 in the BOECS
Genesis 48 in the BOGWICC
Genesis 48 in the BOHCB
Genesis 48 in the BOHCV
Genesis 48 in the BOHLNT
Genesis 48 in the BOHNTLTAL
Genesis 48 in the BOICB
Genesis 48 in the BOILNTAP
Genesis 48 in the BOITCV
Genesis 48 in the BOKCV
Genesis 48 in the BOKCV2
Genesis 48 in the BOKHWOG
Genesis 48 in the BOKSSV
Genesis 48 in the BOLCB
Genesis 48 in the BOLCB2
Genesis 48 in the BOMCV
Genesis 48 in the BONAV
Genesis 48 in the BONCB
Genesis 48 in the BONLT
Genesis 48 in the BONUT2
Genesis 48 in the BOPLNT
Genesis 48 in the BOSCB
Genesis 48 in the BOSNC
Genesis 48 in the BOTLNT
Genesis 48 in the BOVCB
Genesis 48 in the BPBB
Genesis 48 in the BPH
Genesis 48 in the BSB
Genesis 48 in the CCB
Genesis 48 in the CUV
Genesis 48 in the CUVS
Genesis 48 in the DBT
Genesis 48 in the DGDNT
Genesis 48 in the DHNT
Genesis 48 in the DNT
Genesis 48 in the ELBE
Genesis 48 in the EMTV
Genesis 48 in the ESV
Genesis 48 in the FBV
Genesis 48 in the FEB
Genesis 48 in the GGMNT
Genesis 48 in the GNT
Genesis 48 in the HARY
Genesis 48 in the HNT
Genesis 48 in the IRVA
Genesis 48 in the IRVB
Genesis 48 in the IRVG
Genesis 48 in the IRVH
Genesis 48 in the IRVK
Genesis 48 in the IRVM
Genesis 48 in the IRVM2
Genesis 48 in the IRVO
Genesis 48 in the IRVP
Genesis 48 in the IRVT
Genesis 48 in the IRVT2
Genesis 48 in the IRVU
Genesis 48 in the ISVN
Genesis 48 in the JSNT
Genesis 48 in the KAPI
Genesis 48 in the KBT1ETNIK
Genesis 48 in the KBV
Genesis 48 in the KJV
Genesis 48 in the KNFD
Genesis 48 in the LBA
Genesis 48 in the LBLA
Genesis 48 in the LNT
Genesis 48 in the LSV
Genesis 48 in the MAAL
Genesis 48 in the MBV
Genesis 48 in the MBV2
Genesis 48 in the MHNT
Genesis 48 in the MKNFD
Genesis 48 in the MNG
Genesis 48 in the MNT
Genesis 48 in the MNT2
Genesis 48 in the MRS1T
Genesis 48 in the NAA
Genesis 48 in the NASB
Genesis 48 in the NBLA
Genesis 48 in the NBS
Genesis 48 in the NBVTP
Genesis 48 in the NET2
Genesis 48 in the NIV11
Genesis 48 in the NNT
Genesis 48 in the NNT2
Genesis 48 in the NNT3
Genesis 48 in the PDDPT
Genesis 48 in the PFNT
Genesis 48 in the RMNT
Genesis 48 in the SBIAS
Genesis 48 in the SBIBS
Genesis 48 in the SBIBS2
Genesis 48 in the SBICS
Genesis 48 in the SBIDS
Genesis 48 in the SBIGS
Genesis 48 in the SBIHS
Genesis 48 in the SBIIS
Genesis 48 in the SBIIS2
Genesis 48 in the SBIIS3
Genesis 48 in the SBIKS
Genesis 48 in the SBIKS2
Genesis 48 in the SBIMS
Genesis 48 in the SBIOS
Genesis 48 in the SBIPS
Genesis 48 in the SBISS
Genesis 48 in the SBITS
Genesis 48 in the SBITS2
Genesis 48 in the SBITS3
Genesis 48 in the SBITS4
Genesis 48 in the SBIUS
Genesis 48 in the SBIVS
Genesis 48 in the SBT
Genesis 48 in the SBT1E
Genesis 48 in the SCHL
Genesis 48 in the SNT
Genesis 48 in the SUSU
Genesis 48 in the SUSU2
Genesis 48 in the SYNO
Genesis 48 in the TBIAOTANT
Genesis 48 in the TBT1E
Genesis 48 in the TBT1E2
Genesis 48 in the TFTIP
Genesis 48 in the TFTU
Genesis 48 in the TGNTATF3T
Genesis 48 in the THAI
Genesis 48 in the TNFD
Genesis 48 in the TNT
Genesis 48 in the TNTIK
Genesis 48 in the TNTIL
Genesis 48 in the TNTIN
Genesis 48 in the TNTIP
Genesis 48 in the TNTIZ
Genesis 48 in the TOMA
Genesis 48 in the TTENT
Genesis 48 in the UBG
Genesis 48 in the UGV
Genesis 48 in the UGV2
Genesis 48 in the UGV3
Genesis 48 in the VBL
Genesis 48 in the VDCC
Genesis 48 in the YALU
Genesis 48 in the YAPE
Genesis 48 in the YBVTP
Genesis 48 in the ZBP