Genesis 5 (BOYCB)
1 Èyí ni àkọsílẹ̀ ìran Adamu. Nígbà tí Ọlọ́run dá ènìyàn, ní àwòrán Ọlọ́run ni ó dá a. 2 Àti akọ àti abo ni Ó dá wọn, ó sì súre fún wọn, ó sì pe orúkọ wọ́n ní Adamu ní ọjọ́ tí ó dá wọn. 3 Nígbà tí Adamu di ẹni àádóje ọdún, ó bí ọmọkùnrin kan tí ó jọ ọ́, tí ó jẹ́ àwòrán ara rẹ̀, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Seti. 4 Ọjọ́ Adamu, lẹ́yìn ìgbà tí ó bí Seti, jẹ́ ẹgbẹ̀rin (800) ọdún, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. 5 Àpapọ̀ ọdún tí Adamu gbé ní orí ilẹ̀ jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ọdún ó lé ọgbọ̀n (930), ó sì kú. 6 Nígbà tí Seti pé àrùnlélọ́gọ́rùn-ún ọdún, ó bí Enoṣi. 7 Lẹ́yìn ìgbà tí ó bí Enoṣi, Seti sì gbé fún ẹgbẹ̀rin ọdún ó lé méje (807), ó sì bí àwọn; ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. 8 Àpapọ̀ ọdún Seti sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ọdún ó lé méjìlá (912), ó sì kú. 9 Nígbà tí Enoṣi di ẹni àádọ́rùn-ún ọdún ni ó bí Kenani. 10 Lẹ́yìn tí ó bí Kenani, Enoṣi sì wà láààyè fún ẹgbẹ̀rin ọdún ó lé mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (815), ó sì bí àwọn ọkùnrin àti obìnrin. 11 Àpapọ̀ ọdún Enoṣi jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ọdún ó lé márùn-ún (905), ó sì kú. 12 Nígbà tí Kenani di àádọ́rin ọdún ni ó bí Mahalaleli. 13 Lẹ́yìn tí ó bí Mahalaleli, Kenani wà láààyè fún òjìlélẹ́gbẹ̀rin ọdún (840), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. 14 Àpapọ̀ ọjọ́ Kenani jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ọdún ó lé mẹ́wàá (910), ó sì kú. 15 Nígbà tí Mahalaleli pé ọmọ àrùnlélọ́gọ́ta ọdún ni ó bí Jaredi. 16 Mahalaleli sì gbé fún ẹgbẹ̀rin ọdún ó lé ọgbọ̀n (830) lẹ́yìn ìgbà tí ó bí Jaredi, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. 17 Àpapọ̀ iye ọdún Mahalaleli jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ọdún ó dín márùn-ún (895), ó sì kú. 18 Nígbà tí Jaredi pé ọmọ ọgọ́jọ ọdún ó lé méjì ni ó bí Enoku. 19 Lẹ́yìn èyí, Jaredi wà láààyè fún ẹgbẹ̀rin (800) ọdún Enoku sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. 20 Àpapọ̀ ọdún Jaredi sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún dín méjìdínlógójì (962), ó sì kú. 21 Nígbà tí Enoku pé ọmọ ọgọ́ta ọdún ó lé márùn ni ó bí Metusela. 22 Lẹ́yìn tí ó bí Metusela, Enoku sì bá Ọlọ́run rìn ní ọ̀ọ́dúnrún (300) ọdún, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. 23 Àpapọ̀ ọjọ́ Enoku sì jẹ́ irinwó ọdún dín márùndínlógójì (365). 24 Enoku bá Ọlọ́run rìn; a kò sì rí i mọ́ nítorí Ọlọ́run mú un lọ. 25 Nígbà tí Metusela pé igba ọdún dín mẹ́tàlá ní o bí Lameki. 26 Lẹ́yìn èyí Metusela wà láààyè fún ẹgbẹ̀rin ọdún dín méjìdínlógún (782), lẹ́yìn ìgbà tí ó bí Lameki, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. 27 Àpapọ̀ ọdún Metusela jẹ́ ẹgbẹ̀rún ọdún dín mọ́kànlélọ́gbọ̀n (969), ó sì kú. 28 Nígbà tí Lameki pé ọdún méjìlélọ́gọ́sàn án ni ó bí ọmọkùnrin kan. 29 Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Noa, ó sì wí pé, “Eléyìí ni yóò tù wá nínú ni iṣẹ́ àti làálàá ọwọ́ wa, nítorí ilẹ̀ tí OLÚWA ti fi gégùn ún.” 30 Lẹ́yìn tí ó bí Noa, Lameki gbé fún ẹgbẹ̀ta ọdún dín márùn-ún (595), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. 31 Àpapọ̀ ọdún Lameki sì jẹ́ ẹgbẹ̀rin ọdún dín mẹ́tàlélógún (777), ó sì kú. 32 Lẹ́yìn tí Noa pé ọmọ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) ọdún ni ó bí Ṣemu, Hamu àti Jafeti.
In Other Versions
Genesis 5 in the ANGEFD
Genesis 5 in the ANTPNG2D
Genesis 5 in the AS21
Genesis 5 in the BAGH
Genesis 5 in the BBPNG
Genesis 5 in the BBT1E
Genesis 5 in the BDS
Genesis 5 in the BEV
Genesis 5 in the BHAD
Genesis 5 in the BIB
Genesis 5 in the BLPT
Genesis 5 in the BNT
Genesis 5 in the BNTABOOT
Genesis 5 in the BNTLV
Genesis 5 in the BOATCB
Genesis 5 in the BOATCB2
Genesis 5 in the BOBCV
Genesis 5 in the BOCNT
Genesis 5 in the BOECS
Genesis 5 in the BOGWICC
Genesis 5 in the BOHCB
Genesis 5 in the BOHCV
Genesis 5 in the BOHLNT
Genesis 5 in the BOHNTLTAL
Genesis 5 in the BOICB
Genesis 5 in the BOILNTAP
Genesis 5 in the BOITCV
Genesis 5 in the BOKCV
Genesis 5 in the BOKCV2
Genesis 5 in the BOKHWOG
Genesis 5 in the BOKSSV
Genesis 5 in the BOLCB
Genesis 5 in the BOLCB2
Genesis 5 in the BOMCV
Genesis 5 in the BONAV
Genesis 5 in the BONCB
Genesis 5 in the BONLT
Genesis 5 in the BONUT2
Genesis 5 in the BOPLNT
Genesis 5 in the BOSCB
Genesis 5 in the BOSNC
Genesis 5 in the BOTLNT
Genesis 5 in the BOVCB
Genesis 5 in the BPBB
Genesis 5 in the BPH
Genesis 5 in the BSB
Genesis 5 in the CCB
Genesis 5 in the CUV
Genesis 5 in the CUVS
Genesis 5 in the DBT
Genesis 5 in the DGDNT
Genesis 5 in the DHNT
Genesis 5 in the DNT
Genesis 5 in the ELBE
Genesis 5 in the EMTV
Genesis 5 in the ESV
Genesis 5 in the FBV
Genesis 5 in the FEB
Genesis 5 in the GGMNT
Genesis 5 in the GNT
Genesis 5 in the HARY
Genesis 5 in the HNT
Genesis 5 in the IRVA
Genesis 5 in the IRVB
Genesis 5 in the IRVG
Genesis 5 in the IRVH
Genesis 5 in the IRVK
Genesis 5 in the IRVM
Genesis 5 in the IRVM2
Genesis 5 in the IRVO
Genesis 5 in the IRVP
Genesis 5 in the IRVT
Genesis 5 in the IRVT2
Genesis 5 in the IRVU
Genesis 5 in the ISVN
Genesis 5 in the JSNT
Genesis 5 in the KAPI
Genesis 5 in the KBT1ETNIK
Genesis 5 in the KBV
Genesis 5 in the KJV
Genesis 5 in the KNFD
Genesis 5 in the LBA
Genesis 5 in the LBLA
Genesis 5 in the LNT
Genesis 5 in the LSV
Genesis 5 in the MAAL
Genesis 5 in the MBV
Genesis 5 in the MBV2
Genesis 5 in the MHNT
Genesis 5 in the MKNFD
Genesis 5 in the MNG
Genesis 5 in the MNT
Genesis 5 in the MNT2
Genesis 5 in the MRS1T
Genesis 5 in the NAA
Genesis 5 in the NASB
Genesis 5 in the NBLA
Genesis 5 in the NBS
Genesis 5 in the NBVTP
Genesis 5 in the NET2
Genesis 5 in the NIV11
Genesis 5 in the NNT
Genesis 5 in the NNT2
Genesis 5 in the NNT3
Genesis 5 in the PDDPT
Genesis 5 in the PFNT
Genesis 5 in the RMNT
Genesis 5 in the SBIAS
Genesis 5 in the SBIBS
Genesis 5 in the SBIBS2
Genesis 5 in the SBICS
Genesis 5 in the SBIDS
Genesis 5 in the SBIGS
Genesis 5 in the SBIHS
Genesis 5 in the SBIIS
Genesis 5 in the SBIIS2
Genesis 5 in the SBIIS3
Genesis 5 in the SBIKS
Genesis 5 in the SBIKS2
Genesis 5 in the SBIMS
Genesis 5 in the SBIOS
Genesis 5 in the SBIPS
Genesis 5 in the SBISS
Genesis 5 in the SBITS
Genesis 5 in the SBITS2
Genesis 5 in the SBITS3
Genesis 5 in the SBITS4
Genesis 5 in the SBIUS
Genesis 5 in the SBIVS
Genesis 5 in the SBT
Genesis 5 in the SBT1E
Genesis 5 in the SCHL
Genesis 5 in the SNT
Genesis 5 in the SUSU
Genesis 5 in the SUSU2
Genesis 5 in the SYNO
Genesis 5 in the TBIAOTANT
Genesis 5 in the TBT1E
Genesis 5 in the TBT1E2
Genesis 5 in the TFTIP
Genesis 5 in the TFTU
Genesis 5 in the TGNTATF3T
Genesis 5 in the THAI
Genesis 5 in the TNFD
Genesis 5 in the TNT
Genesis 5 in the TNTIK
Genesis 5 in the TNTIL
Genesis 5 in the TNTIN
Genesis 5 in the TNTIP
Genesis 5 in the TNTIZ
Genesis 5 in the TOMA
Genesis 5 in the TTENT
Genesis 5 in the UBG
Genesis 5 in the UGV
Genesis 5 in the UGV2
Genesis 5 in the UGV3
Genesis 5 in the VBL
Genesis 5 in the VDCC
Genesis 5 in the YALU
Genesis 5 in the YAPE
Genesis 5 in the YBVTP
Genesis 5 in the ZBP