Jeremiah 34 (BOYCB)
1 Nígbà tí Nebukadnessari ọba Babeli àti àwọn ọmọ-ogun rẹ̀, pẹ̀lú gbogbo ìjọba àti àwọn ènìyàn ní ilẹ̀ ọba tí ó jẹ ọba lé lórí ń bá Jerusalẹmu jà, àti gbogbo àwọn ìlú tí ó yíká, ọ̀rọ̀ yìí tọ Jeremiah wá láti ọ̀dọ̀ OLÚWA pé: 2 “Èyí ni ohun tí OLÚWA Ọlọ́run Israẹli ọmọ-ogun wí: Lọ sí ọ̀dọ̀ Sedekiah ọba Juda kí o sì sọ fún un pé, ‘Èyí ni ohun tí Ọlọ́run wí: Èmi fẹ́ fa ìlú yìí lé ọba Babeli lọ́wọ́, yóò sì jó palẹ̀. 3 Ìwọ kò ní sá àsálà, ṣùgbọ́n à ó mú ọ, bẹ́ẹ̀ ni a ó sì fà ọ́ lé e lọ́wọ́. Ìwọ yóò rí ọba Babeli pẹ̀lú ojú ara rẹ; yóò sì bá ọ sọ̀rọ̀ lójúkojú; ìwọ yóò sì lọ sí Babeli. 4 “ ‘Síbẹ̀, gbọ́ ìlérí OLÚWA, ìwọ Sedekiah ọba Juda. Èyí ni ohun tí Ọlọ́run wí nípa rẹ; ìwọ kì yóò ti ipa idà kú; 5 ìwọ yóò kú ní àlàáfíà. Bí àwọn ènìyàn sì ti ń ṣe iná ìsìnkú ní ọlá fún àwọn baba rẹ, ọba tí ó jẹ ṣáájú rẹ, bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò ṣe iná ní ọlá rẹ, wọn ó sì pohùnréré pé, “Yé, olúwa!” Èmi fúnra mi ni ó ṣèlérí yìí ni OLÚWA wí.’ ” 6 Nígbà náà ni Jeremiah wòlíì sọ gbogbo nǹkan yìí fún Sedekiah ọba Juda ní Jerusalẹmu. 7 Nígbà tí ogun ọba Babeli ń bá Jerusalẹmu jà, àti gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ó kù ní Juda, Lakiṣi, Aseka; àwọn nìkan ni ìlú olódi tí ó kù ní Juda. 8 Ọ̀rọ̀ OLÚWA sì tọ Jeremiah wá lẹ́yìn ìgbà tí ọba Sedekiah ti dá májẹ̀mú pẹ̀lú gbogbo àwọn ènìyàn ní Jerusalẹmu láti polongo ìtúsílẹ̀ fún àwọn ẹrú. 9 Kí oníkálùkù lè jẹ́ kí ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin tí í ṣe Heberu lọ lọ́fẹ̀ẹ́, kí ẹnikẹ́ni kí ó má mú ará Juda arákùnrin rẹ̀ sìn. 10 Nítorí náà, gbogbo àwọn aláṣẹ àti àwọn ènìyàn tí wọ́n fi ọwọ́ sí májẹ̀mú náà láti dá ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin sílẹ̀ kí wọ́n sì má ṣe fi wọ́n sínú ìgbèkùn mọ́. Wọ́n sì gbà, wọ́n sì jẹ́ kí wọn lọ lọ́fẹ̀ẹ́. 11 Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, wọ́n yí ọkàn wọn padà; wọ́n sì mú àwọn ẹrú tí wọ́n ti dá sílẹ̀ padà láti tún máa sìn wọ́n. 12 Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ OLÚWA tọ Jeremiah wá wí pé: 13 “Èyí ni ohun tí OLÚWA, Ọlọ́run Israẹli wí pé: Mo dá májẹ̀mú kan pẹ̀lú àwọn baba ńlá yín nígbà tí mo mú wọn kúrò ní Ejibiti; kúrò ní oko ẹrú. Mo wí pé, 14 ‘Ní ọdún keje, ẹnìkọ̀ọ̀kan yín gbọdọ̀ tú àwọn Heberu tí wọ́n ti ta ara wọn fún un yín sílẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ti sìn yín fún ọdún mẹ́fà. Ẹ gbọdọ̀ jẹ́ kí wọn kí ó lọ’; ṣùgbọ́n àwọn baba yín kò gbọ́; bẹ́ẹ̀ ni wọn kò fetí sí mi. 15 Láìpẹ́ yìí ẹ ti ronúpìwàdà, ẹ sì ṣe ohun tí ó tọ́ lójú mi, ẹnìkọ̀ọ̀kan yín sì ṣe ìtúsílẹ̀ fún àwọn ènìyàn. Ẹ sì tún bá mi dá májẹ̀mú ní àwọn ilé tí a ti ń pe orúkọ mi. 16 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin yípadà, ẹ sì sọ orúkọ mi di èérí, olúkúlùkù sì mú kí àwọn ẹni rẹ tí ó ti sọ di òmìnira bí ọkàn wọn ti fẹ́ padà; ẹ̀yin sì tún fi wọ́n ṣe ẹrú. 17 “Nítorí náà báyìí ni OLÚWA wí: Ẹ̀yin kò fetí sí mi nípa ọ̀rọ̀ òmìnira láàrín ẹ̀gbọ́n sí àbúrò, láàrín ẹnìkan sí èkejì rẹ̀. Wò ó, èmi yóò kéde òmìnira fún un yín ni OLÚWA wí. Sí idà, sí àjàkálẹ̀-ààrùn, àti sí ìyàn, èmi ó sì fi yín fún ìwọ̀sí ní gbogbo ìjọba ilẹ̀ ayé. 18 Èmi ó ṣe àwọn ọkùnrin náà tí ó da májẹ̀mú mi, tí kò tẹ̀lé májẹ̀mú tí wọ́n ti dá níwájú mi bí ẹgbọrọ màlúù tí wọ́n gé sí méjì, tí ó sì kọjá láàrín ìpín méjì náà. 19 Àwọn ìjòyè Juda àti àwọn ti Jerusalẹmu, àwọn aláṣẹ àti àwọn àlùfáà àti gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà tí ó kọjá láàrín àwọn ìpín méjèèjì ẹgbọrọ màlúù náà. 20 Èmi ó fi wọ́n lé ọwọ́ àwọn ọ̀tá wọn, àti lé àwọn tí ń wá ẹ̀mí wọn lọ́wọ́. Òkú wọn yóò jẹ́ oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti fún àwọn ẹranko igbó. 21 “Sedekiah ọba àti àwọn ìjòyè rẹ̀ ní Juda ni èmí yóò fi lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́, àti àwọn tí ń wá ẹ̀mí wọn àti lé ọwọ́ ogun Babeli tí ó ti lọ kúrò lọ́dọ̀ yín. 22 Wò ó èmi ó pàṣẹ ni OLÚWA wí, èmi ó sì mú wọn padà sí ìlú yìí, wọn ó sì bá a jà, wọn ó sì kó o, wọn ó fi iná jó o. Èmi ó sì sọ ìlú Juda dí ahoro.”
In Other Versions
Jeremiah 34 in the ANGEFD
Jeremiah 34 in the ANTPNG2D
Jeremiah 34 in the AS21
Jeremiah 34 in the BAGH
Jeremiah 34 in the BBPNG
Jeremiah 34 in the BBT1E
Jeremiah 34 in the BDS
Jeremiah 34 in the BEV
Jeremiah 34 in the BHAD
Jeremiah 34 in the BIB
Jeremiah 34 in the BLPT
Jeremiah 34 in the BNT
Jeremiah 34 in the BNTABOOT
Jeremiah 34 in the BNTLV
Jeremiah 34 in the BOATCB
Jeremiah 34 in the BOATCB2
Jeremiah 34 in the BOBCV
Jeremiah 34 in the BOCNT
Jeremiah 34 in the BOECS
Jeremiah 34 in the BOGWICC
Jeremiah 34 in the BOHCB
Jeremiah 34 in the BOHCV
Jeremiah 34 in the BOHLNT
Jeremiah 34 in the BOHNTLTAL
Jeremiah 34 in the BOICB
Jeremiah 34 in the BOILNTAP
Jeremiah 34 in the BOITCV
Jeremiah 34 in the BOKCV
Jeremiah 34 in the BOKCV2
Jeremiah 34 in the BOKHWOG
Jeremiah 34 in the BOKSSV
Jeremiah 34 in the BOLCB
Jeremiah 34 in the BOLCB2
Jeremiah 34 in the BOMCV
Jeremiah 34 in the BONAV
Jeremiah 34 in the BONCB
Jeremiah 34 in the BONLT
Jeremiah 34 in the BONUT2
Jeremiah 34 in the BOPLNT
Jeremiah 34 in the BOSCB
Jeremiah 34 in the BOSNC
Jeremiah 34 in the BOTLNT
Jeremiah 34 in the BOVCB
Jeremiah 34 in the BPBB
Jeremiah 34 in the BPH
Jeremiah 34 in the BSB
Jeremiah 34 in the CCB
Jeremiah 34 in the CUV
Jeremiah 34 in the CUVS
Jeremiah 34 in the DBT
Jeremiah 34 in the DGDNT
Jeremiah 34 in the DHNT
Jeremiah 34 in the DNT
Jeremiah 34 in the ELBE
Jeremiah 34 in the EMTV
Jeremiah 34 in the ESV
Jeremiah 34 in the FBV
Jeremiah 34 in the FEB
Jeremiah 34 in the GGMNT
Jeremiah 34 in the GNT
Jeremiah 34 in the HARY
Jeremiah 34 in the HNT
Jeremiah 34 in the IRVA
Jeremiah 34 in the IRVB
Jeremiah 34 in the IRVG
Jeremiah 34 in the IRVH
Jeremiah 34 in the IRVK
Jeremiah 34 in the IRVM
Jeremiah 34 in the IRVM2
Jeremiah 34 in the IRVO
Jeremiah 34 in the IRVP
Jeremiah 34 in the IRVT
Jeremiah 34 in the IRVT2
Jeremiah 34 in the IRVU
Jeremiah 34 in the ISVN
Jeremiah 34 in the JSNT
Jeremiah 34 in the KAPI
Jeremiah 34 in the KBT1ETNIK
Jeremiah 34 in the KBV
Jeremiah 34 in the KJV
Jeremiah 34 in the KNFD
Jeremiah 34 in the LBA
Jeremiah 34 in the LBLA
Jeremiah 34 in the LNT
Jeremiah 34 in the LSV
Jeremiah 34 in the MAAL
Jeremiah 34 in the MBV
Jeremiah 34 in the MBV2
Jeremiah 34 in the MHNT
Jeremiah 34 in the MKNFD
Jeremiah 34 in the MNG
Jeremiah 34 in the MNT
Jeremiah 34 in the MNT2
Jeremiah 34 in the MRS1T
Jeremiah 34 in the NAA
Jeremiah 34 in the NASB
Jeremiah 34 in the NBLA
Jeremiah 34 in the NBS
Jeremiah 34 in the NBVTP
Jeremiah 34 in the NET2
Jeremiah 34 in the NIV11
Jeremiah 34 in the NNT
Jeremiah 34 in the NNT2
Jeremiah 34 in the NNT3
Jeremiah 34 in the PDDPT
Jeremiah 34 in the PFNT
Jeremiah 34 in the RMNT
Jeremiah 34 in the SBIAS
Jeremiah 34 in the SBIBS
Jeremiah 34 in the SBIBS2
Jeremiah 34 in the SBICS
Jeremiah 34 in the SBIDS
Jeremiah 34 in the SBIGS
Jeremiah 34 in the SBIHS
Jeremiah 34 in the SBIIS
Jeremiah 34 in the SBIIS2
Jeremiah 34 in the SBIIS3
Jeremiah 34 in the SBIKS
Jeremiah 34 in the SBIKS2
Jeremiah 34 in the SBIMS
Jeremiah 34 in the SBIOS
Jeremiah 34 in the SBIPS
Jeremiah 34 in the SBISS
Jeremiah 34 in the SBITS
Jeremiah 34 in the SBITS2
Jeremiah 34 in the SBITS3
Jeremiah 34 in the SBITS4
Jeremiah 34 in the SBIUS
Jeremiah 34 in the SBIVS
Jeremiah 34 in the SBT
Jeremiah 34 in the SBT1E
Jeremiah 34 in the SCHL
Jeremiah 34 in the SNT
Jeremiah 34 in the SUSU
Jeremiah 34 in the SUSU2
Jeremiah 34 in the SYNO
Jeremiah 34 in the TBIAOTANT
Jeremiah 34 in the TBT1E
Jeremiah 34 in the TBT1E2
Jeremiah 34 in the TFTIP
Jeremiah 34 in the TFTU
Jeremiah 34 in the TGNTATF3T
Jeremiah 34 in the THAI
Jeremiah 34 in the TNFD
Jeremiah 34 in the TNT
Jeremiah 34 in the TNTIK
Jeremiah 34 in the TNTIL
Jeremiah 34 in the TNTIN
Jeremiah 34 in the TNTIP
Jeremiah 34 in the TNTIZ
Jeremiah 34 in the TOMA
Jeremiah 34 in the TTENT
Jeremiah 34 in the UBG
Jeremiah 34 in the UGV
Jeremiah 34 in the UGV2
Jeremiah 34 in the UGV3
Jeremiah 34 in the VBL
Jeremiah 34 in the VDCC
Jeremiah 34 in the YALU
Jeremiah 34 in the YAPE
Jeremiah 34 in the YBVTP
Jeremiah 34 in the ZBP