Jeremiah 37 (BOYCB)

1 Sedekiah ọmọ Josiah sì jẹ ọba ní ipò Jehoiakini ọmọ Jehoiakimu ẹni tí Nebukadnessari ọba Babeli fi jẹ ọba ní ilẹ̀ Juda. 2 Ṣùgbọ́n àti òun àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà kò fetísí ọ̀rọ̀ OLÚWA tí ó sọ nípa wòlíì Jeremiah. 3 Sedekiah ọba sì rán Jehukali ọmọ Ṣelemiah àti Sefaniah ọmọ Maaseiah sí Jeremiah wòlíì wí pé, “Jọ̀wọ́ gbàdúrà sí OLÚWA Ọlọ́run wa fún wa.” 4 Nígbà yìí Jeremiah sì ń wọlé, ó sì ń jáde láàrín àwọn ènìyàn nítorí wọ́n ti fi sínú túbú. 5 Àwọn ọmọ-ogun Farao ti jáde kúrò nílẹ̀ Ejibiti àti nígbà tí àwọn ará Babeli tó ń ṣàtìpó ní Jerusalẹmu gbọ́ ìròyìn nípa wọn, wọ́n kúrò ní Jerusalẹmu. 6 Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ OLÚWA tọ Jeremiah wòlíì Ọlọ́run wá: 7 “Èyí ni, ohun tí OLÚWA Ọlọ́run àwọn Israẹli sọ fún ọba àwọn Juda tó rán ọ láti wádìí nípa mi. ‘Àwọn ọmọ-ogun Farao tó jáde láti kún ọ lọ́wọ́ yóò padà sílẹ̀ wọn sí Ejibiti. 8 Nígbà náà ni àwọn ará Babeli yóò padà láti gbógun ti ìlú. Wọn yóò mú wọn nígbèkùn, wọn yóò sì fi iná jó ìlú náà kanlẹ̀.’ 9 “Èyí ni ohun tí OLÚWA wí, ẹ má ṣe tan ara yín jẹ ní èrò wí pé, ‘Àwọn ará Babeli yóò fi wá sílẹ̀ pẹ̀lú ìdánilójú.’ Wọn kò ní ṣe bẹ́ẹ̀. 10 Kódà tó bá ṣe pé wọn yóò ṣẹ́gun àwọn ọmọ-ogun Babeli tí ń gbóguntì yín àti àwọn tí ìjàǹbá ṣe, tí wọ́n ti fi sílẹ̀ ní ibùdó wọn; wọn yóò jáde láti jó ìlú náà kanlẹ̀.” 11 Lẹ́yìn tí àwọn ọmọ-ogun Babeli ti kúrò ní Jerusalẹmu nítorí àwọn ọmọ-ogun Farao. 12 Jeremiah múra láti fi ìlú náà sílẹ̀, láti lọ sí olú ìlú Benjamini láti gba ẹ̀tọ́ rẹ̀ nínú ohun ìní láàrín àwọn ènìyàn tó wà níbẹ̀. 13 Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n dé ẹnu ibodè Benjamini, olórí àwọn olùṣọ́ tí orúkọ rẹ ń jẹ́ Irijah ọmọ Ṣelemiah ọmọ Hananiah mú un, ó wí pé, “Ìwọ ń fi ara mọ́ àwọn ará Babeli.” 14 Jeremiah sọ wí pé, “Èyí kì í ṣe òtítọ́! Èmi kò yapa sí àwọn ará Babeli.” Ṣùgbọ́n Irijah ko gbọ́ tirẹ̀, dípò èyí a mú Jeremiah, ó sì mú un lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ìjòyè. 15 Nítorí náà ni àwọn ìjòyè ṣe bínú sí Jeremiah, wọ́n jẹ ẹ́ ní yà, wọ́n tún fi sí túbú nílé Jonatani akọ̀wé nítorí wọ́n ti fi èyí ṣe ilé túbú. 16 Wọ́n fi Jeremiah sínú túbú tí ó ṣókùnkùn biribiri; níbi tí ó wà fún ìgbà pípẹ́. 17 Nígbà náà ni ọba Sedekiah ránṣẹ́ sí i, tí ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n mú wá sí ààfin níbi tí ó ti bi í ní ìkọ̀kọ̀ pé, “Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ kan wà láti ọ̀dọ̀ OLÚWA?”Jeremiah fèsì pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, wọn ó fi ọ́ lé ọwọ́ ọba Babeli.” 18 Nígbà náà, Jeremiah sọ fún ọba Sedekiah pé, “Irú ẹ̀ṣẹ̀ wo ni mo ṣẹ̀ yín, àwọn ìjòyè yín pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ẹ fi sọ mí sínú túbú? 19 Níbo ni àwọn wòlíì yín tí wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún un yín wí pé ọba Babeli kò ní gbóguntì yín wá? 20 Ṣùgbọ́n ní báyìí, olúwa mi ọba, èmí bẹ̀ ọ. Jẹ́ kí n mú ẹ̀dùn ọkàn mi tọ̀ ọ́ wá; má ṣe rán mi padà sí ilé Jonatani akọ̀wé, àfi kí n kú síbẹ̀.” 21 Ọba Sedekiah wá pàṣẹ pé kí wọ́n fi Jeremiah sínú àgbàlá àwọn ẹ̀ṣọ́, àti kí wọn sì fún ní àkàrà ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan títí tí àkàrà tó wà ní ìlú yóò fi tán; bẹ́ẹ̀ ni Jeremiah wà nínú àgbàlá náà.

In Other Versions

Jeremiah 37 in the ANGEFD

Jeremiah 37 in the ANTPNG2D

Jeremiah 37 in the AS21

Jeremiah 37 in the BAGH

Jeremiah 37 in the BBPNG

Jeremiah 37 in the BBT1E

Jeremiah 37 in the BDS

Jeremiah 37 in the BEV

Jeremiah 37 in the BHAD

Jeremiah 37 in the BIB

Jeremiah 37 in the BLPT

Jeremiah 37 in the BNT

Jeremiah 37 in the BNTABOOT

Jeremiah 37 in the BNTLV

Jeremiah 37 in the BOATCB

Jeremiah 37 in the BOATCB2

Jeremiah 37 in the BOBCV

Jeremiah 37 in the BOCNT

Jeremiah 37 in the BOECS

Jeremiah 37 in the BOGWICC

Jeremiah 37 in the BOHCB

Jeremiah 37 in the BOHCV

Jeremiah 37 in the BOHLNT

Jeremiah 37 in the BOHNTLTAL

Jeremiah 37 in the BOICB

Jeremiah 37 in the BOILNTAP

Jeremiah 37 in the BOITCV

Jeremiah 37 in the BOKCV

Jeremiah 37 in the BOKCV2

Jeremiah 37 in the BOKHWOG

Jeremiah 37 in the BOKSSV

Jeremiah 37 in the BOLCB

Jeremiah 37 in the BOLCB2

Jeremiah 37 in the BOMCV

Jeremiah 37 in the BONAV

Jeremiah 37 in the BONCB

Jeremiah 37 in the BONLT

Jeremiah 37 in the BONUT2

Jeremiah 37 in the BOPLNT

Jeremiah 37 in the BOSCB

Jeremiah 37 in the BOSNC

Jeremiah 37 in the BOTLNT

Jeremiah 37 in the BOVCB

Jeremiah 37 in the BPBB

Jeremiah 37 in the BPH

Jeremiah 37 in the BSB

Jeremiah 37 in the CCB

Jeremiah 37 in the CUV

Jeremiah 37 in the CUVS

Jeremiah 37 in the DBT

Jeremiah 37 in the DGDNT

Jeremiah 37 in the DHNT

Jeremiah 37 in the DNT

Jeremiah 37 in the ELBE

Jeremiah 37 in the EMTV

Jeremiah 37 in the ESV

Jeremiah 37 in the FBV

Jeremiah 37 in the FEB

Jeremiah 37 in the GGMNT

Jeremiah 37 in the GNT

Jeremiah 37 in the HARY

Jeremiah 37 in the HNT

Jeremiah 37 in the IRVA

Jeremiah 37 in the IRVB

Jeremiah 37 in the IRVG

Jeremiah 37 in the IRVH

Jeremiah 37 in the IRVK

Jeremiah 37 in the IRVM

Jeremiah 37 in the IRVM2

Jeremiah 37 in the IRVO

Jeremiah 37 in the IRVP

Jeremiah 37 in the IRVT

Jeremiah 37 in the IRVT2

Jeremiah 37 in the IRVU

Jeremiah 37 in the ISVN

Jeremiah 37 in the JSNT

Jeremiah 37 in the KAPI

Jeremiah 37 in the KBT1ETNIK

Jeremiah 37 in the KBV

Jeremiah 37 in the KJV

Jeremiah 37 in the KNFD

Jeremiah 37 in the LBA

Jeremiah 37 in the LBLA

Jeremiah 37 in the LNT

Jeremiah 37 in the LSV

Jeremiah 37 in the MAAL

Jeremiah 37 in the MBV

Jeremiah 37 in the MBV2

Jeremiah 37 in the MHNT

Jeremiah 37 in the MKNFD

Jeremiah 37 in the MNG

Jeremiah 37 in the MNT

Jeremiah 37 in the MNT2

Jeremiah 37 in the MRS1T

Jeremiah 37 in the NAA

Jeremiah 37 in the NASB

Jeremiah 37 in the NBLA

Jeremiah 37 in the NBS

Jeremiah 37 in the NBVTP

Jeremiah 37 in the NET2

Jeremiah 37 in the NIV11

Jeremiah 37 in the NNT

Jeremiah 37 in the NNT2

Jeremiah 37 in the NNT3

Jeremiah 37 in the PDDPT

Jeremiah 37 in the PFNT

Jeremiah 37 in the RMNT

Jeremiah 37 in the SBIAS

Jeremiah 37 in the SBIBS

Jeremiah 37 in the SBIBS2

Jeremiah 37 in the SBICS

Jeremiah 37 in the SBIDS

Jeremiah 37 in the SBIGS

Jeremiah 37 in the SBIHS

Jeremiah 37 in the SBIIS

Jeremiah 37 in the SBIIS2

Jeremiah 37 in the SBIIS3

Jeremiah 37 in the SBIKS

Jeremiah 37 in the SBIKS2

Jeremiah 37 in the SBIMS

Jeremiah 37 in the SBIOS

Jeremiah 37 in the SBIPS

Jeremiah 37 in the SBISS

Jeremiah 37 in the SBITS

Jeremiah 37 in the SBITS2

Jeremiah 37 in the SBITS3

Jeremiah 37 in the SBITS4

Jeremiah 37 in the SBIUS

Jeremiah 37 in the SBIVS

Jeremiah 37 in the SBT

Jeremiah 37 in the SBT1E

Jeremiah 37 in the SCHL

Jeremiah 37 in the SNT

Jeremiah 37 in the SUSU

Jeremiah 37 in the SUSU2

Jeremiah 37 in the SYNO

Jeremiah 37 in the TBIAOTANT

Jeremiah 37 in the TBT1E

Jeremiah 37 in the TBT1E2

Jeremiah 37 in the TFTIP

Jeremiah 37 in the TFTU

Jeremiah 37 in the TGNTATF3T

Jeremiah 37 in the THAI

Jeremiah 37 in the TNFD

Jeremiah 37 in the TNT

Jeremiah 37 in the TNTIK

Jeremiah 37 in the TNTIL

Jeremiah 37 in the TNTIN

Jeremiah 37 in the TNTIP

Jeremiah 37 in the TNTIZ

Jeremiah 37 in the TOMA

Jeremiah 37 in the TTENT

Jeremiah 37 in the UBG

Jeremiah 37 in the UGV

Jeremiah 37 in the UGV2

Jeremiah 37 in the UGV3

Jeremiah 37 in the VBL

Jeremiah 37 in the VDCC

Jeremiah 37 in the YALU

Jeremiah 37 in the YAPE

Jeremiah 37 in the YBVTP

Jeremiah 37 in the ZBP