Joshua 14 (BOYCB)
1 Ìwọ̀nyí ni ilẹ̀ tí àwọn ọmọ Israẹli gbà gẹ́gẹ́ bí ogún ní ilẹ̀ Kenaani, tí Eleasari àlùfáà, Joṣua ọmọ Nuni àti olórí ẹ̀yà àwọn agbo ilé Israẹli pín fún wọn. 2 Ìbò ni a fi pín ìní wọn fún àwọn ẹ̀yà mẹ́sàn-án ààbọ̀ gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti pàṣẹ láti ọwọ́ Mose. 3 Mose ti fún àwọn ẹ̀yà méjì àti ààbọ̀ ní ogún wọn ní ìlà-oòrùn Jordani, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Lefi ni kò fi ìní fún ní àárín àwọn tí ó kù. 4 Àwọn ọmọ Josẹfu sì di ẹ̀yà méjì, Manase àti Efraimu. Àwọn ọmọ Lefi kò gba ìpín ní ilẹ̀ náà bí kò ṣe àwọn ìlú tí wọn yóò máa gbé, pẹ̀lú pápá oko tútù fún ọ̀wọ́ ẹran àti agbo ẹran wọn. 5 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ará Israẹli pín ilẹ̀ náà, gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti pàṣẹ fún Mose. 6 Àwọn ọkùnrin Juda wá sí ọ̀dọ̀ Joṣua ní Gilgali. Kalebu ọmọ Jefunne ti Kenissiti wí fún un pé, “Ìwọ rántí ohun tí OLÚWA sọ fún Mose ènìyàn Ọlọ́run ní Kadeṣi-Barnea nípa ìwọ àti èmi. 7 Mo jẹ́ ọmọ ogójì ọdún nígbà tí Mose ìránṣẹ́ OLÚWA rán mi láti Kadeṣi-Barnea lọ rin ilẹ̀ náà wò. Mo sì mú ìròyìn wá fún un gẹ́gẹ́ bí o ti dá mi lójú, 8 ṣùgbọ́n àwọn arákùnrin mi tí wọ́n bá mi lọ mú àyà àwọn ènìyàn já. Ṣùgbọ́n ní tèmi, èmi fi gbogbo ọkàn tẹ̀lé OLÚWA Ọlọ́run mi. 9 Ní ọjọ́ náà, Mose búra fún mi pé, ‘Ilẹ̀ tí ẹsẹ̀ rẹ ti rìn ni yóò jẹ́ ìní rẹ àti ti àwọn ọmọ rẹ láéláé, nítorí pé ìwọ fi tọkàntọkàn wà pẹ̀lú OLÚWA Ọlọ́run mi.’ 10 “Ǹjẹ́ nísinsin yìí, kíyèsi i OLÚWA dá mi sí gẹ́gẹ́ bí ó ti wí, láti ọdún márùndínláàádọ́ta yìí wá, láti ìgbà tí OLÚWA ti sọ ọ̀rọ̀ yìí fún Mose, nígbà tí Israẹli ń rìn kiri nínú aginjù, sì kíyèsi i nísinsin yìí, èmi nìyìí lónìí, ọmọ àrùndínláàdọ́rùn-ún ọdún. 11 Síbẹ̀ èmi ní agbára lónìí, bí ìgbà tí Mose rán mi jáde. Èmi sì ní agbára láti jáde fún ogun nísinsin yìí gẹ́gẹ́ bí mo ti wà ní ìgbà náà. 12 Nísinsin yìí fi ìlú orí òkè fún mi èyí tí OLÚWA ṣe ìlérí fún mi ní ọjọ́ náà. Ìwọ gbọ́ ní ìgbà náà pé àwọn ọmọ Anaki ti wà ní ibẹ̀, àti àwọn ìlú wọn tóbi, pé ó sì ṣe olódi, ṣùgbọ́n bí OLÚWA ba fẹ́, èmi yóò lé wọn jáde, gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ.” 13 Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua súre fun Kalebu ọmọ Jefunne ó si fun un ní Hebroni ni ilẹ̀ ìní. 14 Bẹ́ẹ̀ ni Hebroni jẹ́ ti Kalebu ọmọ Jefunne ará Kenissiti láti ìgbà náà, nítorí tí ó tẹ̀lé OLÚWA Ọlọ́run Israẹli tọkàntọkàn. 15 (Hebroni a sì máa jẹ́ Kiriati-Arba ní ẹ̀yìn Arba, èyí tí ó jẹ́ ènìyàn ńlá nínú àwọn ọmọ Anaki.)Nígbà náà ni ilẹ̀ náà sinmi ogun.
In Other Versions
Joshua 14 in the ANGEFD
Joshua 14 in the ANTPNG2D
Joshua 14 in the AS21
Joshua 14 in the BAGH
Joshua 14 in the BBPNG
Joshua 14 in the BBT1E
Joshua 14 in the BDS
Joshua 14 in the BEV
Joshua 14 in the BHAD
Joshua 14 in the BIB
Joshua 14 in the BLPT
Joshua 14 in the BNT
Joshua 14 in the BNTABOOT
Joshua 14 in the BNTLV
Joshua 14 in the BOATCB
Joshua 14 in the BOATCB2
Joshua 14 in the BOBCV
Joshua 14 in the BOCNT
Joshua 14 in the BOECS
Joshua 14 in the BOGWICC
Joshua 14 in the BOHCB
Joshua 14 in the BOHCV
Joshua 14 in the BOHLNT
Joshua 14 in the BOHNTLTAL
Joshua 14 in the BOICB
Joshua 14 in the BOILNTAP
Joshua 14 in the BOITCV
Joshua 14 in the BOKCV
Joshua 14 in the BOKCV2
Joshua 14 in the BOKHWOG
Joshua 14 in the BOKSSV
Joshua 14 in the BOLCB
Joshua 14 in the BOLCB2
Joshua 14 in the BOMCV
Joshua 14 in the BONAV
Joshua 14 in the BONCB
Joshua 14 in the BONLT
Joshua 14 in the BONUT2
Joshua 14 in the BOPLNT
Joshua 14 in the BOSCB
Joshua 14 in the BOSNC
Joshua 14 in the BOTLNT
Joshua 14 in the BOVCB
Joshua 14 in the BPBB
Joshua 14 in the BPH
Joshua 14 in the BSB
Joshua 14 in the CCB
Joshua 14 in the CUV
Joshua 14 in the CUVS
Joshua 14 in the DBT
Joshua 14 in the DGDNT
Joshua 14 in the DHNT
Joshua 14 in the DNT
Joshua 14 in the ELBE
Joshua 14 in the EMTV
Joshua 14 in the ESV
Joshua 14 in the FBV
Joshua 14 in the FEB
Joshua 14 in the GGMNT
Joshua 14 in the GNT
Joshua 14 in the HARY
Joshua 14 in the HNT
Joshua 14 in the IRVA
Joshua 14 in the IRVB
Joshua 14 in the IRVG
Joshua 14 in the IRVH
Joshua 14 in the IRVK
Joshua 14 in the IRVM
Joshua 14 in the IRVM2
Joshua 14 in the IRVO
Joshua 14 in the IRVP
Joshua 14 in the IRVT
Joshua 14 in the IRVT2
Joshua 14 in the IRVU
Joshua 14 in the ISVN
Joshua 14 in the JSNT
Joshua 14 in the KAPI
Joshua 14 in the KBT1ETNIK
Joshua 14 in the KBV
Joshua 14 in the KJV
Joshua 14 in the KNFD
Joshua 14 in the LBA
Joshua 14 in the LBLA
Joshua 14 in the LNT
Joshua 14 in the LSV
Joshua 14 in the MAAL
Joshua 14 in the MBV
Joshua 14 in the MBV2
Joshua 14 in the MHNT
Joshua 14 in the MKNFD
Joshua 14 in the MNG
Joshua 14 in the MNT
Joshua 14 in the MNT2
Joshua 14 in the MRS1T
Joshua 14 in the NAA
Joshua 14 in the NASB
Joshua 14 in the NBLA
Joshua 14 in the NBS
Joshua 14 in the NBVTP
Joshua 14 in the NET2
Joshua 14 in the NIV11
Joshua 14 in the NNT
Joshua 14 in the NNT2
Joshua 14 in the NNT3
Joshua 14 in the PDDPT
Joshua 14 in the PFNT
Joshua 14 in the RMNT
Joshua 14 in the SBIAS
Joshua 14 in the SBIBS
Joshua 14 in the SBIBS2
Joshua 14 in the SBICS
Joshua 14 in the SBIDS
Joshua 14 in the SBIGS
Joshua 14 in the SBIHS
Joshua 14 in the SBIIS
Joshua 14 in the SBIIS2
Joshua 14 in the SBIIS3
Joshua 14 in the SBIKS
Joshua 14 in the SBIKS2
Joshua 14 in the SBIMS
Joshua 14 in the SBIOS
Joshua 14 in the SBIPS
Joshua 14 in the SBISS
Joshua 14 in the SBITS
Joshua 14 in the SBITS2
Joshua 14 in the SBITS3
Joshua 14 in the SBITS4
Joshua 14 in the SBIUS
Joshua 14 in the SBIVS
Joshua 14 in the SBT
Joshua 14 in the SBT1E
Joshua 14 in the SCHL
Joshua 14 in the SNT
Joshua 14 in the SUSU
Joshua 14 in the SUSU2
Joshua 14 in the SYNO
Joshua 14 in the TBIAOTANT
Joshua 14 in the TBT1E
Joshua 14 in the TBT1E2
Joshua 14 in the TFTIP
Joshua 14 in the TFTU
Joshua 14 in the TGNTATF3T
Joshua 14 in the THAI
Joshua 14 in the TNFD
Joshua 14 in the TNT
Joshua 14 in the TNTIK
Joshua 14 in the TNTIL
Joshua 14 in the TNTIN
Joshua 14 in the TNTIP
Joshua 14 in the TNTIZ
Joshua 14 in the TOMA
Joshua 14 in the TTENT
Joshua 14 in the UBG
Joshua 14 in the UGV
Joshua 14 in the UGV2
Joshua 14 in the UGV3
Joshua 14 in the VBL
Joshua 14 in the VDCC
Joshua 14 in the YALU
Joshua 14 in the YAPE
Joshua 14 in the YBVTP
Joshua 14 in the ZBP