Leviticus 5 (BOYCB)
1 “ ‘Bí ẹnìkan bá dẹ́ṣẹ̀ nítorí pé kò sọ̀rọ̀ nígbà tí a bi í ní gbangba pé kó jẹ́rìí nípa nǹkan tó rí tàbí nǹkan tó mọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ kan, a ó di ẹ̀bi rẹ̀ rù ú. 2 “ ‘Tàbí bí ẹnìkan bá fọwọ́ kan ohun tí a kà sí àìmọ́ yálà òkú ẹranko aláìmọ́ tàbí òkú ẹran ọ̀sìn aláìmọ́ tàbí òkú ẹ̀dá yówù tó ń rìn lórí ilẹ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni náà kò mọ̀, ó ti di aláìmọ́, ó sì ti jẹ̀bi. 3 Tàbí bí ó bá fọwọ́ kan ohun àìmọ́ ti ènìyàn, ohunkóhun tó lè mú ènìyàn di aláìmọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni náà kò mọ̀, nígbà tí ó bá mọ̀ nípa rẹ̀ yóò jẹ̀bi. 4 Tàbí bí ẹni kan bá búra láti ṣe ohun kan láì ronú lé e lórí, yálà ohun tó dára tàbí ohun búburú, nínú ọ̀rọ̀ yówù tó ti búra láì kíyèsi ara, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, kò mọ̀ nípa rẹ̀ tẹ́lẹ̀, bí ó ti wù kó rí, nígbà tó bá mọ̀ yóò jẹ̀bi. 5 Bí ẹnikẹ́ni bá jẹ̀bi ọ̀kan nínú àwọn nǹkan wọ̀nyí, ó gbọdọ̀ jẹ́wọ́ irú ọ̀nà tó ti dẹ́ṣẹ̀ 6 àti pé gẹ́gẹ́ bí ìtánràn fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣẹ̀, ó gbọdọ̀ mú wa fún OLÚWA, abo àgùntàn tàbí abo ewúrẹ́ láti inú agbo ẹran wá gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àlùfáà yóò sì ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣẹ̀. 7 “ ‘Bí kò bá lágbára àti mú ọ̀dọ́-àgùntàn wá, kí ó mú àdàbà méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì fún OLÚWA gẹ́gẹ́ bí ìtánràn fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀—ọ̀kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, èkejì fún ẹbọ sísun. 8 Kí ó kó wọn wá fún àlùfáà tí yóò kọ́kọ́ rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ kí ó yín in lọ́rùn, ṣùgbọ́n kí ó má já orí rẹ̀ tan, 9 kí ó sì wọ́n díẹ̀ lára ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà sí ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ, ìyókù ẹ̀jẹ̀ náà ni kí ó ro sí ìsàlẹ̀ pẹpẹ. Ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni. 10 Lẹ́yìn èyí àlùfáà yóò wá rú ẹbọ sísun gẹ́gẹ́ bí ìlànà, yóò sì ṣe ètùtù fún un nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣẹ̀, a ó sì dáríjì í. 11 “ ‘Bí ó bá sì jẹ́ pé kò ní agbára àti mú àdàbà méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì wá, kí ó mú ìdámẹ́wàá òsùwọ̀n ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára wá fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ, kò gbọdọ̀ fi òróró tàbí tùràrí sí i nítorí pé ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni. 12 Kí ó gbé e wá sí ọ̀dọ̀ àlùfáà, àlùfáà yóò sì bu ẹ̀kúnwọ́ ìyẹ̀fun gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìrántí, kí ó sì sun ún lórí pẹpẹ, gẹ́gẹ́ bí ẹbọ tí a fi iná sun sí OLÚWA. Ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni. 13 Báyìí ni àlùfáà yóò ṣe ètùtù fún ẹni náà fún èyíkéyìí nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá, a ó sì dáríjì í: ìyókù sì jẹ́ ti àlùfáà, bí ẹbọ ohun jíjẹ.’ ” 14 OLÚWA sọ fún Mose pé, 15 “Nígbà tí ẹnìkan bá dẹ́ṣẹ̀ ìrékọjá tí ó sì ṣe láìmọ̀ ní ti àwọn ohun mímọ́ OLÚWA, kí ó mú àgbò láti inú agbo ẹran wá fún OLÚWA gẹ́gẹ́ bí ìtánràn, àgbò tí kò lábùkù tí ó sì níye lórí gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́. Ẹbọ ẹ̀bi ni. 16 Kí ó ṣe àtúnṣe nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti ṣẹ̀ nínú ti àwọn ohun mímọ́, kí ó sì fi ìdámárùn-ún kún iye rẹ̀, kí ó sì kó gbogbo rẹ̀ fún àlùfáà. Àlùfáà yóò sì fi àgbò ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà ṣe ètùtù fún, a ó sì dáríjì í. 17 “Bí ẹnìkan bá dẹ́ṣẹ̀ tí ó sì ṣe ohun tí kó yẹ ko ṣe sí ọ̀kan nínú òfin OLÚWA, bí kò tilẹ̀ mọ̀, ó jẹ̀bi, yóò sì ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ 18 kí ó mú àgbò kan láti inú agbo ẹran wá sọ́dọ̀ àlùfáà, fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àgbò tí kò lábùkù tí ó sì níye lórí bí iye owó ibi mímọ́. Báyìí ni àlùfáà yóò ṣe ètùtù fún ẹni náà, fún àṣìṣe tí ó ṣe láìmọ̀, a ó sì dáríjì í. 19 Ẹbọ ẹ̀bi ni, ó ti jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣẹ̀ sí OLÚWA.”
In Other Versions
Leviticus 5 in the ANGEFD
Leviticus 5 in the ANTPNG2D
Leviticus 5 in the AS21
Leviticus 5 in the BAGH
Leviticus 5 in the BBPNG
Leviticus 5 in the BBT1E
Leviticus 5 in the BDS
Leviticus 5 in the BEV
Leviticus 5 in the BHAD
Leviticus 5 in the BIB
Leviticus 5 in the BLPT
Leviticus 5 in the BNT
Leviticus 5 in the BNTABOOT
Leviticus 5 in the BNTLV
Leviticus 5 in the BOATCB
Leviticus 5 in the BOATCB2
Leviticus 5 in the BOBCV
Leviticus 5 in the BOCNT
Leviticus 5 in the BOECS
Leviticus 5 in the BOGWICC
Leviticus 5 in the BOHCB
Leviticus 5 in the BOHCV
Leviticus 5 in the BOHLNT
Leviticus 5 in the BOHNTLTAL
Leviticus 5 in the BOICB
Leviticus 5 in the BOILNTAP
Leviticus 5 in the BOITCV
Leviticus 5 in the BOKCV
Leviticus 5 in the BOKCV2
Leviticus 5 in the BOKHWOG
Leviticus 5 in the BOKSSV
Leviticus 5 in the BOLCB
Leviticus 5 in the BOLCB2
Leviticus 5 in the BOMCV
Leviticus 5 in the BONAV
Leviticus 5 in the BONCB
Leviticus 5 in the BONLT
Leviticus 5 in the BONUT2
Leviticus 5 in the BOPLNT
Leviticus 5 in the BOSCB
Leviticus 5 in the BOSNC
Leviticus 5 in the BOTLNT
Leviticus 5 in the BOVCB
Leviticus 5 in the BPBB
Leviticus 5 in the BPH
Leviticus 5 in the BSB
Leviticus 5 in the CCB
Leviticus 5 in the CUV
Leviticus 5 in the CUVS
Leviticus 5 in the DBT
Leviticus 5 in the DGDNT
Leviticus 5 in the DHNT
Leviticus 5 in the DNT
Leviticus 5 in the ELBE
Leviticus 5 in the EMTV
Leviticus 5 in the ESV
Leviticus 5 in the FBV
Leviticus 5 in the FEB
Leviticus 5 in the GGMNT
Leviticus 5 in the GNT
Leviticus 5 in the HARY
Leviticus 5 in the HNT
Leviticus 5 in the IRVA
Leviticus 5 in the IRVB
Leviticus 5 in the IRVG
Leviticus 5 in the IRVH
Leviticus 5 in the IRVK
Leviticus 5 in the IRVM
Leviticus 5 in the IRVM2
Leviticus 5 in the IRVO
Leviticus 5 in the IRVP
Leviticus 5 in the IRVT
Leviticus 5 in the IRVT2
Leviticus 5 in the IRVU
Leviticus 5 in the ISVN
Leviticus 5 in the JSNT
Leviticus 5 in the KAPI
Leviticus 5 in the KBT1ETNIK
Leviticus 5 in the KBV
Leviticus 5 in the KJV
Leviticus 5 in the KNFD
Leviticus 5 in the LBA
Leviticus 5 in the LBLA
Leviticus 5 in the LNT
Leviticus 5 in the LSV
Leviticus 5 in the MAAL
Leviticus 5 in the MBV
Leviticus 5 in the MBV2
Leviticus 5 in the MHNT
Leviticus 5 in the MKNFD
Leviticus 5 in the MNG
Leviticus 5 in the MNT
Leviticus 5 in the MNT2
Leviticus 5 in the MRS1T
Leviticus 5 in the NAA
Leviticus 5 in the NASB
Leviticus 5 in the NBLA
Leviticus 5 in the NBS
Leviticus 5 in the NBVTP
Leviticus 5 in the NET2
Leviticus 5 in the NIV11
Leviticus 5 in the NNT
Leviticus 5 in the NNT2
Leviticus 5 in the NNT3
Leviticus 5 in the PDDPT
Leviticus 5 in the PFNT
Leviticus 5 in the RMNT
Leviticus 5 in the SBIAS
Leviticus 5 in the SBIBS
Leviticus 5 in the SBIBS2
Leviticus 5 in the SBICS
Leviticus 5 in the SBIDS
Leviticus 5 in the SBIGS
Leviticus 5 in the SBIHS
Leviticus 5 in the SBIIS
Leviticus 5 in the SBIIS2
Leviticus 5 in the SBIIS3
Leviticus 5 in the SBIKS
Leviticus 5 in the SBIKS2
Leviticus 5 in the SBIMS
Leviticus 5 in the SBIOS
Leviticus 5 in the SBIPS
Leviticus 5 in the SBISS
Leviticus 5 in the SBITS
Leviticus 5 in the SBITS2
Leviticus 5 in the SBITS3
Leviticus 5 in the SBITS4
Leviticus 5 in the SBIUS
Leviticus 5 in the SBIVS
Leviticus 5 in the SBT
Leviticus 5 in the SBT1E
Leviticus 5 in the SCHL
Leviticus 5 in the SNT
Leviticus 5 in the SUSU
Leviticus 5 in the SUSU2
Leviticus 5 in the SYNO
Leviticus 5 in the TBIAOTANT
Leviticus 5 in the TBT1E
Leviticus 5 in the TBT1E2
Leviticus 5 in the TFTIP
Leviticus 5 in the TFTU
Leviticus 5 in the TGNTATF3T
Leviticus 5 in the THAI
Leviticus 5 in the TNFD
Leviticus 5 in the TNT
Leviticus 5 in the TNTIK
Leviticus 5 in the TNTIL
Leviticus 5 in the TNTIN
Leviticus 5 in the TNTIP
Leviticus 5 in the TNTIZ
Leviticus 5 in the TOMA
Leviticus 5 in the TTENT
Leviticus 5 in the UBG
Leviticus 5 in the UGV
Leviticus 5 in the UGV2
Leviticus 5 in the UGV3
Leviticus 5 in the VBL
Leviticus 5 in the VDCC
Leviticus 5 in the YALU
Leviticus 5 in the YAPE
Leviticus 5 in the YBVTP
Leviticus 5 in the ZBP