Nehemiah 11 (BOYCB)

1 Nísinsin yìí àwọn olórí àwọn ènìyàn tẹ̀dó sí Jerusalẹmu, àwọn ènìyàn tókù sì dìbò láti mú ẹnìkọ̀ọ̀kan jáde nínú àwọn mẹ́wàá mẹ́wàá láti máa gbé ní Jerusalẹmu, ìlú mímọ́, nígbà tí àwọn mẹ́sàn-án tókù yóò dúró sí àwọn ìlú u wọn. 2 Àwọn ènìyàn súre fún gbogbo àwọn ọkùnrin tí wọ́n jọ̀wọ́ ara wọn láti gbé ní Jerusalẹmu. 3 Wọ̀nyí ni àwọn olórí agbègbè ìjọba tí wọ́n tẹ̀dó sí Jerusalẹmu (díẹ̀ nínú àwọn ọmọ Israẹli àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Lefi, àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili àti àwọn ìran àwọn ìránṣẹ́ Solomoni ń gbé àwọn ìlú Juda, olúkúlùkù ń gbé lórí ilẹ̀ ìní rẹ̀ ní àwọn ìlú náà. 4 Nígbà tí àwọn ènìyàn tókù nínú àwọn Juda àti Benjamini ń gbé ní Jerusalẹmu). Nínú àwọn ọmọ Juda:Ataiah ọmọ Ussiah ọmọ Sekariah, ọmọ Amariah, ọmọ Ṣefatia, ọmọ Mahalaleli, ìran Peresi; 5 àti Maaseiah ọmọ Baruku, ọmọ Koli-Hose, ọmọ Hasaiah, ọmọ Adaiah, ọmọ Joiaribu, ọmọ Sekariah, ọmọ Ṣilo. 6 Àwọn ìran Peresi tó gbé ní Jerusalẹmu jẹ́ àádọ́rinlénírinwó ó dín méjì (468) alágbára ọkùnrin. 7 Nínú àwọn ìran Benjamini:Sallu ọmọ Meṣullamu, ọmọ Joẹdi, ọmọ Pedaiah, ọmọ Kolaiah, ọmọ Maaseiah, ọmọ Itieli, ọmọ Jeṣaiah, 8 àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Gabbai àti Sallai jẹ́ ọ̀rìndínlẹ́gbẹ̀rún ó lé mẹ́jọ (928) ọkùnrin. 9 Joẹli ọmọ Sikri ni olórí òṣìṣẹ́ wọn, Juda ọmọ Hasenuah sì ni olórí agbègbè kejì ní ìlú náà. 10 Nínú àwọn àlùfáà:Jedaiah; ọmọ Joiaribu; Jakini; 11 Seraiah ọmọ Hilkiah, ọmọ Meṣullamu, ọmọ Sadoku, ọmọ Meraioti, ọmọ Ahitubu, àwọn ni olórí tó ń bojútó ilé Ọlọ́run, 12 àti àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn, ẹni tí ó ń ṣe iṣẹ́ ní tẹmpili jẹ́ ẹgbẹ̀rin ó lé mẹ́rìnlélógún (822) ọkùnrin:Adaiah ọmọ Jerohamu, ọmọ Pelaiah, ọmọ Amisi, ọmọ Sekariah, ọmọ Paṣuri, ọmọ Malkiah, 13 àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ olórí ìdílé jẹ́ òjìlúgba ó lé méjì (242) ọkùnrin:Amaṣai ọmọ Asareeli, ọmọ Ahsai, ọmọ Meṣilemoti, ọmọ Immeri, 14 àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ alágbára ọkùnrin jẹ́ méjìdínláàádóje (128).Olórí òṣìṣẹ́ ẹ wọn ni Sabdieli ọmọ Hagedolimu. 15 Láti inú àwọn ọmọ Lefi:Ṣemaiah ọmọ Haṣubu, ọmọ Asrikamu, ọmọ Haṣabiah ọmọ Bunni; 16 Ṣabbetai àti Josabadi, olórí méjì nínú àwọn ọmọ Lefi, àwọn tí ó jẹ́ alábojútó iṣẹ́ tí ó wà ní ẹ̀yìn àgbàlá ilé Ọlọ́run; 17 Mattaniah ọmọ Mika, ọmọ Sabdi, ọmọ Asafu, adarí tí ó ń ṣáájú ìdúpẹ́ àti àdúrà;Bakbukiah ẹnìkejì láàrín àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀;àti Abida ọmọ Ṣammua, ọmọ Galali, ọmọ Jedutuni. 18 Àwọn ọmọ Lefi nínú ìlú mímọ́ jẹ́ ọ̀rìnlélúgba ó lé mẹ́rin (284). 19 Àwọn aṣọ́nà:Akkubu, Talmoni, àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn, tí wọ́n máa ń ṣọ́nà jẹ́ méjìléláàádọ́sàn-án (172) ọkùnrin. 20 Àwọn tókù nínú àwọn ọmọ Israẹli, pẹ̀lú àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi, wà ní gbogbo ìlú u Juda, olúkúlùkù lórí ilẹ̀ ìní tirẹ̀. 21 Àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili ń gbé lórí òkè Ofeli, Siha àti Giṣpa sì ni alábojútó wọn. 22 Olórí òṣìṣẹ́ àwọn ọmọ Lefi ní Jerusalẹmu ní Ussi ọmọ Bani, ọmọ Haṣabiah, ọmọ Mattaniah ọmọ Mika. Ussi jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìran Asafu tí wọ́n jẹ́ akọrin ojúṣe nínú ìjọ́sìn ní ilé Ọlọ́run. 23 Àwọn akọrin wà ní abẹ́ àṣẹ ọba, èyí tí ó n díwọ̀n iṣẹ́ ojoojúmọ́ wọn. 24 Petahiah ọmọ Meṣesabeli, ọ̀kan nínú àwọn Sera ọmọ Juda ní aṣojú ọba nínú ohun gbogbo tí ó jẹ mọ́ ti àwọn ènìyàn náà. 25 Fún ìletò pẹ̀lú oko wọn, díẹ̀ nínú àwọn ènìyàn Juda tí ń gbé Kiriati-Arba, àti àwọn ìletò agbègbè e rẹ̀, ní Diboni àti ìletò rẹ̀, ní Jekabseeli. 26 Ní Jeṣua, ní Molada, ní Beti-Peleti 27 ní Hasari-Ṣuali, ní Beerṣeba àti àwọn agbègbè rẹ̀. 28 Ní Siklagi, ní Mekona àti àwọn ìletò rẹ̀, 29 ní Ẹni-Rimoni, ní Sora, ní Jarmatu, 30 Sanoa, Adullamu àti àwọn ìletò o wọn, ní Lakiṣi àti àwọn oko rẹ̀, àti ní Aseka àti àwọn ìletò rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń gbé láti Beerṣeba títí dé àfonífojì Hinnomu. 31 Àwọn ọmọ Benjamini láti Geba ń gbé ní Mikmasi, Aija, Beteli àti àwọn ìletò rẹ̀. 32 Ní Anatoti, Nobu àti Ananiah, 33 ní Hasori Rama àti Gittaimu, 34 ní Hadidi, Seboimu àti Neballati, 35 ní Lodi àti Ono, àti ní àfonífojì àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà. 36 Nínú ìpín àwọn ọmọ Lefi ni Juda tẹ̀dó sí Benjamini.

In Other Versions

Nehemiah 11 in the ANGEFD

Nehemiah 11 in the ANTPNG2D

Nehemiah 11 in the AS21

Nehemiah 11 in the BAGH

Nehemiah 11 in the BBPNG

Nehemiah 11 in the BBT1E

Nehemiah 11 in the BDS

Nehemiah 11 in the BEV

Nehemiah 11 in the BHAD

Nehemiah 11 in the BIB

Nehemiah 11 in the BLPT

Nehemiah 11 in the BNT

Nehemiah 11 in the BNTABOOT

Nehemiah 11 in the BNTLV

Nehemiah 11 in the BOATCB

Nehemiah 11 in the BOATCB2

Nehemiah 11 in the BOBCV

Nehemiah 11 in the BOCNT

Nehemiah 11 in the BOECS

Nehemiah 11 in the BOGWICC

Nehemiah 11 in the BOHCB

Nehemiah 11 in the BOHCV

Nehemiah 11 in the BOHLNT

Nehemiah 11 in the BOHNTLTAL

Nehemiah 11 in the BOICB

Nehemiah 11 in the BOILNTAP

Nehemiah 11 in the BOITCV

Nehemiah 11 in the BOKCV

Nehemiah 11 in the BOKCV2

Nehemiah 11 in the BOKHWOG

Nehemiah 11 in the BOKSSV

Nehemiah 11 in the BOLCB

Nehemiah 11 in the BOLCB2

Nehemiah 11 in the BOMCV

Nehemiah 11 in the BONAV

Nehemiah 11 in the BONCB

Nehemiah 11 in the BONLT

Nehemiah 11 in the BONUT2

Nehemiah 11 in the BOPLNT

Nehemiah 11 in the BOSCB

Nehemiah 11 in the BOSNC

Nehemiah 11 in the BOTLNT

Nehemiah 11 in the BOVCB

Nehemiah 11 in the BPBB

Nehemiah 11 in the BPH

Nehemiah 11 in the BSB

Nehemiah 11 in the CCB

Nehemiah 11 in the CUV

Nehemiah 11 in the CUVS

Nehemiah 11 in the DBT

Nehemiah 11 in the DGDNT

Nehemiah 11 in the DHNT

Nehemiah 11 in the DNT

Nehemiah 11 in the ELBE

Nehemiah 11 in the EMTV

Nehemiah 11 in the ESV

Nehemiah 11 in the FBV

Nehemiah 11 in the FEB

Nehemiah 11 in the GGMNT

Nehemiah 11 in the GNT

Nehemiah 11 in the HARY

Nehemiah 11 in the HNT

Nehemiah 11 in the IRVA

Nehemiah 11 in the IRVB

Nehemiah 11 in the IRVG

Nehemiah 11 in the IRVH

Nehemiah 11 in the IRVK

Nehemiah 11 in the IRVM

Nehemiah 11 in the IRVM2

Nehemiah 11 in the IRVO

Nehemiah 11 in the IRVP

Nehemiah 11 in the IRVT

Nehemiah 11 in the IRVT2

Nehemiah 11 in the IRVU

Nehemiah 11 in the ISVN

Nehemiah 11 in the JSNT

Nehemiah 11 in the KAPI

Nehemiah 11 in the KBT1ETNIK

Nehemiah 11 in the KBV

Nehemiah 11 in the KJV

Nehemiah 11 in the KNFD

Nehemiah 11 in the LBA

Nehemiah 11 in the LBLA

Nehemiah 11 in the LNT

Nehemiah 11 in the LSV

Nehemiah 11 in the MAAL

Nehemiah 11 in the MBV

Nehemiah 11 in the MBV2

Nehemiah 11 in the MHNT

Nehemiah 11 in the MKNFD

Nehemiah 11 in the MNG

Nehemiah 11 in the MNT

Nehemiah 11 in the MNT2

Nehemiah 11 in the MRS1T

Nehemiah 11 in the NAA

Nehemiah 11 in the NASB

Nehemiah 11 in the NBLA

Nehemiah 11 in the NBS

Nehemiah 11 in the NBVTP

Nehemiah 11 in the NET2

Nehemiah 11 in the NIV11

Nehemiah 11 in the NNT

Nehemiah 11 in the NNT2

Nehemiah 11 in the NNT3

Nehemiah 11 in the PDDPT

Nehemiah 11 in the PFNT

Nehemiah 11 in the RMNT

Nehemiah 11 in the SBIAS

Nehemiah 11 in the SBIBS

Nehemiah 11 in the SBIBS2

Nehemiah 11 in the SBICS

Nehemiah 11 in the SBIDS

Nehemiah 11 in the SBIGS

Nehemiah 11 in the SBIHS

Nehemiah 11 in the SBIIS

Nehemiah 11 in the SBIIS2

Nehemiah 11 in the SBIIS3

Nehemiah 11 in the SBIKS

Nehemiah 11 in the SBIKS2

Nehemiah 11 in the SBIMS

Nehemiah 11 in the SBIOS

Nehemiah 11 in the SBIPS

Nehemiah 11 in the SBISS

Nehemiah 11 in the SBITS

Nehemiah 11 in the SBITS2

Nehemiah 11 in the SBITS3

Nehemiah 11 in the SBITS4

Nehemiah 11 in the SBIUS

Nehemiah 11 in the SBIVS

Nehemiah 11 in the SBT

Nehemiah 11 in the SBT1E

Nehemiah 11 in the SCHL

Nehemiah 11 in the SNT

Nehemiah 11 in the SUSU

Nehemiah 11 in the SUSU2

Nehemiah 11 in the SYNO

Nehemiah 11 in the TBIAOTANT

Nehemiah 11 in the TBT1E

Nehemiah 11 in the TBT1E2

Nehemiah 11 in the TFTIP

Nehemiah 11 in the TFTU

Nehemiah 11 in the TGNTATF3T

Nehemiah 11 in the THAI

Nehemiah 11 in the TNFD

Nehemiah 11 in the TNT

Nehemiah 11 in the TNTIK

Nehemiah 11 in the TNTIL

Nehemiah 11 in the TNTIN

Nehemiah 11 in the TNTIP

Nehemiah 11 in the TNTIZ

Nehemiah 11 in the TOMA

Nehemiah 11 in the TTENT

Nehemiah 11 in the UBG

Nehemiah 11 in the UGV

Nehemiah 11 in the UGV2

Nehemiah 11 in the UGV3

Nehemiah 11 in the VBL

Nehemiah 11 in the VDCC

Nehemiah 11 in the YALU

Nehemiah 11 in the YAPE

Nehemiah 11 in the YBVTP

Nehemiah 11 in the ZBP