Numbers 19 (BOYCB)

1 OLÚWA sọ fún Mose àti Aaroni pé, 2 “Èyí ni ohun tí òfin OLÚWA pàṣẹ béèrè lọ́wọ́ yín. Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli, kí wọn mú ẹgbọrọ ọ̀dọ́ màlúù pupa tí kò lábùkù tàbí àbàwọ́n, lára èyí tí a kò tí ì di àjàgà mọ́. 3 Ẹ mú fún Eleasari àlùfáà, yóò sì mu jáde lọ sí ẹ̀yìn ibùdó kí ó sì pa á ní ojú rẹ. 4 Nígbà náà ni Eleasari àlùfáà yóò mú lára ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sórí ìka ọwọ́ rẹ̀ yóò sì wọn lẹ́ẹ̀méje ní ọ̀kánkán iwájú àgọ́ ìpàdé. 5 Ní ojú rẹ̀ ni àlùfáà yóò ti sun ọ̀dọ́ abo màlúù yìí: awọ ara rẹ̀, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ẹran-ara àti ìgbẹ́ rẹ̀. 6 Àlùfáà yóò mú igi kedari, hísópù àti òwú òdòdó yóò sì jù wọ́n sí àárín ọ̀dọ́ abo màlúù tí a ń sun. 7 Lẹ́yìn náà, àlùfáà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ ara rẹ̀ pẹ̀lú omi lẹ́yìn náà ó lè wá sínú àgọ́. Ṣùgbọ́n yóò jẹ́ aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́. 8 Ẹni tí ó sun ún náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀ kí ó sì wẹ̀ pẹ̀lú omi, òun náà yóò jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. 9 “Ẹni tó wà ní mímọ́ ni yóò kó eérú ọ̀dọ́ màlúù náà lọ sí ibi tí a yà sí mímọ́ lẹ́yìn ibùdó. Kí gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli kó o pamọ́ fún lílò fún omi ìwẹ̀nùmọ́. Ó jẹ́ ìwẹ̀nùmọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀. 10 Ọkùnrin tí ó kó eérú ọ̀dọ́ abo màlúù náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, òun náà yóò sì jẹ́ aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́. Èyí ni yóò jẹ́ ìlànà láéláé fún àwọn ọmọ Israẹli àti fún àwọn àjèjì tí ó ń gbé láàrín wọn. 11 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan òkú ẹnikẹ́ni, yóò jẹ́ aláìmọ́ fún ọjọ́ méje. 12 Ó gbọdọ̀ wẹ ara rẹ̀ pẹ̀lú omi ní ọjọ́ kẹta àti ní ọjọ́ keje; nígbà náà ni yóò jẹ́ mímọ́. Ṣùgbọ́n tí ó bá jẹ́ pé kò wẹ ara rẹ̀ mọ́ ní ọjọ́ kẹta àti ní ọjọ́ keje yóò jẹ́ aláìmọ́. 13 Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan òkú ẹnìkan tí kò sì wẹ ara rẹ̀ mọ́, ó ba àgọ́ OLÚWA jẹ́. A ó ké irú ẹni bẹ́ẹ̀ kúrò lára àwọn ọmọ Israẹli. Nítorí pé a kò tí ì wọ́n omi ìwẹ̀nùmọ́ lé e lórí, ó jẹ́ aláìmọ́, àìmọ́ rẹ̀ sì wà lára rẹ̀. 14 “Èyí ni òfin tí ó jẹ mọ́ bí ènìyàn bá kú nínú àgọ́, ẹnikẹ́ni tí ó bá wọ inú àgọ́ àti ẹni tí ó wà nínú àgọ́ yóò di aláìmọ́ fún ọjọ́ méje, 15 gbogbo ohun èlò tí a kò bá fi omọrí dé ni yóò jẹ́ aláìmọ́. 16 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá wà ní ìta tí ó sì fi ọwọ́ kan ẹni tí a fi idà pa tàbí ẹni tí ó kú ikú àtọ̀runwá, tàbí bí ẹnìkan bá fi ọwọ́ kan egungun òkú ènìyàn tàbí isà òkú, yóò jẹ́ aláìmọ́ fún ọjọ́ méje. 17 “Fún aláìmọ́ ènìyàn, mú eérú díẹ̀ lára eérú ọrẹ ìwẹ̀nùmọ́ sínú ìgò, kí o sì da omi tó ń sàn lé e lórí. 18 Nígbà náà, ọkùnrin tí a yà sí mímọ́ yóò mú hísópù díẹ̀ yóò rì í sínú omi yóò sì fi wọ́n àgọ́ àti gbogbo ohun èlò tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ àti àwọn ènìyàn tí ó wà níbẹ̀. O gbọdọ̀ tún fi wọ́n ẹnikẹ́ni tí ó fi ọwọ́ kan egungun òkú ènìyàn tàbí isà òkú, tàbí ẹni tí ó kú ikú ara rẹ̀, tàbí ẹni tí ó kú ikú àti ọ̀run wá. 19 Ọkùnrin tí ó mọ́ ni kí ó bu omi wọ́n àwọn ènìyàn aláìmọ́ ní ọjọ́ kẹta àti ọjọ́ keje, ní ọjọ́ keje ó gbọdọ̀ wẹ ara rẹ̀ mọ́. Ẹni tí a wẹ̀mọ́ gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀ kí ó sì wẹ̀ pẹ̀lú omi, ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà yóò mọ́. 20 Ṣùgbọ́n bí ẹni tí ó bá jẹ́ aláìmọ́ kò bá wẹ ara rẹ̀ mọ́, a gbọdọ̀ gé e kúrò nínú ìjọ ènìyàn, nítorí wí pé ó ti ba àgọ́ OLÚWA jẹ́. A kò tí ì fi omi ìwẹ̀nùmọ́ sí ara rẹ̀, ó sì jẹ́ aláìmọ́. 21 Èyí jẹ́ ìlànà láéláé fún wọn.“Ọkùnrin tí ó wọ́n omi ìwẹ̀nùmọ́ náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀ àti ẹnikẹ́ni tí ó fi ọwọ́ kan omi ìwẹ̀nùmọ́ yóò di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. 22 Gbogbo ohun tí ẹni tí ó jẹ́ aláìmọ́ bá fi ọwọ́ kàn yóò di àìmọ́, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì fi ọwọ́ kàn án yóò jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.”

In Other Versions

Numbers 19 in the ANGEFD

Numbers 19 in the ANTPNG2D

Numbers 19 in the AS21

Numbers 19 in the BAGH

Numbers 19 in the BBPNG

Numbers 19 in the BBT1E

Numbers 19 in the BDS

Numbers 19 in the BEV

Numbers 19 in the BHAD

Numbers 19 in the BIB

Numbers 19 in the BLPT

Numbers 19 in the BNT

Numbers 19 in the BNTABOOT

Numbers 19 in the BNTLV

Numbers 19 in the BOATCB

Numbers 19 in the BOATCB2

Numbers 19 in the BOBCV

Numbers 19 in the BOCNT

Numbers 19 in the BOECS

Numbers 19 in the BOGWICC

Numbers 19 in the BOHCB

Numbers 19 in the BOHCV

Numbers 19 in the BOHLNT

Numbers 19 in the BOHNTLTAL

Numbers 19 in the BOICB

Numbers 19 in the BOILNTAP

Numbers 19 in the BOITCV

Numbers 19 in the BOKCV

Numbers 19 in the BOKCV2

Numbers 19 in the BOKHWOG

Numbers 19 in the BOKSSV

Numbers 19 in the BOLCB

Numbers 19 in the BOLCB2

Numbers 19 in the BOMCV

Numbers 19 in the BONAV

Numbers 19 in the BONCB

Numbers 19 in the BONLT

Numbers 19 in the BONUT2

Numbers 19 in the BOPLNT

Numbers 19 in the BOSCB

Numbers 19 in the BOSNC

Numbers 19 in the BOTLNT

Numbers 19 in the BOVCB

Numbers 19 in the BPBB

Numbers 19 in the BPH

Numbers 19 in the BSB

Numbers 19 in the CCB

Numbers 19 in the CUV

Numbers 19 in the CUVS

Numbers 19 in the DBT

Numbers 19 in the DGDNT

Numbers 19 in the DHNT

Numbers 19 in the DNT

Numbers 19 in the ELBE

Numbers 19 in the EMTV

Numbers 19 in the ESV

Numbers 19 in the FBV

Numbers 19 in the FEB

Numbers 19 in the GGMNT

Numbers 19 in the GNT

Numbers 19 in the HARY

Numbers 19 in the HNT

Numbers 19 in the IRVA

Numbers 19 in the IRVB

Numbers 19 in the IRVG

Numbers 19 in the IRVH

Numbers 19 in the IRVK

Numbers 19 in the IRVM

Numbers 19 in the IRVM2

Numbers 19 in the IRVO

Numbers 19 in the IRVP

Numbers 19 in the IRVT

Numbers 19 in the IRVT2

Numbers 19 in the IRVU

Numbers 19 in the ISVN

Numbers 19 in the JSNT

Numbers 19 in the KAPI

Numbers 19 in the KBT1ETNIK

Numbers 19 in the KBV

Numbers 19 in the KJV

Numbers 19 in the KNFD

Numbers 19 in the LBA

Numbers 19 in the LBLA

Numbers 19 in the LNT

Numbers 19 in the LSV

Numbers 19 in the MAAL

Numbers 19 in the MBV

Numbers 19 in the MBV2

Numbers 19 in the MHNT

Numbers 19 in the MKNFD

Numbers 19 in the MNG

Numbers 19 in the MNT

Numbers 19 in the MNT2

Numbers 19 in the MRS1T

Numbers 19 in the NAA

Numbers 19 in the NASB

Numbers 19 in the NBLA

Numbers 19 in the NBS

Numbers 19 in the NBVTP

Numbers 19 in the NET2

Numbers 19 in the NIV11

Numbers 19 in the NNT

Numbers 19 in the NNT2

Numbers 19 in the NNT3

Numbers 19 in the PDDPT

Numbers 19 in the PFNT

Numbers 19 in the RMNT

Numbers 19 in the SBIAS

Numbers 19 in the SBIBS

Numbers 19 in the SBIBS2

Numbers 19 in the SBICS

Numbers 19 in the SBIDS

Numbers 19 in the SBIGS

Numbers 19 in the SBIHS

Numbers 19 in the SBIIS

Numbers 19 in the SBIIS2

Numbers 19 in the SBIIS3

Numbers 19 in the SBIKS

Numbers 19 in the SBIKS2

Numbers 19 in the SBIMS

Numbers 19 in the SBIOS

Numbers 19 in the SBIPS

Numbers 19 in the SBISS

Numbers 19 in the SBITS

Numbers 19 in the SBITS2

Numbers 19 in the SBITS3

Numbers 19 in the SBITS4

Numbers 19 in the SBIUS

Numbers 19 in the SBIVS

Numbers 19 in the SBT

Numbers 19 in the SBT1E

Numbers 19 in the SCHL

Numbers 19 in the SNT

Numbers 19 in the SUSU

Numbers 19 in the SUSU2

Numbers 19 in the SYNO

Numbers 19 in the TBIAOTANT

Numbers 19 in the TBT1E

Numbers 19 in the TBT1E2

Numbers 19 in the TFTIP

Numbers 19 in the TFTU

Numbers 19 in the TGNTATF3T

Numbers 19 in the THAI

Numbers 19 in the TNFD

Numbers 19 in the TNT

Numbers 19 in the TNTIK

Numbers 19 in the TNTIL

Numbers 19 in the TNTIN

Numbers 19 in the TNTIP

Numbers 19 in the TNTIZ

Numbers 19 in the TOMA

Numbers 19 in the TTENT

Numbers 19 in the UBG

Numbers 19 in the UGV

Numbers 19 in the UGV2

Numbers 19 in the UGV3

Numbers 19 in the VBL

Numbers 19 in the VDCC

Numbers 19 in the YALU

Numbers 19 in the YAPE

Numbers 19 in the YBVTP

Numbers 19 in the ZBP