Numbers 28 (BOYCB)
1 OLÚWA sọ fún Mose pé, 2 “Fún àwọn ọmọ Israẹli ní òfin yìí kí o sì wí fún wọn pé: ‘Ẹ rí i wí pé ẹ gbé e wá sí iwájú mi ní àkókò tí a ti yàn, oúnjẹ ọrẹ ẹbọ mi tí a fi iná ṣe sí mi, gẹ́gẹ́ bí òórùn dídùn sí mi.’ 3 Sọ fún wọn, ‘Èyí ní ọrẹ ẹbọ tí a fi iná sun tí ẹ gbọdọ̀ mú wá fún OLÚWA: akọ ọ̀dọ́-àgùntàn méjì ọlọ́dún kan aláìlábàwọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sísun ní ojoojúmọ́. 4 Pèsè ọ̀dọ́-àgùntàn kan ní òwúrọ̀ àti òmíràn ní àfẹ̀mọ́júmọ́. 5 Pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ tí ó jẹ́ ìdámẹ́wàá efa ìyẹ̀fun dáradára tí a pò mọ́ ìdámẹ́rin hínì òróró tí a yọ lára Olifi. 6 Èyí ni ẹbọ sísun gbogbo ìgbà tí a fi lélẹ̀ ní òkè Sinai gẹ́gẹ́ bí olóòórùn dídùn ẹbọ tí a fi iná sun fún OLÚWA pẹ̀lú iná. 7 Àfikún ọrẹ ohun mímu rẹ gbọdọ̀ jẹ́ ìdámẹ́rin ti hínì dídé omi mímu tí ó kan pẹ̀lú ọ̀kọ̀ọ̀kan ọ̀dọ́-àgùntàn. Da ẹbọ mímu náà síta sí OLÚWA ní ibi mímọ́. 8 Pèsè ọ̀dọ́-àgùntàn kejì ní àfẹ̀mọ́júmọ́, pẹ̀lú oríṣìí ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu èyí tí ó pèsè ní òwúrọ̀, èyí ni ẹbọ tí a fi iná ṣe, olóòórùn dídùn sí OLÚWA. 9 “ ‘Ní ọjọ́ ìsinmi, pèsè akọ ọ̀dọ́-àgùntàn méjì ọlọ́dún kan tí kò lábùkù, pẹ̀lú ẹbọ ohun mímu àti ẹbọ ohun jíjẹ tí i ṣe ìdá méjì nínú ìdámẹ́wàá òsùwọ̀n ìyẹ̀fun tí a fi òróró pò. 10 Èyí ni ẹbọ sísun fún gbogbo ọjọ́ ìsinmi kọ̀ọ̀kan, ní àfikún pẹ̀lú ẹbọ sísun àti ẹbọ ohun mímu. 11 “ ‘Àti ní ọjọ́ tí o bẹ̀rẹ̀ oṣù kọ̀ọ̀kan, kí ẹ̀yin kí ó gbé ẹbọ sísun fún OLÚWA pẹ̀lú ọ̀dọ́ akọ màlúù méjì, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn méje ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan, kí gbogbo rẹ̀ sì jẹ́ aláìlábùkù. 12 Pẹ̀lú akọ màlúù kọ̀ọ̀kan ni kí wọn ó rú ẹbọ ohun jíjẹ ẹbọ ìdámẹ́ta nínú mẹ́wàá ìyẹ̀fun tí a pòpọ̀ pẹ̀lú òróró; pẹ̀lú àgbò, ni kí wọn ó rú ẹbọ ohun jíjẹ tí í ṣe ìdá méjì nínú mẹ́wàá òsùwọ̀n ìyẹ̀fun tí a pòpọ̀ mọ́ òróró; 13 pẹ̀lú ọ̀kọ̀ọ̀kan ọ̀dọ́-àgùntàn, ni kí ẹ rú ẹbọ ìyẹ̀fun ìyẹ̀fun kíkúnná tí a pò mọ́ òróró. Èyí ni ẹbọ sísun, òórùn dídùn, àti ẹbọ tí a ṣe fún OLÚWA pẹ̀lú iná. 14 Kí ẹbọ ohun mímu wọn jẹ́ ààbọ̀ òsùwọ̀n hínì ti ọtí wáìnì, fún akọ màlúù kan, àti ìdámẹ́wàá òsùwọ̀n hínì fún àgbò kan àti ìdámẹ́rin òsùwọ̀n hínì fún ọ̀dọ́-àgùntàn kan. Èyí ni ẹbọ sísun tí wọn ó máa rú ní oṣù kọ̀ọ̀kan nínú ọdún. 15 Yàtọ̀ sí ẹbọ sísun pẹ̀lú ẹbọ ohun mímu, ẹ gbọdọ̀ fi akọ ewúrẹ́ kọ̀ọ̀kan fún OLÚWA gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. 16 “ ‘Ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìn-ín-ní ni ìrékọjá OLÚWA gbọdọ̀ wáyé. 17 Ní ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù yìí ẹ gbọdọ̀ ṣiṣẹ́ àjọ̀dún fún ọjọ́ méje kí ó jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà. 18 Ní ọjọ́ kìn-ín-ní kí àpéjọ mímọ́ kí ó wà; ẹ́yin kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ agbára kankan. 19 Ẹ rú ẹbọ sísun sí OLÚWA, ẹ rú u pẹ̀lú ọ̀dọ́ màlúù méjì akọ, ẹbọ sísun pẹ̀lú iná àgbò kan àti ọ̀dọ́-àgùntàn méje ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan kí wọn kí ó jẹ́ aláìlábùkù. 20 Pẹ̀lú akọ màlúù kọ̀ọ̀kan ni kí ẹ pèsè ẹbọ ohun mímu pẹ̀lú ìdámẹ́ta nínú mẹ́wàá ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò; pẹ̀lú àgbò, ìdá méjì nínú mẹ́wàá; 21 pẹ̀lú ọ̀dọ́-àgùntàn kọ̀ọ̀kan ìdákan nínú mẹ́wàá. 22 Pẹ̀lú òbúkọ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣètùtù fún un yín. 23 Ṣe eléyìí ní àfikún sí ẹbọ sísun àràárọ̀. 24 Báyìí ní kí ẹ̀yin rúbọ ní ọjọọjọ́, jálẹ̀ ní ọjọ́ méjèèje, oúnjẹ ẹbọ tí a fi iná ṣe, tí olóòórùn dídùn sí OLÚWA; ó rú u pẹ̀lú ẹbọ sísun ìgbà gbogbo, àti ẹbọ ohun mímu. 25 Ní ọjọ́ keje kí ẹ̀yin kí ó ní àpéjọ mímọ́, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan. 26 “ ‘Ní ọjọ́ àkọ́so pẹ̀lú, nígbà tí ẹ̀yin bá mú ẹbọ ohun jíjẹ tuntun wá fún OLÚWA lẹ́yìn àsìkò àjọ̀dún, kí ẹ̀yin kí ó ní àpéjọ mímọ́, ẹ̀yin kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan. 27 Kí ẹ mú ẹbọ sísun ẹgbọrọ màlúù méjì, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn méje ọlọ́dún kan gẹ́gẹ́ bí òórùn dídùn fún OLÚWA. 28 Pẹ̀lú ọ̀kọ̀ọ̀kan akọ màlúù ní kí ẹ rú ẹbọ ohun mímu ìdámẹ́ta pẹ̀lú òsùwọ̀n ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò pẹ̀lú àgbò kan. 29 Àti pẹ̀lú ọ̀kọ̀ọ̀kan ọ̀dọ́-àgùntàn méje, kí ó jẹ́ ìdákan nínú mẹ́wàá. 30 Ẹ fi òbúkọ kan ṣe ètùtù fún ara yín. 31 Kí ẹ̀yin kí ó rú wọn pẹ̀lú ẹbọ sísun ìgbà gbogbo, àti ẹbọ ohun mímu yín àti ẹbọ ohun jíjẹ yín. Kí ẹ sì ri dájú pé àwọn ẹranko náà jẹ́ aláìlábùkù.
In Other Versions
Numbers 28 in the ANGEFD
Numbers 28 in the ANTPNG2D
Numbers 28 in the AS21
Numbers 28 in the BAGH
Numbers 28 in the BBPNG
Numbers 28 in the BBT1E
Numbers 28 in the BDS
Numbers 28 in the BEV
Numbers 28 in the BHAD
Numbers 28 in the BIB
Numbers 28 in the BLPT
Numbers 28 in the BNT
Numbers 28 in the BNTABOOT
Numbers 28 in the BNTLV
Numbers 28 in the BOATCB
Numbers 28 in the BOATCB2
Numbers 28 in the BOBCV
Numbers 28 in the BOCNT
Numbers 28 in the BOECS
Numbers 28 in the BOGWICC
Numbers 28 in the BOHCB
Numbers 28 in the BOHCV
Numbers 28 in the BOHLNT
Numbers 28 in the BOHNTLTAL
Numbers 28 in the BOICB
Numbers 28 in the BOILNTAP
Numbers 28 in the BOITCV
Numbers 28 in the BOKCV
Numbers 28 in the BOKCV2
Numbers 28 in the BOKHWOG
Numbers 28 in the BOKSSV
Numbers 28 in the BOLCB
Numbers 28 in the BOLCB2
Numbers 28 in the BOMCV
Numbers 28 in the BONAV
Numbers 28 in the BONCB
Numbers 28 in the BONLT
Numbers 28 in the BONUT2
Numbers 28 in the BOPLNT
Numbers 28 in the BOSCB
Numbers 28 in the BOSNC
Numbers 28 in the BOTLNT
Numbers 28 in the BOVCB
Numbers 28 in the BPBB
Numbers 28 in the BPH
Numbers 28 in the BSB
Numbers 28 in the CCB
Numbers 28 in the CUV
Numbers 28 in the CUVS
Numbers 28 in the DBT
Numbers 28 in the DGDNT
Numbers 28 in the DHNT
Numbers 28 in the DNT
Numbers 28 in the ELBE
Numbers 28 in the EMTV
Numbers 28 in the ESV
Numbers 28 in the FBV
Numbers 28 in the FEB
Numbers 28 in the GGMNT
Numbers 28 in the GNT
Numbers 28 in the HARY
Numbers 28 in the HNT
Numbers 28 in the IRVA
Numbers 28 in the IRVB
Numbers 28 in the IRVG
Numbers 28 in the IRVH
Numbers 28 in the IRVK
Numbers 28 in the IRVM
Numbers 28 in the IRVM2
Numbers 28 in the IRVO
Numbers 28 in the IRVP
Numbers 28 in the IRVT
Numbers 28 in the IRVT2
Numbers 28 in the IRVU
Numbers 28 in the ISVN
Numbers 28 in the JSNT
Numbers 28 in the KAPI
Numbers 28 in the KBT1ETNIK
Numbers 28 in the KBV
Numbers 28 in the KJV
Numbers 28 in the KNFD
Numbers 28 in the LBA
Numbers 28 in the LBLA
Numbers 28 in the LNT
Numbers 28 in the LSV
Numbers 28 in the MAAL
Numbers 28 in the MBV
Numbers 28 in the MBV2
Numbers 28 in the MHNT
Numbers 28 in the MKNFD
Numbers 28 in the MNG
Numbers 28 in the MNT
Numbers 28 in the MNT2
Numbers 28 in the MRS1T
Numbers 28 in the NAA
Numbers 28 in the NASB
Numbers 28 in the NBLA
Numbers 28 in the NBS
Numbers 28 in the NBVTP
Numbers 28 in the NET2
Numbers 28 in the NIV11
Numbers 28 in the NNT
Numbers 28 in the NNT2
Numbers 28 in the NNT3
Numbers 28 in the PDDPT
Numbers 28 in the PFNT
Numbers 28 in the RMNT
Numbers 28 in the SBIAS
Numbers 28 in the SBIBS
Numbers 28 in the SBIBS2
Numbers 28 in the SBICS
Numbers 28 in the SBIDS
Numbers 28 in the SBIGS
Numbers 28 in the SBIHS
Numbers 28 in the SBIIS
Numbers 28 in the SBIIS2
Numbers 28 in the SBIIS3
Numbers 28 in the SBIKS
Numbers 28 in the SBIKS2
Numbers 28 in the SBIMS
Numbers 28 in the SBIOS
Numbers 28 in the SBIPS
Numbers 28 in the SBISS
Numbers 28 in the SBITS
Numbers 28 in the SBITS2
Numbers 28 in the SBITS3
Numbers 28 in the SBITS4
Numbers 28 in the SBIUS
Numbers 28 in the SBIVS
Numbers 28 in the SBT
Numbers 28 in the SBT1E
Numbers 28 in the SCHL
Numbers 28 in the SNT
Numbers 28 in the SUSU
Numbers 28 in the SUSU2
Numbers 28 in the SYNO
Numbers 28 in the TBIAOTANT
Numbers 28 in the TBT1E
Numbers 28 in the TBT1E2
Numbers 28 in the TFTIP
Numbers 28 in the TFTU
Numbers 28 in the TGNTATF3T
Numbers 28 in the THAI
Numbers 28 in the TNFD
Numbers 28 in the TNT
Numbers 28 in the TNTIK
Numbers 28 in the TNTIL
Numbers 28 in the TNTIN
Numbers 28 in the TNTIP
Numbers 28 in the TNTIZ
Numbers 28 in the TOMA
Numbers 28 in the TTENT
Numbers 28 in the UBG
Numbers 28 in the UGV
Numbers 28 in the UGV2
Numbers 28 in the UGV3
Numbers 28 in the VBL
Numbers 28 in the VDCC
Numbers 28 in the YALU
Numbers 28 in the YAPE
Numbers 28 in the YBVTP
Numbers 28 in the ZBP