Psalms 138 (BOYCB)
undefined Ti Dafidi. 1 Èmi yóò yìn ọ́ tinútinú mi gbogbo;níwájú àwọn òrìṣà ni èmi ó kọrin ìyìn sí ọ. 2 Èmi ó máa gbàdúrà sí ìhà tẹmpili mímọ́ rẹ̀èmi ó sì máa yin orúkọ rẹnítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ àti òtítọ́ rẹ;nítorí ìwọ gbé ọ̀rọ̀ rẹ ga ju orúkọ rẹ lọ. 3 Ní ọjọ́ tí mo ké pè é ọ́, ìwọ dá mi lóhùn,ìwọ sì fi ipa mú mi lára le ní ọkàn mi. 4 Gbogbo àwọn ọba ayé yóò yìn ọ́, OLÚWA, ní ìgbà tí wọn bá gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ. 5 Nítòótọ́, wọn ó máa kọrin ní ipa ọ̀nà OLÚWA;nítorí pé ńlá ni ògo OLÚWA. 6 Bí OLÚWA tilẹ̀ ga, síbẹ̀ ó júbà àwọn onírẹ̀lẹ̀;ṣùgbọ́n agbéraga ni ó mọ̀ ní òkèrè réré. 7 Bí èmi tilẹ̀ ń rìn nínú ìpọ́njú ìwọ ni yóò sọ mi di ààyè;ìwọ ó na ọwọ́ rẹ sí àwọn ọ̀tá mi,ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò sì gbà mí. 8 OLÚWA yóò ṣe ohun tí ń ṣe tèmi láṣepé; OLÚWA, àánú rẹ dúró láéláé;má ṣe kọ iṣẹ́ ọwọ́ ara rẹ sílẹ̀.